Ṣó O Lóye Àwọn Àfiwé Ọ̀rọ̀ Tó Wà Nínú Bíbélì?
ÀLÀYÉ sábà máa ń pọ̀ nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà tá a bá lo àfiwé, ṣókí lọ̀rọ̀ máa ń mọ, ó sì máa ń nítumọ̀. Onírúurú àfiwé àtàwọn ọ̀rọ̀ míì tó máa ń jẹ́ kẹ́ni tó bá gbọ́rọ̀ fọkàn yàwòrán bí nǹkan ṣe rí ló wà nínú Bíbélì.a Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ní ká fojú bù ú, ó ju àádọ́ta [50] ìgbà lọ tí Jésù lo àfiwé nínú ìwàásù tó ṣe lórí òkè.
Kí nìdí tó fi yẹ kó o nífẹ̀ẹ́ sáwọn àfiwé ọ̀rọ̀ wọ̀nyí? Ìdí kan ni pé, ó máa jẹ́ kó o túbọ̀ gbádùn kíka Bíbélì, wàá túbọ̀ lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wàá sì túbọ̀ mọyì rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, tó o bá mọ àfiwé ọ̀rọ̀ dáadáa, wàá lóye àwọn ìsọfúnni tó wà nínú Bíbélì lọ́nà tó péye. Ká sòótọ́, téèyàn ò bá lóye àfiwé ọ̀rọ̀ kan nínú Bíbélì dáadáa, ó lè mú kọ́rọ̀ náà dojú rú, ó sì lè mú kéèyàn lóye ọ̀rọ̀ ọ̀hún sódì.
Bó O Ṣe Lè Lóye Àwọn Àfiwé Ọ̀rọ̀
Àfiwé sábà máa ń fi èrò kan wé òmíràn. Èrò tá a fi ń wéra là ń pè ní kókó ọ̀rọ̀, ohun tá à ń fi èrò náà wé la mọ̀ sí àwòrán, àbájáde ìfiwéra náà ni ibi tọ́rọ̀ ti jọra. Ó ṣe pàtàkì nígbà náà pé ká lóye, ká sì mọ ìtúmọ̀ àwọn kókó mẹ́ta tó ṣe pàtàkì wọ̀nyí dáadáa torí pé ìyẹn ló máa jẹ́ ká mọ ìtumọ̀ àwọn àfiwé ọ̀rọ̀.
Ìgbà míì wà tó lè rọrùn láti lóye kókó ọ̀rọ̀ àti àwòrán tí àfiwé kan gbé wá sí wa lọ́kàn, àmọ́ kí ibi tí ọ̀rọ̀ ti jọra pín sí onírúurú ọ̀nà. Kí ló wá lè jẹ́ kó rọrùn fún wa láti lóye ibi tí ọ̀rọ̀ ti jọra? Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ọ̀rọ̀ tó wà ní àyíká ọ̀rọ̀ náà ló máa ràn wá lọ́wọ́.b
Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ́ fún ìjọ tó wà nílùú Sádísì pé: “Dájúdájú, láìjẹ́ pé o jí, èmi yóò wá gẹ́gẹ́ bí olè.” Nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, Jésù fi bóun ṣe máa wá (ìyẹn kókó ọ̀rọ̀) wéra pẹ̀lú bí olè ṣe máa ń wá (ìyẹn ni àwòrán). Àmọ́ ọ̀nà wo ni àfiwé yìí gbà jọra pẹ̀lú kókó ọ̀rọ̀? Ọ̀rọ̀ tó sọ tẹ̀ lé e jẹ́ ká mọ bó ṣe jọra. Jésù sọ pé: “Ìwọ kì yóò sì mọ̀ rárá ní ti wákàtí tí èmi yóò dé bá ọ.” (Ìṣípayá 3:3) Torí náà, àfiwé tí Jésù ṣe yìí ò dá lórí ìdí tí Jésù fi fẹ́ wá. Bẹ́ẹ̀ ni kò sì túmọ̀ sí pé Jésù máa wá jí nǹkan kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó fi ń wéra nínú àpèjúwe yìí ni bóun ṣe máa yọ sáwọn èèyàn náà lójijì, nígbà tí wọn ò retí.
Nígbà míì, àfiwé ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì kan lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti lóye irú àfiwé ọ̀rọ̀ kan náà nínú ẹsẹ míì nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo àfiwé kan náà tí Jésù lò, ó kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ dáadáa pé ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bí olè ní òru.” (1 Tẹsalóníkà 5:2) Àwọn ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ ṣáájú àti lẹ́yìn náà nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn ò ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé tó lè jẹ́ ká mọ bí àfiwé tó ṣe yẹn ṣe bá ohun tó ń sọ mu. Àmọ́ tá a bá fi àfiwé ọ̀rọ̀ yẹn wéra pẹ̀lú èyí tí Jésù lò nínú ìwé Ìṣípayá 3:3, ìyẹn á jẹ́ ká lóye bí ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù fi ṣàpèjúwe yẹn ṣe bá ohun tó ń sọ mu. Ẹ ò rí i pé ohun tí Pọ́ọ̀lù rán gbogbo àwa Kristẹni létí rẹ̀ yìí ṣe pàtàkì gan-an ni, ìyẹn ni pé ká wà lójúfò nípa tẹ̀mí.
Àwọn Àfiwé Ọ̀rọ̀ Tó Ń Kọ́ Wa Lẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ọlọ́run
Kò ṣeé ṣe fáwa èèyàn láti mohun gbogbo nípa irú Ọlọ́run tí Jèhófà jẹ́ àti gbogbo bí agbára rẹ̀ ṣe pọ̀ tó. Nígbà àtijọ́, Dáfídì Ọba kọ̀wé pé, ‘àwámáridìí ni títóbi’ Jèhófà. (Sáàmù 145:3) Lẹ́yìn tí Jóòbù ti ṣàyẹ̀wò àwọn kan lára àwọn ohun tí Ọlọ́run dá, ó ní: ‘Kíyè sí i, èyí ni díẹ̀ nínú ọ̀nà rẹ̀, ohun èyí tí a gbọ́ ti kéré tó! Ṣùgbọ́n ààrá ipa rẹ̀ ta ni òye rẹ̀ lè yé?’—Jóòbù 26:14, Bibeli Yoruba Atọ́ka.
Bá ò tiẹ̀ lè lóye lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nípa bí Ọlọ́run ṣe tóbi tó, Bíbélì lo àwọn àfiwé ọ̀rọ̀ tó máa jẹ́ ká lè lóye àwọn ànímọ́ àtàtà tí Bàbá wa ọ̀run ní. Bíbélì ṣàpèjúwe Jèhófà bí Ọba, Aṣòfin, Adájọ́ àti Jagunjagun, ó dájú pé àwọn àpèjúwe yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ẹni tó yẹ ká bọ̀wọ̀ fún ni. Bíbélì tún ṣàpèjúwe Jèhófà bí Olùṣọ́ Àgùntàn, Agbaninímọ̀ràn, Olùkọ́, Bàbá, Oníwòsàn àti Olùgbàlà, àwọn àpèjúwe yìí sì jẹ́ ká mọ̀ pé ẹni tá a lè fẹ́ràn ni. (Sáàmù 16:7; 23:1; 32:8; 71:17; 89:26; 103:3; 106:21; Aísáyà 33:22; 42:13; Jòhánù 6:45) Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àpèjúwe tó ṣe kedere yìí gbé àwọn àwòrán tó wọni lọ́kàn tó sì jọra lónírúurú ọ̀nà yọ. Àwọn àfiwé ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sọ púpọ̀ gan-an fún wa nípa Ọlọ́run ju bá a ṣe lè ṣàlàyé lọ.
Bíbélì tún fàwọn nǹkan tí kò lẹ́mìí ṣàpèjúwe Jèhófà. Ó pè é ní “Àpáta Ísírẹ́lì,” “àpáta gàǹgà” ó sì tún pè é ní “odi agbára.” (2 Sámúẹ́lì 23:3; Sáàmù 18:2; Diutarónómì 32:4) Báwo làwọn nǹkan tí Bíbélì fi ṣàpèjúwe Jèhófà yìí ṣe bá irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ mu? Bí àpáta ńlá ṣe máa ń fìdí múlẹ̀ gbọ-ingbọ-in, tí kì í sì í ṣeé ṣí nídìí, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà Ọlọ́run ṣe lè jẹ́ atóófaratì-bí-òkè fún wa.
Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àfiwé ọ̀rọ̀ tó ṣàpèjúwe onírúurú ànímọ́ Jèhófà ló kúnnú ìwé Sáàmù. Bí àpẹẹrẹ, ìwé Sáàmù 84:11 ṣàpèjúwe Jèhófà bí “oòrùn àti apata” torí pé òun ni Orísun ìmọ́lẹ̀ àtàwọn ohun àmúṣagbára, òun náà ló dá wa tó sì ń dáàbò bò wá. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìwé Sáàmù 121:5 sọ pé, “Jèhófà ni ibòji rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.” Bí ibòji ṣe lè ṣíji bo ẹnì kan nígbà tí oòrùn bá ń mú ganrínganrín, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe lágbára láti dáàbò bo àwọn tó bá ń sìn ín, kúrò lọ́wọ́ àjálù, bí ìgbà tó fi “ọwọ́” rẹ̀ ṣíji bò wọ́n, tàbí bíi pé ó dáàbò bò wọ́n lábẹ́ “ìyẹ́” apá rẹ̀.—Aísáyà 51:16; Sáàmù 17:8; 36:7.
Àwọn Àfiwé Ọ̀rọ̀ Tó Ṣàpèjúwe Jésù
Léraléra ni Bíbélì pe Jésù ní “Ọmọ Ọlọ́run.” (Jòhánù 1:34; 3:16-18) Àwọn kan tí kì í ṣe ẹlẹ́sìn Kristẹni ò fara mọ́ gbólóhùn yìí, wọ́n ronú pé nígbà tí Ọlọ́run ò níyàwó, tí ò sì dà bí àwa èèyàn, báwo ló ṣe lè bímọ? Kò sí àní-àní pé, Ọlọ́run ò bímọ lọ́nà táwa èèyàn gbà ń bímọ. Torí náà, àfiwé ni ọ̀rọ̀ yìí. Bíbélì lò ó láti jẹ́ káwọn èèyàn lóye pé àjọṣe bíi ti bàbá, tó jẹ́ ẹ̀dá èèyàn sọ́mọ ẹ̀ ló wà láàárín Jésù àti Ọlọ́run. Àfiwé yìí tún tẹ̀ ẹ́ mọ́ wa lọ́kàn pé Jèhófà ló dá Jésù, òun ló mú kó wà láàyè. Bíi ti Jésù, Bíbélì pe, Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́ náà ní ‘Ọmọ Ọlọ́run.’—Lúùkù 3:38, Bibeli Mimọ.
Jésù fi onírúurú àfiwé ọ̀rọ̀ ṣàpèjúwe ipa tó yàtọ̀ síra tóun máa kó nínú mímú àwọn ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn ṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, ó ní: “Èmi ni àjàrà tòótọ́, Baba mi sì ni aroko.” Ó wá fàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wé àwọn ẹ̀ka igi àjàrà náà. (Jòhánù 15:1, 4) Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni àfiwé ọ̀rọ̀ yìí kọ́ wa? Bí ẹ̀ka igi àjàrà kan bá fẹ́ máa wà láàyè nìṣó, kó sì máa sèso, kò gbọ́dọ̀ kúrò lára igi náà. Bẹ́ẹ̀ náà làwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi ṣe gbọ́dọ̀ máa wà níṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀. Jésù sọ pé: “Láìsí mi, ẹ kò lè ṣe nǹkan kan rárá.” (Jòhánù 15:5) Bí àgbẹ̀ tó gbin igi àjàrà ṣe máa ń retí pé kí igi náà sèso, Jèhófà retí pé káwọn tó bá wà níṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi sèso nípa tẹ̀mí.—Jòhánù 15:8.
Rí I Dájú Pó O Mọ Ibi Tọ́rọ̀ Ti Jọra
A lè ṣi àfiwé ọ̀rọ̀ kan lóye tá ò bá mọ bí àwòrán tí àfiwé náà gbé wá sí wa lọ́kàn ṣe jọra pẹ̀lú kókó ọ̀rọ̀ tọ́rọ̀ náà dá lé. Bí àpẹẹrẹ, kíyè sí ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Róòmù 12:20, tó kà pé: “Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ; bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní ohun kan láti mu; nítorí nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò máa kó òkìtì ẹyín iná lé e ní orí.” Téèyàn bá ń kó òkìtì ẹyín iná lé ẹnì kan lórí, ṣó túmọ̀ sí pé èèyàn ń gbẹ̀san nìyẹn? Rárá o, a ò ní sọ bẹ́ẹ̀ tá a bá lóye bọ́rọ̀ yẹn ṣe bára mu. Bí wọ́n ṣe máa ń yọ́ irin láyé àtijọ́ ni ẹni tó kọ ẹsẹ Bíbélì yìí ní lọ́kàn. Ẹyín iná tàbí ẹ̀ṣẹ́ iná ni wọ́n fi máa ń yọ́ irin tútù nígbà yẹn, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti kó ẹyín iná díẹ̀ jọ, wọ́n á wá fi irin yẹn sáàárín rẹ̀, wọ́n á sì tún kó ẹyín iná lé e lórí. Ooru gbígbóná látara ẹyín iná yẹn máa mú kí irin náà yọ́, ìyẹn sì máa yọ ìdàrọ́ kúrò lára irin tútù náà. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé tá a bá ń hùwà rere sẹ́ni tó ń ṣe búburú sí wa, ìyẹn lè mú kẹ́ni náà yíwà pa dà, kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe rere.
Tá a bá lóye àwọn àfiwé ọ̀rọ̀ lọ́nà tó tọ́, a máa lóye ohun tí àwòrán tó bá gbé sí wa lọ́kàn túmọ̀ sí gan-an, ìyẹn á sì múnú wa dùn. Nígbà tí Bíbélì fi ẹ̀ṣẹ̀ wé gbèsè, ó jẹ́ ká mọ̀ ọ́n lára pé kì í ṣọ̀ràn kékeré. (Lúùkù 11:4) Àmọ́ tí Jèhófà bá dárí jì wá, tó sì wá mú ohun tó dà bíi gbèsè tó wà lọ́rùn wa kúrò, ìyẹn máa ń tù wá lára gan-an! Nígbà tí Bíbélì sọ pé Jèhófà máa ń ‘bo ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́lẹ̀’, ó sì máa ń ‘pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa rẹ́,’ ṣe ló dà bí ìgbà téèyàn bá fọ àbàwọ́n kúrò lára aṣọ funfun tí aṣọ náà sì wá mọ́ tónítóní, ìyẹn mú un dá wa lójú pé Ọlọ́run ò tún ní ka ẹ̀ṣẹ̀ yẹn sí wa lọ́rùn mọ́ lọ́jọ́ iwájú. (Sáàmù 32:1, 2; Ìṣe 3:19) Ẹ ò rí i bó ṣe tù wá lára tó láti mọ̀ pé Jèhófà lè sọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa tó pupa bí ẹ̀jẹ̀ di funfun bí ìrì dídì!—Aísáyà 1:18.
Ìwọ̀nba làwọn àfiwé tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn yìí jẹ́ lára ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àfiwé ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Torí náà, tó o bá ń ka Bíbélì, máa fún àwọn àfiwé ọ̀rọ̀ tó bá wà níbẹ̀ láfiyèsí àrà ọ̀tọ̀. Fara balẹ̀ kà á, kó o lè lóye báwọn àfiwé náà ṣe bá kókó ọ̀rọ̀ mu, kó o sì ṣàṣàrò lórí rẹ̀. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ lóye Ìwé Mímọ́, wàá sì túbọ̀ mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àfiwé ni onírúurú ọ̀rọ̀ àpèjúwe, àkànlò èdè àti onírúurú ẹwà èdè téèyàn lè fi sọ̀rọ̀ lówelówe.
b Ìwé gbédègbẹ́yọ̀, aládìpọ̀ méjì, tó dá lórí Bíbélì, ìyẹn Insight on the Scriptures, táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe, ṣàwọn àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ tó lè jẹ́ kéèyàn mọ ibi tọ́rọ̀ ti jọra.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]
Báwọn Àfiwé Ọ̀rọ̀ Ṣe Máa Ń Là Wá Lóye
Onírúurú ọ̀nà ni àfiwé ọ̀rọ̀ máa ń gbà là wá lóye. Ó lè fi ọ̀rọ̀ kan tó ṣòro láti lóye wé nǹkan míì tá a ti mọ̀ dáadáa. A lè fi onírúurú àfiwé ṣàlàyé oríṣiríṣi nǹkan tá a bá fẹ́ káwọn èèyàn lóye nípa kókó ọ̀rọ̀ kan. A sì lè fi tẹnu mọ́ kókó ọ̀rọ̀ pàtàkì kan tàbí ká lò ó láti fi jẹ́ kọ́rọ̀ náà fani lọ́kàn mọ́ra.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 14]
Fòye Mọ Àwọn Kókó Pàtàkì
ÀFIWÉ Ọ̀RỌ̀: “Ẹ̀yin ni iyọ̀ ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 5:13)
KÓKÓ Ọ̀RỌ̀: Ẹ̀yin (Ìyẹn àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù)
ÀWÒRÁN: Iyọ̀
IBI TỌ́RỌ̀ TI JỌRA: Iyọ̀ máa ń dáàbò bo nǹkan, kì í jẹ́ kó tètè bà jẹ́
Ẹ̀KỌ́ TÁ A RÍ KỌ́: Àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní láti jíṣẹ́ tó máa dáàbò bo ẹ̀mí àwọn èèyàn
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 15]
“Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi. Èmi kì yóò ṣaláìní nǹkan kan.”—SÁÀMÙ 23:1