Àkọsílẹ̀ Mátíù
27 Nígbà tó di àárọ̀, gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà àwọn èèyàn náà gbìmọ̀ pọ̀ kí wọ́n lè pa Jésù.+ 2 Lẹ́yìn tí wọ́n dè é, wọ́n mú un lọ, wọ́n sì fà á lé Pílátù lọ́wọ́, òun ni gómìnà.+
3 Nígbà tí Júdásì, ẹni tó dà á, rí i pé wọ́n ti dá Jésù lẹ́bi, ẹ̀dùn ọkàn bá a, ó sì kó ọgbọ̀n (30) ẹyọ fàdákà náà pa dà wá fún àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà,+ 4 ó sọ pé: “Mo dẹ́ṣẹ̀ nígbà tí mo fi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ lé yín lọ́wọ́.” Wọ́n sọ pé: “Kí ló kàn wá pẹ̀lú ìyẹn? Ìwọ ni kí o lọ wá nǹkan ṣe sí i!”* 5 Torí náà, ó da àwọn ẹyọ fàdákà náà sínú tẹ́ńpìlì, ó sì kúrò níbẹ̀. Ó wá lọ pokùn so.+ 6 Àmọ́ àwọn olórí àlùfáà kó àwọn ẹyọ fàdákà náà, wọ́n sì sọ pé: “Kò bófin mu ká kó o sí ibi ìṣúra mímọ́, torí pé owó ẹ̀jẹ̀ ni.” 7 Lẹ́yìn tí wọ́n gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n fi owó náà ra pápá amọ̀kòkò, kí wọ́n lè máa sin àwọn àjèjì síbẹ̀. 8 Torí náà, Pápá Ẹ̀jẹ̀+ ni wọ́n ń pe pápá náà títí dòní yìí. 9 Ìgbà yẹn ni ohun tí a sọ nípasẹ̀ wòlíì Jeremáyà ṣẹ pé: “Wọ́n kó ọgbọ̀n (30) ẹyọ fàdákà, iye owó tí wọ́n dá lé ọkùnrin náà, ẹni tí àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá iye owó kan lé, 10 wọ́n sì fi ra pápá amọ̀kòkò, gẹ́gẹ́ bí ohun tí Jèhófà* pa láṣẹ fún mi.”+
11 Jésù wá dúró níwájú gómìnà, gómìnà sì bi í pé: “Ṣé ìwọ ni Ọba Àwọn Júù?” Jésù fèsì pé: “Ìwọ fúnra rẹ ti sọ ọ́.”+ 12 Àmọ́ bí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà ṣe ń fẹ̀sùn kàn án, kò dáhùn.+ 13 Pílátù wá bi í pé: “Ṣé o ò gbọ́ bí ẹ̀rí tí wọ́n ń jẹ́ lòdì sí ọ ṣe pọ̀ tó ni?” 14 Àmọ́ kò dá a lóhùn, àní kò sọ nǹkan kan, débi pé ó ya gómìnà náà lẹ́nu gan-an.
15 Tí wọ́n bá ń ṣe àjọyọ̀, ó jẹ́ àṣà gómìnà láti tú ẹlẹ́wọ̀n kan sílẹ̀ fún àwọn èèyàn, ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá fẹ́.+ 16 Àkókò yẹn gan-an ni ẹlẹ́wọ̀n burúkú kan tó lókìkí wà ní àhámọ́ wọn, Bárábà lorúkọ rẹ̀. 17 Torí náà, nígbà tí wọ́n kóra jọ, Pílátù sọ fún wọn pé: “Ta lẹ fẹ́ kí n tú sílẹ̀ fún yín, ṣé Bárábà ni àbí Jésù tí wọ́n ń pè ní Kristi?” 18 Torí Pílátù mọ̀ pé wọ́n ń ṣe ìlara rẹ̀ ni wọ́n ṣe fà á lé òun lọ́wọ́. 19 Bákan náà, nígbà tó jókòó sórí ìjókòó ìdájọ́, ìyàwó rẹ̀ ránṣẹ́ sí i pé: “Má ṣe ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ọkùnrin olódodo yẹn, torí mo jìyà gan-an lójú àlá lónìí nítorí rẹ̀.” 20 Àmọ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà rọ àwọn èrò náà pé kí wọ́n sọ pé Bárábà ni àwọn fẹ́,+ àmọ́ kí wọ́n pa Jésù.+ 21 Gómìnà dá wọn lóhùn pé: “Èwo nínú àwọn méjèèjì lẹ fẹ́ kí n tú sílẹ̀ fún yín?” Wọ́n sọ pé: “Bárábà.” 22 Pílátù sọ fún wọn pé: “Kí wá ni kí n ṣe sí Jésù tí wọ́n ń pè ní Kristi?” Gbogbo wọ́n sọ pé: “Kàn án mọ́gi!”*+ 23 Ó sọ pé: “Kí ló dé? Nǹkan burúkú wo ló ṣe?” Síbẹ̀, wọ́n túbọ̀ ń kígbe ṣáá pé: “Kàn án mọ́gi!”+
24 Nígbà tó rí i pé òun ò rí nǹkan kan ṣe sí i, àmọ́ tí ariwo ń sọ, Pílátù bu omi, ó sì wẹ ọwọ́ rẹ̀ níwájú àwọn èrò náà, ó sọ pé: “Ọwọ́ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí. Ẹ̀yin fúnra yín ni kí ẹ lọ wá nǹkan ṣe sí i.” 25 Ni gbogbo àwọn èèyàn náà bá dá a lóhùn pé: “Kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sórí àwa àti àwọn ọmọ wa.”+ 26 Ó wá tú Bárábà sílẹ̀ fún wọn, àmọ́ ó ní kí wọ́n na Jésù,+ ó sì fà á lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè kàn án mọ́gi.+
27 Àwọn ọmọ ogun gómìnà wá mú Jésù wọnú ilé gómìnà, wọ́n sì kó gbogbo ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun jọ sọ́dọ̀ rẹ̀.+ 28 Wọ́n bọ́ aṣọ rẹ̀, wọ́n sì fi aṣọ ìlékè rírẹ̀dòdò kan bò ó lára,+ 29 wọ́n wá fi ẹ̀gún hun adé, wọ́n dé e sí i lórí, wọ́n sì fi ọ̀pá esùsú sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀. Wọ́n wá kúnlẹ̀ síwájú rẹ̀, wọ́n sì ń fi ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n ń sọ pé: “A kí ọ o,* ìwọ Ọba Àwọn Júù!” 30 Wọ́n tutọ́ sí i lára,+ wọ́n gba ọ̀pá esùsú náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbá a ní orí. 31 Níkẹyìn, lẹ́yìn tí wọ́n fi ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n bọ́ aṣọ ìlékè náà kúrò lára rẹ̀, wọ́n wá wọ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ fún un, wọ́n sì mú un lọ kí wọ́n lè kàn án mọ́gi.+
32 Bí wọ́n ṣe ń jáde lọ, wọ́n rí ọkùnrin ará Kírénè kan tó ń jẹ́ Símónì. Wọ́n fi dandan mú ọkùnrin yìí pé kó gbé òpó igi oró* rẹ̀.+ 33 Nígbà tí wọ́n dé ibì kan tí wọ́n ń pè ní Gọ́gọ́tà, ìyẹn Ibi Agbárí,+ 34 wọ́n fún un ní wáìnì tí wọ́n pò mọ́ òróòro* mu;+ àmọ́ nígbà tó tọ́ ọ wò, ó kọ̀ láti mu ún. 35 Lẹ́yìn tí wọ́n kàn án mọ́gi, wọ́n fi kèké pín aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀,+ 36 wọ́n sì jókòó síbẹ̀, wọ́n ń ṣọ́ ọ. 37 Wọ́n tún gbé àkọlé sókè orí rẹ̀, tí wọ́n kọ ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án sí, pé: “Jésù Ọba Àwọn Júù nìyí.”+
38 Wọ́n wá kan àwọn olè méjì mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ọ̀kan ní ọ̀tún rẹ̀ àti ọ̀kan ní òsì rẹ̀.+ 39 Àwọn tó ń kọjá lọ ń bú u,+ wọ́n sì ń mi orí wọn,+ 40 wọ́n ń sọ pé: “Ìwọ tí o fẹ́ wó tẹ́ńpìlì palẹ̀, kí o sì fi ọjọ́ mẹ́ta kọ́ ọ,+ gba ara rẹ là! Tó bá jẹ́ pé ọmọ Ọlọ́run ni ọ́, sọ̀ kalẹ̀ lórí òpó igi oró!”*+ 41 Bákan náà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin pẹ̀lú àwọn àgbààgbà bẹ̀rẹ̀ sí í fi ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n ń sọ pé:+ 42 “Ó gba àwọn ẹlòmíì là; kò lè gba ara rẹ̀ là! Òun ni Ọba Ísírẹ́lì;+ kó sọ̀ kalẹ̀ báyìí látorí òpó igi oró,* a sì máa gbà á gbọ́. 43 Ó ti gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run; kí Ó gbà á sílẹ̀ báyìí tí Ó bá fẹ́ ẹ,+ torí ó sọ pé, ‘Ọmọ Ọlọ́run ni mí.’”+ 44 Bákan náà, àwọn olè tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ pàápàá ń fi ṣe ẹlẹ́yà.+
45 Láti wákàtí kẹfà* lọ, òkùnkùn ṣú bo gbogbo ilẹ̀ náà, títí di wákàtí kẹsàn-án.*+ 46 Ní nǹkan bíi wákàtí kẹsàn-án, Jésù ké jáde pé: “Élì, Élì, làmá sàbákìtanì?” tó túmọ̀ sí, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?”+ 47 Nígbà tí àwọn kan lára àwọn tó dúró síbẹ̀ gbọ́ èyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Ọkùnrin yìí ń pe Èlíjà.”+ 48 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọ̀kan lára wọn sáré lọ mú kànrìnkàn, ó sì rẹ ẹ́ sínú wáìnì kíkan, ó wá fi sórí ọ̀pá esùsú, ó sì fún un pé kó mu ún.+ 49 Àmọ́ àwọn yòókù sọ pé: “Ẹ fi sílẹ̀! Ká wò ó bóyá Èlíjà máa wá gbà á là.” 50 Jésù tún ké jáde, ó sì jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀.*+
51 Wò ó! aṣọ ìdábùú ibi mímọ́+ ya sí méjì,+ látòkè dé ìsàlẹ̀,+ ilẹ̀ mì tìtì, àwọn àpáta sì là. 52 Àwọn ibojì* ṣí, ọ̀pọ̀ òkú àwọn ẹni mímọ́ tó ti sùn la sì gbé dìde, 53 (àwọn èèyàn tó ń jáde bọ̀ láti àárín àwọn ibojì lẹ́yìn tí a gbé e dìde wọnú ìlú mímọ́ náà), ọ̀pọ̀ èèyàn sì rí wọn. 54 Àmọ́ nígbà tí ọ̀gágun àti àwọn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ tí wọ́n ń ṣọ́ Jésù rí bí ilẹ̀ ṣe mì tìtì àtàwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, wọ́n sì sọ pé: “Ó dájú pé Ọmọ Ọlọ́run nìyí.”+
55 Ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin wà níbẹ̀ tí wọ́n ń wòran láti ọ̀ọ́kán, àwọn tó tẹ̀ lé Jésù wá láti Gálílì kí wọ́n lè ṣe ìránṣẹ́ fún un;+ 56 lára wọn ni Màríà Magidalénì, Màríà ìyá Jémíìsì àti Jósè àti ìyá àwọn ọmọ Sébédè.+
57 Bó ṣe ń di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tó jẹ́ ará Arimatíà dé, Jósẹ́fù lorúkọ rẹ̀, òun náà ti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù.+ 58 Ọkùnrin yìí lọ bá Pílátù, ó sì ní kó gbé òkú Jésù fún òun.+ Pílátù wá pàṣẹ pé kí wọ́n gbé e fún un.+ 59 Jósẹ́fù gbé òkú náà, ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀* tó dáa, tó sì mọ́ dì í,+ 60 ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì* rẹ̀ tuntun,+ èyí tó ti gbẹ́ sínú àpáta. Lẹ́yìn tó yí òkúta ńlá sí ẹnu ọ̀nà ibojì* náà, ó kúrò níbẹ̀. 61 Àmọ́ Màríà Magidalénì àti Màríà kejì ò kúrò níbẹ̀, wọ́n jókòó síwájú sàréè náà.+
62 Lọ́jọ́ kejì, lẹ́yìn Ìpalẹ̀mọ́,+ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí kóra jọ síwájú Pílátù, 63 wọ́n sọ pé: “Ọ̀gá, a rántí ohun tí afàwọ̀rajà yẹn sọ nígbà tó ṣì wà láàyè, pé, ‘Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, a máa jí mi dìde.’+ 64 Torí náà, pàṣẹ kí wọ́n sé sàréè náà mọ́ títí di ọjọ́ kẹta, kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ má bàa wá jí i gbé,+ kí wọ́n sì sọ fún àwọn èèyàn pé, ‘A ti jí i dìde!’ Ẹ̀tàn tó gbẹ̀yìn yìí máa wá burú ju ti àkọ́kọ́ lọ.” 65 Pílátù sọ fún wọn pé: “Ẹ mú ẹ̀ṣọ́. Ẹ lọ sé ibẹ̀ mọ́ bí ẹ bá ṣe lè ṣe é.” 66 Torí náà, wọ́n lọ sé sàréè náà mọ́, wọ́n gbé èdìdì lé òkúta náà, wọ́n sì fi ẹ̀ṣọ́ síbẹ̀.