Ẹ Máa Ṣe Rere
“Ẹ . . . máa ṣe rere.”—LÚÙKÙ 6:35.
1, 2. Kí nìdí tí kì í fi í rọrùn láti máa ṣoore fáwọn èèyàn?
KÌ Í rọrùn láti máa ṣoore fáwọn èèyàn. Èèyàn lè ṣoore fáwọn ẹlòmíì kí wọ́n má moore. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń sapá gidigidi láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nípa wíwàásù “ìhìnrere ológo ti Ọlọ́run” àti ti Ọmọ rẹ̀ fún wọn, ohun tá à ń ṣe lè má jọ wọ́n lójú rárá, wọ́n sì lè má mọrírì rẹ̀. (1 Tím. 1:11) Àwọn mìíràn ti sọ ara wọn di “ọ̀tá òpó igi oró Kristi.” (Fílí. 3:18) Báwo ló ṣe yẹ káwa Kristẹni máa ṣe sírú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀?
2 Jésù Kristi sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa ṣe rere.” (Lúùkù 6:35) Ẹ jẹ́ ká wá fara balẹ̀ ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ ìyànjú yìí. Yàtọ̀ síyẹn, a óò tún jàǹfààní látinú àwọn kókó mìíràn tí Jésù mẹ́nu kàn lórí ọ̀rọ̀ ṣíṣe rere fáwọn èèyàn.
‘Ẹ Máa Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ọ̀tá Yín’
3. (a) Ní ṣókí, ṣàlàyé bó o ṣe lóye ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Mátíù 5:43-45. (b) Irú èrò wo làwọn aṣáájú ìsìn àwọn Júù ti ọ̀rúndún kìíní ní nípa àwọn Júù àtàwọn tí kì í ṣe Júù?
3 Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, èyí táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó, Jésù sọ fáwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kí wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn kí wọ́n sì máa gbàdúrà fáwọn tó ń ṣenúnibíni sí wọn. (Ka Mátíù 5:43-45.) Júù làwọn tó ń gbọ́rọ̀ Jésù lọ́jọ́ yẹn, gbogbo wọn ló sì mọ òfin Ọlọ́run tó sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ gbẹ̀san tàbí kí o di kùnrùngbùn sí ọmọ àwọn ènìyàn rẹ; kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Léf. 19:18) Àwọn aṣáájú ìsìn Júù ní ọ̀rúndún kìíní gbà pé àwọn Júù nìkan ni òfin yìí pè ní “ọmọ àwọn ènìyàn rẹ” àti “ọmọnìkejì rẹ.” Ohun tí Òfin Mósè sọ ni pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tó kù. Àmọ́ àwọn Júù yẹn wá bẹ̀rẹ̀ sí í ní èrò pé ọ̀tá ni gbogbo àwọn tí kì í ṣe Júù jẹ́ sáwọn, ńṣe ló sì yẹ káwọn kórìíra wọn.
4. Kí ni Jésù sọ pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa ṣe fáwọn ọ̀tá wọn?
4 Ṣùgbọ́n ohun tí Jésù sọ yàtọ̀ síyẹn. Ó ní: “Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín.” (Mát. 5:44) Jésù sọ pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ máa fìfẹ́ hàn sáwọn tó ń ṣàìdáa sí wọn. Gẹ́gẹ́ bí Lúùkù ṣe kọ ọ́ nínú Ìhìn Rere rẹ̀, Jésù sọ pé: “Mo wí fún ẹ̀yin tí ń fetí sílẹ̀ pé, Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín, láti máa ṣe rere sí àwọn tí ó kórìíra yín, láti máa súre fún àwọn tí ń gégùn-ún fún yín, láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń fi ìwọ̀sí lọ̀ yín.” (Lúùkù 6:27, 28) Ó yẹ káwa náà kọbi ara sí ọ̀rọ̀ Jésù yìí báwọn tó gbọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní ti ṣe. Ká máa “ṣe rere sí àwọn tí ó kórìíra” wa, nípa ṣíṣoore fún wọn bí wọ́n bá tiẹ̀ ṣàìdá sí wa. Ká máa “súre fún àwọn tí ń gégùn-ún fún” wa nípa bíbá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́tù. Ká sì máa “gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni” sí wa, yálà wọ́n ń fìyà jẹ wá ni tàbí wọ́n ń fi “ìwọ̀sí” lọ̀ wá lọ́nà mìíràn. Tá a bá ń gba irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀, ó fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wa, nítorí pé ńṣe là ń bẹ Jèhófà pé kó yí wọn lọ́kàn padà kí wọ́n sì ṣohun tó máa mú inú Jèhófà dùn.
5, 6. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wa?
5 Kí nìdí tó fi yẹ ká máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wa? Jésù sọ pé: “Kí ẹ lè fi ara yín hàn ní ọmọ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mát. 5:45) Tá a bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yẹn, ńṣe là ń fi hàn pé “ọmọ” Ọlọ́run ni wá, nítorí pé a ń fara wé Jèhófà, ẹni ti ń “mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere, tí ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.” Nígbà tí Lúùkù ń sọ ọ̀rọ̀ yìí ní tiẹ̀, ó ní Ọlọ́run “jẹ́ onínúrere sí àwọn aláìlọ́pẹ́ àti àwọn ẹni burúkú.”—Lúùkù 6:35.
6 Nígbà tí Jésù ń tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ‘máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn,’ ó sọ pé: “Bí ẹ bá nífẹ̀ẹ́ àwọn tí wọ́n ń nífẹ̀ẹ́ yín, èrè wo ni ẹ ní? Àwọn agbowó orí kò ha ń ṣe ohun kan náà bí? Bí ẹ bá sì kí àwọn arákùnrin yín nìkan, ohun àrà ọ̀tọ̀ wo ni ẹ ń ṣe? Àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú kò ha ń ṣe ohun kan náà bí?” (Mát. 5:46, 47) Tó bá jẹ́ pé àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa nìkan la nífẹ̀ẹ́, a ò ní “èrè” kankan lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn ò sì lè jẹ́ ká rí ojú rere rẹ̀. Kódà, àwọn agbowó orí táwọn èèyàn ò fojú rere wò pàápàá ń nífẹ̀ẹ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ wọn.—Lúùkù 5:30; 7:34.
7. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kì í ṣe “ohun àrà ọ̀tọ̀” la ṣe tó bá jẹ́ pé àwọn “arákùnrin” wa nìkan là ń kí?
7 Ọ̀rọ̀ náà, “àlááfíà” wà nínú gbólóhùn táwọn Júù sábà máa fi ń kíra wọn. (Oníd. 19:20; Jòh. 20:19) Ńṣe ni wọ́n máa ń fi ìkíni yìí sọ pé àwọ́n ń fẹ́ kí ẹni táwọn ń kí ní àlàáfíà, ara líle àti aásìkí. Kì í ṣe “ohun àrà ọ̀tọ̀” la ṣe tó bá jẹ́ pé àwọn tá a kà sí “arákùnrin” wa nìkan là ń kí. Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ, ohun kan náà tí “àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè” ńṣe nìyẹn.
8. Kí ni Jésù ń gba àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ níyànjú láti ṣe nígbà tó sọ pé: “Kí ẹ jẹ́ pípé”?
8 Ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá ni kò jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi láti jẹ́ ẹni pípé, tí kò lè ṣàṣìṣe. (Róòmù 5:12) Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ tí Jésù fi kádìí kókó yìí nínú ìwàásù rẹ̀ rèé: “Kí ẹ jẹ́ pípé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, bí Baba yín ọ̀run ti jẹ́ pípé.” (Mát. 5:48) Ńṣe ni Jésù ń fi ọ̀rọ̀ yìí gba àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ níyànjú láti máa fara wé ‘Baba wọn ọ̀run,’ Jèhófà, nípa sísọ ìfẹ́ wọn di pípé, ìyẹn ni pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn. Ohun tó yẹ káwa náà máa ṣe nìyẹn.
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Dárí Jini?
9. Kí ni ìtumọ̀ gbólóhùn náà: “Dárí àwọn gbèsè wa jì wá”?
9 Tá a bá ń ṣàánú àwọn tó ṣẹ̀ wá tá à ń dárí jì wọ́n, rere là ń ṣe yẹn. Kódà, gbólóhùn kan nínú àdúrà tí Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ pé: “Dárí àwọn gbèsè wa jì wá, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ti dárí ji àwọn ajigbèsè wa.” (Mát. 6:12) Àmọ́, kì í ṣe gbèsè owó ni Jésù ń sọ o. Ìhìn Rere Lúùkù jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ ni “gbèsè” tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yìí, nítorí ó sọ pé: “Dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, nítorí àwa fúnra wa pẹ̀lú a máa dárí ji olúkúlùkù ẹni tí ó jẹ wá ní gbèsè.”—Lúùkù 11:4.
10. Tó bá dọ̀rọ̀ ìdáríjì, báwo la ṣe lè fara wé Ọlọ́run?
10 Ó yẹ ká fara wé Ọlọ́run tó máa ń dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà ní fàlàlà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kí ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run pẹ̀lú ti tipasẹ̀ Kristi dárí jì yín fàlàlà.” (Éfé. 4:32) Dáfídì, tó wà lára àwọn tó kọ Sáàmù kọ ọ́ lórin pé: “Jèhófà jẹ́ aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́. . . . Òun kì í ṣe sí wa àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa; bẹ́ẹ̀ ni òun kì í mú ohun tí ó yẹ wá wá sórí wa gẹ́gẹ́ bí àwọn ìṣìnà wa. . . . Bí yíyọ oòrùn ti jìnnà réré sí wíwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú àwọn ìrélànàkọjá wa jìnnà réré sí wa. Bí baba ti ń fi àánú hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń fi àánú hàn sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Nítorí tí òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé ekuru ni wá.”—Sm. 103:8-14.
11. Àwọn wo ni Ọlọ́run máa ń dárí jì?
11 Táwọn èèyàn bá fẹ́ kí Ọlọ́run dárí ji àwọn, àfi kí wọ́n kọ́kọ́ dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ wọ́n. (Máàkù 11:25) Nígbà tí Jésù ń sọ bí kókó yìí ti ṣe pàtàkì tó, ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Nítorí bí ẹ bá dárí àṣemáṣe àwọn ènìyàn jì wọ́n, Baba yín ọ̀run yóò dárí jì yín pẹ̀lú; nígbà tí ó jẹ́ pé, bí ẹ kò bá dárí àṣemáṣe àwọn ènìyàn jì wọ́n, Baba yín kì yóò dárí àwọn àṣemáṣe yín jì yín.” (Mát. 6:14, 15) Bó ṣe rí nìyẹn o. Àwọn tó bá ń dárí ji àwọn ẹlòmíì pátápátá nìkan ni Ọlọ́run máa ń dárí jì. Ọ̀nà kan téèyàn sì lè gbà máa ṣe rere ni pé kó tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe.”—Kól. 3:13.
“Ẹ Dẹ́kun Dídánilẹ́jọ́”
12. Ìmọ̀ràn wo ni Jésù fúnni nípa dídá àwọn èèyàn lẹ́jọ́?
12 Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, Jésù tún mẹ́nu kan ọ̀nà míì téèyàn lé gbà máa ṣe rere. Ó sọ fáwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ pé kí wọ́n dẹ́kun dídá àwọn èèyàn lẹ́jọ́, lẹ́yìn náà, ó wá lo àpèjúwe kan tó fa kíki láti fìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀. (Ka Mátíù 7:1-5.) Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Ẹ dẹ́kun dídánilẹ́jọ́.”
13. Báwo làwọn tó ń gbọ́rọ̀ Jésù ṣe lè máa “bá a nìṣó ní títúnisílẹ̀”?
13 Gẹ́gẹ́ bí Ìhìn Rere Mátíù ṣe sọ, Jésù sọ pé: “Ẹ dẹ́kun dídánilẹ́jọ́ kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́.” (Mát. 7:1) Ohun tí Ìhìn Rere Lúùkù sọ pé Jésù sọ rèé: “Ẹ dẹ́kun dídánilẹ́jọ́, a kì yóò sì dá yín lẹ́jọ́ lọ́nàkọnà; ẹ sì dẹ́kun dídánilẹ́bi, a kì yóò sì dá yín lẹ́bi lọ́nàkọnà. Ẹ máa bá a nìṣó ní títúnisílẹ̀, a ó sì tú yín sílẹ̀.” (Lúùkù 6:37) Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn Farisí máa ń dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ lọ́nà líle koko, àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu ni wọ́n sì máa ń lò. Bí ẹnikẹ́ni lára àwọn tó ń gbọ́rọ̀ Jésù bá ti ń ṣerú nǹkan bẹ́ẹ̀, ó ní láti “dẹ́kun dídánilẹ́jọ́” lọ́nà bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kí wọ́n máa “bá a nìṣó ní títúnisílẹ̀,” ìyẹn ni pé kí wọ́n máa dárí jini. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú fún wa ní ìmọ̀ràn tó jọ èyí lórí ọ̀ràn ìdáríjì.
14. Báwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bá ń dárí jini, kí ló máa mú káwọn ẹlòmíì náà máa ṣe?
14 Báwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bá ń dárí jini, èyí á mú káwọn ẹlòmíì pẹ̀lú máa dárí jì wọ́n. Jésù sọ pé: “Irú ìdájọ́ tí ẹ fi ń dáni lẹ́jọ́, ni a ó fi dá yín lẹ́jọ́; àti òṣùwọ̀n tí ẹ fi ń díwọ̀n fúnni, ni wọn yóò fi díwọ̀n fún yín.” (Mát. 7:2) Tó bá dọ̀rọ̀ bá a ṣe ń ṣe sáwọn èèyàn, ohun tá a bá fúnrúgbìn la máa ká.—Gál. 6:7.
15. Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ó burú pé kéèyàn jẹ́ alárìíwísí?
15 Rántí pé nígbà tí Jésù ń ṣàlàyé nípa bó ṣe burú tó pé kéèyàn jẹ́ alárìíwísí, ó béèrè pé: “Èé ṣe tí ìwọ fi wá ń wo èérún pòròpórò tí ó wà nínú ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n tí o kò ronú nípa igi ìrólé tí ó wà nínú ojú ìwọ fúnra rẹ? Tàbí báwo ni ìwọ ṣe lè sọ fún arákùnrin rẹ pé, ‘Yọ̀ǹda fún mi láti yọ èérún pòròpórò kúrò nínú ojú rẹ’; nígbà tí, wò ó! igi ìrólé kan ń bẹ nínú ojú ìwọ fúnra rẹ?” (Mát. 7:3, 4) Téèyàn kan bá ya alárìíwísí, àbùkù tí ò tó nǹkan lá máa ṣọ́ ní “ojú” arákùnrin rẹ̀. Tó bá sì ti wá rí bẹ́ẹ̀ ohun tí alárìíwísí náà ń sọ ni pé ojú tí arákùnrin òun fi ń wo nǹkan kò tọ́, kò sì mọ béèyàn ṣe ń fi làákàyè ṣe nǹkan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àbùkù arákùnrin rẹ̀ yìí kò tó nǹkan rárá, ó dà bí èérún pòròpórò. Àmọ́ alárìíwísí yìí sọ fún arákùnrin rẹ̀ pé kó jẹ́ kóun bá a “yọ èérún pòròpórò” náà, pé òun fẹ́ ran arákùnrin òun lọ́wọ́ kó lè ríran kedere. Ẹ ò rí i pé ìwà àgàbàgebè nìyẹn!
16. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé “igi ìrólé” wà nínú ojú àwọn Farisí?
16 Tó bá dọ̀rọ̀ ṣíṣàríwísí, ọ̀gá làwọn aṣáájú ìsìn Júù. Bí àpẹẹrẹ: Nígbà tí ọ̀kùnrin afọ́jú kan tí Kristi wò sàn sọ pé ó ní láti jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Jésù ti wá. Ìbínú làwọn Farisí fi fèsì pé: “Gbogbo-ẹ̀ gbògbò-ẹ̀, inú ẹ̀ṣẹ̀ ni a bí ọ sí, síbẹ̀ ìwọ ha ń kọ́ wa bí?” (Jòh. 9:30-34) Ojú àwọn Farisí wọ̀nyẹn ò mọ́lẹ̀ dáadáa nípa tẹ̀mí, wọn ò sì mọ béèyàn ṣe ń lo làákàyè. Nítorí náà, a lè sọ pé “igi ìrólé” wà lójú wọn, ojú wọn sì ti fọ́ pátápátá. Èyí ló mú kí Jésù la ọ̀rọ̀ náà mọ́lẹ̀ pé: “Alágàbàgebè! Kọ́kọ́ yọ igi ìrólé kúrò nínú ojú tìrẹ ná, nígbà náà ni ìwọ yóò sì ríran kedere ní ti bí o ṣe lè yọ èérún pòròpórò kúrò nínú ojú arákùnrin rẹ.” (Mát. 7:5; Lúùkù 6:42) Tá a bá pinnu pé rere la ó máa ṣe fáwọn èèyàn, a ò ní jẹ́ alárìíwísí tó máa ń wá èérún pòròpórò nínú ojú àwọn arákùnrin wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ó máa rántí pé aláìpé ni gbogbo wa. Èyí ni kò ní jẹ́ ká máa dá àwọn ará wa lẹ́jọ́ a ò sì ní máa ṣàríwísí wọn.
Bó Ṣe Yẹ Ká Máa Ṣe Sáwọn Èèyàn
17. Gẹ́gẹ́ bí Mátíù 7:12 ṣe sọ, báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn èèyàn?
17 Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé bíi bàbá ni Ọlọ́run ṣe ń ṣe sáwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀, ní ti pé ó máa ń dáhùn àdúrà wọn. (Ka Mátíù 7:7-12.) Ó gbàfiyèsí pé Jésù fi ìlànà kan lélẹ̀ nípa bó ṣe yẹ kéèyàn máa hùwà. Ó ní: “Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” (Mát. 7:12) Ìgbà tá a bá ń tẹ̀ lé ìlànà tí Jésù fi lélẹ̀ yìí ni a tó lè máa fi hàn pé ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi ni wá lóòótọ́.
18. Báwo ni “Òfin” ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé bá a bá ṣe fẹ́ káwọn èèyàn máa ṣe sí wa náà ló ṣe yẹ ká máa ṣe sí wọn?
18 Lẹ́yìn tí Jésù sọ pé bá a bá ṣe fẹ́ káwọn èèyàn máa ṣe sí wa náà ni ká má ṣe sí wọn, ó fi kún un pé: “Ní tòótọ́, èyí ni ohun tí Òfin àti àwọn Wòlíì túmọ̀ sí.” Tá a bá ń ṣe ohun tí Jésù sọ yìí, ó fi hàn pé à ń tẹ̀ lé àpapọ̀ gbogbo ohun tó wà nínú “Òfin,” ìyẹn àwọn àkọsílẹ̀ tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì sí Diutarónómì. Yàtọ̀ sí pé àwọn ìwé Bíbélì yìí jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe pinnu láti mú irú ọmọ kan wá, tó máa mú ìwà ibi kúrò, wọ́n tún sọ nípa Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípasẹ̀ Mósè lọ́dún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (Jẹ́n. 3:15) Lára àwọn nǹkan tí Òfin yẹn ṣe ni pé ó mú kó ṣe kedere pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ máa ṣe ẹ̀tọ́, wọn ò gbọ́dọ̀ ṣojúsàájú, wọ́n sì gbọ́dọ̀ máa ṣoore fáwọn aláìní àtàwọn àtìpó tó wà ní ilẹ̀ wọn.—Léf. 19:9, 10, 15, 34.
19. Báwo ni ìwé “àwọn Wòlíì” ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ ká máa ṣe rere?
19 Àwọn ìwé tí Jésù pè ní “àwọn Wòlíì” ni àwọn ìwé táwọn wòlíì kọ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Lára àwọn ohun tó wà nínú àwọn ìwé wọ̀nyí ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà tó ṣẹ mọ́ Kristi lára. Àwọn ìwé yìí tún jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa ń bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n bá ṣe ohun tó tọ́ lójú rẹ̀ tí wọ́n sì ń hùwà tó dáa sáwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: ‘Ẹ pa ìdájọ́ òdodo mọ́, kí ẹ sì máa ṣe ohun tí í ṣe òdodo. . . . Aláyọ̀ ni ẹni kíkú tí ń ṣe èyí, àti ọmọ aráyé tí ó rọ̀ mọ́ ọn, . . . tí ó sì ń pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kí ó má bàa ṣe búburú èyíkéyìí.’” (Aísá. 56:1, 2) Bó ṣe rí gan-an nìyẹn, Ọlọ́run ń fẹ́ káwọn èèyàn rẹ̀ máa ṣe rere.
Máa Ṣe Rere Fáwọn Èèyàn Nígbà Gbogbo
20, 21. Báwo ni Ìwàásù Lórí Òkè tí Jésù ṣe ṣe rí lára àwọn ogunlọ́gọ̀ tó gbọ́ ọ, kí sì nìdí tó fi yẹ ká ṣàṣàrò lórí ìwàásù náà?
20 Ìwọ̀nba díẹ̀ la tíì gbé yẹ̀ wò lára ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ pàtàkì tí Jésù kọ́ni nínú Ìwàásù Lórí Òkè tí kò láfiwé. Síbẹ̀, kedere la rí bí ọ̀rọ̀ Jésù yẹn ṣe rí lára àwọn tó gbọ́ ọ nígbà yẹn. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Wàyí o, nígbà tí Jésù parí àwọn àsọjáde wọ̀nyí, ìyọrísí rẹ̀ ni pé háà ń ṣe ogunlọ́gọ̀ sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀; nítorí ó ń kọ́ wọn bí ẹnì kan tí ó ní ọlá àṣẹ, kì í sì í ṣe bí àwọn akọ̀wé òfin wọn.”—Mát. 7:28, 29.
21 Dájúdájú, Jésù Kristi fi hàn pé òun ni “Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn” tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀. (Aísá. 9:6) Àpẹẹrẹ pàtàkì kan tó fi hàn pé Jésù mọ ojú tí Bàbá rẹ̀ ọ̀run fi ń wo nǹkan ni Ìwàásù Lórí Òkè jẹ́. Láfikún sáwọn kókó tá a ti gbé yẹ̀ wò nínú ìwàásù yìí, Jésù tún sọ nǹkan púpọ̀ nípa béèyàn ṣe lè ní ayọ̀ tòótọ́, béèyàn ṣe lè sá fún ìṣekúṣe, béèyàn ṣe lè máa ṣohun tó jẹ́ òdodo, ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la wa dára kó sì fini lọ́kàn balẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ mìíràn. Á dáa kó o fara balẹ̀ ka Mátíù orí karùn-ún sí ìkeje tàdúràtàdúrà lẹ́ẹ̀kan sí i. Ṣàṣàrò lórí àwọn àgbàyanu ìmọ̀ràn Jésù tó wà níbẹ̀. Máa fi ohun tí Kristi sọ nínú Ìwàásù Lórí Òkè sílò nígbèésí ayé rẹ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ máa ṣohun táá máa múnú Jèhófà dùn, wàá máa ṣe dáadáa sáwọn èèyàn, wàá sì máa ṣe rere.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn ọ̀tá wa?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká máa dárí jini?
• Kí ni Jésù sọ nípa dídá àwọn èèyàn lẹ́jọ́?
• Gẹ́gẹ́ bí Mátíù 7:12 ṣe sọ, báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn èèyàn?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 10]
Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Jésù fi sọ pé: “Ẹ dẹ́kun dídánilẹ́jọ́”?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn tó ń ṣenúnibíni sí wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ṣé bó o ṣe fẹ́ káwọn èèyàn ṣe sí ọ lo máa ń ṣe sí wọn nígbà gbogbo?