ORÍ 137
Ọ̀pọ̀ Èèyàn Ló Rí Jésù Ṣáájú Ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì
MÁTÍÙ 28:16-20 LÚÙKÙ 24:50-52 ÌṢE 1:1-12; 2:1-4
JÉSÙ FARA HAN Ọ̀PỌ̀LỌPỌ̀ ÈÈYÀN
JÉSÙ GÒKÈ LỌ SỌ́RUN
JÉSÙ TÚ Ẹ̀MÍ MÍMỌ́ JÁDE SÓRÍ ỌGỌ́FÀ (120) ỌMỌ Ẹ̀YÌN
Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó ṣètò bí òun àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ́kànlá ṣe máa pàdé lórí òkè kan ní Gálílì. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn míì náà wà níbẹ̀, gbogbo àwọn tó kóra jọ sì tó nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500). Ọ̀pọ̀ lára wọn ló ti ń ṣiyèméjì tẹ́lẹ̀. (Mátíù 28:17; 1 Kọ́ríńtì 15:6) Àmọ́, ohun tí Jésù sọ nígbà tí wọ́n débẹ̀ jẹ́ kí wọ́n gbà pé òótọ́ ni Jésù ti jíǹde.
Jésù ṣàlàyé fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé Ọlọ́run ti fún òun ní gbogbo àṣẹ lọ́run àti láyé. Ó ní: “Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn pé kí wọ́n máa pa gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:18-20) Kì í ṣe pé Jésù jíǹde nìkan ni, ó tún wù ú kàwọn èèyàn gbọ́ nípa ìhìn rere.
Gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù lọ́kùnrin, lóbìnrin, lọ́mọdé àti lágbà ni Jésù sọ fún pé kí wọ́n máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Àwọn alátakò lè fẹ́ dá iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni yẹn dúró, àmọ́ Jésù jẹ́ kó dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lójú pé: “Gbogbo àṣẹ ní ọ̀run àti ayé la ti fún mi.” Kí nìyẹn túmọ̀ sí fáwọn ọmọlẹ́yìn Jésù? Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ wò ó! Mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” Jésù ò sọ pé gbogbo àwọn tó bá ń wàásù ìhìn rere náà máa lágbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu. Àmọ́, ẹ̀mí Ọlọ́run máa ràn wọ́n lọ́wọ́.
Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ “jálẹ̀ ogójì (40) ọjọ́” lẹ́yìn tó jíǹde. Onírúurú ọ̀nà ló gbà “fara hàn wọ́n láàyè nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ ẹ̀rí tó dájú,” kó lè kọ́ wọn “nípa Ìjọba Ọlọ́run.”—Ìṣe 1:3; 1 Kọ́ríńtì 15:7.
Ó dájú pé Gálílì làwọn àpọ́sítélì yẹn wà nígbà tí Jésù sọ fún wọn pé kí wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí Jésù wá ń ṣèpàdé pẹ̀lú wọn ní Jerúsálẹ́mù, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe kúrò ní Jerúsálẹ́mù, àmọ́ ẹ dúró de ohun tí Baba ti ṣèlérí, èyí tí ẹ gbọ́ lẹ́nu mi; lóòótọ́, Jòhánù fi omi batisí, àmọ́ a ó fi ẹ̀mí mímọ́ batisí yín láìpẹ́ ọjọ́.”—Ìṣe 1:4, 5.
Láìpẹ́ sígbà yẹn, Jésù tún ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Wọ́n tẹ̀ lé e “jáde títí dé Bẹ́tánì” tó wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ìlà oòrùn Òkè Ólífì. (Lúùkù 24:50) Léraléra ni Jésù ti sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn yìí pé òun máa pa dà lọ sọ́dọ̀ Baba, síbẹ̀ èrò wọn ni pé ayé yìí ni Ìjọba rẹ máa wà.—Lúùkù 22:16, 18, 30; Jòhánù 14:2, 3.
Torí náà, àwọn àpọ́sítélì bi Jésù pé: “Olúwa, ṣé àkókò yìí lo máa dá ìjọba pa dà fún Ísírẹ́lì?” Jésù wá fèsì pé: “Kì í ṣe tiyín láti mọ ìgbà tàbí àsìkò tí Baba ti fi sí ìkáwọ́ rẹ̀.” Lẹ́yìn náà, Jésù tẹnu mọ́ iṣẹ́ tó yẹ kí wọ́n gbájú mọ́, ó ní: “Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù, ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.”—Ìṣe 1:6-8.
Orí Òkè Ólífì yẹn ni Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ wà, bí Jésù ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í gòkè lọ sọ́run nìyẹn. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó wọnú àwọsánmà, wọn ò sì rí i mọ́. Onírúurú ọ̀nà ni Jésù ti gbà fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́yìn tó jíǹde. Àmọ́ ní báyìí, ó bọ́ ara èèyàn sílẹ̀, ó sì para dà di ẹni ẹ̀mí kó lè pa dà sí ọ̀run. (1 Kọ́ríńtì 15:44, 50; 1 Pétérù 3:18) Nígbà táwọn àpọ́sítélì olóòótọ́ yẹn tẹjú mọ́ Jésù bó ṣe ń lọ sọ́run, wọ́n rí àwọn “ọkùnrin méjì tó wọ aṣọ funfun” tí wọ́n dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. Áńgẹ́lì làwọn ọkùnrin yẹn, wọ́n ti gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀, wọ́n bi àwọn àpọ́sítélì náà pé: “Ẹ̀yin èèyàn Gálílì, kí ló dé tí ẹ dúró tí ẹ̀ ń wojú sánmà? Jésù yìí tí a gbà sókè kúrò lọ́dọ̀ yín sínú sánmà yóò wá ní irú ọ̀nà kan náà bí ẹ ṣe rí i tó ń lọ sínú sánmà.”—Ìṣe 1:10, 11.
Ọ̀nà tí kò la ariwo lọ ni Jésù gbà kúrò láyé, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ olóòótọ́ nìkan ló rí i. “Irú ọ̀nà kan náà” ló máa gbà pa dà, ìwọ̀nba àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́ nìkan ló máa fòye mọ̀ pé ó ti gba agbára Ìjọba rẹ̀.
Lẹ́yìn náà, àwọn àpọ́sítélì pa dà sí Jerúsálẹ́mù. Láwọn ọjọ́ bíi mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn, àwọn àpọ́sítélì yìí wà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù, títí kan “Màríà ìyá Jésù àti àwọn arákùnrin rẹ̀.” (Ìṣe 1:14) Àwọn èèyàn náà tẹra mọ́ àdúrà. Ọ̀kan lára ohun tí wọ́n gbàdúrà nípa rẹ̀ ni bí wọ́n ṣe máa yan ẹni táá rọ́pò Júdásì Ìsìkáríọ́tù, káwọn àpọ́sítélì lè pa dà pé méjìlá. (Mátíù 19:28) Wọ́n fẹ́ kí ọmọ ẹ̀yìn yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ti máa ń wà pẹ̀lú Jésù, tó sì wà níbẹ̀ nígbà tí Jésù jíǹde. Torí náà wọ́n ṣẹ́ kèké láti yan ẹni náà, ìyẹn sì ni ìgbà tí Bíbélì sọ pé àwọn èèyàn ṣẹ́ kèké kẹ́yìn láti mọ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run. (Sáàmù 109:8; Òwe 16:33) Màtáyásì ni kèké náà mú, ó ṣeé ṣe kó wà lára àwọn àádọ́rin (70) tí Jésù rán jáde láti lọ wàásù, wọ́n sì “kà á mọ́ àwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá.”—Ìṣe 1:26.
Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́wàá tí Jésù gòkè lọ sọ́run, àwọn Júù ṣe Àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 S.K. Nǹkan bí ọgọ́fà (120) ọmọ ẹ̀yìn kóra jọ sínú yàrá òkè kan ní Jerúsálẹ́mù. Lójijì, ariwo kan bíi ti atẹ́gùn líle tó ń rọ́ yìì kún gbogbo inú ilé tí wọ́n wà. Wọ́n rí iná tó dà bí ahọ́n, ó sì bà lé ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ oríṣiríṣi èdè. Ẹ̀mí mímọ́ yìí ni Jésù ṣèlérí pé Ọlọ́run máa rán sí wọn láti ràn wọ́n lọ́wọ́.—Jòhánù 14:26.