“Olúwa, Kọ́ Wa Bí A Ṣe Ń Gbàdúrà”
“Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé: ‘Olúwa, kọ́ wa bí a ṣe ń gbàdúrà.’”—LÚÙKÙ 11:1.
1. Kí nìdí tí ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe sọ pé kí Jésù kọ́ àwọn bí wọ́n á ṣe máa gbàdúrà?
NÍ ÌGBÀ kan tí Jésù ń gbàdúrà ní ọdún 32 Sànmánì Tiwa, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń wò ó. Ọmọ ẹ̀yìn náà kò gbọ́ ohun tí Jésù ń bá Bàbá rẹ̀ sọ, nítorí ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́ ni. Àmọ́ bí Jésù ti parí àdúrà rẹ̀ ni ọmọ ẹ̀yìn náà sọ fún un pé: “Olúwa, kọ́ wa bí a ṣe ń gbàdúrà.” (Lúùkù 11:1) Kí ló sún ọmọ ẹ̀yìn yìí láti béèrè ohun yìí? Àdúrà jẹ́ apá pàtàkì nínú ìgbésí ayé àti ìjọsìn àwọn Júù. Ìwé Sáàmù àti àwọn ibòmíràn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ní oríṣiríṣi àdúrà nínú. Nítorí náà, ọmọ ẹ̀yin náà kò béèrè fún ohun tó ṣàjèjì tàbí ohun tí kò ṣe rí. Ó dájú pé ó ti mọ bí àwọn aṣáájú ìsìn Júù ṣe máa ń gbàdúrà. Ṣùgbọ́n báyìí tó rí Jésù bó ṣe ń gbàdúrà, ó ṣeé ṣe kó ti ṣàkíyèsí pé ìyàtọ̀ ńlá ló wà nínú bí àwọn rábì tí wọ́n gbà pé àwọn jẹ́ olódodo jù àwọn yòókù lọ ṣe máa ń gbàdúrà àti bí Jésù ṣe ń gbàdúrà.—Mátíù 6:5-8.
2. (a) Kí ló fi hàn pé Jésù kò ni lọ́kàn pé kí á máa ka àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ náà lákàtúnkà bí a ṣe kọ̀ ọ́ sílẹ̀ gẹ́lẹ́? (b) Kí nìdí tá a fi fẹ́ láti mọ bí a ó ṣe máa gbàdúrà?
2 Jésù ti kọ́kọ́ fi àpẹẹrẹ bí a ṣe ń gbàdúrà lélẹ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nígbà Ìwàásù rẹ̀ lórí Òkè ní nǹkan bí oṣù méjìdínlógún ṣáájú àkókò yẹn. (Mátíù 6:9-13) Ó ṣeé ṣe kí ọmọ ẹ̀yìn yìí máà sí níbẹ̀ nígbà yẹn, ìdí nìyẹn tí Jésù fi rọra tún àwọn kókó tó wà nínú àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ náà sọ. Kókó kan tó gbàfiyèsí ni pé, kò tún àwọn ọ̀rọ̀ inú àdúrà náà sọ bó ṣe sọ ọ́ gẹ́lẹ́ nígbà àkọ́kọ́, èyí tó fi hàn pé kò kan kọ́ wa ní àdúrà àkọ́sórí tí a ó máa kà lákàtúnkà láìronú lé e lórí. (Lúùkù 11:1-4) Bíi ti ọmọ ẹ̀yìn tá ò dárúkọ yẹn, àwa náà fẹ́ kọ́ bí á ó ṣe máa gbàdúrà, ká bàa lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà dáadáa. Ẹ jẹ́ ká wá ṣàyẹ̀wò àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ yẹn lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Mátíù ṣe ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀. Ohun méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà nínú àdúrà náà, mẹ́ta nínú rẹ̀ kan àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe, mẹ́rin tó kù sì dá lórí àwọn ohun tá a nílò nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Àwọn ohun mẹ́ta àkọ́kọ́ là ó gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí.
Baba Onífẹ̀ẹ́ Kan
3, 4. Kí ló túmọ̀ sí láti pe Jèhófà ní “Baba wa”?
3 Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Jésù ti fi hàn pé àdúrà wa gbọ́dọ̀ fi hàn pé àjọṣe tímọ́tímọ́ wà láàárín àwa àti Jèhófà, síbẹ̀ ó gbọ́dọ̀ fi ọ̀wọ̀ hàn. Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ tó máa ṣe àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè ńlá yẹn làǹfààní, ó ní kí wọ́n bá Jèhófà sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bíi “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mátíù 6:9) Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé, bóyá èdè Hébérù tí gbogbo èèyàn ń sọ ni Jésù fi sọ̀rọ̀ ni o tàbí èdè Árámáíkì, ọ̀rọ̀ tó lò fún “Baba” fara jọ ‘èdè ọmọdé’ tó ń fi ìfẹ́ bá baba rẹ̀ sọ̀rọ̀. Bákan náà, bá a ṣe ń pe Jèhófà ní “Bàbá wa” fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti pé a ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àjọṣe tó wà láàárín àwa àti òun.
4 Nípá sísọ pé “Baba wa,” a tún ń fi hàn pé a wà lára ìdílé ńlá tó ní ọkùnrin àti obìnrin nínú, ìyẹn àwọn tó gbà pé Jèhófà ni Olùfúnni-Ní-Ìyè. (Aísáyà 64:8; Ìṣe 17:24, 28) Nípasẹ̀ ìgbàṣọmọ la fi sọ àwọn Kristẹni tí a fi ẹ̀mí bí dọmọ láti jẹ́ àwọn “ọmọ Ọlọ́run,” wọ́n sì ‘ké jáde sí Ọlọ́run pé: “Ábà, Baba!”’ (Róòmù 8:14, 15) Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn ló sì ti dúró ṣinṣin tì wọ́n. Àwọn wọ̀nyí ti ya ìgbésí ayé ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, wọ́n sì ti fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi. Gbogbo àwọn “àgùntàn mìíràn” wọ̀nyí náà lè tọ Jèhófà lọ nípasẹ̀ orúkọ Jésù kí wọ́n sì pè é ní “Baba wa.” (Jòhánù 10:16; 14:6) A lè lọ sọ́dọ̀ Baba wa ọ̀run déédéé nínú àdúrà ìyìn, ká dúpẹ́ fún àwọn ohun rere tó ń ṣe fún wa, ká sì tún kó àwọn ẹrù ìnira wa lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí a ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ó bìkítà fún wa.—Fílípì 4:6, 7; 1 Pétérù 5:6, 7.
Ìfẹ́ fún Orúkọ Jèhófà
5. Kí ni ohun tí a kọ́kọ́ bẹ̀bẹ̀ fún nínú àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ, kí nìdí tí èyí sì fi yẹ bẹ́ẹ̀?
5 Ọ̀rọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ àdúrà ẹ̀bẹ̀ yẹn fi ohun tó yẹ kó ṣáájú sí ipò àkọ́kọ́. Ó sọ pé: “Kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” (Mátíù 6:9) Bẹ́ẹ̀ ni o, ìsọdimímọ́ orúkọ Jèhófà yẹ kó jẹ wá lógún nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, a sì kórìíra ẹ̀gàn pelemọ táwọn èèyàn ti mú bá orúkọ rẹ̀. Ọ̀tẹ̀ tí Sátánì dì àti bó ṣe sún àwọn tọkọtaya àkọ́kọ́ láti ṣàìgbọràn sí Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ ohun tó ba orúkọ Ọlọ́run jẹ́ nípa mímú kí wọ́n máa ṣiyèméjì lórí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń lo ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ láyé àti lọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Síwájú sí i, látìgbà tí ìṣọ̀tẹ̀ àkọ́kọ́ ti wáyé ni àwọn tó sọ pé àwọn ń ṣojú fún Ọlọ́run ti fi ìwà àti ẹ̀kọ́ wọn tó ń tini lójú kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà.
6. Kí ni a ó yàgò fún bá a ṣe ń gbàdúrà pé kí orúkọ Jèhófà di èyí tí a sọ di mímọ́?
6 Àdúrà tá a bá gbà fún sísọ orúkọ Jèhófà di mímọ́ ló ń fi ìhà tá a wà hàn nínú ọ̀ràn ipò ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run, èyí túmọ̀ sí pé kí á dúró gbágbáágbá ti Jèhófà pé òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso ayé òun ọ̀run. Ohun tí Jèhófà ń fẹ́ ni pé kí àwọn onílàákàyè ẹ̀dá máa gbé lọ́run àti láyé, ìyẹn àwọn tó jẹ́ pé tinútinú àti tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n fi juwọ́ sílẹ̀ fún ìṣàkóso òdodo rẹ̀ nítorí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ohun gbogbo tí orúkọ rẹ̀ dúró fún. (1 Kíróníkà 29:10-13; Sáàmù 8:1; 148:13) Ìfẹ́ tá a ní fún orúkọ Jèhófà ní yóò ràn wá lọ́wọ́ láti yàgò fún ṣíṣe ohunkóhun tó lè kó ẹ̀gàn bá orúkọ mímọ́ yẹn. (Ìsíkíẹ́lì 36:20, 21; Róòmù 2:21-24) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kí àlàáfíà tó lè wà lágbàáyé àti fún àwọn olùgbé inú rẹ̀, orúkọ Jèhófà gbọ́dọ̀ di mímọ́, àwọn èèyàn sì gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́, nígbà náà, àdúrà wa pé “kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́” fi hàn pé a ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà yóò ṣe àwọn ohun tó fẹ́ ṣe kí á lè yìn ín.—Ìsíkíẹ́lì 38:23.
Ìjọba Tá À Ń Gbàdúrà Fún
7, 8. (a) Ìjọba wo ni Jésù kọ́ wa láti máa gbàdúrà fún? (b) Kí ni a rí kọ́ nípa Ìjọba yìí nínú ìwé Dáníẹ́lì àti ìwé Ìṣípayá?
7 Ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ tó ṣìkejì nínú àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ yìí ni: “Kí ìjọba rẹ dé.” (Mátíù 6:10) Ìbéèrè yìí jọ èyí tá a sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ níṣàájú. Ohun tí Jèhófà yóò lò láti sọ orúkọ rẹ̀ dí mímọ́ ni Ìjọba Mèsáyà, ìṣàkóso rẹ̀ ti ọ̀run, èyí tó ti fi Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀, ṣe Ọba lé lórí. (Sáàmù 2:1-9) Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì ṣàpèjúwe Ìjọba Mèsáyà náà gẹ́gẹ́ bí “òkúta kan” tí a gé kúrò lára “òkè ńlá” kan. (Dáníẹ́lì 2:34, 35, 44, 45) Òkè ńlá yẹn dúró fún ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ láyé àti lọ́run, Ìjọba tí òkúta náà ṣàpẹẹrẹ jẹ́ ọ̀nà tuntun tí Jèhófà yóò gbà ṣàkóso láyé àti lọ́run. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn, òkúta yẹn ‘di òkè ńlá tí ó tóbi, ó sì kún gbogbo ilẹ̀ ayé’ tó fi hàn pé Ìjọba Mèsáyà náà dúró fún agbára tí Ọlọ́run ní láti ṣàkóso lé ayé lórí.
8 Àwọn mìíràn tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ Kristi nínú ìṣàkóso Ìjọba yìí ni àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] “tí a ti rà láti inú gbogbo àwọn ènìyàn” láti bá a ṣàkóso bí ọba àti àlùfáà. (Ìṣípayá 5:9, 10; 14:1-4; 20:6) Dáníẹ́lì pe àwọn wọ̀nyí ní “àwọn ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ,” tó jẹ́ pé àwọn àti Kristi tó jẹ́ Orí wọn ni wọ́n jọ gba “ìjọba àti agbára ìṣàkóso àti ìtóbilọ́lá àwọn ìjọba lábẹ́ gbogbo ọ̀run. . . Ìjọba wọ́n jẹ́ ìjọba tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní àwọn ni gbogbo agbára ìṣàkóso yóò máa sìn, tí wọn yóò sì ṣègbọràn sí.” (Dáníẹ́lì 7:13, 14, 18, 27) Èyí gan-an ni ìṣàkóso ti ọ̀run tí Kristi kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà fún.
Kí Nìdí Tá A Tún Fi Ń Gbàdúrà Pé Kí Ìjọba Náà Dé?
9. Kí nìdí tó fi bá a mu pé ká máa gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé?
9 Nínú àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ tí Kristi gbà, ó kọ́ wa láti máa gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé. Ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé à ti fìdí Ìjọba Mèsáyà múlẹ̀ lọ́run ní ọdún 1914.a Ṣé ó wá bójú mu fún wa nígbà náà pé ká tún máa gbàdúrà pé kí Ìjọba yẹn “dé”? Bẹ́ẹ̀ ni, ó bọ́gbọ́n mu. Nítorí pé nínú àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, òkúta tó ṣàpẹẹrẹ Ìjọba Mèsáyà náà kọlu ère arabaríbí tó ṣàpẹẹrẹ ìṣàkóso olóṣèlú ti ènìyàn. Òkúta yẹn ṣì máa kọlu èrè náà, yóò sì fọ́ ọ túútúú. Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì sọ pé: “Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Dáníẹ́lì 2:44.
10. Kí nìdí tá a fi ń hára gàgà fún dídé Ìjọba Ọlọ́run?
10 À ń hára gàgà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé láti mú ètò àwọn nǹkan búburú Sátánì kúrò. Èyí yóò túmọ̀ sí sísọ orúkọ mímọ́ Jèhófà di mímọ́ àti mímú gbogbo àwọn tó ń ṣe àtakò ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ kúrò. Gbogbo ara la fi ń gbàdúrà pé: ‘Kí ìjọba yẹn dé,’ à sì ń dara pọ̀ mọ́ àpọ́sítélì Jòhánù ní sísọ pé: “Àmín! Máa bọ̀, Jésù Olúwa.” (Ìṣípayá 22:20) Bẹ́ẹ̀ ni o, kí Jésù dé láti wá sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́, kí ó sì dá ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ láre, kí ọ̀rọ̀ onísáàmù náà lè ṣẹ pé: “Kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, Ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 83:18.
“Kí Ìfẹ́ Rẹ Ṣẹ”
11, 12. (a) Kí ni ohun tí a ń béèrè nígbà tá a bá gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ “gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú”? (b) Kí ni ohun mìíràn tí àdúrà wa pé kí ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ tún túmọ̀ sí?
11 Jésù tún kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbàdúrà pé: “Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:10) Jèhófà dá àgbáálá ayé yìí nítorí pé ó wù ú láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn ẹ̀dá alágbára tó wà lọ́run fi ohùn rara wí pé: “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.” (Ìṣípayá 4:11) Jèhófà ní àwọn ohun kan lọ́kàn fún “àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.” (Éfésù 1:8-10) Bá a bá ń gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ, ohun tí à ń sọ ni pé kí Jèhófà mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ. Síwájú sí i, à ń fi hàn pé ó wù wá kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ láyé àtọ̀run.
12 Nípasẹ̀ àdúrà yìí, a tún ń fi hàn pé ó wù wá láti gbé ìgbésí ayé tó bá ìfẹ́ Jèhófà mu. Jésù sọ pé: “Oúnjẹ mi ni kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 4:34) Gẹ́gẹ́ bíi ti Jésù, inú àwa Kristẹni tó ti ya ara wa sí mímọ́ náà máa ń dùn láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ni kò jẹ́ ká máa gbé ìgbésí ayé wa “fún ìfẹ́-ọkàn ènìyàn mọ́, bí kò ṣe fún ìfẹ́ Ọlọ́run.” (1 Pétérù 4:1, 2; 2 Kọ́ríńtì 5:14, 15) À ń làkàkà láti máa yàgò fún ṣíṣe àwọn ohun tá a mọ̀ pé kò bá ìfẹ́ Jèhófà mu. (1 Tẹsalóníkà 4:3-5) Bí a bá ń wá àkókò fún kíká Bíbélì àti kíkẹ́kọ̀ọ́, a ó “máa bá a lọ ní ríróye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́,” èyí tó kan bí a ṣe ń kópa déédéé nínú wíwàásù “ìhìn rere ìjọba yìí.”—Éfésù 5:15-17; Mátíù 24:14.
Ìfẹ́ Jèhófà ní Ọ̀run
13. Báwo ni a ti ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí ìṣọ̀tẹ̀ Sátánì tó wáyé?
13 Ó ti pẹ́ gan-an tí wọ́n tí ń ṣe ìfẹ́ Jèhófà lọ́run kí ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ̀ nípa tẹ̀mí tó dìtẹ̀ tó si tipa bẹ́ẹ̀ di Sátánì. Ọgbọ́n tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ bí ènìyàn nínú ìwé Òwe ni àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run. Ó dájú pé à kò lè sọ ìgbà tí Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run tí “ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ níwájú [Baba] rẹ̀ ní gbogbo ìgbà” tí inú rẹ̀ sì ń dùn láti ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó di “àgbà òṣìṣẹ́” fún Jèhófà nínú dídá gbogbo ohun mìíràn “ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé, àwọn ohun tí a lè rí àti àwọn ohun tí a kò lè rí.” (Òwe 8:22-31; Kólósè 1:15-17) Jèhófà lo Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tàbí Agbọ̀rọ̀sọ.—Jòhánù 1:1-3.
14. Kí ni a lè rí kọ́ látinú Sáàmù 103 nípa bí àwọn áńgẹ́lì ṣe ń ṣe ìfẹ́ Jèhófà lọ́run?
14 Onísáàmù náà fi hàn pé ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ga ju ìṣẹ̀dá èyíkéyìí lọ àti pé ogunlọ́gọ̀ àwọn áńgẹ́lì ló ń ṣègbọràn tí wọ́n sì ń fetí sí àṣẹ rẹ̀. A kà pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ti fìdí ìtẹ́ rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in ní ọ̀run gan-an; àkóso rẹ̀ sì ń jọba lórí ohun gbogbo. Ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà, ẹ̀yin áńgẹ́lì rẹ̀, tí ẹ tóbi jọjọ nínú agbára, tí ẹ ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́, nípa fífetísí ohùn ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, ẹ̀yin òjíṣẹ́ rẹ̀, tí ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin iṣẹ́ rẹ̀, ní gbogbo ibi tí ó ń jọba lé [ìyẹn ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ].”—Sáàmù 103:19-22.
15. Báwo ni gbígbà tí Jésù gba agbára Ìjọba ṣe nípa lórí ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ní ọ̀run?
15 Lẹ́yìn tí Sátánì dìtẹ̀ tán, ó ṣì tún ń rí ọ̀nà àtidé àjùlé ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ìwé Jóòbù ṣe sọ. (Jóòbù 1:6-12; 2:1-7) Àmọ́ sá o, ìwé Ìṣípayá sọ tẹ́lẹ̀ pé àkókò kan ń bọ̀ tí á ó lé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò lọ́run. Kò pẹ́ rárá sí ìgbà tí Jésù Kristi gba agbára Ìjọba ní ọdún 1914 tí àkókò náà fi dé. Látìgbà náà ni kò ti sí àyè lọ́run mọ́ fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn. A ti lé wọn jù sí sàkání ayé. (Ìṣípayá 12:7-12) Kò sí ẹni tó fẹ́ gba ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ mọ́ lọ́run, ńṣe ni gbogbo àwọn tó wà lọ́run ń pa ohùn wọn pọ̀ láti yin “Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,” Kristi Jésù, tí wọ́n sì ń fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ yin Jèhófà. (Ìṣípayá 4:9-11) Láìṣe àní-àní, wọ́n ti ń ṣe ìfẹ́ Jèhófà lọ́run.
Ohun Tí Jèhófà Fẹ́ Ṣe fún Ayé Yìí
16. Báwo ni àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ ṣe fi hàn pé irọ́ gbuu ni ẹ̀kọ́ tí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni nípa ohun tí ìran ènìyàn ń retí?
16 Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti yọ ayé kúrò nínú ibi tí Ọlọ́run fẹ́ tún ṣe, wọ́n gbà pé ọ̀run ni gbogbo àwọn ẹni rere ń lọ. Ṣùgbọ́n Jésù kọ́ wa láti gbàdúrà pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:10) Ǹjẹ́ a wá lè fi gbogbo ẹnu sọ pé ìfẹ́ Jèhófà tí ń ṣẹ pátápátá nínú ayé yìí tó kún fún ìwà ipá, ìrẹ́nijẹ, àìsàn àti ikú? Rárá o! À gbọ́dọ̀ máa fi gbogbo ara gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé, gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí àpọ́sítélì Pétérù kọ sílẹ̀ pé: “Ọ̀run tuntun [Ìjọba Mèsáyà tí Kristi yóò ṣàkóso] àti ilẹ̀ ayé tuntun [àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn olódodo] wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.”—2 Pétérù 3:13.
17. Kí ni ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe fún ayé yìí?
17 Jèhófà ní ohun kan lọ́kàn kó tó dá ayé yìí. Ó mí sí wòlíì Aísáyà láti kọ̀wé pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, Ẹlẹ́dàá ọ̀run, Ẹni tí í ṣe Ọlọ́run tòótọ́, Aṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé àti Olùṣẹ̀dá rẹ̀, Òun tí í ṣe Ẹni tí ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, ẹni tí kò wulẹ̀ dá a lásán, ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀: ‘Èmi ni Jèhófà, kò sì sí ẹlòmíràn.’” (Aísáyà 45:18) Ọlọ́run fi tọkọtaya àkọ́kọ́ sínú ọgbà Párádísè, ó sì fún wọ́n ní ìtọ́ni pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28; 2:15) O ṣe kedere pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún ayé yìí ni pé kí ó kún fún ìran pípé tó jẹ́ ti àwọn ènìyàn olódodo, àwọn tí inú wọn dùn láti tẹrí ba fún ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, kí wọ́n sì máa wà láàyè títí láé nínú Párádísè tí Kristi ṣèlérí.—Sáàmù 37:11, 29; Lúùkù 23:43.
18, 19. (a) Kí ló gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ kí ìfẹ́ Ọlọ́run tó ṣẹ ní kíkún níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé? (b) Àpá wo la ó gbé yẹ̀ wò lára àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ tí Jésù kọ́ni nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí?
18 Ayé yìí kò lè rí bí Jèhófà ṣe fẹ́ kó rí níwọ̀n ìgbà tí àtọkùnrin àtobìnrin tó ń tàpá sí ọlá àṣẹ rẹ̀ bá ṣì wà níbẹ̀. Ọlọ́run yóò lo àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára ńlá lábẹ́ ìdarí Kristi láti “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” Ètò àwọn nǹkan burúkú Sátánì lápapọ̀, ìsìn èké rẹ̀, ètò ìṣèlú tó ti dómùkẹ̀, ètò ọrọ̀ ajé tó kún fún ìwọra òun àbòsí àti ohun ìjà ogun tó jẹ́ runlé rùnnà la óò pa run títí láé. (Ìṣípayá 11:18; 18:21; 19:1, 2, 11-18) A óò dá ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ láre, orúkọ rẹ̀ yóò sì di mímọ́. Gbogbo èyí là ń gbàdúrà fún nígbà tá a bá sọ pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—Mátíù 6:9, 10.
19 Bí ó ti wù kí ó rí, nínú àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ tí Jésù gbà, ó fi hàn pé a lè gbàdúrà nípa àwọn ọ̀ràn ti ara wa náà. Apá yìí nínú ohun tí Jésù kọ́ni nípa àdúrà la ó gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo orí kẹfà nínú ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì!, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe.
Àtúnyẹ̀wò
• Kí nìdí tó fi bá a mu gẹ́lẹ́ láti pé Jèhófà ní “Baba wa”?
• Kí nìdí tó fi jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ fún wa láti máa gbàdúrà pé kí orúkọ Jèhófà di èyí tí a sọ di mímọ́?
• Kí nìdí tá a fi ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé?
• Kí ló túmọ̀ sí láti gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé bíi ti ọ̀run?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Àdúrà Jésù yàtọ̀ pátápátá sí àdúrà ṣekárími ti àwọn Farisí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn Kristẹni ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, kí orúkọ rẹ̀ dí èyí tá a sọ di mímọ́, kí ìfẹ́ rẹ̀ sì di ṣíṣe