Orí 16
Bí O Ṣe Lè Súnmọ́ Ọlọrun
1. Kí ni àwọn ìjọra tí ó wà nínú ọ̀pọ̀ ìsìn?
Ó YA arìnrìn-àjò kan tí ó ṣèbẹ̀wò sí orílẹ̀-èdè Ìlà-Oòrùn kan lẹ́nu láti rí àwọn ààtò-àṣà ìsìn tí ó ṣàkíyèsí ní tẹmpili ìsìn Buddha kan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ère náà kì í ṣe yálà ti Maria tàbí ti Kristi, ọ̀pọ̀ àwọn ààtò-àṣà náà jọ ti ṣọ́ọ̀ṣì tí ó ń lọ ní orílẹ̀-èdè rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ó ṣàkíyèsí ìlò àwọn ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà àti àsọtúnsọ àdúrà. Àwọn mìíràn pẹ̀lú ti ṣe irú ìfiwéra kan náà. Ní Ìlà-Oòrùn tàbí Ìwọ̀-Oòrùn, àwọn ọ̀nà tí àwọn olùfọkànsìn ń gbà gbìyànjú láti súnmọ́ Ọlọrun tàbí àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ ìjọsìn wọn jọra lọ́nà tí ó pẹtẹrí.
2. Báwo ni a ti ṣàpèjúwe àdúrà, kí sì ni ìdí tí ọ̀pọ̀ ènìyàn fi ń gbàdúrà?
2 Ní pàtàkì ọ̀pọ̀ ń gbìyànjú láti súnmọ́ Ọlọrun nípa gbígbàdúrà sí i. Àdúrà ni a ti ṣàpèjúwe bí “ìgbésẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ènìyàn pẹ̀lú ohun mímọ́-ọlọ́wọ̀ tàbí mímọ́—Ọlọrun, àwọn ọlọrun, ilẹ̀-ọba tí ó ga rékọjá, tàbí àwọn agbára tí ó ju ti ẹ̀dá lọ.” (The New Encyclopædia Britannica) Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí wọ́n bá ń tọ Ọlọrun lọ nínú àdúrà, àwọn díẹ̀ ń ronú nípa kìkì ohun tí wọ́n lè rí gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, nígbà kan ọkùnrin kan béèrè lọ́wọ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa pé: “Bí o bá gbàdúrà fún mi, ìṣòro tí mo ní nínú ìdílé mi, lẹ́nu iṣẹ́, àti pẹ̀lú ìlera mi yóò ha yanjú bí?” Ó jọ bí ẹni pé ohun tí ọkùnrin náà rò nìyẹn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ń gbàdúrà wọ́n sì ríi pé àwọn ìṣòro wọn ṣì wà síbẹ̀. Nítorí náà a lè béèrè pé, ‘Kí ni ìdí rẹ̀ gan-an tí ó fi yẹ kí a súnmọ́ Ọlọrun?’
ÌDÍ TÍ Ó FI YẸ KÍ A SÚNMỌ́ ỌLỌRUN
3. Ta ni a gbọ́dọ̀ darí àwọn àdúrà wa sí, èésìtiṣe?
3 Àdúrà kì í ṣe ààtò-àṣà tí kò nítumọ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe ọ̀nà kan ṣáá láti jèrè ohun kan. Ìdí pàtàkì fún títọ Ọlọrun lọ ni láti ní ipò-ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Nítorí náà a níláti darí àdúrà wa sí Jehofa Ọlọrun. Dafidi onipsalmu náà sọ pé: “[Jehofa, NW] wà létí ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí ń ké pè é.” (Orin Dafidi 145:18) Jehofa ń késí wa láti wá sínú ipò-ìbátan alálàáfíà pẹ̀lú rẹ̀. (Isaiah 1:18) Àwọn wọnnì tí ń dáhùnpadà sí ìkésíni yìí fohùnṣọ̀kan pẹ̀lú onipsalmu náà tí ó sọ pé: “Ó dára fún mi láti súnmọ́ Ọlọrun.” Èéṣe? Nítorí àwọn wọnnì tí wọ́n fà súnmọ́ Jehofa Ọlọrun yóò gbádùn ayọ̀ tòótọ́ àti àlàáfíà èrò-inú.—Orin Dafidi 73:28.
4, 5. (a) Èéṣe tí ó fi ṣe pàtàkì láti gbàdúrà sí Ọlọrun? (b) Irú ipò-ìbátan wo ni a lè mú dàgbà pẹ̀lú Ọlọrun nípasẹ̀ àdúrà?
4 Kí ni ìdí rẹ̀ tí a fi ń gbàdúrà sí Ọlọrun fún ìrànlọ́wọ́ bí ó bá ‘mọ awọn ohun tí a ṣe aláìní kí a tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀’? (Matteu 6:8; Orin Dafidi 139:4) Àdúrà fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun a sì wò ó bí Orísun “gbogbo ẹ̀bùn rere ati gbogbo ọrẹ pípé.” (Jakọbu 1:17; Heberu 11:6) Jehofa ń rí adùn nínú àwọn àdúrà wa. (Owe 15:8) Inú rẹ̀ dùn láti gbọ́ àwọn ìsọjáde ìmọrírì àti ìyìn wa tí ó nítumọ̀, gan-an bí inú bàbá kan ti ń dùn bí ó bá gbọ́ tí ọmọ rẹ̀ kékeré bá sọ àwọn ọ̀rọ̀ olótìítọ́-inú ti ìmoore jáde. (Orin Dafidi 119:108) Níbi tí àjọṣepọ̀ tí ó dára láàárín bàbá àti ọmọ bá wà, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ọlọ́yàyà máa ń wà níbẹ̀. Ọmọ kan tí a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ń fẹ́ láti bá bàbá rẹ̀ sọ̀rọ̀. Ọ̀kan náà ni ó jẹ́ òtítọ́ nígbà tí ó bá kan ọ̀ràn ipò-ìbátan wa pẹ̀lú Ọlọrun. Bí a bá mọrírì ohun tí a ń kọ́ nípa Jehofa àti ìfẹ́ tí ó fi hàn sí wa nítòótọ́, a óò ní ìfẹ́ ọkàn tí ó lágbára láti sọ èyí jáde fún un nínú àdúrà.—1 Johannu 4:16-18.
5 Nígbà tí a bá ń tọ Ọlọrun Ẹni Gíga Jùlọ náà lọ, a níláti ṣe èyí tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ìdí láti ṣàníyàn rékọjá ààlà nípa àwọn ọ̀rọ̀ tí a óò lò gan-an. (Heberu 4:16) Nígbà gbogbo ni a ní ọ̀nà láti dé ọ̀dọ̀ Jehofa. Ẹ sì wo àǹfààní tí ó jẹ́ pé a lè ‘tú ọkàn-àyà wa jáde’ sí Ọlọrun nínú àdúrà! (Orin Dafidi 62:8) Ìmọrírì fún Jehofa ń ṣamọ̀nà sí ipò-ìbátan ọlọ́yàyà pẹ̀lú rẹ̀, bí èyí tí ọkùnrin olùṣòtítọ́ náà Abrahamu gbádùn rẹ̀ bí ọ̀rẹ́ Ọlọrun. (Jakọbu 2:23) Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá ń gbàdúrà sí Oluwa Ọba-Aláṣẹ àgbáyé, a gbọ́dọ̀ mú ara bá àwọn ohun tí ó béèrè fún láti lè tọ̀ ọ́ lọ mu.
ÀWỌN OHUN TÍ A BÉÈRÈ FÚN LÁTI SÚNMỌ́ ỌLỌRUN
6, 7. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọrun kò béèrè fún owó láti gbọ́ àdúrà wa, kí ni ohun tí ó béèrè lọ́wọ́ wa nígbà tí a bá ń gbàdúrà?
6 A ha nílò owó kí a tó lè tọ Ọlọrun lọ bí? Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń sanwó fún àwùjọ àlùfáà láti gbàdúrà fún wọn. Àwọn kan tilẹ̀ gbàgbọ́ pé àwọn àdúrà wọn ni a óò gbọ́ ní ìbámu pẹ̀lú bí ìtọrẹ tí wọ́n ṣe ti tó. Bí ó ti wù kí ó rí, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kò sọ pé a nílò ìrúbọ owó kí a tó tọ Jehofa lọ nínú àdúrà. Àwọn ìpèsè tẹ̀mí àti ìbùkún níní ìbátan kan pẹ̀lú rẹ̀ nínú àdúrà wà lárọ̀ọ́wọ́tó láìsí sísan owó kankan.—Isaiah 55:1, 2.
7 Nígbà náà, kí ni a béèrè fún? Ipò ọkàn-àyà tí ó tọ́ jẹ́ ohun kan tí ó ṣe kókó. (2 Kronika 6:29, 30; Owe 15:11) Nínú ọkàn-àyà wa a gbọ́dọ̀ lo ìgbàgbọ́ nínú Jehofa Ọlọrun bí ‘ẹni tí ń gbọ àdúrà’ àti “olùsẹ̀san fún awọn wọnnì tí ń fi taratara wá a.” (Orin Dafidi 65:2; Heberu 11:6) A tún gbọ́dọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ní ọkàn-àyà. (2 Ọba 22:19; Orin Dafidi 51:17) Nínú ọ̀kan lára àwọn àkàwé rẹ̀, Jesu Kristi fi hàn pé nígbà tí onírẹ̀lẹ̀ agbowó-orí kan tí ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ní ọkàn-àyà ń tọ Ọlọrun lọ, ó fi ara rẹ̀ hàn ní olódodo ju Farisi agbéraga kan lọ. (Luku 18:10-14) Bí a ti ń tọ Ọlọrun lọ nínú àdúrà, ẹ jẹ́ kí a rántí pé “olúkúlùkù ènìyàn tí ó gbéraga ní àyà, ìríra ni lójú Oluwa.”—Owe 16:5.
8. Bí a bá fẹ́ kí Ọlọrun dáhùn àdúrà wa, láti inú kí ni a ti níláti wẹ ara wa mọ́?
8 Bí a bá fẹ́ kí Ọlọrun dáhùn àwọn àdúrà wa, a níláti wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀. Nígbà tí ọmọ-ẹ̀yìn Jakọbu fún àwọn mìíràn níṣìírí láti súnmọ́ Ọlọrun, ó fikún un pé: “Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, kí ẹ sì wẹ ọkàn-àyà yín mọ́ gaara, ẹ̀yin aláìnípinnu.” (Jakọbu 4:8) Kódà àwọn oníwà àìtọ́ pàápàá lè wá sínú ipò-ìbátan alálàáfíà pẹ̀lú Jehofa bí wọ́n bá ronúpìwàdà tí wọ́n sì fi ọ̀nà ìgbésí-ayé wọn àtijọ́ sílẹ̀. (Owe 28:13) Jehofa kò lè gbọ́ tiwa bí a bá wulẹ̀ ń díbọ́n pé a ti wẹ ọ̀nà wa mọ́ tónítóní nípa tẹ̀mí. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ pé: “Awọn ojú Jehofa ń bẹ lára awọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn; ṣugbọn ojú Jehofa lòdì sí awọn wọnnì tí ń ṣe awọn ohun búburú.”—1 Peteru 3:12.
9. Nípasẹ̀ ta ni a níláti tọ Jehofa lọ, èésìtiṣe?
9 Bibeli sọ pé: “Kò sí olóòótọ́ ènìyàn lórí ilẹ̀, tí ń ṣe rere tí kò sì dẹ́ṣẹ̀.” (Oniwasu 7:20) Nígbà náà o lè béèrè pé: ‘Nígbà náà, báwo ni a ṣe lè tọ Jehofa Ọlọrun lọ?’ Bibeli dáhùn pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá sì dá ẹ̀ṣẹ̀ kan, awa ní olùrànlọ́wọ́ kan lọ́dọ̀ Baba, Jesu Kristi, ẹni tí í ṣe olódodo.” (1 Johannu 2:1) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, a lè tọ Ọlọrun lọ pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ nípasẹ̀ Jesu Kristi, ẹni tí ó kú bí ìràpadà fún wa. (Matteu 20:28) Òun ni ipa ojú ọ̀nà kanṣoṣo tí a lè gbà tọ Jehofa Ọlọrun lọ. (Johannu 14:6) A kò gbọdọ̀ fojú kéré ìtóye ẹbọ ìràpadà Jesu kí a sì mọ̀ọ́mọ̀ máa dẹ́ṣẹ̀. (Heberu 10:26) Bí ó ti wù kí ó rí, bí a bá ń sa gbogbo ipá wa láti fàsẹ́yìn kúrò nínú ohun tí ó burú síbẹ̀ tí a ń ṣiṣe nígbà mìíràn, a lè ronúpìwàdà kí a sì tọrọ ìdáríjì lọ́dọ̀ Ọlọrun. Nígbà tí a bá tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn-àyà, òun yóò gbọ́ tiwa.—Luku 11:4.
ÀWỌN ÀKÓKÒ ÀǸFÀÀNÍ LÁTI BÁ ỌLỌRUN SỌ̀RỌ̀
10. Bí ó bá kan àdúrà, báwo ni a ṣe lè farawé Jesu, àwọn àkókò wo ni ó sì wà fún àdúrà ìkọ̀kọ̀?
10 Jesu Kristi mọyì ipò-ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú Jehofa gidigidi. Nítorí náà, Jesu wá àkókò láti bá Ọlọrun sọ̀rọ̀ nínú àdúrà ìkọ̀kọ̀. (Marku 1:35; Luku 22:40-46) A óò ṣe dáradára láti ṣàfarawé àpẹẹrẹ Jesu kí a sì gbàdúrà sí Ọlọrun déédéé. (Romu 12:12) Ó bá a mu láti bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ kan pẹ̀lú àdúrà, àti ṣáájú kí a tó sùn, pẹ̀lú ẹ̀tọ́ a lè dúpẹ́ lọ́wọ́ Jehofa fún ìgbòkègbodò ọjọ́ náà. Láàárín ọjọ́ náà, fi í ṣe góńgó kan láti tọ Ọlọrun lọ “ní gbogbo ìgbà.” (Efesu 6:18) A tilẹ̀ lè gbàdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́ nínú ọkàn-àyà wa, ní mímọ̀ pé Jehofa lè gbọ́ wa. Bíbá Ọlọrun sọ̀rọ̀ níkọ̀kọ̀ ń ràn wá lọ́wọ́ láti sọ ipò-ìbátan wa pẹ̀lú rẹ̀ di èyí tí ó fìdímúlẹ̀, gbígbàdúrà sí Jehofa lójoojúmọ́ sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ súnmọ́ ọn.
11. (a) Èéṣe tí àwọn ìdílé fi níláti gbàdúrà papọ̀? (b) Kí ni ó túmọ̀ sí nígbà tí o bá sọ pé “Àmín” ní òpin àdúrà kan?
11 Jehofa tún ń fetísílẹ̀ sí àwọn àdúrà tí a gbà fún ẹgbẹ́ àwùjọ ènìyàn. (1 Ọba 8:22-53) A lè súnmọ́ Ọlọrun bí ìdílé kan, pẹ̀lú olórí agboolé náà tí ó mú ipò iwájú. Èyí ń fún ìdè ìdílé lókun, Jehofa yóò sì wá di ẹni gidi fún àwọn ọ̀dọ́ náà bí wọ́n ti ń gbọ́ tí àwọn òbí wọn ń gbàdúrà sí Ọlọrun tìrẹ̀lẹ̀ tìrẹ̀lẹ̀. Bí ẹnì kan bá ń ṣojú fún àwùjọ nínú àdúrà, bóyá ní ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń kọ́? Bí a bá wà lára àwùjọ náà, ẹ jẹ́ kí a fetísílẹ̀ dáradára, kí á baà lè fi tọkàntọkàn ṣe “Àmín,” tí ó túmọ̀ sí “Bẹ́ẹ̀ ni kí ó rí,” ní òpin àdúrà náà.—1 Korinti 14:16.
ÀWỌN ÀDÚRÀ TÍ JEHOFA Ń GBỌ́
12. (a) Èéṣe tí Ọlọrun kì í fi í dáhùn àwọn àdúrà kan? (b) Èéṣe tí kò fi yẹ kí a pọkànpọ̀ sórí àwọn àìní ti ara-ẹni nìkan nígbà tí a bá ń gbàdúrà?
12 Àwọn kan lè nímọ̀lára pé Ọlọrun kò dáhùn àdúrà wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbàdúrà sí i nípasẹ̀ Kristi. Bí ó ti wù kí ó rí, aposteli Johannu sọ pé: “Ohun yòówù tí ìbáà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹlu ìfẹ́-inú [Ọlọrun], ó ń gbọ́ tiwa.” (1 Johannu 5:14) Wàyí o, nígbà náà, a níláti béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-inú Ọlọrun. Níwọ̀n bí ó ti lọ́kàn ìfẹ́ nínú ire aásìkí wa nípa tẹ̀mí, ohunkóhun tí ó lè kan ipò tẹ̀mí wa jẹ́ kókó tí ó bá a mu wẹ́kú fún àdúrà. A gbọ́dọ̀ dènà ìdẹwò náà láti pọkànpọ̀ pátápátá sórí àwọn àìní ti ara. Fún àpẹẹrẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó tọ́ láti gbàdúrà fún òye àti okun láti fàyàrán àìsàn, kò yẹ kí àníyàn nípa ìlera bo àwọn ire tẹ̀mí mọ́lẹ̀. (Orin Dafidi 41:1-3) Lẹ́yìn tí ó wá mọ̀ pé àníyàn rẹ̀ nípa ìlera rẹ̀ ti pọ̀ jù, Kristian obìnrin kan béèrè lọ́wọ́ Jehofa fún ìrànlọ́wọ́ láti ní ojú-ìwòye tí ó tọ́ nípa àìsàn rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí, ìṣòro ìlera rẹ̀ kò tóbi lójú rẹ̀ mọ́, ó sì nímọ̀lára pé a fún òun ní “agbára tí ó rékọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.” (2 Korinti 4:7) Ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí gbóná sí i, ó sì di olùpòkìkí Ìjọba alákòókò kíkún.
13. Bí a ti fi hàn nínú Matteu 6:9-13, kí ni àwọn kókó tí ó yẹ tí a lè fi sínú àwọn àdúrà wa?
13 Kí ni a lè fikún àdúrà wa kí ó baà lè wu Jehofa láti gbọ́ wọn? Jesu Kristi kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bí wọ́n ṣe níláti gbàdúrà. Nínú àdúrà àwòṣe tí a kọsílẹ̀ nínú Matteu 6:9-13, o fi àpẹẹrẹ kan ṣe ìlàlẹ́sẹẹsẹ àwọn kókó tí ó tọ́ tí a lè gbàdúrà fún. Kí ni ó yẹ kí ó jẹ́ olórí ìdàníyàn nínú àdúrà wa? Orukọ Jehofa Ọlọrun àti Ìjọba rẹ̀ gbọ́dọ̀ mú ipò iwájú. Bíbéèrè fún àwọn ohun ìní ti ara yẹ. Ó tún ṣe pàtàkì láti béèrè fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa àti fún ìdáǹdè lọ́wọ́ ìdẹwò àti ẹni ibi náà, Satani Èṣù. Jesu kò fẹ́ kí a máa sọ àsọtúnsọ àdúrà yìí tàbí ṣe àwítúnwí rẹ̀ léraléra, ní kíkà á láìronú lórí ohun tí ó túmọ̀ sí. (Matteu 6:7) Irú ipò-ìbátan wo ni yóò jẹ́ bí ọmọ kan bá lo àwọn ọ̀rọ̀ kan náà ní gbogbo ìgbà tí ó bá ń bá bàbá rẹ̀ sọ̀rọ̀?
14. Yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀bẹ̀, àdúrà wo ni ó yẹ kí a gbà?
14 Yàtọ̀ sí ẹ̀bẹ̀ àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ àtọkànwá, a níláti gbàdúrà ìyìn àti ìdúpẹ́. (Orin Dafidi 34:1; 92:1; 1 Tessalonika 5:18) A tún lè gbàdúrà fún àwọn mìíràn. Àwọn àdúrà nípa àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nípa tẹ̀mí tí a ń pọ́n lójú tàbí tí a ń ṣe inúnibíni sí fi ọkàn-ìfẹ́ wa hàn nínú wọn, ó sì wu Jehofa láti gbọ kí a sọ irú ìdàníyàn wa bẹ́ẹ̀ jáde. (Luku 22:32; Johannu 17:20; 1 Tessalonika 5:25) Níti tòótọ́, aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Ẹ máṣe máa ṣàníyàn nipa ohunkóhun, ṣugbọn ninu ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà ati ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ papọ̀ pẹlu ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ awọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọrun; àlàáfíà Ọlọrun tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yoo sì máa ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn-àyà yín ati agbára èrò-orí yín nípasẹ̀ Kristi Jesu.”—Filippi 4:6, 7.
Ẹ MÁA NÍ ÌFORÍTÌ NÍNÚ ÀDÚRÀ
15. Kí ni ó yẹ kí a rántí bí ó bá dàbí ẹni pé a kò rí ìdáhùn àwọn àdúrà wa?
15 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o ń jèrè ìmọ̀ nípa Ọlọrun, ó lè nímọ̀lára pé nígbà mìíràn o kò rí ìdáhùn àwọn àdúrà rẹ. Èyí lè rí bẹ́ẹ̀ nítorí ó lè má jẹ́ àkókò Ọlọrun láti dáhùn àwọn àdúrà pàtó kan. (Oniwasu 3:1-9) Jehofa lè yọ̀ǹda kí ipò kan máa báa lọ fún àkókò kan, ṣùgbọ́n ó ń dáhùn àdúrà ó sì mọ ìgbà tí ó dára jùlọ láti ṣe bẹ́ẹ̀.—2 Korinti 12:7-9.
16. Kí ni ìdí tí ó fi yẹ kí a tẹpẹlẹ mọ́ àdúrà gbígbà, báwo sì ni èyí ṣe lè nípa lórí ipò-ìbátan wa pẹ̀lú Ọlọrun?
16 Ìtẹpẹlẹmọ́ wa nínú àdúrà ṣí ìfẹ́ àtọkànwá tí a ní nínú ohun tí a ń bá Ọlọrun sọ payá. (Luku 18:1-8) Fún àpẹẹrẹ, a lè béèrè pé kí Jehofa ràn wá lọ́wọ́ láti borí àìlera kan. Nípa lílo ìforítì nínú àdúrà àti gbígbé ìgbésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a béèrè fún, a ń fi òtítọ́ inú wa hàn. A níláti ṣe pàtó kí a sì wà láìlábòsí nínú ohun tí a ń béèrè fún. Ó ṣe pàtàkì pàápàá láti gbàdúrà gbígbóná janjan nígbà tí a bá ń ní ìrírí ìdẹwò kan. (Matteu 6:13) Bí a ti ń bá a lọ láti gbàdúrà nígbà tí a ń gbìyànjú láti ṣàkóso ìrọni ẹ̀ṣẹ̀ tí a ní, a óò rí bí Jehofa yóò ṣe ràn wá lọ́wọ́. Èyí yóò gbé ìgbàgbọ́ wa ró yóò sì fún ipò-ìbátan wa pẹ̀lú rẹ̀ lókun.—1 Korinti 10:13; Filippi 4:13.
17. Báwo ni a óò ṣe jàǹfààní láti inú ìṣarasíhùwà láti gbàdúrà nínú iṣẹ́-ìsìn wa sí Ọlọrun?
17 Nípa mímú ìṣarasíhùwà láti gbàdúrà dàgbà nínú ṣíṣe iṣẹ́-ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ sí Jehofa Ọlọrun, a óò wá mọ̀ pé a kò sìn ín pẹ̀lú agbára tiwa fúnra wa. Jehofa ní ń mú kí àwọn nǹkan ṣeé ṣe. (1 Korinti 4:7) Mímọ èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ yóò sì mú ipò-ìbátan wa pẹ̀lú rẹ̀ sunwọ̀n sí i. (1 Peteru 5:5, 6) Bẹ́ẹ̀ni, a ní ìdí tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀ láti lo ìforítì nínú àdúrà. Àwọn àdúrà onífọkànsí wa àti ìmọ̀ ṣíṣeyebíye nípa bí a ṣe lè súnmọ́ Bàbá wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ yóò mú kí ìgbésí-ayé wa láyọ̀ nítòótọ́.
ÌJÙMỌ̀SỌ̀RỌ̀PỌ̀ PẸ̀LÚ JEHOFA KÌ Í ṢE ALÁPÁ KAN
18. Báwo ni a ṣe lè fetísílẹ̀ sí Ọlọrun?
18 Bí a bá fẹ́ kí Ọlọrun gbọ́ àwọn àdúrà wa, a gbọ́dọ̀ fetísílẹ̀ sí ohun tí o sọ. (Sekariah 7:13) Kò fi àwọn ìhìn-iṣẹ́ rẹ̀ ránṣẹ́ nípasẹ̀ àwọn wòlíì tí a mí sí látọ̀runwá mọ́, ó sì dájú pé kì í lo àwọn ọ̀nà ìbẹ́mìílò. (Deuteronomi 18:10-12) Ṣùgbọ́n a lè fetísílẹ̀ sí Ọlọrun nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Romu 15:4; 2 Timoteu 3:16, 17) Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti lè níláti mú ìtọ́wò fún oúnjẹ ti ara tí ó dára fún ara wa dàgbà, a rọ̀ wá láti “ní ìyánhànhàn kan fún wàrà aláìlábùlà tí ó jẹ́ ti ọ̀rọ̀ naa.” Mú ìtọ́wò fún oúnjẹ tẹ̀mí dàgbà nípa kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun lójoojúmọ́.—1 Peteru 2:2, 3; Ìṣe 17:11.
19. Àǹfààní wo ni ó wà nínú ṣíṣàṣàrò lórí ohun tí o kà nínú Bibeli?
19 Ṣe àṣàrò lórí ohun tí o kà nínú Bibeli. (Orin Dafidi 1:1-3; 77:11, 12) Ìyẹn túmọ̀ sí pé kí o ronú jinlẹ̀ lórí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà. O lè fi èyí wéra pẹ̀lú ọ̀nà tí òòlọ̀ rẹ gba ń ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ oúnjẹ. O lè ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ oúnjẹ tẹ̀mí nípa ṣíṣe ìsopọ̀ ohun tí o ń kà pẹ̀lú ohun tí o ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Ṣe àgbéyẹ̀wò bí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà ṣe nípa lórí ìgbésí-ayé rẹ, tàbí kí o ronú lórí ohun tí ó ṣípayá nípa àwọn ànímọ́ Jehofa àti ìbálò rẹ̀. Nípa báyìí nípasẹ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́, o lè gba oúnjẹ tẹ̀mí tí Jehofa pèsè sínú. Èyí yóò fà ọ́ súnmọ́ Ọlọrun yóò sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro ojoojúmọ́.
20. Báwo ni pípésẹ̀ sí àwọn ìpàdé Kristian ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti súnmọ́ Ọlọrun?
20 O tún lè súnmọ́ Ọlọrun nípa fífetísílẹ̀ sí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí a jíròrò ní àwọn ìpàdé Kristian, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Israeli ti fetísílẹ̀ dáradára nígbà tí wọ́n péjọ láti gbọ́ kíka Òfin Ọlọrun ní gbangba. Àwọn olùkọ́ni àkókò yẹn mú kí ohun tí wọ́n kà nínú Òfin ní ìtumọ̀, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ ran àwọn tí ó tẹ́tí sí wọn lọ́wọ́ láti lóye kí a sì sún wọn láti fi ohun tí wọ́n gbọ́ sílò. Èyí ṣamọ̀nà sí ìdùnnú-ayọ̀ ńláǹlà. (Nehemiah 8:8, 12) Nítorí náà sọ ọ́ di àṣà rẹ láti pésẹ̀ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. (Heberu 10:24, 25) Èyí yóò ràn ọ lọ́wọ́ láti lóye àti lẹ́yìn náà kí o fi ìmọ̀ Ọlọrun sílò nínú ìgbésí-ayé rẹ yóò sì mú ayọ̀ wá fún ọ. Jíjẹ́ apá kan ẹgbẹ́ àwọn ará Kristian kárí-ayé yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti súnmọ́ Jehofa. Bí a óò sì ti rí i, o lè rí ààbò tòótọ́ láàárín àwọn ènìyàn Ọlọrun.
DÁN ÌMỌ̀ RẸ WÒ
Kí ni ìdí tí o fi níláti súnmọ́ Jehofa?
Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tí a béèrè fún láti súnmọ́ Ọlọrun?
Kí ni o lè fikún àdúrà rẹ?
Èéṣe tí o fi níláti lo ìforítì nínú àdúrà?
Báwo ni o ṣe lè fetí sí Jehofa lónìí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 157]