Aṣọ Ìsìnkú Turin—Aṣọ Ìsìnkú Jésù Ni Bí?
LÁTI ỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ NÍ ÍTÁLÌ
Aṣọ ìsìnkú, tàbí aṣọ tí a sọ pé wọ́n fi di òkú Jésù ti Násárẹ́tì ni wọ́n tẹ́ fádà rẹ sí Ṣọ́ọ̀ṣì San Giovanni Battista, Turin, ní Ítálì láti April 18 sí June 14, 1998. Wọ́n gbé e sínú àpótí onídígí kan tí a fẹ́ gáàsì tí kò lágbára sí nínú, tí afẹ́fẹ́ tàbí ọta ìbọn kò sì lè wọ inú rẹ̀. Wọ́n sì pa á mọ́ síbẹ̀ lábẹ́ ipò ojú ọjọ́ tí kì í yí padà.
ÀWỌN olùṣèbẹ̀wò ń kọjá níwájú aṣọ ìsìnkú tí a dáàbò bò dáradára náà bí wọ́n ti tò sórí pèpéle mẹ́ta tí kò ga dọ́gba. Èyí mú kí gbogbo wọn lè rí i dáadáa. Ìṣẹ́jú méjì péré ni a gbà wọ́n láyè láti lò, wọn sì ti gbọ́dọ̀ sọ tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó wá. Ìmọ̀lára àwọn ènìyàn náà yàtọ̀ síra, ẹlòmíràn ń yọ ayọ̀ àyọ̀jù, àwọn mìíràn ń ronú jinlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kan ń ṣe ojú-mìí-tó bí aláìmọ̀kan. A gbọ́ pé àwọn tí ó ṣe ìbẹ̀wò síbẹ̀ tó nǹkan bí mílíọ̀nù méjì ààbọ̀.
“Kí ni aṣọ ìsìnkú náà túmọ̀ sí fún ọ?” ni ìbéèrè tí a sábà ń béèrè. Àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ yìí fún ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ láti máa jíròrò nípa ìsìn láǹfààní láti túbọ̀ yẹ ọ̀rọ̀ náà wò, kí wọ́n sì tún àwọn ojú ewé tí ó sọ̀rọ̀ nípa ìsìnkú Jésù kà dáadáa nínú Bíbélì.—Wo àpótí tí ó wà ní ojú ewé tí ó tẹ̀ lé èyí.
Aṣọ ìsìnkú náà jẹ́ aṣọ ọ̀gbọ̀ kan tí gígùn rẹ̀ jẹ́ irínwó lé mẹ́rìndínlógójì [436] sẹ̀ǹtímítà, tí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ àádọ́fà sẹ̀ǹtímítà, tí ayédèrú àmì ara ọkùnrin kan tí a sọ pé ó kú ikú oró wà lára rẹ̀. Àmọ́ ìbéèrè náà ni pé, Ǹjẹ́ Aṣọ Ìsìnkú Turin yìí ni a fi wé òkú Jésù ní ohun tí ó lé ní ọ̀rúndún mọ́kàndínlógún sẹ́yìn?
Ohun Tí Ìtàn Sọ
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia sọ pé: “Kò sí ẹ̀rí pé aṣọ ìsìnkú kan wà ní ọ̀rúndún kìíní ti sànmánì Kristẹni.” Ní ọdún 544 Sànmánì Tiwa, àwòrán àgbàyanu kan tí gbogbo ènìyàn gbà gbọ́ pé a kò fọwọ́ yà fara hàn ní Edessa, tí ó jẹ́ apá ibì kan ní Turkey òde òní. Àwòrán náà ni a sọ pé ó fi ojú Jésù hàn. Wọ́n sọ pé àwòrán náà tún wà ní Constantinople ní ọdún 944 Sànmánì Tiwa. Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ òpìtàn ni kò gbà gbọ́ pé àwòrán yìí ni ohun tí a wá mọ̀ sí Aṣọ Ìsìnkú Turin nísinsìnyí.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹrìnlá, Geoffroi de Charny ní aṣọ ìsìnkú kan ní ilẹ̀ Faransé. Ní 1453, ó di ti Louis, Ọba Savoy, ẹni tí ó gbé e ránṣẹ́ sí Ṣọ́ọ̀ṣì kan ní Chambéry, olú ìlú Savoyard. Láti ibẹ̀ ni Emmanuel Philibert ti gbé e lọ sí Turin ni 1578.
Onírúurú Èrò
Ní 1988, Anastasio Ballestrero, bíṣọ́ọ̀bù àgbà ti Turin nígbà náà, ní kí a fi èròjà carbon yẹ bí Aṣọ Ìsìnkú Turin náà ṣe lọ́jọ́ lórí tó wò. Àwọn àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe ní ibi ìwádìí ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ mẹ́ta tí ó gbayì gidigidi ní Switzerland, England, àti United States, fi hàn pé ó jẹ́ ti sànmánì agbedeméjì, ìyẹn sì jẹ́ àkókò kan tí ó pẹ́ gan-an lẹ́yìn ikú Kristi. Ballestrero fara mọ́ ìpinnu náà, nípa pípolongo nínú ọ̀rọ̀ kan tí a fàṣẹ sí pé: “Ní fífa àyẹ̀wò àwọn èsì wọ̀nyí lé sáyẹ́ǹsì lọ́wọ́, ńṣe ni ṣọ́ọ̀ṣì náà ń lọ́ra láti fọ̀wọ̀ àti ìjúbà rẹ̀ fún ère Kristi yìí, tí ó sì jẹ́ ohun ìfọkànsìn fún àwọn onígbàgbọ́.”
Giovanni Saldarini tó jẹ́ bíṣọ́ọ̀bù àgbà báyìí, sọ pé: “A kò lè sọ pé ère náà jẹ́ ti Kristi tí a gbé kúrò lórí àgbélébùú.” Síbẹ̀, ó tún sọ pé: “Kò sí àní-àní pé àwọn onígbàgbọ́ lè rí àwòrán ọkùnrin tí a ṣàpèjúwe nínú Ìhìn Rere nínú àmì yẹn.” Nígbà tí a tẹ́ fádà aṣọ ìsìnkú náà ní May 24, 1998, Póòpù John Paul Kejì pe ère náà ní “àmì tí ara ìdálóró Ẹni Tí A Kàn Mọ́ Àgbélébùú náà fi sílẹ̀.”
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i, ẹ̀rí gidi wà pé Aṣọ Ìsìnkú Turin kì í ṣe aṣọ ìsìnkú Jésù. Àmọ́, bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ bẹ́ẹ̀ ńkọ́? Ǹjẹ́ yóò bójú mu kí ẹnì kan tí ó fẹ́ ṣègbọràn sí ẹ̀kọ́ Bíbélì máa jọ́sìn aṣọ yẹn?
Ṣàgbéyẹ̀wò èkejì nínú Òfin Mẹ́wàá, tí ó sọ ní ìbámu pẹ̀lú ìtumọ̀ Bíbélì ti Roman Kátólíìkì kan pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ère gbígbẹ́ kan fún ara rẹ tàbí àwòrán ohunkóhun ní ọ̀run lókè tàbí lórí ilẹ̀ ayé ní ìsàlẹ̀ tàbí nínú omi lábẹ́ ilẹ̀ ayé. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹríba fún wọn.” (Ẹ́kísódù 20:4, 5, New Jerusalem Bible) Láìsí àní-àní, àwọn Kristẹni tòótọ́ ń ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni àwa ń rìn, kìí ṣe nípa ohun tí a rí.”—2 Kọ́ríńtì 5:7; 1 Jòhánù 5:21.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]
Aṣọ Ìsìnkú Náà àti Àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere
Àwọn òǹkọ̀wé Ìhìn Rere náà sọ pé, lẹ́yìn tí Jósẹ́fù ará Arimatíà gbé òkú Jésù kúrò lórí igi, ó fi “aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà tí ó mọ́” dì í. (Mátíù 27:57-61; Máàkù 15:42-47; Lúùkù 23:50-56) Àpọ́sítélì Jòhánù fi kún un pé: “Nikodémù pẹ̀lú . . . mú àdìpọ̀ òjíá àti àwọn álóè wá, nǹkan bí ọgọ́rùn ún ìwọ̀n pọ́n-ùn. Nítorí náà, wọ́n gbé òkú Jésù, wọ́n sì fi àwọn ọ̀já ìdìkú dì í pẹ̀lú àwọn èròjà atasánsán náà gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn Júù ti ní àṣà mímúra sílẹ̀ fún ìsìnkú.”—Jòhánù 19:39-42.
Ó jẹ́ àṣà àwọn Júù láti wẹ̀ fún òkú, kí wọ́n wá fi òróró àti èròjà atasánsán pa ara òkú náà lẹ́yìn náà. (Mátíù 26:12; Ìṣe 9:37) Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì Sábáàtì, àwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù gbèrò láti lọ parí ìmúra fún òkú rẹ̀ tí a ti tẹ́ sínú ibojì. Àmọ́, nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀ pẹ̀lú ‘èròjà atasánsán’ wọn ‘láti fi pa á lára,’ òkú Jésù kò mà sí nínú ibojì náà mọ́ o!—Máàkù 16:1-6; Lúùkù 24:1-3.
Kí ni Pétérù rí nígbà tí ó dé ibẹ̀ kété lẹ́yìn náà, tí ó sì wọ inú ibojì náà? Jòhánù tó fojú rí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ròyìn pé: “Ó sì rí àwọn ọ̀já ìdìkú náà nílẹ̀, pẹ̀lúpẹ̀lù, aṣọ tí ó wà ní orí rẹ̀ kò sí nílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀já ìdìkú náà ṣùgbọ́n a ká a jọ sọ́tọ̀ ní ibì kan.” (Jòhánù 20:6, 7) Ṣàkíyèsí pé a kò mẹ́nu kan aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára—àyàfi ọ̀já ìdìkú àti aṣọ tí a fi di orí nìkan. Níwọ̀n bí Jòhánù ti dárúkọ ọ̀já ìdìkú àti aṣọ tí a fi di orí ní pàtó, ǹjẹ́ kò dàbí ẹni pé òun ì bá ti mẹ́nu kan aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára, tàbí aṣọ ìsìnkú náà bí ó bá jẹ́ pé ó wà níbẹ̀?
Láfikún sí i, rò ó wò ná: Ká ní àwọn aṣọ inú ibojì Jésù ní àwòrán rẹ̀ lára ni, ǹjẹ́ kò dà bí ẹni pé wọn ì bá ti rí i tí ì bá sì ti di ohun tí a ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Àmọ́ yàtọ̀ sí ohun tí ó wà nínú Ìhìn Rere, Bíbélì kò sọ ohunkóhun nípa àwọn aṣọ inú ibojì náà.
Kódà àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni tí wọ́n jẹ́ òǹkọ̀wé ní ọ̀rúndún kẹta àti ìkẹrin, tí ọ̀pọ̀ nínú wọn kọ àìmọye ohun tí wọ́n pè ní iṣẹ́ ìyanu tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ohun ìránnilétí àwọn ẹni mímọ́, kò mẹ́nu kàn án pé aṣọ ìsìnkú kan tí ó ní àwòrán Jésù lára ń bẹ. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Jesuit náà, Herbert Thurston, sọ pé, èyí kò yéni, níwọ̀n bí àwọn òǹwòran ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún àti ti ìkẹrìndínlógún ti “ṣàpèjúwe àwọn àmì tí ó wà lára aṣọ ìsìnkú náà àti àwọn àwọ̀ tí a lò kínníkínní gan-an tí ó fi dà bí ẹni pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe é ni.”
[Credit Line]
David Lees/©Corbis