Ìwé Kẹta Jòhánù
1 Àgbà ọkùnrin,* sí Gáyọ́sì, ẹni ọ̀wọ́n, tí mo nífẹ̀ẹ́ tọkàntọkàn.
2 Ẹni ọ̀wọ́n, bí nǹkan ṣe ń lọ dáadáa fún ọ,* àdúrà mi ni pé kí gbogbo nǹkan túbọ̀ máa lọ dáadáa fún ọ, kí ara rẹ sì máa le. 3 Nítorí inú mi dùn gan-an nígbà tí àwọn ará dé, tí wọ́n sì jẹ́rìí sí i pé o rọ̀ mọ́ òtítọ́, bí o ṣe ń rìn nínú òtítọ́.+ 4 Kò sí ohun tó ń mú inú mi dùn* bíi kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń rìn nínú òtítọ́.+
5 Ẹni ọ̀wọ́n, ohun tí ò ń ṣe fún àwọn ará, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àlejò ni wọ́n jẹ́ sí ọ,+ fi hàn pé o jẹ́ olóòótọ́. 6 Wọ́n jẹ́rìí níwájú ìjọ sí ìfẹ́ tí o ní. Tí wọ́n bá ti ń lọ, jọ̀wọ́ ràn wọ́n lọ́wọ́ ní ọ̀nà tí inú Ọlọ́run dùn sí.+ 7 Ìdí ni pé torí orúkọ rẹ̀ ni wọ́n ṣe jáde lọ, láìgba ohunkóhun+ lọ́wọ́ àwọn aláìgbàgbọ́. 8 Torí náà, ó di dandan pé ká fi aájò àlejò hàn sí àwọn ẹni bẹ́ẹ̀,+ ká lè jọ máa ṣiṣẹ́ nínú òtítọ́.+
9 Mo kọ̀wé kan sí ìjọ, àmọ́ Díótíréfè tó fẹ́ fi ara rẹ̀ ṣe olórí láàárín wọn,+ kì í fi ìrẹ̀lẹ̀ gba ohunkóhun tí a bá sọ.+ 10 Torí náà, tí mo bá dé, màá sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ń ṣe, bó ṣe ń bà wá jẹ́ káàkiri.*+ Kò fi mọ síbẹ̀ o, kì í tẹ́wọ́ gba àwọn ará,+ kò sì bọ̀wọ̀ fún wọn. Kódà, ó tún ń ṣèdíwọ́ fún àwọn tó fẹ́ gbà wọ́n, ó sì fẹ́ lé wọn kúrò nínú ìjọ.
11 Ẹni ọ̀wọ́n, má ṣe tẹ̀ lé àpẹẹrẹ búburú, àpẹẹrẹ rere ni kí o máa tẹ̀ lé.+ Ẹni tó bá ń ṣe rere wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+ Ẹni tó bá ń ṣe búburú kò tíì mọ* Ọlọ́run.+ 12 Gbogbo wọn ló ròyìn Dímẹ́tíríù dáadáa, ìwà rẹ̀ sì bá ẹ̀kọ́ òtítọ́ mu. Kódà, àwa gan-an gba ẹ̀rí rẹ̀ jẹ́, ìwọ náà sì mọ̀ pé òótọ́ ni ẹ̀rí wa.
13 Ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo fẹ́ bá ọ sọ, àmọ́ mi ò fẹ́ máa fi gègé àti yíǹkì kọ wọ́n sí ọ. 14 Mò ń retí láti rí ọ láìpẹ́, a sì máa sọ̀rọ̀ lójúkojú.
Kí o wà ní àlàáfíà.
Àwọn ọ̀rẹ́ wa níbí ń kí ọ. Bá mi kí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ wa lọ́hùn-ún lọ́kọ̀ọ̀kan.*