Kọ “Àwọn Ohun Tí Kò Ní Láárí” Sílẹ̀
“Ẹni tí ń lépa àwọn ohun tí kò ní láárí jẹ́ ẹni tí ọkàn-àyà kù fún.”—ÒWE 12:11.
1. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun iyebíye tá a ní, ọ̀nà wo ló sì dára jù lọ tá a lè gbà lò wọ́n?
GBOGBO àwa Kristẹni la ní ohun kan tàbí òmíràn tó ṣeyebíye. Ohun iyebíye tiwa lè jẹ́ ara wa tó le àti okun inú tá a ní ju àwọn míì lọ, ó lè jẹ́ bá a ṣe ní ọpọlọ pípé, ó sì lè jẹ́ pé a rí towó ṣe. Èyí ó wù kó jẹ́, ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà ń mú ká máa fi ìdùnnú lo àwọn nǹkan wọ̀nyí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, à ń tipa báyìí tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Ọlọ́run mí sí yìí, pé: “Fi àwọn ohun ìní rẹ tí ó níye lórí bọlá fún Jèhófà.”—Òwe 3:9.
2. Ìkìlọ̀ wo ni Bíbélì ṣe nípa àwọn ohun tí kò ní láárí, kí sì lohun tí ìkìlọ̀ náà túmọ̀ sí?
2 Bíbélì tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí kò ní láárí, ó sì kìlọ̀ fún wa pé ká má fi àkókò wa àtàwọn nǹkan ìní wa ṣòfò lórí wọn. Ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí Òwe 12:11 sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí, ó ní: “Ẹni tí ń ro ilẹ̀ ara rẹ̀ ni a ó fi oúnjẹ tẹ́ òun fúnra rẹ̀ lọ́rùn, ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa àwọn ohun tí kò ní láárí jẹ́ ẹni tí ọkàn-àyà kù fún.” Kò ṣòro láti lóye ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ. Ohun tó ń sọ ni pé, tí ọkùnrin kan bá ń fi àkókò rẹ̀ ṣiṣẹ́ kára kó bàa lè rówó tọ́jú ìdílé rẹ̀, ó ṣeé ṣe kí ọkàn rẹ̀ balẹ̀, kó má fi bẹ́ẹ̀ níṣòro àtirówóná. (1 Tím. 5:8) Àmọ́ tó bá ń fi àwọn ohun ìní rẹ̀ ṣòfò lórí àwọn ohun tí kò ní láárí, ńṣe ló ń fi hàn pé “ọkàn-àyà kù fún” òun, ìyẹn ni pé kò lè ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání àti pé kò mọ irú ìgbésẹ̀ tó yẹ kóun máa gbé. Àfàìmọ̀ kírú ẹni bẹ́ẹ̀ má di akúùṣẹ́.
3. Báwo ni ìkìlọ̀ Bíbélì nípa àwọn ohun tí kò ní láárí ṣe kan ọ̀ràn ìjọsìn wa?
3 Tá a bá wá tẹ̀ lé ìlànà inú ìwé Òwe yìí nínú ọ̀ràn ìjọsìn wa ńkọ́? A ó rí i pé bí Kristẹni kan bá ń jọ́sìn Jèhófà tọkàntara láìyẹsẹ̀, yóò máa ní ìbàlẹ̀ ọkàn gidi. Ọkàn rẹ̀ lè balẹ̀ pé Ọlọ́run á bù kún òun nísinsìnyí, àti pé ìrètí tó dájú wà fóun lọ́jọ́ iwájú. (Mát. 6:33; 1 Tím. 4:10) Àmọ́, bí Kristẹni kan bá jẹ́ kí àwọn ohun tí kò ní láárí pín ọkàn rẹ̀ níyà, ńṣe ló fẹ́ ba àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́, ó sì lè pàdánù ìyè àìnípẹ̀kun. Kí la lè ṣe tíyẹn ò fi ní ṣẹlẹ̀ sí wa? A ní láti fòye mọ àwọn ohun tó wà nígbèésí ayé wa tó jẹ́ ohun “tí kò ní láárí,” ká sì pinnu láti kọ̀ wọ́n sílẹ̀.—Ka Títù 2:11, 12.
4. Ní ṣókí, kí làwọn ohun tí kò ní láárí?
4 Kí wá làwọn ohun tí kò ní láárí? Ní ṣókí, ohun tí kò ní láárí ni ohunkóhun tí kò bá ti ní jẹ́ ká lè fi gbogbo ọkàn wa sin Jèhófà. Lára ẹ̀ ni oríṣiríṣi nǹkan tá a lè kà sí fàájì. Lóòótọ́, kò burú téèyàn bá ṣe fàájì níwọ̀nba. Ṣùgbọ́n tí fàájì bá ti pọ̀ débi pé ó ń gba àkókò tó yẹ ká lò fún àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn wa, fàájì ti di ohun tí kò ní láárí nìyẹn, ó ti ń pa àjọṣe àwa àti Ọlọ́run lára. (Oníw. 2:24; 4:6) Tí Kristẹni kan kò bá fẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀ sí òun, ó ní láti jẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì, kó máa ṣọ́ bó ṣe ń lo àkókò rẹ̀ tó jẹ́ ara ohun iyebíye tó ní. (Ka Kólósè 4:5.) Àmọ́ ṣá o, àwọn ohun tí kò ní láárí kan wà tó léwu ju fàájì lọ fíìfíì. Lára àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọlọ́run èké.
Kọ Àwọn Ọlọ́run Tí Kò Ní Láárí Sílẹ̀
5. Báwo ni Bíbélì ṣe sábà máa ń lo gbólóhùn náà, “tí kò ní láárí”?
5 Ohun kan tó gbàfiyèsí ni pé ọ̀pọ̀ jù lọ ibi tí Bíbélì ti lo gbólóhùn náà, “tí kò ní láárí,” ọ̀rọ̀ nípa àwọn ọlọ́run èké ló ń sọ. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí fún ara yín, ẹ kò sì gbọ́dọ̀ gbé ère gbígbẹ́ tàbí ọwọ̀n ọlọ́wọ̀ kalẹ̀ fún ara yín, ẹ kò sì gbọ́dọ̀ gbé òkúta kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun àfihàn ní ilẹ̀ yín láti tẹrí ba fún un.” (Léf. 26:1) Dáfídì Ọba pẹ̀lú kọ̀wé pé: “Jèhófà tóbi lọ́lá, ó sì yẹ fún ìyìn gidigidi, ó sì yẹ ní bíbẹ̀rù ju gbogbo ọlọ́run yòókù. Nítorí gbogbo ọlọ́run àwọn ènìyàn jẹ́ àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí. Ní ti Jèhófà, òun ni ó ṣe ọ̀run.”—1 Kíró. 16:25, 26.
6. Kí nìdí tí àwọn ọlọ́run èké fi jẹ́ ohun tí kò ní láárí?
6 Gẹ́gẹ́ bí Dáfídì ṣe sọ, à ń rí ẹ̀rí tó fi hàn pé Jèhófà tóbi lọ́ba. (Sm. 139:14; 148:1-10) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, pé májẹ̀mú wà láàárín àwọn àti Jèhófà! Ìwà omùgọ̀ pátápátá gbáà ló jẹ́ pé wọ́n padà lẹ́yìn Jèhófà tí wọ́n sì lọ ń tẹrí ba fún ère gbígbẹ́ àti ọwọ̀n ọlọ́wọ̀! Nígbà tí ìṣòro dé sí wọn, ó wá hàn lóòótọ́ pé ohun tí kò ní láárí ni àwọn ọlọ́run èké wọn, àwọn ọlọ́run náà ò lè gba ara wọn sílẹ̀, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé kí wọ́n gba àwọn tó ń jọ́sìn wọn.—Oníd. 10:14, 15; Aísá. 46:5-7.
7, 8. Ọ̀nà wo ni “Ọrọ̀” lè gbà di ọlọ́run?
7 Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè lóde òní, àwọn èèyàn ṣì máa ń tẹrí ba fún àwọn ère táwọn èèyàn ṣe, àwọn ọlọ́run ọ̀hún ò sì wúlò fún nǹkan kan, gẹ́gẹ́ bí wọn kò ṣe wúlò fún nǹkan kan láyé àtijọ́. (1 Jòh. 5:21) Àmọ́ Bíbélì pe àwọn nǹkan míì tó yàtọ̀ sí ère ní ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, kíyè sí ohun tí Jésù sọ yìí: “Kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì; nítorí yálà òun yóò kórìíra ọ̀kan, kí ó sì nífẹ̀ẹ́ èkejì, tàbí òun yóò fà mọ́ ọ̀kan, kí ó sì tẹ́ńbẹ́lú èkejì. Ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.”—Mát. 6:24.
8 Báwo ni “Ọrọ̀” ṣe lè di ọlọ́run? Jẹ́ ká fi òkúta kan tó wà nínú pápá lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un ṣàpẹẹrẹ. Wọ́n lè fi òkúta yẹn mọ ilé tàbí ògiri. Àmọ́ tẹ́nì kan bá gbé òkúta yẹn nà ró gẹ́gẹ́ bí “ọwọ̀n ọlọ́wọ̀” tàbí “ohun àfihàn,” òkúta yẹn ti di ohun ìkọsẹ̀ fáwọn èèyàn Jèhófà nìyẹn. (Léf. 26:1) Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ owó rí, owó ní ìwúlò tiẹ̀. Ìwúlò ẹ̀ kò ju pé ká fi gbọ́ bùkátà, ó sì wúlò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (Oníw. 7:12; Lúùkù 16:9) Àmọ́ tá a bá jẹ́ kí ìlépa owó gba ipò iṣẹ́ ìsìn tó yẹ káwa Kristẹni máa ṣe, owó ti di ọlọ́run wa nìyẹn o. (Ka 1 Tímótì 6:9, 10.) Láyé tá a wà yìí, tó jẹ́ pé báwọn èèyàn ṣe máa dolówó ni wọ́n ń wá lójú méjèèjì, àfi ká yáa rí i dájú pé a wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì tó bá dọ̀ràn olówódé.—1 Tím. 6:17-19.
9, 10. (a) Ojú wo làwa Kristẹni fi ń wo lílọ sí ilé ẹ̀kọ́? (b) Ewu wo ló wà nínú lílọ sí ilé ìwé gíga?
9 Àpẹẹrẹ nǹkan míì tó wúlò àmọ́ tó lè di ohun tí kò ní láárí ni lílọ sí ilé ẹ̀kọ́. A fẹ́ káwọn ọmọ wa kàwé yanjú kí ọwọ́ wọn bàa lè tẹ́nu lọ́jọ́ ọ̀la. Èyí tó tún wá ṣe pàtàkì jùyẹn lọ ni pé tí Kristẹni kan bá kàwé ní àkàyanjú á lè máa ka Bíbélì ní àkàyé. Tíṣòro bá dé, á lè ronú jinlẹ̀ débi táá fi lè ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání, á sì lè máa fi ẹ̀kọ́ Bíbélì kọ́ni lọ́nà tó ṣe kedere táá sì wọ àwọn èèyàn lọ́kàn. Ó máa ń gba àkókò kéèyàn tó lè kàwé yanjú o, àmọ́, ó tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.
10 Tó bá wá dọ̀rọ̀ lílọ sí ilé ìwé gíga, irú bíi yunifásítì ńkọ́? Èrò táwọn èèyàn ní ni pé ẹni tó bá fẹ́ rọ́wọ́ mú láyé yìí gbọ́dọ̀ lọ sí ilé ìwé gíga. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó lọ sílé ìwé gíga ni wọ́n ti kó ọgbọ́nkọ́gbọ́n ayé yìí sí lágbárí. Irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ ń mú káwọn ọ̀dọ́ fi àkókò tó yẹ kí wọ́n lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ṣòfò. (Oníw. 12:1) Abájọ tó fi jẹ́ pé láwọn orílẹ̀-èdè kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti lọ sílé ìwé gíga, ńṣe làwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́ túbọ̀ ń pọ̀ sí i níbẹ̀. Dípò tí Kristẹni kan ì bá fi máa rò pé ẹ̀kọ́ ìwé ayé yìí ló máa jẹ́ kóun níbàlẹ̀ ọkàn, ohun tó dára ni pé kó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.—Òwe 3:5.
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ Ara Di Ọlọ́run Rẹ
11, 12. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé ikùn àwọn kan ni ọlọ́run wọn?
11 Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Fílípì, ó sọ ohun míì tó lè di ọlọ́run. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn kan tí wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ tẹ́lẹ̀, ó ní: “Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń bẹ, mo ti máa ń mẹ́nu kàn wọ́n ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ṣùgbọ́n nísinsìnyí mo tún ń mẹ́nu kàn wọ́n pẹ̀lú ẹkún sísun, àwọn ẹni tí ń rìn gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá òpó igi oró Kristi, ìparun sì ni òpin wọn, ikùn wọn sì ni ọlọ́run wọn, . . . wọ́n sì gbé èrò inú wọn lé àwọn nǹkan orí ilẹ̀ ayé.” (Fílí. 3:18, 19) Báwo ni ikùn ẹnì kan ṣe lè di ọlọ́run rẹ̀?
12 Ó dà bíi pé ìṣòro àwọn ojúlùmọ̀ Pọ́ọ̀lù yẹn ni pé ọkàn wọn fà sí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ju ìjọsìn Jèhófà táwọn pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù jọ ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ó lè jẹ́ pé ńṣe làwọn kan nínú wọn kúndùn oúnjẹ àti ohun mímu débi tí wọ́n fi di alájẹkì àti ọ̀mùtípara. (Òwe 23:20, 21; fi wé Diutarónómì 21:18-21) Àwọn míì ní ọ̀rúndún kìíní sì lè máa lo gbogbo àǹfààní tó wà láti rọ́wọ́ mú nígbà yẹn lọ́hùn-ún, èyí sì mú kí wọ́n ṣíwọ́ sísin Jèhófà. Ǹjẹ́ ká má ṣe tìtorí pé ọkàn wa ń fà sí ohun táwọn èèyàn ayé kà sí ìgbádùn ká wá dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn tá à ń ṣe tọkàntọkàn fún Jèhófà.—Kól. 3:23, 24.
13. (a) Kí ni ojúkòkòrò, kí sì ni Pọ́ọ̀lù sọ nípa rẹ̀? (b) Báwo la ṣe lè yẹra fún ojúkòkòrò?
13 Pọ́ọ̀lù tún sọ̀rọ̀ nípa ìjọsìn èké lọ́nà míì. Ó sọ pé: “Ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò, tí í ṣe ìbọ̀rìṣà.” (Kól. 3:5) Ojúkòkòrò ni kí ọkàn èèyàn máa fà sí ohun tí kì í ṣe tiẹ̀. Ojúkòkòrò kò mọ sórí ohun ìní nìkan, ojúkòkòrò lè mú kí ọkàn èèyàn fẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe aya tàbí ọkọ rẹ̀. (Ẹ́kís. 20:17) Ẹ ò rí i pé ó gba àròjinlẹ̀ kéèyàn tó lè rí i pé irú ìfẹ́ ọkàn bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìbọ̀rìṣà, ìyẹn ìjọsìn ọlọ́run èké! Jésù fi àpèjúwe kan ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká sa gbogbo ipá wa láti má ṣe jẹ́ kírú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yẹn gbilẹ̀ lọ́kàn wa.—Ka Máàkù 9:47; 1 Jòh. 2:16.
Ṣọ́ra fún Àwọn Ọ̀rọ̀ Tí Kò Ní Láárí
14, 15. (a) “Ohun tí kò ní láárí” wo ló ṣàkóbá fún ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà ayé Jeremáyà? (b) Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ Mósè fi ṣeyebíye?
14 Ọ̀rọ̀ ẹnu pẹ̀lú wà lára àwọn ohun tí kò ní láárí. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ fún Jeremáyà pé: “Èké ni àwọn wòlíì náà ń sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ mi. Èmi kò rán wọn, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò pàṣẹ fún wọn tàbí bá wọn sọ̀rọ̀. Ìran èké àti ìwoṣẹ́ àti ohun tí kò ní láárí àti àgálámàṣà ọkàn-àyà wọn ni wọ́n ń sọ ní àsọtẹ́lẹ̀ fún yín.” (Jer. 14:14) Àwọn wòlíì èké yẹn ń sọ pé àwọn ń sọ̀rọ̀ lórúkọ Jèhófà, àmọ́ èrò ara wọn, ìyẹn ọgbọ́n orí wọn, ni wọ́n ń gbé kalẹ̀. Ìdí nìyẹn tí ọ̀rọ̀ wọn fi jẹ́ “ohun tí kò ní láárí.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọn ò wúlò fún nǹkan kan, ewu ńlá sì ni wọ́n jẹ́ fáwọn èèyàn Ọlọ́run. Lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn tó fetí sí irú ọ̀rọ̀ tí kò ní láárí bẹ́ẹ̀ kú ikú àìtọ́jọ́ nígbà táwọn ọmọ ogun Bábílónì kógun jà wọ́n.
15 Ọ̀rọ̀ ti Mósè yàtọ̀, ó sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, pé: “Ẹ fi ọkàn-àyà yín sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ń sọ láti fi kìlọ̀ fún yín lónìí . . . Nítorí kì í ṣe ọ̀rọ̀ tí kò ní láárí fún yín, ṣùgbọ́n ó túmọ̀ sí ìwàláàyè yín, àti pé nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ yìí ni ẹ̀yin yóò mú ọjọ́ yín gùn lórí ilẹ̀ tí ẹ̀yin ń sọdá Jọ́dánì láti gbà.” (Diu. 32:46, 47) Bó ṣe rí nìyẹn, Ọlọ́run ló mí sí ọ̀rọ̀ tí Mósè sọ. Ìdí nìyẹn tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi ṣeyebíye, àní ọ̀rọ̀ tó yẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa fetí sí tí wọ́n bá fẹ́ kó dára fáwọn ni. Àwọn tó fetí sí ọ̀rọ̀ yẹn ní ẹ̀mí gígùn àti aásìkí. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò ní láárí sílẹ̀, ká sì rọ̀ mọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ tó ṣeyebíye.
16. Ojú wo la fi ń wo ohun tó ta ko Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ?
16 Ṣé àwa náà máa ń gbọ́ táwọn èèyàn ń sọ ohun tí kò ní láárí lónìí? A kúkú ń gbọ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan sọ pé ohun táwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n àtàwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣàwárí fi hàn pé kò tún sídìí láti gbà mọ́ pé Ọlọ́run wà, wọ́n ní gbogbo nǹkan tó wà láyé ṣàdédé wà ni. Ṣó yẹ ká fetí sí irú ọ̀rọ̀ táwọn agbéraga yẹn ń sọ? Rárá o! Ọgbọ́n Ọlọ́run yàtọ̀ sí ti èèyàn. (1 Kọ́r. 2:6, 7) Àmọ́ ṣá, a mọ̀ pé ní gbogbo ìgbà tí ìyàtọ̀ bá ti wà láàárín ẹ̀kọ́ èèyàn àti ohun tí Ọlọ́run ṣí payá, a máa ń rí i pé ẹ̀kọ́ èèyàn ni kò tọ̀nà. (Ka Róòmù 3:4.) Pẹ̀lú gbogbo ibi tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti tẹ̀ síwájú dé, ohun tí Bíbélì sọ nípa ọgbọ́n èèyàn ṣì jẹ́ òótọ́, pé: “Ọgbọ́n ayé yìí jẹ́ nǹkan òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.” A ó rí i pé ìmúlẹ̀mófo ni èrò èèyàn tá a bá fi wé ọgbọ́n Ọlọ́run tí kò láàlà.—1 Kọ́r. 3:18-20.
17. Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo ọ̀rọ̀ àwọn olórí ṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn apẹ̀yìndà?
17 À ń rí àpẹẹrẹ ohun mìíràn tó jẹ́ ohun tí kò ní láárí táwọn olórí ṣọ́ọ̀ṣì ń ṣe. Àwọn wọ̀nyí ń sọ pé Ọlọ́run ló ń gbẹnu àwọn sọ̀rọ̀, àmọ́ ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n ń sọ kò bá Ìwé Mímọ́ mu, ọ̀rọ̀ tí kò ní láárí ló sì ń jáde lẹ́nu wọn. Àwọn apẹ̀yìndà pẹ̀lú ń sọ ohun tí kò ní láárí, wọ́n sọ pé àwọn gbọ́n ju “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” tí Jésù yàn lọ. (Mát. 24:45-47) Àmọ́ ṣá o, ọgbọ́n orí ara wọn làwọn apẹ̀yìndà fi ń sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ tí kò ní láárí ni wọ́n ń sọ, ohun ìkọ̀sẹ̀ lọ̀rọ̀ wọn sì jẹ́ fáwọn tó bá fetí sí i. (Lúùkù 17:1, 2) Báwo la ṣe lè ṣọ́ra kí wọ́n má bàa ṣì wá lọ́nà?
Bá A Ṣe Lè Kọ Ọ̀rọ̀ Tí Kò Ní Láárí Sílẹ̀
18. Ọ̀nà wo la lè gbà fi ìmọ̀ràn tó wà nínú 1 Jòhánù 4:1 sílò?
18 Àpọ́sítélì Jòhánù tó ti darúgbó fún wa ní ìmọ̀ràn àtàtà lórí ọ̀rọ̀ yìí. (Ka 1 Jòhánù 4:1.) Ìmọ̀ràn Jòhánù yìí la máa ń tẹ̀ lé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa nígbà tá a bá ń sọ fáwọn tá a bá pàdé pé kí wọ́n dán ohun tí wọ́n ti fi kọ́ wọn wò nípa fífi wé ohun tí Bíbélì sọ. Ó yẹ káwa náà máa tẹ̀ lé ìlànà yìí. Tí ọ̀rọ̀ kan tó ń ta ko òtítọ́ bá dé etígbọ̀ọ́ wa, tàbí tá a gbọ́ tẹ́nì kan ń sọ̀rọ̀ tí kò dáa nípa ìjọ, nípa àwọn alàgbà tàbí èyíkéyìí lára àwọn ará wa, ojú ẹsẹ̀ kọ́ ló yẹ ká gba irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ gbọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká bi ara wa pé: “Ṣóhun tẹ́ni tó ń tan ọ̀rọ̀ yìí kálẹ̀ ń ṣe bá Bíbélì mu? Ṣé ọ̀rọ̀ yìí àbí ẹ̀sùn tó fi ń kan àwọn ará yìí ń mú kí ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ? Ṣé wọ́n ń ṣàlékún àlàáfíà ìjọ?” Ọ̀rọ̀ èyíkéyìí tá a bá gbọ́ tó ń ba àwọn ará wa jẹ́, dípò kó máa gbé wọn ró jẹ́ ohun tí kò ní láárí.—2 Kọ́r. 13:10, 11.
19. Kí làwọn alàgbà ní láti ṣe kí ọ̀rọ̀ wọn má bàa di èyí tí kò ní láárí?
19 Tó bá kan àwọn ọ̀rọ̀ tí kò ní láárí yìí, àwọn alàgbà lè rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kọ́. Tí wọ́n bá ń fúnni nímọ̀ràn, ó yẹ kí wọ́n máa rántí pé àwọn ò mọ gbogbo nǹkan tán, kí wọ́n má máa rò pé àwọn ìmọ̀ràn táwọn bá fún ẹnì kan látinú ìrírí àwọn ti tó. Ohun tí Bíbélì sọ ló yẹ kí wọ́n máa tọ́ka sí. Ìlànà pàtàkì kan rèé nínú ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ, ó ní: “Má ṣe ré kọjá àwọn ohun tí a ti kọ̀wé rẹ̀.” (1 Kọ́r. 4:6) Àwọn alàgbà ò gbọ́dọ̀ ré kọjá ohun tí a ti kọ sínú Bíbélì. Ìlànà yìí sì tún kan àwọn ìmọ̀ràn tá a gbé karí Bíbélì, èyí tó wà nínú àwọn ìwé tí ẹrú olóòótọ́ àti olóye ṣe, àwọn alàgbà ò gbọ́dọ̀ ré kọjá àwọn ìmọ̀ràn yẹn pẹ̀lú.
20. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti kọ àwọn ohun tí kò ní láárí sílẹ̀?
20 Àwọn ohun tí kò ní láárí léwu púpọ̀, yálà wọ́n jẹ́ “ọlọ́run” èké tàbí ọ̀rọ̀ tàbí nǹkan mìíràn. Ìdí rèé tá a fi ní láti máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ láti dá àwọn ohun tí kò ní láárí mọ̀, a sì ní láti máa bẹ̀ ẹ́ pé kó máa tọ́ wa sọ́nà láti kọ̀ wọ́n sílẹ̀. Tá a bá ń gba irú àdúrà bẹ́ẹ̀, ohun tí onísáàmù kan sọ làwa náà ń sọ, pé: “Mú kí ojú mi kọjá lọ láìrí ohun tí kò ní láárí; pa mí mọ́ láàyè ní ọ̀nà tìrẹ.” (Sm. 119:37) Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò àǹfààní tó wà nínú títẹ̀lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Ní ṣókí, kí ni “àwọn ohun tí kò ní láárí” tó yẹ ká kọ̀ sílẹ̀?
• Báwo la ò ṣe ní jẹ́ kí owó di ọlọ́run wa?
• Àwọn ọ̀nà wo ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara lè gbà jẹ́ ìbọ̀rìṣà?
• Báwo la ṣe lè kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò ní láárí sílẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Ọlọ́run rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa ‘ro ilẹ̀ ara wọn,’ kí wọ́n má ṣe lépa àwọn ohun tí kò ní láárí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ láti ní nǹkan tara mú kó o dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ọ̀rọ̀ àwọn alàgbà ṣeyebíye púpọ̀