Jẹ́nẹ́sísì
49 Jékọ́bù sì pe àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, ó sọ pé: “Ẹ kó ara yín jọ, kí n lè sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí yín lọ́jọ́ iwájú. 2 Ẹ kó ara yín jọ, kí ẹ sì fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọmọkùnrin Jékọ́bù, àní, ẹ fetí sí Ísírẹ́lì bàbá yín.
3 “Rúbẹ́nì,+ ìwọ ni àkọ́bí+ mi, okun mi, ìbẹ̀rẹ̀ agbára ìbímọ mi, iyì àti okun rẹ ta yọ. 4 Torí ara rẹ kò balẹ̀ bí omi tó ń ru gùdù, o ò ní ta yọ, torí pé o gun ibùsùn+ bàbá rẹ. O sọ ibùsùn mi di ẹlẹ́gbin* nígbà yẹn. Ó gun orí rẹ̀!
5 “Tẹ̀gbọ́n-tàbúrò+ ni Síméónì àti Léfì. Ohun èlò ìwà ipá ni ohun ìjà wọn.+ 6 Má ṣe wá sáàárín wọn, ìwọ ọkàn* mi. Má ṣe bá wọn pé jọ, ìwọ ọlá* mi. Torí wọ́n fi ìbínú pa àwọn ọkùnrin,+ wọ́n sì tún já iṣan ẹsẹ̀* àwọn akọ màlúù láti tẹ́ ara wọn lọ́rùn. 7 Ègún sì ni fún ìbínú wọn, torí ìkà ni wọ́n fi ṣe àti ìrunú wọn, torí ó le jù.+ Jẹ́ kí n tú wọn ká sí ilẹ̀ Jékọ́bù, kí n sì tú wọn ká sáàárín Ísírẹ́lì.+
8 “Ní ti ìwọ Júdà,+ àwọn arákùnrin rẹ yóò yìn ọ́.+ Ọwọ́ rẹ yóò wà ní ọrùn àwọn ọ̀tá rẹ.+ Àwọn ọmọ bàbá rẹ yóò tẹrí ba fún ọ.+ 9 Ọmọ kìnnìún+ ni Júdà. Ọmọ mi, ìwọ yóò jẹ ẹran tí o pa, wàá sì dìde kúrò níbẹ̀. Ó ti dùbúlẹ̀, ó sì nà tàntàn bíi kìnnìún. Ó rí bíi kìnnìún, ta ló láyà láti jí i? 10 Ọ̀pá àṣẹ kò ní kúrò lọ́dọ̀ Júdà,+ ọ̀pá aláṣẹ kò sì ní kúrò láàárín ẹsẹ̀ rẹ̀ títí Ṣílò* yóò fi dé,+ òun ni àwọn èèyàn yóò máa ṣègbọràn sí.+ 11 Yóò so kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ mọ́ àjàrà, yóò sì so ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ mọ́ àjàrà tó dára, yóò fọ aṣọ rẹ̀ nínú wáìnì, yóò sì fọ ẹ̀wù rẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ èso àjàrà. 12 Wáìnì mú kí ojú rẹ̀ pọ́n gan-an, wàrà sì mú kí eyín rẹ̀ funfun.
13 “Sébúlúnì+ yóò máa gbé ní etíkun, ní èbúté tí àwọn ọkọ̀ òkun gúnlẹ̀ sí,+ ààlà rẹ̀ tó jìnnà jù yóò sì wà ní ọ̀nà Sídónì.+
14 “Ísákà+ jẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí egungun rẹ̀ le, tó dùbúlẹ̀ sáàárín àpò ẹrù méjì tí wọ́n so mọ́ ẹ̀yìn rẹ̀. 15 Yóò rí i pé ibi ìsinmi náà dáa àti pé ilẹ̀ náà wuni. Yóò tẹ èjìká rẹ̀ wálẹ̀ kó lè gbé ẹrù, yóò sì gbà láti ṣiṣẹ́ àṣekára.
16 “Dánì+ tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì+ máa ṣèdájọ́ àwọn èèyàn rẹ̀. 17 Kí Dánì jẹ́ ejò tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, ejò tó ní ìwo lẹ́bàá ọ̀nà, tó ń bu ẹṣin jẹ ní gìgísẹ̀, kí ẹni tó ń gùn ún lè ṣubú sẹ́yìn.+ 18 Jèhófà, èmi yóò dúró de ìgbàlà láti ọ̀dọ̀ rẹ.
19 “Ní ti Gádì,+ àwọn jàǹdùkú* yóò jà á lólè, àmọ́ òun yóò kọ lù wọ́n ní gìgísẹ̀.+
20 “Oúnjẹ* Áṣérì+ yóò pọ̀ gan-an,* yóò sì pèsè oúnjẹ tó tọ́ sí ọba.+
21 “Náfútálì+ jẹ́ abo àgbọ̀nrín tó rí pẹ́lẹ́ńgẹ́. Ó ń sọ ọ̀rọ̀ tó dùn.+
22 “Jósẹ́fù+ jẹ́ èéhù igi eléso, igi tó ń so lẹ́bàá ìsun omi, tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ nà sórí ògiri. 23 Àmọ́ àwọn tafàtafà ń fòòró rẹ̀, wọ́n ta á lọ́fà, wọ́n sì ń dì í sínú.+ 24 Síbẹ̀, ọfà* rẹ̀ dúró sí àyè rẹ̀,+ ọwọ́ rẹ̀ lágbára, ó sì já fáfá.+ Èyí wá láti ọwọ́ alágbára Jékọ́bù, láti ọwọ́ olùṣọ́ àgùntàn, òkúta Ísírẹ́lì. 25 Ó* wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bàbá rẹ, yóò sì ràn ọ́ lọ́wọ́, ó wà pẹ̀lú Olódùmarè, yóò sì fi àwọn ìbùkún ọ̀run lókè bù kún ọ, pẹ̀lú àwọn ìbùkún ibú nísàlẹ̀,+ pẹ̀lú àwọn ìbùkún ọmú àti ilé ọmọ. 26 Àwọn ìbùkún bàbá rẹ yóò ga ju àwọn ìbùkún òkè ayérayé lọ, yóò ga ju àwọn ohun tó wuni lórí àwọn òkè tó ti wà tipẹ́.+ Wọn yóò máa wà ní orí Jósẹ́fù, ní àtàrí ẹni tí Ọlọ́run yà sọ́tọ̀ láàárín àwọn arákùnrin rẹ̀.+
27 “Bẹ́ńjámínì+ yóò máa fani ya bí ìkookò.+ Ní àárọ̀, yóò jẹ ẹran tó pa. Ní ìrọ̀lẹ́, yóò pín ẹrù ogun.”+
28 Ìwọ̀nyí ni ẹ̀yà méjìlá (12) Ísírẹ́lì. Ohun tí bàbá wọn sì sọ fún wọn nìyẹn nígbà tó ń súre fún wọn. Ó súre+ fún kálukú bó ṣe tọ́ sí i.
29 Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ fún wọn pé: “Wọn ò ní pẹ́ kó mi jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn mi.*+ Torí náà, kí ẹ sin mí pẹ̀lú àwọn bàbá mi sínú ihò tó wà lórí ilẹ̀ Éfúrónì ọmọ Hétì,+ 30 ihò tó wà lórí ilẹ̀ Mákípẹ́là níwájú Mámúrè ní ilẹ̀ Kénáánì, ilẹ̀ tí Ábúráhámù rà lọ́wọ́ Éfúrónì ọmọ Hétì tó fi ṣe ibi ìsìnkú. 31 Ibẹ̀ ni wọ́n sin Ábúráhámù àti Sérà+ ìyàwó rẹ̀ sí. Ibẹ̀ náà ni wọ́n sin Ísákì+ àti Rèbékà ìyàwó rẹ̀ sí, ibẹ̀ sì ni mo sin Líà sí. 32 Ọwọ́ àwọn ọmọ Hétì+ ni Ábúráhámù ti ra ilẹ̀ náà àti ihò tó wà nínú rẹ̀.”
33 Nígbà tí Jékọ́bù fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ní ìtọ́ni wọ̀nyí tán, ó ká ẹsẹ̀ rẹ̀ sórí ibùsùn, ó mí èémí ìkẹyìn, wọ́n sì kó o jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀.*+