Pa Ìṣọ̀kan Mọ́ Ní Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Wọ̀nyí
“Kí ẹ máa hùwà ní irú ọ̀nà kan tí ó yẹ ìhìn rere . . . , [kí] ẹ dúró gbọn-ingbọn-in nínú ẹ̀mí kan, pẹ̀lú ọkàn kan tí ẹ ń làkàkà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ fún ìgbàgbọ́ ìhìn rere.”—FÍLÍPÌ 1:27.
1. Ìyàtọ̀ wo ni ó wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ayé?
“ÀWỌN ọjọ́ ìkẹyìn” nìwọ̀nyí. Láìsí àní-àní, “àwọn àkókò líle koko tí ó nira láti bá lò” ti wà níhìn-ín. (Tímótì Kejì 3:1-5) Ní “ìgbà ìkẹyìn” yìí, pẹ̀lú rúkèrúdò rẹ̀ tí ń bá àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn fínra, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dá yàtọ̀ gédégbé, nítorí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wọn. (Dáníẹ́lì 12:4) Ṣùgbọ́n a ń ké sí ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ó jẹ́ apá kan ìdílé àwọn olùjọsìn Jèhófà láti ṣiṣẹ́ kára láti pa ìṣọ̀kan yìí mọ́.
2. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ nípa pípa ìṣọ̀kan mọ́, ìbéèrè wo sì ni a óò gbé yẹ̀ wò?
2 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ létí láti pa ìṣọ̀kan mọ́. Ó kọ̀wé pé: “Kí ẹ máa hùwà ní irú ọ̀nà kan tí ó yẹ ìhìn rere nípa Kristi, kí ó lè jẹ́ pé, yálà mo wá wò yín tàbí n kò wá, kí n lè máa gbọ́ nípa àwọn ohun tí ó kàn yín, pé ẹ dúró gbọn-ingbọn-in nínú ẹ̀mí kan, pẹ̀lú ọkàn kan tí ẹ ń làkàkà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ fún ìgbàgbọ́ ìhìn rere, tí àwọn akọjúùjàsíni yín kò sì kó jìnnìjìnnì bá yín lọ́nàkọnà. Ohun yìí gan-an ni ẹ̀rí ìdánilójú ìparun fún wọn, ṣùgbọ́n ti ìgbàlà fún yín; ìtọ́kafihàn yìí sì wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (Fílípì 1:27, 28) Àwọn ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù fi hàn kedere pé, a gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, nígbà náà, kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti pa ìṣọ̀kan Kristẹni wa mọ́ ní àwọn àkókò adánniwò wọ̀nyí?
Jọ̀wọ́ Ara Rẹ fún Ìfẹ́ Ọlọ́run
3. Nígbà wo àti báwo ni àwọn Kèfèrí aláìkọlà àkọ́kọ́ ṣe di ọmọlẹ́yìn Kristi?
3 Ọ̀nà kan láti pa ìṣọ̀kan wa mọ́ ni láti jọ̀wọ́ ara wa fún ìfẹ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà. Èyí lè béèrè fún ṣíṣe àtúnṣe kan nínú ìrònú wa. Gbé ọ̀ràn àwọn Júù ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi ní ìjímìjí yẹ̀ wò. Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù kọ́kọ́ wàásù fún àwọn Kèfèrí aláìkọlà ní ọdún 36 Sànmánì Tiwa, Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ dà sórí àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí, a sì batisí wọn. (Ìṣe, orí 10) Títí di ìgbà yẹn, kìkì àwọn Júù, tí wọ́n di aláwọ̀ṣe ìsìn àwọn Júù, àti àwọn ará Samáríà nìkan ni wọ́n ṣì jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi.—Ìṣe 8:4-8, 26-38.
4. Lẹ́yìn ṣíṣàlàyé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Kọ̀nílíù, kí ni Pétérù sọ, ìdánwò wo sì ni èyí gbé dìde fún àwọn Júù ọmọlẹ́yìn Jésù?
4 Nígbà tí àwọn àpọ́sítélì àti àwọn arákùnrin mìíràn ní Jerúsálẹ́mù gbọ́ nípa ìyílọ́kànpadà Kọ̀nílíù àti àwọn Kèfèrí mìíràn, wọ́n fẹ́ gbọ́ ìròyìn lẹ́nu Pétérù. Lẹ́yìn ṣíṣàlàyé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Kọ̀nílíù àti àwọn Kèfèrí mìíràn tí wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́, àpọ́sítélì náà parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pé: “Nítorí náà, bí Ọlọ́run bá fi ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ kan náà [ti ẹ̀mí mímọ́] fún wọn [àwọn Kèfèrí onígbàgbọ́ wọ̀nyẹn] gẹ́gẹ́ bí òún ti fi fún wa pẹ̀lú [àwọn Júù] àwa tí a ti gba Jésù Kristi Olúwa gbọ́, ta ni èmi tí èmi yóò fi lè dí Ọlọ́run lọ́wọ́?” (Ìṣe 11:1-17) Èyí gbé ìdánwò kan dìde fún àwọn Júù ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi. Wọn yóò ha jọ̀wọ́ ara wọn fún ìfẹ́ Ọlọ́run, kí wọ́n sì tẹ́wọ́ gba àwọn Kèfèrí onígbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọn bí? Àbí wọn yóò wu ìṣọ̀kan àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé léwu?
5. Báwo ni àwọn àpọ́sítélì àti àwọn arákùnrin mìíràn ṣe dáhùn padà sí òtítọ́ náà pé Ọlọ́run ti dárí ji àwọn Kèfèrí, kí sì ni a lè kọ́ láti inú ìṣarasíhùwà wọn?
5 Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Wàyí o nígbà tí wọ́n [àwọn àpọ́sítélì àti àwọn arákùnrin mìíràn] gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, wọ́n gbà láìjampata, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, wí pé: ‘Tóò, nígbà náà, Ọlọ́run ti yọ̀ǹda ìrònúpìwàdà fún ète ìyè fún àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú.’” (Ìṣe 11:18) Ìṣarasíhùwà yẹn pa ìṣọ̀kan àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù mọ́, ó sì gbé e lárugẹ. Níwọ̀nba àkókò díẹ̀, iṣẹ́ ìwàásù tẹ̀ síwájú láàárín àwọn Kèfèrí, tàbí àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè, ìbùkún Jèhófà sì wà lórí irú ìgbòkègbodò bẹ́ẹ̀. Àwa pẹ̀lú ní láti gbà láìjampata nígbà tí a bá béèrè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wa nínú dídá ìjọ tuntun kan sílẹ̀ tàbí nígbà tí a bá ṣàtúnṣe ní ti ìlànà ìṣàkóso Ọlọ́run lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wa tọkàntọkàn yóò dùn mọ́ Jèhófà nínú, yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti pa ìṣọ̀kan wa mọ́ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí.
Dìrọ̀ Mọ́ Òtítọ́
6. Ipa wo ni òtítọ́ ní lórí ìṣọ̀kan àwọn olùjọsìn Jèhófà?
6 Gẹ́gẹ́ bí apá kan ìdílé àwọn olùjọsìn Jèhófà, a ń pa ìṣọ̀kan mọ́ nítorí pé, gbogbo wa ni a ‘kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà,’ tí a sì di òtítọ́ rẹ̀ tí a ṣí payá mú ṣinṣin. (Jòhánù 6:45; Orin Dáfídì 43:3) Níwọ̀n bí a ti gbé àwọn ẹ̀kọ́ wa ka orí Ọ̀rọ Ọlọ́run, gbogbo wa ń sọ̀rọ̀ ní ìfohùnṣọ̀kan. A ń fi tayọ̀tayọ̀ tẹ́wọ́ gba oúnjẹ tẹ̀mí tí Jèhófà ń pèsè nípasẹ̀ “olùṣòtítọ́ àti ọlọgbọ́n inú ẹrú.” (Mátíù 24:45-47) Irú ẹ̀kọ́ kan náà bẹ́ẹ̀ ń ràn wá lọ́wọ́ láti pa ìṣọ̀kan wa mọ́ kárí ayé.
7. Bí àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kán bá ní ìṣòro lílóye kókó kan, kí ni ó yẹ kí a ṣe, kí sì ni kò yẹ kí á ṣe?
7 Bí àwa fúnra wá bá ní ìṣòro lílóye tàbí títẹ́wọ́ gba kókó kan pàtó ńkọ́? A ní láti gbàdúrà fún ọgbọ́n, kí a sì ṣe ìwádìí nínú Ìwé Mímọ́ àti àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni. (Òwe 2:4, 5; Jákọ́bù 1:5-8) Ìjíròrò pẹ̀lú alàgbà lè ṣèrànwọ́. Bí a kò bá lóye kókó náà síbẹ̀, yóò dára kí a pa ọ̀ràn náà tì. Bóyá a óò tẹ ìsọfúnni síwájú sí i jáde lórí kókó ẹ̀kọ́ náà, tí òye wa yóò sì gbòòrò sí i. Bí ó ti wù kí ó rí, yóò jẹ́ ohun tí ó lòdì láti gbìyànjú láti yí àwọn mìíràn lérò padà nínú ìjọ láti tẹ́wọ́ gba èrò tiwa tí ó yàtọ̀. Èyí yóò jẹ́ dídá ìyapa sílẹ̀, kì í ṣe ṣíṣiṣẹ́ láti pa ìṣọ̀kan mọ́. Ẹ wo bí ó ti dára tó láti ‘máa bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́’ àti láti fún àwọn ẹlòmíràn níṣìírí láti ṣe bẹ́ẹ̀!—Jòhánù Kẹta 4.
8. Ìṣarasíhùwà wo sí òtítọ́ ni ó tọ́?
8 Ní ọ̀rúndún kìíní, Pọ́ọ̀lù wí pé: “Nísinsìnyí àwa ń ríran ní ìlà àwòrán fírífírí nípasẹ̀ jígí mẹ́tààlì, ṣùgbọ́n nígbà náà yóò jẹ́ ní ojúkojú. Nísinsìnyí mo mọ̀ lápá kan, ṣùgbọ́n nígbà náà èmi yóò mọ̀ lọ́nà pípéye àní gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ mí lọ́nà pípéye.” (Kọ́ríńtì Kìíní 13:12) Bí àwọn Kristẹni ìjímìjí kò tilẹ̀ rí gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀, wọ́n wà ní ìṣọ̀kan. Nísinsìnyí, a ní òye tí ó túbọ̀ ṣe kedere nípa ète Jèhófà àti Ọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a ṣọpẹ́ fún òtítọ́ tí a ti rí gbà nípasẹ̀ ‘olùṣòtítọ́ ẹrú’ náà. Ẹ sì jẹ́ kí a dúpẹ́ pé, Jèhófà ti fi ètò àjọ rẹ̀ ṣamọ̀nà wa. Bí a kò tilẹ̀ fìgbà gbogbo ní ìwọ̀n ìmọ̀ kan náà, ebi kò pa wá, bẹ́ẹ̀ sì ni òùngbẹ kò gbẹ wá nípa tẹ̀mí. Kàkà bẹ́ẹ̀, Olùṣọ́ Àgùntàn wa, Jèhófà, ti mú wa ṣọ̀kan ó sì ti tọ́jú wa dáradára.—Orin Dáfídì 23:1-3.
Lo Ahọ́n Lọ́nà Tí Ó Tọ́!
9. Báwo ni a ṣe lè lo ahọ́n láti gbé ìṣọ̀kan lárugẹ?
9 Lílo ahọ́n láti fún àwọn ẹlòmíràn níṣìírí jẹ́ ọ̀nà pàtàkì láti gbé ìṣọ̀kan àti ẹ̀mí ẹgbẹ́ àwọn ará lárugẹ. Lẹ́tà tí ó yanjú ọ̀ràn lórí ìkọlà, gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ olùṣàkóso ọ̀rúndún kìíní ti fi ránṣẹ́, jẹ́ orísun ìṣírí. Lẹ́yìn tí wọ́n kà á, àwọn Kèfèrí ọmọlẹ́yìn ní Áńtíókù “yọ̀ nítorí ìṣírí náà.” Júdásì àti Sílà, àwọn tí a fi lẹ́tà rán láti Jerúsálẹ́mù, “fi ọ̀pọ̀ àwíyé fún àwọn ará ní ìṣírí wọ́n sì fún wọn lókun.” Láìsí iyè méjì, wíwà níbẹ̀ Pọ́ọ̀lù àti Bánábà tún fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn ní Áńtíókù ní ìṣírí, ó sì fún wọn lókun. (Ìṣe 15:1-3, 23-32) A lè ṣe púpọ̀ lọ́nà kan náà nígbà tí a bá pé jọ fún àwọn ìpàdé Kristẹni, tí a sì “fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kíní kejì” nípa wíwà níbẹ̀ wa àti sísọ àwọn ọ̀rọ̀ ìlóhùnsí tí ń gbéni ró.—Hébérù 10:24, 25.
10. Láti pa ìṣọ̀kan mọ́, kí ni a lè ṣe bí kíkẹ́gàn bá ṣẹlẹ̀?
10 Síbẹ̀, ṣíṣi ahọ́n lò lè wu ìṣọ̀kan wa léwu. Ọmọlẹ́yìn náà Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Ahọ́n jẹ́ ẹ̀yà ara kékeré síbẹ̀ a sì máa ṣe ìfọ́nnu ńlá. Wò ó! Bí iná tí a fi ń dáná ran igbó igi tí ó tóbi gan-an ti kéré tó!” (Jákọ́bù 3:5) Jèhófà kórìíra àwọn tí ń dá asọ̀ sílẹ̀. (Òwe 6:16-19) Irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lè fa àìsí ìṣọ̀kan. Nígbà náà, bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, bí a bá ń kẹ́gàn ẹnì kan ńkọ́, ìyẹn ni pé, rírọ̀jò èébú sórí ẹnì kan tàbí sísọ̀rọ̀ àlùfààṣá sí i? Àwọn alàgbà yóò gbìyànjú láti ran oníwà àìtọ́ náà lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n, a ní láti yọ olùkẹ́gàn kan tí kò ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́ kí ìjọ baà lè wà ní àlàáfíà, létòlétò, kí a sì lè pa ìṣọ̀kan mọ́. Ó ṣe tán, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ jáwọ dídara pọ̀ nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí a pè ní arákùnrin tí ó jẹ́ . . . olùkẹ́gàn . . . , kí ẹ má tilẹ̀ bá irúfẹ́ ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹun.”—Kọ́ríńtì Kìíní 5:11.
11. Èé ṣe tí ìrẹ̀lẹ̀ fi ṣe pàtàkì bí a bá ti sọ ohun kan tí ó ti fa wàhálà láàárín wa àti ẹlẹgbẹ́ wa onígbàgbọ́?
11 Kíkó ahọ́n níjàánu ń ràn wá lọ́wọ́ láti pa ìṣọ̀kan mọ́. (Jákọ́bù 3:10-18) Ṣùgbọ́n ká ní ohun kan tí a sọ ti dá wàhálà sílẹ̀ láàárín wa àti Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa ńkọ́. Kì yóò ha tọ́ láti lo ìdánúṣe ní wíwá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin wa, kí a tọrọ àforíjì bí ó bá pọn dandan bí? (Mátíù 5:23, 24) Ní tòótọ́, èyí ń béèrè fún ìrẹ̀lẹ̀, tàbí ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ṣùgbọ́n Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú di ara yín lámùrè sí ara yín lẹ́nì kíní kejì, nítorí Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.” (Pétérù Kìíní 5:5) Ìrẹ̀lẹ̀ yóò sún wa láti ‘lépa àlàáfíà’ pẹ̀lú àwọn arákùnrin wa, ní títẹ́wọ́ gba àṣìṣe wa, kí a sì tọrọ àforíjì tí ó tọ́. Èyí ń ṣèrànwọ́ láti pa ìṣọ̀kan ìdílé Jèhófà mọ́.—Pétérù Kìíní 3:10, 11.
12. Báwo ni a ṣe lè lo ahọ́n wa láti gbé ìṣọ̀kan àwọn ènìyàn Jèhófà lárugẹ, kí a sì pa á mọ́?
12 A lè gbé ẹ̀mí ìdílé tí ó wà láàárín àwọn tí ó wà nínú ètò àjọ Jèhófà lárugẹ bí a bá lo ahọ́n wa lọ́nà tí ó tọ́. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe nìyẹn, ó lè rán àwọn ará Tẹsalóníkà létí pé: “Ẹ̀yín mọ̀ dáadáa bí a ti ń bá a nìṣó ní gbígba ẹnì kọ̀ọ̀kan yín níyànjú, àti ní rírẹ̀ yín lẹ́kún àti ní jíjẹ́rìí yín, bí bàbá ti ń ṣe sí àwọn ọmọ rẹ̀, fún ète pé kí ẹ lè máa bá a lọ ní rírìn lọ́nà tí ó yẹ Ọlọ́run.” (Tẹsalóníkà Kìíní 2:11, 12) Níwọ̀n bí ó ti fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ ní ọ̀nà yìí, Pọ́ọ̀lù lè rọ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti “sọ̀rọ̀ ìrẹ̀lẹ́kún fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́.” (Tẹsalóníkà Kìíní 5:14) Ronú nípa ọ̀pọ̀ ohun rere tí a lè ṣe nípa lílo ahọ́n wa láti rẹni lẹ́kún, láti fúnni níṣìírí, àti láti gbé àwọn ẹlòmíràn ró. Bẹ́ẹ̀ ni, “ẹ . . . wo bí ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò rẹ̀ ti dára tó!” (Òwe 15:23, NW) Ní àfikún sí i, irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ń ṣèrànwọ́ láti gbé ìṣọ̀kan àwọn ènìyàn Jèhófà lárugẹ, kí ó sì pa á mọ́.
Jẹ́ Adáríjini!
13. Èé ṣe tí a fi ní láti jẹ́ adáríjini?
13 Dídárí ji olùṣeláìfí kan tí ó tọrọ àforíjì ṣe kókó bí a bá ní láti pa ìṣọ̀kan Kristẹni mọ́. Ìgbà mélòó sì ni a ní láti máa dárí jini? Jésù sọ fún Pétérù pé: “Kì í ṣe, Títí dé ìgbà méje, bí kò ṣe, Títí dé ìgbà àádọ́rin lé méje.” (Mátíù 18:22) Bí a bá jẹ́ aláìlèdáríjini, ara wa ni a ń ṣe. Lọ́nà wo? Tóò, kèéta àti dídi kùnrùngbùn yóò já àlàáfíà ọkàn gbà mọ́ wa lọ́wọ́. Bí a bá sì mọ̀ wá bí-ẹní-mowó fún jíjẹ́ òǹrorò àti aláìlèdáríjini, a lè máa yọ ara wa lẹ́nu. (Òwe 11:17) Dídi kùnrùngbùn kò dùn mọ́ Ọlọ́run nínú, ó sì lè yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀ lílé kenkà. (Léfítíkù 19:18) Rántí pé a bẹ́ Jòhánù Olùbatisí lórí látàrí ìhùmọ̀ tí Hẹrodíà onínú burúkú ṣe, ẹni tí ó “di kùnrùngbùn” sí i.—Máàkù 6:19-28.
14. (a) Kí ni Mátíù 6:14, 15 kọ́ wa nípa ìdáríjì? (b) A ha gbọ́dọ̀ máa fìgbà gbogbo dúró de títọrọ àforíjì kí a tó lè dárí ji ẹnì kan bí?
14 Àdúrà àwòkọ́ṣe tí Jésù gbà ní àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nínú: “Dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, nítorí àwa fúnra wa pẹ̀lú a máa dárí ji olúkúlùkù ẹni tí ó jẹ wá ní gbèsè.” (Lúùkù 11:4) Bí a bá jẹ́ aláìlèdáríjini, ewu náà ń bẹ pé lọ́jọ́ kan, Jèhófà Ọlọ́run yóò dẹ́kun dídárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, nítorí Jésù sọ pé: “Bí ẹ̀yín bá dárí aṣemáṣe àwọn ènìyàn jì wọ́n, Bàbá yín ọ̀run yóò dárí jì yín pẹ̀lú; nígbà tí ó jẹ́ pé bí ẹ kò bá dárí aṣemáṣe àwọn ènìyàn jì wọ́n, Bàbá yín kì yóò dárí àwọn aṣemáṣe yín jì yín.” (Mátíù 6:14, 15) Nítorí náà bí a bá kúkú fẹ́ ṣe ipa tiwa nínú pípa ìṣọ̀kan inú ìdílé àwọn olùjọsìn ti Jèhófà mọ́, a óò jẹ́ adáríjini, bóyá nípa wíwulẹ̀ gbàgbé láìfí kan tí ó lè jẹ́ nítorí àìbìkítà, tí kò sì ní ète búburú kankan nínú. Pọ́ọ̀lù wí pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífara dà á fún ara yín lẹ́nì kíní kejì kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kíní kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní èrèdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe.” (Kólósè 3:13) Nígbà tí a bá jẹ́ adáríjini, a ń ṣèrànwọ́ láti pa ìṣọ̀kan ṣíṣeyebíye ti ètò àjọ Jèhófà mọ́.
Ìṣọ̀kan àti Ìpinnu Ara Ẹni
15. Kí ní ń ran àwọn ènìyàn Jèhófà lọ́wọ́ láti pa ìṣọ̀kan mọ́ nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìpinnu ara ẹni?
15 Ọlọ́run dá wa ní ẹ̀dá olómìnira ìwà híhù tí yóò jíhìn fún ìgbésẹ̀ rẹ̀, pẹ̀lú àǹfààní àti ẹrù iṣẹ́ láti ṣe ìpinnu ara ẹni. (Diutarónómì 30:19, 20; Gálátíà 6:5) Síbẹ̀, ó ṣeé ṣe fún wa láti pa ìṣọ̀kan mọ́ nítorí pé a ń tẹ̀ lé àwọn òfin àti ìlànà Bíbélì. A ń gbé wọn yẹ̀ wò nígbà tí a bá ń ṣe ìpinnu ara ẹni. (Ìṣe 5:29; Jòhánù Kìíní 5:3) Ká ní ìbéèrè kán dìde nípa àìdásí tọ̀tún tòsì ńkọ́. A lè ṣe ìpinnu ara ẹni tí a gbé ka ìsọfúnni nípa rírántí pé, àwa “kì í ṣe apá kan ayé,” a sì ti ‘fi idà wa rọ ọ̀bẹ píláù.’ (Jòhánù 17:16; Aísáyà 2:2-4) Lọ́nà kan náà, nígbà tí a bá gbọ́dọ̀ ṣe ìpinnu ara ẹni tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ipò ìbátan wa pẹ̀lú Orílẹ̀-Èdè, a ń gbé ohun tí Bíbélì sọ nípa sísan “ohun ti Ọlọ́run” padà “fún Ọlọ́run” yẹ̀ wò, nígbà tí a sì ń fi ara wa sábẹ́ “àwọn aláṣẹ onípò gíga” nínú ọ̀ràn ayé. (Lúùkù 20:25; Róòmù 13:1-7; Títù 3:1, 2) Bẹ́ẹ̀ ni, gbígbé àwọn òfin àti ìlànà Bíbélì yẹ̀ wò nígbà tí a bá ń ṣe ìpinnu ara ẹni ń ṣèrànwọ́ láti pa ìṣọ̀kan Kristẹni wa mọ́.
16. Báwo ni a ṣe lè ṣèrànwọ́ láti pa ìṣọ̀kan mọ́ nígbà tí a bá ń ṣe ìpinnu tí kò kan òfin tàbí ìlànà Ìwé Mímọ́? Ṣàkàwé.
16 A lè ṣèrànwọ́ láti pa ìṣọ̀kan Kristẹni mọ́ àní nígbà tí a bá ń ṣe ìpinnu tí ó jẹ́ ti ara ẹni pátápátá tí kò kan òfin tàbí ìlànà Ìwé Mímọ́. Lọ́nà wo? Nípa fífi ìfẹ́ hàn sí àwọn ẹlòmíràn tí ìpinnu wa lé nípa lé lórí. Láti ṣàkàwé: Nínú ìjọ Kọ́ríńtì ìgbàanì, ìbéèrè kan dìde nípa ẹran àpabọ òrìṣà. Dájúdájú, Kristẹni kan kì yóò lọ́wọ́ nínú ayẹyẹ ìbọ̀rìṣà. Ṣùgbọ́n, kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ láti jẹ irú àṣẹ́kù ẹran yìí tí a dú lọ́nà tí ó tọ́, tí a sì gbé wá sí ọjà láti tà. (Ìṣe 15:28, 29; Kọ́ríńtì Kìíní 10:25) Síbẹ̀, ẹ̀rí ọkàn àwọn Kristẹni kan dà wọ́n láàmú lóri jíjẹ ẹran yìí. Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni láti yẹra fún mímú wọn kọsẹ̀. Kódà, ó kọ̀wé pé: “Bí oúnjẹ bá mú arákùnrin mi kọsẹ̀, dájúdájú èmi kì yóò tún jẹ ẹran rárá láé, kí èmi má baà mú arákùnrin mi kọsẹ̀.” (Kọ́ríńtì Kìíní 8:13) Nítorí náà, bí kò bá kan òfin tàbí ìlàna Bíbélì kankan pàápàá, ẹ wo bí ó ṣe fi ìfẹ́ hàn tó láti gba ti àwọn ẹlòmíràn rò nígbà tí a bá ń ṣe ìpinnu ara ẹni tí ó lè nípa lórí ìṣọ̀kan ìdílé Ọlọ́run!
17. Kí ni ó dára láti ṣe nígbà tí a bá gbọ́dọ̀ ṣe ìpinnu ara ẹni?
17 Bí a kò bá mọ ìgbésẹ̀ tí ó yẹ kí a gbé, ó bọ́gbọ́n mu láti pinnu lọ́nà kan tí yóò jẹ́ kí a ní ẹ̀rí ọkàn mímọ́ tónítóní, tí àwọn ẹlòmíràn yóò sì bọ̀wọ̀ fún ìpinnu wa. (Róòmù 14:10-12) Àmọ́ ṣáá o, nígbà tí a bá gbọ́dọ̀ ṣe ìpinnu ara ẹni, a ní láti wá ìdarí Jèhófà nínú àdúrà. Gẹ́gẹ́ bí onísáàmù náà, a lè fi ìgbọ́kànlé gbàdúrà pé: “Dẹ etí rẹ sílẹ̀ sí mi: . . . Nítorí ìwọ ni àpáta mi àti odi mi: nítorí náà nítorí orúkọ rẹ máa ṣe ìtọ́ mi, kí o sì máa ṣe amọ̀nà mi.”—Orin Dáfídì 31:2, 3.
Máa Pa Ìṣọ̀kan Kristẹni Mọ́ Nígbà Gbogbo
18. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàkàwé ìṣọ̀kan ìjọ Kristẹni?
18 Ní Kọ́ríńtì Kìíní orí 12, Pọ́ọ̀lù lo ara ẹ̀dá ènìyàn láti ṣàkàwé ìṣọ̀kan ìjọ Kristẹni. Ó tẹnu mọ́ bí wọ́n ṣe sinmi léra wọn àti ìjẹ́pàtàkì ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Pọ́ọ̀lù béèrè pé: “Bí gbogbo wọ́n bá jẹ́ ẹ̀yà ara kan ṣoṣo, níbo ni ara yoo wà? Ṣùgbọ́n nísinsìnyí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà ara púpọ̀, síbẹ̀ ara kan ṣoṣo. Ojú kò lè wí fún ọwọ́ pé: ‘Èmi kò nílò rẹ’; tàbí, ẹ̀wẹ̀, orí kò lè wí fún àwọn ẹsẹ̀ pé: ‘Emi kò nílò yín.’” (Kọ́ríńtì Kìíní 12:19-21) Lọ́nà kan náà, kì í ṣe gbogbo wa nínú ìdílé àwọn olùjọsìn Jèhófà ní ń ṣe iṣẹ́ kan náà. Síbẹ̀, a wà ní ìṣọ̀kan, a sì nílò ara wa lẹ́nì kíní kejì.
19. Báwo ni a ṣe lè jàǹfààní láti inú ìpèsè Ọlọ́run nípa tẹ̀mí, kí sì ni arákùnrin àgbàlagbà kan sọ nípa èyí?
19 Gẹ́gẹ́ bí ará ṣe nílò oúnjẹ, àbójútó, àti ìtọ́sọ́nà, a nílò ìpèsè tẹ̀mí tí Ọlọ́run ń fún wa nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí rẹ̀, àti ètò àjọ rẹ̀. Láti lè jàǹfààní nínú àwọn ìpèsè wọ̀nyí, a gbọ́dọ̀ jẹ́ apá kan ìdílé Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, arákùnrin kan kọ̀wé pé: “Mo dúpẹ́ pé mo ti gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ nípa àwọn ète Jèhófà láti àwọn ìgbà àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ṣáájú ọdún 1914 nígbà tí gbogbo rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe kedere . . . títí di ọjọ́ òní tí òtítọ́ náà ń tàn bí oòrùn ọjọ́kanrí. Bí ohunkóhun bá wà tí ó ṣe pàtàkì fún mi, ọ̀ràn sísún mọ́ ètò àjọ Jèhófà tí a lè fojú rí ni. Ìrírí mí nígbà àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kọ́ mi bí kò ti lọ́gbọ́n nínú tó láti gbára lé ìrònú ẹ̀dá ènìyàn. Gbàrà tí mo ti parí èrò lórí kókó yẹn, mo pinnu láti dúró ti ètò àjọ olùṣòtítọ́ náà. Báwo tún ni ẹnì kan ṣe lè rí ojú rere Jèhófà àti ìbùkún rẹ̀ gbà?”
20. Kí ni ó yẹ kí a pinnu láti ṣe nípa ìṣọ̀kan wa gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Jèhófà?
20 Jèhófà ti pe àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde kúrò nínú òkùnkùn ayé àti àìsí ìṣọ̀kan. (Pétérù Kìíní 2:9) Ó ti mú wa wá sínú ìṣọ̀kan oníbùkún pẹ̀lú ara rẹ̀ àti pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa. Ìṣọ̀kan yìí yóò wà nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan tuntun tí ó sún mọ́lé pẹ́kípẹ́kí. Nítorí náà, ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, ẹ jẹ́ kí a máa bá a nìṣó láti ‘fi ìfẹ́ wọ ara wa ní aṣọ,’ kí a sì ṣe ohun gbogbo tí a bá lè ṣe láti gbé ìṣọ̀kan ṣíṣeyebíye wa lárugẹ, kí a sì pa á mọ́.—Kólósè 3:14.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Èé ṣe tí ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run àti dídìrọ̀ mọ́ òtítọ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti pa ìṣọ̀kan mọ́?
◻ Báwo ni ìṣọ̀kan ṣe ní ìsopọ̀ pẹ̀lú lílo ahọ́n lọ́nà títọ́?
◻ Kí ni ó wé mọ́ jíjẹ́ adáríjini?
◻ Báwo ni a ṣe lè pa ìṣọ̀kan mọ́ nígbà tí a bá ń ṣe ìpinnu ara ẹni?
◻ Èé ṣe tí a fi ní láti pa ìṣọ̀kan Kristẹni mọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Bí olùṣọ́ àgùntàn yìí ṣe ń mú kí agbo àgùntàn rẹ̀ wà pa pọ̀, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ṣe ń mú kí àwọn ènìyàn rẹ̀ wà ní ìṣọ̀kan
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Nípa fífi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ tọrọ àforíjì nígbà tí a bá ṣe láìfí, a ń ṣèrànwọ́ láti gbé ìṣọ̀kan lárugẹ