ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 38
Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Tó O Ní fún Jèhófà Àtàwọn Ará Túbọ̀ Jinlẹ̀
“Mò ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi àti Baba yín.”—JÒH. 20:17.
ORIN 3 Agbára Wa, Ìrètí Wa, Ìgbọ́kànlé Wa
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Àjọṣe wo làwọn olóòótọ́ lè ní pẹ̀lú Jèhófà?
ÌDÍLÉ Jèhófà tóbi gan-an. Lára àwọn tó wà nínú ìdílé ẹ̀ ni Jésù tó jẹ́ “àkọ́bí nínú gbogbo ẹ̀dá” àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn áńgẹ́lì. (Kól. 1:15; Sm. 103:20) Nígbà tí Jésù wà láyé, ó jẹ́ kó ṣe kedere pé àwa èèyàn olóòótọ́ lè pe Jèhófà ní Bàbá wa. Nígbà tí Jésù ń bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ sọ̀rọ̀, ó pe Jèhófà ní “Baba mi àti Baba yín.” (Jòh. 20:17) Ìgbà tá a bá yara wa sí mímọ́ fún Jèhófà tá a sì ṣèrìbọmi la máa di ara ẹgbẹ́ ará tó kárí ayé.—Máàkù 10:29, 30.
2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Ó ṣòro fáwọn kan láti gbà pé Baba onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà. Àwọn míì sì lè má mọ bí wọ́n ṣe lè máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ohun tí Jésù ṣe ká lè gbà pé Baba onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà, a sì lè sún mọ́ ọn. Àá tún rí àwọn ọ̀nà tá a lè gbà fara wé Jèhófà nínú ìṣesí wa pẹ̀lú àwọn ará.
JÈHÓFÀ FẸ́ KÓ O SÚN MỌ́ ÒUN
3. Báwo ni àdúrà àwòṣe tí Jésù gbà ṣe lè mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?
3 Baba onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà, Jésù náà sì gbà bẹ́ẹ̀. Kódà, ojú tó fẹ́ káwa náà fi máa wo Jèhófà nìyẹn. Ó mọ̀ pé Baba tó ṣeé sún mọ́ ni, kì í ṣe apàṣẹwàá. Ìyẹn sì ṣe kedere nínú àdúrà àwòṣe tí Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀. Ohun tó fi bẹ̀rẹ̀ àdúrà náà ni: “Baba wa.” (Mát. 6:9) Jésù lè sọ fún wa pé ká máa pe Jèhófà ní “Olódùmarè,” “Ẹlẹ́dàá” tàbí “Ọba ayérayé.” Kò sì sóhun tó burú níbẹ̀ torí àwọn orúkọ oyè yẹn bá Bíbélì mu. (Jẹ́n. 49:25; Àìsá. 40:28; 1 Tím. 1:17) Kàkà bẹ́ẹ̀, “Baba” ni Jésù ní ká máa pe Jèhófà.
4. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ ká sún mọ́ òun?
4 Ṣé ó máa ń ṣòro fún ẹ láti gbà pé Baba onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà? Ó máa ń ṣe àwọn kan lára wa bẹ́ẹ̀. Tó bá jẹ́ pé bàbá tó bí wa kì í fìfẹ́ hàn sí wa, ó lè ṣòro fún wa láti gbà pé Baba onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà. Síbẹ̀, ó tuni nínú láti mọ̀ pé Jèhófà mọ bó ṣe ń ṣe wá àti ìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀ lára wa. Ó fẹ́ ká sún mọ́ òun. Ìdí nìyẹn tí Ọ̀rọ̀ ẹ̀ fi gbà wá níyànjú pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, á sì sún mọ́ yín.” (Jém. 4:8) Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì ṣèlérí pé òun máa jẹ́ Baba tó ju baba lọ fún wa.
5. Bó ṣe wà nínú Lúùkù 10:22, báwo ni Jésù ṣe lè mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?
5 Jésù lè mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Jésù mọ Jèhófà dáadáa, ó sì fìwà jọ ọ́ débi tó fi sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ti rí mi ti rí Baba náà.” (Jòh. 14:9) Bí ẹ̀gbọ́n kan ṣe máa ń kọ́ àwọn àbúrò ẹ̀, Jésù ti jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè máa bọ̀wọ̀ fún Jèhófà ká sì máa ṣègbọràn sí i. Yàtọ̀ síyẹn, ó jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tá a lè máa yẹra fún ká lè máa múnú Jèhófà dùn àti bá a ṣe lè rí ojúure ẹ̀. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, bí Jésù ṣe gbé ìgbésí ayé ẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ ká rí i pé Jèhófà jẹ́ onífẹ̀ẹ́ àti onínúure. (Ka Lúùkù 10:22.) Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ kan.
6. Sọ àpẹẹrẹ àwọn ìgbà tí Jèhófà fetí sí Jésù.
6 Jèhófà máa ń fetí sí àwọn ọmọ rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ìgbà tí Jèhófà fetí sí àkọ́bí Ọmọ rẹ̀. Ó dájú pé Jèhófà dáhùn àwọn àdúrà tí Jésù gbà nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. (Lúùkù 5:16) Jésù máa ń gbàdúrà kó tó ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó fẹ́ yan àwọn àpọ́sítélì méjìlá (12), ó gbàdúrà sí Jèhófà, Jèhófà sì gbọ́ àdúrà ẹ̀. (Lúùkù 6:12, 13) Jèhófà tún gbọ́ àdúrà tí Jésù gbà nígbà tó ní ìdààmú ọkàn. Káwọn alátakò tó wá mú Jésù, ó gbàdúrà gan-an sí Bàbá rẹ̀ nípa àwọn àdánwò líle koko tó máa tó kojú. Kì í ṣe pé Jèhófà gbọ́ àdúrà Jésù nìkan, ó tún rán áńgẹ́lì kan láti fún un lókun.—Lúùkù 22:41-44.
7. Báwo ló ṣe rí lára ẹ láti mọ̀ pé Jèhófà máa ń gbọ́ àdúrà wa?
7 Lónìí, Jèhófà ṣì máa ń gbọ́ àdúrà àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lásìkò tó tọ́ àti lọ́nà tó dáa jù lọ. (Sm. 116:1, 2) Ẹ jẹ́ ká wo bí arábìnrin kan ní Íńdíà ṣe rí ọ̀nà tí Jèhófà gbà dáhùn àdúrà ẹ̀. Ó ní ìdààmú ọkàn tó lékenkà, ó sì gbàdúrà sí Jèhófà gan-an nípa ẹ̀. Ó sọ pé: “Ètò JW Broadcasting® ti May 2019 tó sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè borí àníyàn àti ìdààmú ọkàn bọ́ sásìkò gẹ́lẹ́ fún mi. Ṣe ni Jèhófà fi ètò yẹn dáhùn àdúrà mi.”
8. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà fìfẹ́ hàn sí Jésù?
8 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì ń bójú tó wa, bó ṣe nífẹ̀ẹ́ Jésù tó sì bójú tó o nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. (Jòh. 5:20) Ó pèsè gbogbo ohun tí Jésù nílò nípa tara àti nípa tẹ̀mí, ó sì tún fún un lókun nígbà tó ní ìdààmú ọkàn. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà sọ fún Jésù pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, òun sì ti tẹ́wọ́ gbà á. (Mát. 3:16, 17) Ó dá Jésù lójú pé Bàbá òun nífẹ̀ẹ́ òun àti pé kò ní fi òun sílẹ̀ nígbàkigbà.—Jòh. 8:16.
9. Kí ló mú kó dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa?
9 Bíi ti Jésù, gbogbo wa la ti rí bí Jèhófà ṣe ń fìfẹ́ hàn sí wa lónírúurú ọ̀nà. Rò ó wò ná: Jèhófà jẹ́ ká di ọ̀rẹ́ òun, ó sì jẹ́ ká wà lára ẹgbẹ́ ará kárí ayé tó nífẹ̀ẹ́ wa. Wọ́n máa ń múnú wa dùn, wọ́n sì máa ń fún wa lókun tá a bá rẹ̀wẹ̀sì. (Jòh. 6:44) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún wa déédéé. Ó sì máa ń pèsè jíjẹ àti mímu fún wa lójoojúmọ́. (Mát. 6:31, 32) Tá a bá ń ronú nípa ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa, àá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ẹ̀.
ỌWỌ́ TÍ JÈHÓFÀ FI MÚ ÀWỌN ARÁ NI KÍ ÌWỌ NÁÀ FI MÚ WỌN
10. Kí la rí kọ́ nínú ọwọ́ tí Jèhófà fi ń mú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa?
10 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa gan-an. Àmọ́ nígbà míì, ó lè má rọrùn fún wa láti fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa. Ó ṣe tán, àṣà wa àti ibi tá a ti wá yàtọ̀ síra, gbogbo wa la sì máa ń ṣàṣìṣe tó lè bí àwọn míì nínú. Síbẹ̀, a lè mú kí ìfẹ́ tó wà láàárín wa túbọ̀ jinlẹ̀ sí i. Lọ́nà wo? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń fara wé bí Baba wa ọ̀run ṣe ń fìfẹ́ hàn sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa. (Éfé. 5:1, 2; 1 Jòh. 4:19) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo àwọn ọ̀nà tá a lè gbà fara wé Jèhófà.
11. Báwo ni Jésù ṣe fi “ojú àánú” hàn bíi ti Jèhófà?
11 Jèhófà máa ń fi “ojú àánú” hàn sí wa. (Lúùkù 1:78) Ó máa ń dun ẹni tó lójú àánú tó bá rí àwọn tó ń jìyà, ó sì máa ń wá bó ṣe máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kó sì tù wọ́n nínú. Jésù jẹ́ ká rí i nínú ọwọ́ tó fi mú àwọn èèyàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. (Jòh. 5:19) Nígbà kan tí Jésù rí àwọn èrò, “àánú wọn ṣe é, torí wọ́n dà bí àgùntàn tí a bó láwọ, tí a sì fọ́n ká láìní olùṣọ́ àgùntàn.” (Mát. 9:36) Àmọ́ kì í ṣe pé Jésù kàn káàánú wọn nìkan, ó tún wo àwọn aláìsàn sàn, ó sì pèsè ìtùnú fáwọn “tó ń ṣe làálàá, tí a [sì] di ẹrù wọ̀ lọ́rùn.”—Mát. 11:28-30; 14:14.
12. Sọ ọ̀nà tá a lè gbà máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa.
12 Ká tó lè máa fàánú hàn sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, a gbọ́dọ̀ mọ àwọn ìṣòro tí wọ́n ń kojú. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan lè ní àìsàn kan tó le gan-an. Kì í sábà sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro ẹ̀, àmọ́ inú ẹ̀ máa dùn gan-an tẹ́nì kan bá ràn án lọ́wọ́. A lè bi ara wa pé, báwo ló ṣe ń bójú tó àwọn nǹkan tí ìdílé ẹ̀ nílò? Ṣé inú ẹ̀ máa dùn tá a bá bá a dáná, tá a sì bá a tún ilé ṣe? Ká sọ pé iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ arákùnrin kan, kí la lè ṣe? Láìjẹ́ kó mọ̀, ṣé a lè fi owó díẹ̀ ránṣẹ́ sí i kó lè fi gbéra títí táá fi ríṣẹ́ míì?
13-14. Báwo la ṣe lè jẹ́ ọ̀làwọ́ bíi ti Jèhófà?
13 Ọ̀làwọ́ ni Jèhófà. (Mát. 5:45) Kò yẹ ká dúró dìgbà táwọn ará bá ní ká ran àwọn lọ́wọ́ ká tó ṣe bẹ́ẹ̀. Tá a bá ń ràn wọ́n lọ́wọ́, ṣe là ń fìwà jọ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ojoojúmọ́ ló ń mú kí oòrùn ràn láìjẹ́ pé a béèrè fún un. Gbogbo èèyàn ni ìtànṣán tó ń jáde lára oòrùn ń ṣe láǹfààní títí kan àwọn tí ò sin Jèhófà. Ṣẹ́yin náà gbà pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ló mú kó máa pèsè gbogbo nǹkan yìí fún wa? A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà ń fàánú hàn sí wa, ó sì ń pèsè gbogbo ohun tá a nílò.
14 Ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ń fara wé Baba wa ọ̀run ní ti pé wọ́n ń pèsè ohun táwọn ará wa míì nílò. Bí àpẹẹrẹ ní 2013, ìjì líle kan tí wọ́n pè ní Super Typhoon Haiyan ba nǹkan jẹ́ gan-an lórílẹ̀-èdè Philippines. Ọ̀pọ̀ àwọn ará ló pàdánù ilé wọn àti ohun ìní wọn. Àmọ́ àwọn ará kárí ayé ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ ló fowó ṣètìlẹ́yìn, àwọn míì sì tún yọ̀ǹda ara wọn láti tún àwọn ilé tó bà jẹ́ ṣe. Nípa bẹ́ẹ̀, ilé tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún méje ààbọ̀ (750) ni wọ́n tún kọ́ tàbí tún ṣe láàárín ọdún kan péré! Yàtọ̀ síyẹn lásìkò àrùn Corona, àwọn ará ṣiṣẹ́ gan-an láti ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn lọ́wọ́. Tá a bá ń tètè gbé ìgbésẹ̀ láti ran àwọn ará wa lọ́wọ́, ṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn.
15-16. Kí ni nǹkan pàtàkì tí Lúùkù 6:36 sọ pé ká máa ṣe ká lè fìwà jọ Jèhófà Baba wa ọ̀run?
15 Aláàánú ni Jèhófà, ó sì máa ń dárí jini. (Ka Lúùkù 6:36.) Ojoojúmọ́ là ń rọ́wọ́ àánú Jèhófà láyé wa. (Sm. 103:10-14) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù, Jésù fàánú hàn sí wọn, ó sì dárí jì wọ́n. Kódà, ó fẹ̀mí ẹ̀ lélẹ̀ ká lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. (1 Jòh. 2:1, 2) Ṣé kò wù ẹ́ láti sún mọ́ Jèhófà àti Jésù bó o ṣe mọ̀ pé aláàánú ni wọ́n, wọ́n sì máa ń dárí jini?
16 Ìfẹ́ tó wà láàárín wa máa túbọ̀ jinlẹ̀ tá a bá ń “dárí ji ara [wa] fàlàlà.” (Éfé. 4:32) Nígbà míì, kì í rọrùn láti dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ wá, síbẹ̀ a gbọ́dọ̀ sapá láti ṣe bẹ́ẹ̀. Arábìnrin kan sọ pé àpilẹ̀kọ náà “Ẹ Máa Dárí Ji Ara Yín Fàlàlà” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ ló ran òun lọ́wọ́.b Ó ní: “Àpilẹ̀kọ yẹn jẹ́ kí n rí i pé tí n bá ń dárí ji àwọn míì ó máa ṣe mí láǹfààní. Ó jẹ́ kí n mọ̀ pé bí ẹnì kan bá ní ẹ̀mí ìdáríjì, kò túmọ̀ sí pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń gba ìgbàkugbà láyè tàbí pé ó máa ń fojú kéré bọ́rọ̀ náà ṣe dùn ún tó. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa ń gbé ọ̀rọ̀ kúrò lọ́kàn, ìyẹn á sì jẹ́ kọ́kàn ẹ̀ balẹ̀.” Torí náà, tá a bá ń dárí ji àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ní fàlàlà, ṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, a sì ń fìwà jọ Jèhófà Baba wa ọ̀run.
MỌYÌ ÀǸFÀÀNÍ TÓ O NÍ LÁTI WÀ NÍNÚ ÌDÍLÉ JÈHÓFÀ
17. Bó ṣe wà nínú Mátíù 5:16, báwo la ṣe lè fògo fún Baba wa ọ̀run?
17 Àǹfààní ńlá la ní láti wà lára ẹgbẹ́ ará kárí ayé tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn. A fẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn dara pọ̀ mọ́ wa láti máa jọ́sìn Jèhófà. Torí náà, ó yẹ ká ṣọ́ra ká má bàa ṣe ohunkóhun tó máa kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà tàbí táá mú káwọn èèyàn máa fojú burúkú wo àwa èèyàn rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká máa hùwà lọ́nà tó máa bọlá fún Jèhófà, táá sì mú kó wu àwọn èèyàn láti wá sìn ín.—Ka Mátíù 5:16.
18. Kí ló máa jẹ́ ká lè wàásù láìbẹ̀rù?
18 Nígbà míì, àwọn kan lè máa rí sí wa tàbí kí wọ́n tiẹ̀ ṣenúnibíni sí wa torí pé à ń ṣègbọràn sí Baba wa ọ̀run. Tí ẹ̀rù bá ń bà wá láti sọ ohun tá a gbà gbọ́ fáwọn míì ńkọ́? Ó dájú pé Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ máa ràn wá lọ́wọ́. Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n má ṣàníyàn nípa bí wọ́n ṣe máa sọ̀rọ̀ àti ohun tí wọ́n máa sọ. Kí nìdí? Jésù fi kún un pé: “A máa fún yín ní ohun tí ẹ máa sọ ní wákàtí yẹn; torí kì í kàn ṣe ẹ̀yin lẹ̀ ń sọ̀rọ̀, àmọ́ ẹ̀mí Baba yín ló ń gbẹnu yín sọ̀rọ̀.”—Mát. 10:19, 20.
19. Sọ àpẹẹrẹ ẹnì kan tó wàásù láìbẹ̀rù.
19 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Robert. Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí ò sì tíì ní òye púpọ̀, ìjọba ilẹ̀ South Africa gbé e lọ sílé ẹjọ́ torí pé ó kọ̀ láti wọ iṣẹ́ ológun. Ó fìgboyà ṣàlàyé fún adájọ́ náà pé òun ò wọṣẹ́ ológun torí ìfẹ́ tóun ní fáwọn arákùnrin òun. Ẹ ò rí i pé ó mọyì àǹfààní tó ní láti wà nínú ìdílé Jèhófà. Ni adájọ́ náà bá bi í lójijì pé: “Àwọn wo ni arákùnrin ẹ?” Robert ò ronú pé wọ́n máa bi òun ní ìbéèrè yẹn, àmọ́ ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló rántí ẹ̀kọ́ ojúmọ́ ọjọ́ yẹn. Mátíù 12:50 ni wọ́n gbé e kà, tó ní: “Ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tó wà ní ọ̀run, ẹni yẹn ni arákùnrin mi, arábìnrin mi àti ìyá mi.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Robert ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni, ẹ̀mí Jèhófà ràn án lọ́wọ́ láti dáhùn ìbéèrè yẹn àtàwọn ìbéèrè míì tí ò retí. Ó dájú pé inú Jèhófà máa dùn sí Robert. Láìsí àní-àní, inú Jèhófà máa dùn sáwa náà tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé e, tá a sì fìgboyà wàásù láwọn ìgbà tí kò rọrùn.
20. Kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe? (Jòhánù 17:11, 15)
20 Ẹ jẹ́ ká túbọ̀ mọyì àǹfààní tá a ní láti wà nínú ìdílé onífẹ̀ẹ́ yìí. A ní Baba tó ju baba lọ, a sì ní ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó nífẹ̀ẹ́ wa. A ò gbọ́dọ̀ fojú kéré àǹfààní tá a ní yìí láé. Sátánì àtàwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ ń sapá láti mú ká máa ṣiyèméjì pé bóyá ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti da àárín wa rú. Àmọ́ Jésù ti gbàdúrà pé kí Jèhófà dáàbò bò wá, kó má sì jẹ́ kí Sátánì fa ìyapa láàárín wa. (Ka Jòhánù 17:11, 15.) Ó dájú pé Jèhófà ń dáhùn àdúrà yẹn. Bíi ti Jésù, ẹ má ṣe jẹ́ ká ṣiyèméjì láé pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì máa ràn wá lọ́wọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àtàwọn ará wa túbọ̀ jinlẹ̀ sí i.
ORIN 99 Ẹgbẹẹgbẹ̀rún Àwa Ará
a Inú wa dùn a sì mọyì àǹfààní tá a ní pé a wà láàárín àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó nífẹ̀ẹ́ wa. Gbogbo wa la fẹ́ kí ìfẹ́ tó wà láàárín wa túbọ̀ máa lágbára. Àmọ́ báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń fara wé bí Jèhófà ṣe ń fìfẹ́ hàn sí wa, tá a sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù àtàwọn ará wa.
c ÀWÒRÁN: Jèhófà rán áńgẹ́lì kan láti fún Jésù lókun nínú ọgbà Gẹ́tísémánì.
d ÀWÒRÁN: Lásìkò àrùn Corona, ọ̀pọ̀ ṣiṣẹ́ kára láti ṣètò oúnjẹ kí wọ́n sì pín in fáwọn ará.
e ÀWÒRÁN: Ọmọ kan ń kọ lẹ́tà sí arákùnrin kan tó wà lẹ́wọ̀n kó lè fún un lókun, ìyá ẹ̀ sì ń ràn án lọ́wọ́.