Ìwé Kejì sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì
13 Ìgbà kẹta nìyí tí màá wá sọ́dọ̀ yín. “Nípa ẹ̀rí* ẹni méjì tàbí mẹ́ta, a ó fìdí gbogbo ọ̀rọ̀ múlẹ̀.”+ 2 Bí mi ò tiẹ̀ sí lọ́dọ̀ yín báyìí, ṣe ló dà bíi pé mo wà pẹ̀lú yín lẹ́ẹ̀kejì, mo sì ti kìlọ̀ fún àwọn tó ti dẹ́ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ àti fún gbogbo àwọn yòókù pé, tí mo bá tún pa dà wá, mi ò ní ṣàìbá wọn wí, 3 bó ṣe jẹ́ pé ẹ̀ ń wá ẹ̀rí tó fi hàn pé Kristi, tí kì í ṣe aláìlera nínú ọ̀rọ̀ yín àmọ́ tó jẹ́ alágbára láàárín yín, ló ń gbẹnu mi sọ̀rọ̀. 4 Ní tòótọ́, wọ́n kàn án mọ́gi* nítorí àìlera, àmọ́ ó wà láàyè nípasẹ̀ agbára Ọlọ́run.+ Lóòótọ́, àwa náà jẹ́ aláìlera pẹ̀lú rẹ̀, àmọ́ a máa wà láàyè pẹ̀lú rẹ̀+ nípasẹ̀ agbára Ọlọ́run tó wà lórí yín.+
5 Ẹ máa dán ara yín wò bóyá ẹ wà nínú ìgbàgbọ́; ẹ máa wádìí ohun tí ẹ̀yin fúnra yín jẹ́.+ Àbí ẹ ò mọ̀ pé Jésù Kristi wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú yín? Àfi tí a ò bá tẹ́wọ́ gbà yín. 6 Lóòótọ́, mo retí pé ẹ máa mọ̀ pé a kì í ṣe ẹni tí a kò tẹ́wọ́ gbà.
7 Ní báyìí, àdúrà wa sí Ọlọ́run ni pé kí ẹ má ṣe ohun tí kò tọ́, kì í ṣe torí kó lè hàn pé ẹni ìtẹ́wọ́gbà ni wá, àmọ́ ó jẹ́ torí kí ẹ lè máa ṣe ohun tó dáa, kódà tó bá tiẹ̀ dà bíi pé a kì í ṣe ẹni ìtẹ́wọ́gbà. 8 Nítorí a ò lè ṣe nǹkan kan láti rẹ́yìn òtítọ́, àfi ká ṣe nǹkan láti ti òtítọ́ lẹ́yìn. 9 Inú wa máa ń dùn nígbàkigbà tí a bá jẹ́ aláìlera àmọ́ tí ẹ̀yin jẹ́ alágbára. Ohun tí a sì ń gbàdúrà fún nìyí, pé kí ẹ ṣàtúnṣe. 10 Ìdí nìyẹn tí mo fi kọ àwọn nǹkan yìí nígbà tí mi ò sí lọ́dọ̀ yín, kó lè jẹ́ pé nígbà tí mo bá wá sọ́dọ̀ yín, mi ò ní le koko tí mo bá ń lo àṣẹ tí Olúwa fún mi,+ láti gbéni ró, tí kì í ṣe láti yani lulẹ̀.
11 Tóò, ẹ̀yin ará, ẹ máa yọ̀, ẹ máa ṣe ìyípadà, ẹ máa gba ìtùnú,+ ẹ máa ronú níṣọ̀kan,+ ẹ máa gbé ní àlàáfíà;+ Ọlọ́run ìfẹ́ àti àlàáfíà+ yóò sì wà pẹ̀lú yín. 12 Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín. 13 Gbogbo àwọn ẹni mímọ́ kí yín.
14 Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Kristi Olúwa àti ìfẹ́ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ tí à ń jọlá rẹ̀ wà pẹ̀lú gbogbo yín.