Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ǹjẹ́ àìpé Màríà wúńdíá ran oyún Jésù?
Àkọsílẹ̀ tí ó ní ìmísí sọ nípa “ìbí Jésù,” pé: “Ní àkókò tí ìyá rẹ̀ Màríà jẹ́ àfẹ́sọ́nà Jósẹ́fù, a rí i pé ó lóyún láti ọwọ́ ẹ̀mí mímọ́ ṣáájú kí a tó so wọ́n pọ̀ ṣọ̀kan.” (Mátíù 1:18) Láìṣe àní-àní, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run kó ipa pàtàkì nínú oyún tí Màríà ní.
Màríà alára wá ńkọ́? Ǹjẹ́ ẹyin inú rẹ̀ tiẹ̀ kópa kankan nínú oyún rẹ̀? Lójú ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún àwọn baba ńlá Màríà—ìyẹn Ábúráhámù, Ísákì, Jékọ́bù, Júdà, àti Dáfídì Ọba—ọmọ bíbí náà yóò jẹ́ ojúlówó àtọmọdọ́mọ wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 22:18; 26:24; 28:10-14; 49:10; 2 Sámúẹ́lì 7:16) Ọ̀nà mìíràn wo ni ọmọ tí Màríà bí náà ì bá fi jẹ́ ajogún tòótọ́ àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe wọ̀nyí? Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ọmọ rẹ̀ gan-an.—Lúùkù 3:23-34.
Áńgẹ́lì Jèhófà ti fara han Màríà wúńdíá, ó sì ti sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, Màríà, nítorí ìwọ ti rí ojú rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run; sì wò ó! ìwọ yóò lóyún nínú ilé ọlẹ̀ rẹ, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù.” (Lúùkù 1:30, 31) Bí ẹyin kankan ò bá fẹ́ra kù, èèyàn ò lè lóyún. Dájúdájú, ńṣe ni Jèhófà Ọlọ́run mú kí ẹyin kan fẹ́ra kù nínú ilé ọlẹ̀ Màríà. Bó ṣe ṣe èyí ni pé ó ta àtaré ìwàláàyè Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo láti àjùlé ọ̀run wá sórí ilẹ̀ ayé.—Gálátíà 4:4.
Ǹjẹ́ ọmọ tí obìnrin aláìpé kan lóyún rẹ̀ lọ́nà yìí lè jẹ́ ẹni pípé, kí ó má sì ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan nínú àgọ́ ara rẹ̀? Báwo làwọn òfin ànímọ́ àjogúnbá ṣe ń ṣiṣẹ́ nígbà tí ìjẹ́pípé àti àìpé bá dà pọ̀ mọ́ra? Rántí pé ẹ̀mí mímọ́ ló ta àtaré agbára ìwàláàyè pípé ti Ọmọ Ọlọ́run tó mú kí obìnrin náà lóyún. Èyí fagi lé àìpé èyíkéyìí tó wà nínú ẹyin Màríà, ó sì wá tipa bẹ́ẹ̀ mú apilẹ̀ àbùdá tó jẹ́ pípé látìbẹ̀rẹ̀ jáde.
Bó ti wù kó rí, ìdánilójú wà pé bí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ṣe ṣiṣẹ́ nígbà yẹn mú un dájú pé ète Ọlọ́run ò ní ṣàì kẹ́sẹ járí. Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì ti ṣàlàyé fún Màríà pé: “Ẹ̀mí mímọ́ yóò bà lé ọ, agbára Ẹni Gíga Jù Lọ yóò sì ṣíji bò ọ́. Nítorí ìdí èyí pẹ̀lú, ohun tí a bí ni a ó pè ní mímọ́, Ọmọ Ọlọ́run.” (Lúùkù 1:35) Bẹ́ẹ̀ ni o, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ṣe ohun tá a lè pè ní ògiri ààbò kan kí àìpé tàbí ipa búburú kankan má bàa kó àbààwọ́n bá ọlẹ̀ tó ń dàgbà látìgbà ìlóyún náà.
Ó ṣe kedere pé ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé tí Jésù ní wá látọ̀dọ̀ Baba rẹ̀ ọ̀rún, kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ ènìyàn kankan. Jèhófà “pèsè ara kan” fún un, àtìgbà ìlóyún sì ni Jésù alára ti dìídì jẹ́ “aláìlẹ́gbin, tí a yà sọ́tọ̀ kúrò láàárín àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”—Hébérù 7:26; 10:5.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
“Ìwọ yóò lóyún nínú ilé ọlẹ̀ rẹ, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan”