Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Òǹkàwé
Matteu 28:17 ha tumọsi pe diẹ lara awọn aposteli ń baa lọ lati ṣe iyemeji tipẹtipẹ lẹhin ti Jesu ti a jí dide ti farahan fun wọn bi?
Bẹẹkọ, a kò nilati dé ori ipari-ero yẹn lati inu Matteu 28:16, 17, ti ó kà pe: “Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mọkanla jade lọ si Galili, si ori oke ti Jesu ti sọ fun wọn. Nigba ti wọn sì rí i, wọn foribalẹ fun un: ṣugbọn awọn miiran ṣiyemeji.”
Tipẹtipẹ ṣaaju ni Jesu ti gbiyanju lati ran awọn ọmọ-ẹhin lọwọ lati mọ “bi oun kò ti lè ṣailọ si Jerusalemu, lati jẹ ọpọ ìyà lọwọ awọn agbaagba ati awọn olori alufaa, ati awọn akọwe, ki a sì pa oun, ati ni ijọ kẹta, ki ó sì jinde.” (Matteu 16:21) Laika eyi si, ifofinde ati iṣekupa rẹ̀ fi awọn ọmọ-ẹhin sinu idarudapọ ati ijakulẹ. Ajinde rẹ̀ jọ bii pe ó wá gẹgẹ bi iyalẹnu kan. Nigba ti ó sì fi araarẹ̀ hàn ni iri eniyan, lakọọkọ awọn kan “kò sì tíì gbagbọ fun ayọ.” (Luku 24:36-41) Bi o ti wu ki o ri, awọn ifarahan rẹ̀ lẹhin ajinde ran awọn ọmọlẹhin rẹ̀ timọtimọ lọwọ lati tẹwọgba otitọ ajinde rẹ̀; koda aposteli Tomasi ni ó daloju pe Jesu ti jinde.—Johannu 20:24-29.
Lẹhin eyi awọn aposteli 11 aduroṣinṣin naa “jade lọ si Galili.” (Matteu 28:16; Johannu 21:1) Nigba ti wọn wà nibẹ, Jesu “farahan awọn ará ti ó ju ẹẹdẹgbẹta lọ lẹẹkan naa.” (1 Korinti 15:6) Ó jẹ́ ninu igbekalẹ yii ni Matteu 28:17 ti mẹnukan an pe “awọn miiran ṣiyemeji.” Nitori naa awọn ti ń ṣiyemeji sibẹ dajudaju nilati jẹ́ lara awọn 500 ọmọlẹhin naa.
Ṣakiyesi àlàyé arunilọkansoke ti C. T. Russell, ààrẹ akọkọ ti Watch Tower Society, ṣe lori eyi:
“Awọn wọnni ti wọn ń ṣiyemeji ni a kò lè sọ lọna ti ó bá ọgbọ́n mu pe wọn jẹ́ lara awọn aposteli mọkanla naa, nitori pe ó tẹ́ wọn lọ́rùn daradara, ó dá wọn lójú gidi gan-an, wọn sì ti ṣalaye araawọn bẹẹ ni iṣaaju. Awọn ti wọn ṣiyemeji, gẹgẹ bi a ṣe rò, gbọdọ jẹ́ lara ‘awọn ará ti ó ju ẹẹdẹgbẹta lọ’ naa ti wọn pésẹ̀ sibi ipade ti a ṣeto yii, awọn ti wọn kò ni ibaṣepọ timọtimọ eyikeyii pẹlu rẹ̀ lati ìgbà ajinde rẹ̀, awọn ti, a lè sọ lọna ti ó bá ọgbọ́n mu pe, lara wọn jẹ́ alailera ni igbagbọ ju awọn aposteli ati awọn ọ̀rẹ́ akanṣe ti Jesu bá sọrọ lẹhin ajinde rẹ̀ lọ. Ọ̀rọ̀ naa pe ‘awọn miiran ṣiyemeji’ jẹ́ ẹ̀rí otitọ akọsilẹ Ajihinrere naa. Ó fihàn wá, pẹlu, pe awọn ọmọlẹhin Oluwa kìí ṣe ayára gbagbọ laiwadii, ṣugbọn kaka bẹẹ wọn nitẹsi lati yẹ awọn ẹ̀rí ti a gbekalẹ wò kínníkínní ki wọn sì gbé wọn ka ori ìwọ̀n, itara, okun-inu ati ẹmi ìfara-ẹni-rúbọ ti ó tẹle e lati ọ̀dọ̀ awọn wọnni ti ó gbagbọ sì fun wa ni ọpọlọpọ ẹ̀rí nipa idaniloju atọkanwa wọn nipa ajinde Oluwa wa, eyi ti awọn ati awa pẹlu mọ̀ gẹgẹ bi ohun kan ti igbagbọ wa ninu rẹ̀ sinmi lé. Bi a kò bá jí Kristi dide, asan ni igbagbọ wa a sì wà ninu ẹṣẹ wa sibẹ.—1 Kor. 15:17.”—Zion’s Watch Tower and Herald of Christ’s Presence, May 1, 1901, oju-iwe 152.
A lè kiyesi ní afikun diẹ pe ọ̀nà ti Matteu gbà mẹnukan kókó yii pese ẹ̀rí iṣeegbarale ati ailabosi Bibeli fun wa. Bi eniyan kan bá ń hùmọ̀ irohin kan, oun yoo ni ìtẹ̀sí lati pese awọn kulẹkulẹ ti yoo mú ki ìtàn ti ó hùmọ̀ dabi eyi ti ó ṣeegbagbọ; ó ṣeeṣe ki oun nimọlara pe awọn kulẹkulẹ ti a gbójúfòdá tabi awọn alafo ti ó dabi eyi ti ó wà yoo mú iyemeji wá nipa ìhùmọ̀ rẹ̀. Ki ni nipa ti Matteu?
Oun kò nimọlara dandangbọ̀n lati pese alaye kulẹkulẹ lori ọ̀rọ̀ rẹ̀ naa pe “awọn miiran ṣiyemeji.” Awọn irohin Marku, Luku, ati Johannu kò sì sọ ohunkohun nipa eyi, nitori naa bi a bá lọ nipa ọ̀rọ̀ Matteu nikanṣoṣo ó lè jọbi pe ó kó bá awọn aposteli 11 naa, eyi ti oun jẹ́ ọ̀kan lara wọn. Bi o ti wu ki o ri, Matteu ṣalaye ranpẹ naa laipese imuṣekedere eyikeyii. Ni nǹkan bii oḍun 14 lẹhin naa, aposteli Paulu kọ iwe Korinti Kìn-ín-ní. Loju-iwoye kulẹkulẹ ti ó pese ni 1 Korinti 15:6, a lè dori ipari èrò tí ó ṣeeṣe naa pe awọn ti ó ṣiyemeji kìí ṣe awọn aposteli ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin ni Galili ti Jesu kò tíì farahan fun sibẹ. Nipa bayii, alaye Matteu pe “awọn miiran ṣiyemeji” dún bi otitọ; lọna ti ó tọna ó ni èrò akọwe alailabosi kan ti o gbé irohin otitọ kan kalẹ laigbiyanju lati ṣalaye gbogbo kulẹkulẹ.