Ìwọ Ha Ti Rí Ìsì Tí Ó Tọ̀nà Bí?
“Ìsìn mímọ́ àti àìléèérí níwájú Ọlọrun àti Baba ni èyí.”—JAKỌBU 1:27.
1, 2. (a) Nínú èrò ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, kí ní ń pinnu bóyà ìsìn tiwọn ni ó tọ̀nà? (b) Kí ni ó yẹ kí a fi tọkàntọkàn gbéyẹ̀wò ní ṣíṣèdájọ́ ìsìn?
ÀŃ GBÉ nínú sànmánì kan nínú èyí tí ó ti tẹ́ àwọn ènìyàn lọ́rùn láti fi ọwọ́ tí kò ṣe danyindanyin mú ìsìn nínú ìgbésí-ayé wọn. Wọ́n lè lọ síbi àwọn ètò ìsìn kan, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni ó ń ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé. Ọ̀pọ̀ ènìyàn kò gbà pé gbogbo ìsìn yòókù ni kò tọ̀nà àti pé tiwọn ni ó tọ̀nà. Wọ́n lè wulẹ̀ nímọ̀lára pé ìsìn wọn dára tó lójú wọn.
2 Lójú ìwòye èyí, ǹjẹ́ ìbéèrè náà, Ìwọ ha ti rí ìsìn tí ó tọ̀nà bí? ha wulẹ̀ túmọ̀sí pé, Ìwọ ha ti rí ìsìn kan tí ó wù ọ́ bí? Kí ni ó ń pinnu ohun tí ó wù ọ́? Ìdílé rẹ ha ni bí? Àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ ha ni bí? Ìmọ̀lára rẹ ha ni bí? Ìwọ ha ti gbé ojú-ìwòye Ọlọrun yẹ̀wò tọkàntọkàn lórí ọ̀ràn yìí bí?
Báwo Ni A Ṣe Lè Mọ Ojú-Ìwòye Ọlọrun?
3. (a) Bí a bá níláti mọ ojú-ìwòye Ọlọrun, kí ni ó gbọ́dọ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa? (b) Àwọn ìbéèrè wo ni a níláti béèrè nípa ìdí tí àwa fúnraawa fi gbàgbọ́ pé Bibeli wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun?
3 Bí a bá níláti mọ èrò Ọlọrun fúnraarẹ̀, nígbà náà àwọn ìṣípayá kan níláti wá láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bibeli ni ìwé ọlọ́jọ́ pípẹ́ jùlọ tí ó jẹ́wọ́ pé ohun ní ìmísí Ọlọrun. (2 Timoteu 3:16, 17) Ṣùgbọ́n a ha lè fi tòótọ́ tòótọ́ sọ pé ìwé yìí, ní ìfiwéra pẹ̀lú gbogbo àwọn mìíràn, ní ìhìn-iṣẹ́ Ọlọrun nínú fún gbogbo aráyé bí? Báwo ni ìwọ yóò ṣe dáhùn ìbéèrè yẹn, èésìtiṣe? Ó ha jẹ́ nítorí pé àwọn òbí rẹ ní ojú-ìwòye yẹn bí? Ó ha jẹ́ nítorí ìwà àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ bí? Ìwọ ha ti yẹ ẹ̀rí náà wò fúnraàrẹ bí? Èéṣe tí o kò fi ṣe ìyẹn nísinsìnyí, ní lílo àwọn ẹ̀rí mẹ́rin tí ń pèsè ìsọfúnni tí ó tẹ̀lé e yìí?
4. Níti ìwàlárọ̀ọ́wọ́tó, kí ni ó fihàn pé Bibeli, yàtọ̀ sí àwọn ìwé mìíràn, wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun?
4 Ìwàlárọ̀ọ́wọ́tó: Ìhìn-iṣẹ́ kan tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun nítòótọ́ tí ó sì wà fún ìdílé ènìyàn lápapọ̀ níláti wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún wọn. Ìyẹn ha jẹ́ òtítọ́ nípa Bibeli bí? Gbé èyí yẹ̀wò: Bibeli, lódindi tàbí lápákan, ni a ti tẹ̀jáde nísinsìnyí ní èdè tí ó lé ní 2,000. Gẹ́gẹ́ bí àjọ American Bible Society ṣe sọ, ní èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹ̀wádún sẹ́yìn iye èdè tí a ti tẹ Bibeli jáde ti mú kí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún nǹkan bí ìpín 98 nínú ọgọ́rùn ún iye àwọn olùgbé ayé. Gẹ́gẹ́ bí ìwé Guinness Book of World Records ti fihàn, láìsí tàbí ṣùgbọ́n Bibeli ni “ìwé tí ó tíì ní ìpínkiri jùlọ ní gbogbo àgbáyé.” Ohun tí a níláti retí nìyí níti ìhìn-iṣẹ́ kan tí ó wà fún gbogbo ènìyàn láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun láti inú ẹ̀yà àti orílẹ̀ èdè àti èdè gbogbo. (Fiwé Ìfihàn 14:6.) Kò sí ìwé mìíràn lágbàáyé tí ó ní àkọsílẹ̀ kankan tí ó dàbí rẹ̀.
5. Èéṣe tí àwọn ìpìlẹ̀ ọ̀rọ̀-ìtàn inú Bibeli fi ṣe pàtàkì?
5 Ìjótìítọ́ Ọ̀rọ̀-Ìtàn: Ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ìròyìn inú Bibeli dáradára mú ọ̀nà mìíràn tí Bibeli fi dáyàtọ̀ sí àwọn ìwé mìíràn tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ mímọ́ wá sí ojútáyé. Bibeli ní àwọn ọ̀rọ̀-ìtàn tí ó jẹ́ òtítọ́ nínú, kìí ṣe àwọn ìtàn àròsọ tí kò sí ẹ̀rí láti fi ìjótìítọ́ rẹ̀ hàn. Irwin Linton, tí ó ti jẹ́ àṣà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí agbẹjọ́rò kan láti máa ṣàyẹ̀wò mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tí a ń fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ní ilé ẹjọ́, a kọ̀wé pé: “Nígbà tí àwọn iṣẹ́ ìwé kíkọ, ìtàn àròsọ àti ìjẹ́wọ́ èké máa ń ṣọ́ra láti fi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a ròyìn sí ibìkan tí ó jìnnà àti ní àkókò kan tí kò ṣe gúnmọ́, . . . àwọn ìròyìn Bibeli fún wa ní déètì àti ibi tí àwọn nǹkan tí a ròyìn ti ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú ìṣepàtó tí ó pọ̀ jùlọ.” (Fún àpẹẹrẹ, wo 1 Ọba 14:25; Isaiah 36:1; Luku 3:1, 2.) Èyí jẹ́ ohun pàtàkì kan fún ìgbéyẹ̀wò, fún àwọn ènìyàn tí wọ́n yíjú sí ìsìn fún òtítọ́ kìí ṣe gẹ́gẹ́ bí ibi àjàbọ́ lọ́wọ́ òtítọ́ gidi.
6. (a) Báwo ni Bibeli ṣe ń ṣèrànwọ́ fún ẹnìkan níti gidi nípa àwọn ìṣòro ìgbésí-ayé? (b) Ní àwọn ọ̀nà mẹ́ta wo ni Bibeli gba ń ran ẹnìkan lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lílekoko?
6 Ìgbéṣẹ́: Àwọn tí wọ́n fi tọkàntara ṣàyẹ̀wò Bibeli máa ń tètè ríi pé àwọn àṣẹ àti ìlànà rẹ̀ ní a kò wéwèé láti rẹ́ wọn jẹ. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n ń la ọ̀nà ìgbésí-ayé tí ń mú àǹfààní wá sílẹ̀ fún àwọn wọnnì tí wọ́n rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ wọn. (Isaiah 48:17, 18) Ìtùnú tí ó ń mú wá fún àwọn tí wọ́n wà nínú ìdààmú kìí ṣe ẹ̀tàn, tí a gbéka ọgbọ́n-èrò-orí tí kò lẹ́sẹ̀nílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń ṣèrànwọ́ fún àwọn ènìyàn láti lè kojú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lílekoko. Báwo? Lọ́nà mẹ́ta: (1) nípa fífúnni ní ìmọ̀ràn tí ó lọ́gbọ́n nínú lórí bí a ṣe lè kojú àwọn ìṣòro, (2) nípa ṣíṣàlàyé bí a ṣe lè rí ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ tí Ọlọrun ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nísinsìnyí gbà, àti (3) nípa ṣíṣí àgbàyanu ọjọ́ ọ̀la tí Ọlọrun ní ní ìpamọ́ fún àwọn wọnnì tí wọ́n ń ṣiṣẹ́sìn ín payá, ní fífún wọn ní ìdí yíyèkooro fún ìgbọ́kànlé nínú àwọn ìlérí rẹ̀.
7. (a) Ní lílo àwọn ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ tí a fàyọ ní etí ìwé, ṣàlàyé àwọn ìdáhùn Bibeli sí ọ̀kan lára àwọn ọ̀ràn pàtàkì tí ó kan àwọn ènìyàn lónìí. (b) Fihàn bí ìmọ̀ràn Bibeli ṣe ń dáàbòbò wá tàbí ṣèrànwọ́ fún wa láti kojú ipò tí ó kún fún másùnmáwo.
7 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lọ́pọ̀ ìgbà ìmọ̀ràn Bibeli kò gbajúmọ̀ láàárín àwọn tí wọ́n kọ ọlá-àṣẹ sílẹ̀ tí wọ́n sì ń lépa ìgbésí-ayé onígbọ̀jẹ̀gẹ́, púpọ̀ ti wá ríi pé irú ìgbésí-ayé bẹ́ẹ̀ kò tíì mú ojúlówó ayọ̀ wá fún wọn. (Galatia 6:7, 8) Bibeli fúnni ní ìdáhùn tààràtà sí àwọn ìbéèrè nípa ìṣẹ́yún, ìkọ̀sílẹ̀, àti ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀. Àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀ jẹ́ ìdáàbòbò lòdìsí ìlòkulò oògùn àti àmujù ọtí líle àti lòdìsí kíkó àrùn AIDS nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ tí ó léèràn tàbí ìṣekúṣe takọtabo. Ó fi bí a ṣe lè ní ìdílé aláyọ̀ hàn wá. Ó pèsè àwọn ìdáhùn tí ó lè mú kí ó ṣeéṣe fún ẹnìkan láti kojú ipò tí ó lè kó másùnmáwo báni jùlọ nínú ìgbésí-ayé, títíkan ìṣátì láti ọ̀dọ̀ àwọn mẹ́ḿbà ìdílé tí ó súnmọ́ni, àmódi lílekoko, àti ikú olólùfẹ́ kan. Ó ràn wá lọ́wọ́ láti fi òye mọ àwọn ohun tí ó yẹ kí wọ́n gbapò kìn-ín-ní kí ìgbésí-ayé wa lè kún fún ìtumọ̀ dípò àbámọ̀.a
8, 9. (a) Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni ó fa ìwọ gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan mọ́ra gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé a mísí Bibeli? (b) Níbo ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bibeli fi ẹ̀rí han pé wọ́n ti pilẹ̀ṣẹ̀?
8 Àsọtẹ́lẹ̀: Bibeli jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìwé àsọtẹ́lẹ̀ kan, ìwé kan tí ń sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́-ọ̀la, ó sì ń sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀. Ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìparun Tire ìgbàanì, ìṣubú Babiloni, ṣíṣe àtúnkọ́ Jerusalemu, ìdìde àti ìṣubú àwọn Ọba Medo-Persia àti Griki, àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ nínú ìgbésí-ayé Jesu Kristi. Ó tún sọ kúlẹ̀lúlẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ipò ayé tí ó ti farahàn ní ọ̀rúndún yìí, ó sì ṣàlàyé ìjẹ́pàtàkì wọn. Ó fi bí a ó ṣe yanjú àwọn ìṣòro tí o ti bo àwọn alákòóso ayé mọ́lẹ̀ hàn, ó sì fi Alákòóso náà tí yóò mú àlàáfíà pípẹ́títí àti àìléwu tòótọ́ wá fún aráyé hàn.b—Isaiah 9:6, 7; 11:1-5, 9; 53:4-6.
9 Lọ́nà ṣíṣe pàtàkì, Bibeli fi agbára náà láti lè sàsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́-ọ̀la lọ́nà pípéye hàn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí jíjẹ́ ti Ọlọrun. (Isaiah 41:1–46:13) Ẹni náà tí ó lè ṣe é tàbí tí ó lè mísí àwọn ẹlòmíràn láti ṣe é kìí ṣe òrìṣà aláìlẹ́mìí kan lásán. Òun kìí wulẹ̀ ṣe ènìyàn olótìítọ́-inú lásán kan. Ọlọrun tòótọ́ ni, ìwé náà tí ó sì ní àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ nínú jẹ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀.—1 Tessalonika 2:13.
Gbogbo Àwọn Tí Ń Lo Bibeli Ha Tọ̀nà Bí?
10, 11. Gẹ́gẹ́ bí Jesu ti fihàn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àlùfáà kan lè máa lo Bibeli, kí ni ó lè mú kí ìsìn kan tí òun ṣalágbàwí jẹ́ aláìníyelórí?
10 Ó ha bọ́gbọ́nmu—lọ́nà tí ó ṣe pàtàkì, ó ha bá Ìwé Mímọ́ mu—nígbà náà, láti parí èrò sí pé, gbogbo àwùjọ ìsìn tí wọ́n jẹ́wọ́ pé àwọn ń lo Bibeli ni wọ́n ń kọní ní ìsìn tòótọ́ bí? Ǹjẹ́ gbogbo ẹni tí ń gbé Bibeli tàbí fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú rẹ̀ ni ó ń ṣe ìsìn tí ó tọ̀nà bí?
11 Púpọ̀ nínú àwọn àlùfáà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní Bibeli, ń lo ìsìn gẹgẹ bí ọ̀nà kan láti gba ògo fún araawọn. Wọ́n da òtítọ́ mímọ́ gaara pọ̀ mọ́ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àti àbá-èrò-orí ènìyàn. Ọlọrun ha tẹ́wọ́gba ìjọsìn wọn bí? Jesu Kristi lo ìpolongo Ọlọrun nípasẹ̀ wòlíì Isaiah lọ́nà yíyẹwẹ́kú fún àwọn aṣáájú ìsìn ní Jerusalemu ọ̀rúndún kìn-ín-ní tí wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ní sísọ pé: “Àwọn ènìyàn yìí ń fi ẹnu wọn súnmọ́ mi, wọ́n sì ń fi ètè wọn bọlá fún mi; ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà sí mi. Ṣùgbọ́n lásán ni wọ́n ń tẹríba fún mi, wọ́n ń fi òfin ènìyàn kọ́ni fún ẹ̀kọ́.” (Matteu 15:8, 9; 23:5-10) Ní kedere, irúfẹ́ ìsìn bẹ́ẹ̀ kìí ṣe ìsìn tòótọ́.
12, 13. (a) Báwo ni ìwà àwọn mẹ́ḿbà ṣọ́ọ̀ṣì kan ṣe lè ṣèrànwọ́ fún ẹnìkan láti pinnu bóyá ìsìn tiwọn ni ó tọ̀nà? (b) Ojú wo ni Ọlọrun yóò fi wo ìjọsìn wa bí a bá yàn láti kẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn wọnnì tí òun kọ̀? (2 Kronika 19:2)
12 Kí ni bí èso tí àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn kan mú jáde, gẹ́gẹ́ bí ìgbésí-ayé àwọn mẹ́ḿbà rẹ̀ tí wọ́n ní ìdúró rere ti fihàn bá ti jẹrà? Nínú Ìwàásù rẹ̀ lórí Òkè, Jesu kìlọ̀ pé: “Ẹ máa kíyèsí àwọn èké wòlíì . . . Èso wọn ni ẹ̀yin óò fi mọ̀ wọ́n. . . . Gbogbo igi rere níí so èso rere; ṣùgbọ́n igi búburú níí so èso búburú.” (Matteu 7:15-17) Òtítọ́ ni pé ẹnìkọ̀ọ̀kan lè ṣàṣìṣe kí ó sì nílò ìtọ́sọ́nà. Ṣùgbọ́n ipò ọ̀ràn náà yàtọ̀ nígbà tí àwọn mẹ́ḿbà ṣọ́ọ̀ṣì, àní àlùfáà pàápàá, bá lọ́wọ́ nínú àgbèrè àti panṣágà, ìjà, ọtí àmupara, ìwọra, irọ́ pípa, ìbẹ́mìílò, jíjọ́sìn òrìṣà—èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí tàbí gbogbo wọn—síbẹ̀ tí kò sí ìbáwí kankan tí ó tẹ̀lé e, tí a kò sì yọ àwọn wọnnì tí wọn ń báa lọ nínú ipa ọ̀nà yìí kúrò nínú ìjọ. Bibeli sọ ní kedere pé irú àwọn tí ń sọ nǹkan bẹ́ẹ̀ dàṣà ni a níláti lé jáde kúrò láàárín ìjọ; wọn kì yóò ní àyè kankan ní Ìjọba Ọlọrun. (Galatia 5:19-21) Ìjọsìn wọn kò dùn mọ́ Ọlọrun nínú, bẹ́ẹ̀ sì ni ìjọsìn wa kì yóò dùn mọ́ Ọlọrun nínú bí a bá yàn láti kẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí òun ti kọ̀.—1 Korinti 5:11-13; 6:9, 10; Ìfihàn 21:8.
13 Ó hàn gbangba pé kìí ṣe gbogbo àwùjọ tí wọ́n jẹ́wọ́ pé àwọn ń lo Bibeli ni wọ́n ń ṣe ìsìn tòótọ́ tí ó ṣàpèjúwe. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, nígbà náà kí ni Bibeli là sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àmì tí a fi ń dá ìsìn tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀?
Àwọn Àmì tí A Fi Ń Dá Ìsìn Tòótọ́ Mọ̀ Yàtọ̀
14. (a) Lórí kí ni a gbé gbogbo àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn tòótọ́ kà? (b) Báwo ni àwọn ẹ̀kọ́ Kristẹndọm nípa Ọlọrun àti ọkàn ṣe yege ìdánwò yìí tó?
14 Àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ fìdí múlẹ̀ ṣinṣin nínú Ìwé Mímọ́ tí ó ní ìmísí. “Gbogbo ìwé mímọ́ [ni] ó ní ìmísí Ọlọrun [ti] ó sì ní èrè fùn ẹ̀kọ́, fún ìbániwí, fún ìtọ́ni.” (2 Timoteu 3:16) Ṣùgbọ́n níbo ni Bibeli Mímọ́ ti sọ̀rọ̀ nípa Mẹ́talọ́kan Kristẹndọm? Níbo sì ni Bibeli ti kọ́ni, gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà ti ṣe, pé ènìyàn ní ọkàn kan tí ń wàláàyè lẹ́yìn ikú ara ìyára? Ìwọ ha ti fìgbàkanrí bi àlùfáà kan láti fi àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyẹn hàn ọ́ nínú Bibeli rẹ bí? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Yálà ọ̀rọ̀ náà Mẹ́talọ́kan tàbí àlàyé kedere ẹ̀kọ́ náà kò farahàn nínú Májẹ̀mú Titun.” (1992, Micropædia, Ìdìpọ̀ 11, ojú-ìwé 928) Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà New Catholic Encyclopedia gbà pé: “Láàárín Àwọn Baba Òǹkọ̀wé Lẹ́yìn Àwọn Aposteli, kò sí ohunkóhun àní dé ìwọ̀n-àyè tí ó kéré jọjọ pàápàá tí ó súnmọ́ irúfẹ́ ẹ̀mí èrò orí tàbí kókó ojú-ìwòye bẹ́ẹ̀.” (1967, Ìdìpọ̀ XIV, ojú-ìwé 299) Níti èrò Kristẹndọm nípa ọkàn tí ń fi ara sílẹ̀ lẹ́yìn ikú, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì gbà pé àwọn yá èrò náà láti inú àbá-èrò-orí Griki. Bí ó ti wù kí ó rí, ìsìn tòótọ́ kò fọwọ́ rọ́ òtítọ́ Bibeli sẹ́yìn fún àbá-èrò-orí ènìyàn.—Genesisi 2:7; Deuteronomi 6:4; Esekieli 18:4; Johannu 14:28.
15. (a) Báwo ni Bibeli ṣe fi Ẹni kanṣoṣo náà tí a níláti jọ́sìn hàn? (b) Kí ni ìmọ̀lára àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ nípa sísúnmọ́ Jehofa pẹ́kípẹ́kí?
15 Ìsìn tòótọ́ ń ṣalágbàwí ìjọsìn Ọlọrun tòótọ́ kanṣoṣo náà, Jehofa. (Deuteronomi 4:35; Johannu 17:3) Ní títún ọ̀rọ̀ inú Deuteronomi 5:9 àti 6:13 sọ lọ́nà mìíràn, Jesu Kristi sọ ní ṣàkó pé: “Oluwa Ọlọrun rẹ ni kí ìwọ kí ó foríbalẹ̀ fún, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ máa sìn.” (Matteu 4:10) Ní ìbámu pẹ̀lú ìyẹn, Jesu sọ orúkọ Baba rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (Johannu 17:26) Ìsìn rẹ ha ti kọ́ ọ láti jọ́sìn Jehofa bí? Ìwọ ha ti mọ Ẹni náà tí a mọ orúkọ yẹn mọ̀ bí—àwọn ète rẹ̀, àwọn ìgbòkègbodò rẹ̀, àwọn ànímọ́ rẹ̀—tó bẹ́ẹ̀ tí o fi nímọ̀lára pé o lè fi pẹ̀lú ìgbọ́kànlé súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí bí? Bí tìrẹ bá jẹ́ ìsìn tòótọ́, bẹ́ẹ̀ni ni ìdáhùn náà.—Luku 10:22; 1 Johannu 5:14.
16. Kí ni ìgbàgbọ́ nínú Kristi túmọ̀sí fún àwọn wọnnì tí ń ṣe ìsìn tòótọ́?
16 Apá ṣíṣe pàtàkì nínú ìjọsìn tí ó dùnmọ́ Ọlọrun nínú ni ìgbàgbọ́ nínú Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu Kristi. (Johannu 3:36; Iṣe 4:12) Èyí kò túmọ̀sí wíwulẹ̀ gbàgbọ́ pé ó gbé ayé rí tàbí pé ó jẹ́ ẹni títayọ kan. Ó ní nínú ìmọrírì fún ohun tí Bibeli fi kọ́ni nípa ìníyelórí ẹbọ ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé ti Jesu àti mímọ ipò rẹ̀ lónìí gẹ́gẹ́ bí Ọba ọ̀run. (Orin Dafidi 2:6-8; Johannu 3:16; Ìfihàn 12:10) Bí o bá ti darapọ̀ mọ́ àwọn wọnnì tí wọ́n ń ṣe ìsìn tòótọ́, ìwọ yóò ti mọ̀ pé wọ́n ń lo ìsapá àfitọkàntọkàn ṣe nínú ìgbésí-ayé wọn ojoojúmọ́ láti ṣègbọràn sí Jesu, láti tẹ̀lé àpẹẹrẹ rẹ̀, àti láti nípìn-ín fúnraawọn pẹ̀lú ìtara nínú iṣẹ́ náà tí ó yàn fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (Matteu 28:19, 20; Johannu 15:14; 1 Peteru 2:21) Bí ìyẹn kò bá jẹ́ òtítọ́ nípa àwọn wọnnì tí ìwọ ń bá jọ́sìn papọ̀, o níláti yíjú sí ibòmíràn.
17. Èéṣe tí àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ fi níláti ṣọ́ra láti máṣe di ẹni tí ayé kó àbààwọ́n bá, kí ni ìyẹn sì ní nínú?
17 A kò kó àbààwọ́n bá ìsìn tòótọ́ nípa ìlọ́wọ́ nínú òṣèlú àti ìforígbárí ayé. (Jakọbu 1:27) Èéṣe tí ó fi rí bẹ́ẹ̀? Nítorí Jesu sọ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Wọn kìí ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kìí tií ṣe ti ayé.” (Johannu 17:16) Jesu kò tojúbọ ọ̀ràn òṣèlú, ó sì ká àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́ kò kúrò nínú yíyíjú sí ohun ìjà ti ara. (Matteu 26:52) Àwọn tí wọ́n fi ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ sọ́kàn ‘kò kọ́ ogun jíjà mọ́.’ (Isaiah 2:2-4) Bí ìsìn èyíkéyìí tí ìwọ tilẹ̀ ti ní àjọṣepọ̀ aláfẹnujẹ́ lásán pẹ̀lú rẹ̀ kò bá bá àpèjúwe yẹn mu, ó tó àkókò láti já ìdè rẹ pẹ̀lú rẹ̀.—Jakọbu 4:4; Ìfihàn 18:4, 5.
18. (a) Kí ni ohun tí Johannu 13:35 fihàn pé ó jẹ́ àmì títayọ tí a fi lè dá ìsìn tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀? (b) Báwo ni ìwọ ṣe lè ran ẹnìkan lọ́wọ́ láti pinnu èwo ni àwùjọ tí ó bá Johannu 13:35 ṣedéédéé?
18 Ìsìn tòótọ́ ń kọni ní ìfẹ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan ó sì ń fi ṣèwàhù. (Johannu 13:35; 1 Johannu 3:10-12) A kìí wulẹ̀ mẹ́nukan irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ nínú ìwàásù. Ó ń fa àwọn ènìyàn láti inú ẹ̀yà gbogbo, ẹgbẹ́ àwùjọ ọrọ̀-ajé gbogbo, èdè gbogbo, orílẹ̀-èdè gbogbo, sínú ojulówó ẹgbẹ́ àwọn ará. (Ìfihàn 7:9, 10) Ó ya àwọn Kristian tòótọ́ sọ́tọ̀ kúrò lára ayé tí ó yí wọn ká. Bí ó bá jẹ́ pé o kò tíì ṣe bẹ́ẹ̀, lọ sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, àti àwọn àpéjọpọ̀ ńlá wọn bákan náà. Ṣọ́ wọn bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ papọ̀ láti kọ́ ọ̀kan lára àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn. Kíyèsí bí wọ́n ṣe ń bá àwọn àgbàlagbà (títíkan àwọn opó) àti àwọn ọ̀dọ́ (títíkan àwọn wọnnì tí wọ́n ní kìkì òbí kanṣoṣo tàbí tí wọn kò ní rárá) lò. (Jakọbu 1:27) Fi ohun tí o ti ṣàkíyèsí wéra pẹ̀lú ohun tí o ti rí nínú ìsìn èyíkéyìí mìíràn. Nígbà náà bi araàrẹ léèrè pé, ‘Àwọn wo ní ń ṣe ìsìn tòótọ́?’
19. (a) Ojútùú wo sí ìṣòro aráyé ni ìsìn tòótọ́ ń ṣalágbàwí rẹ̀? (b) Kí ni àwọn mẹ́ḿbà àwùjọ tí ó rọ̀ mọ́ ìsìn tòótọ́ gbọ́dọ̀ máa ṣe?
19 Ìsìn tòótọ́ ń ṣalágbàwí Ìjọba Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ojútùú wíwàpẹ́títí sí ìṣòro aráyé. (Danieli 2:44; 7:13, 14; 2 Peteru 3:13; Ìfihàn 21:4, 5) Ǹjẹ́ èyíkéyìí nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹndọm ń ṣe ìyẹn bí? Nígbà wo ni o gbọ́ kẹ́yìn tí àlùfáà kan ṣàlàyé Ìjọba Ọlọrun àti ohun tí Ìwé Mímọ́ fihàn pé yóò ṣàṣeparí? Ètò-àjọ tí ìwọ wà ha fún ọ níṣìírí láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọrun bí, bí ó bá sì jẹ́ bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ gbogbo àwọn mẹ́ḿbà rẹ̀ lápapọ̀ ń nípìn-ín nínú ṣíṣe é bi? Jesu ṣe irú ìwàásù bẹ́ẹ̀; àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ìjímìjí ṣe bẹ́ẹ̀. Ìwọ lè ní àǹfààní nínípìn-ín nínú ìgbòkègbodò yìí. Ó jẹ́ iṣẹ́ ṣíṣe pàtàkì jùlọ tí a ń ṣe lórí ilẹ̀-ayé lónìí.—Matteu 24:14.
20. Ní àfikún sí dídá ìsìn tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀, kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe?
20 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìsìn ni ó wà, Bibeli tètè ràn wá lọ́wọ́ láti mú àwọn ìdàrúdàpọ̀ kúrò láti lè mọ ìsìn tòótọ́ yàtọ̀. Ṣùgbọ́n ó yẹ kí a ṣe ju dídá a mọ̀ yàtọ̀ lọ. Ó ṣekókó pe kí a ṣe é. Ohun tí èyí ní nínú ni a óò gbéyẹ̀wò ní kíkún nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìṣẹ́yún: Iṣe 17:28; Orin Dafidi 139:1, 16; Eksodu 21:22, 23. Ìkọ̀sílẹ̀: Matteu 19:8, 9; Romu 7:2, 3. Ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀: Romu 1:24-27; 1 Korinti 6:9-11. Ìlòkulò oògùn àti àmujù ọtí líle: 2 Korinti 7:1; Luku 10:25-27; Owe 23:20, 21; Galatia 5:19-21. Ẹ̀jẹ̀ àti ìṣekúṣe: Iṣe 15:28, 29; Owe 5:15-23; Jeremiah 5:7-9. Ìdílé: Efesu 5:22–6:4; Kolosse 3:18-21. Ìṣátì: Orin Dafidi 27:10; Malaki 2:13-16; Romu 8:35-39. Àmódi: Ìfihàn 21:4, 5; 22:1, 2; Titu 1:2; Orin Dafidi 23:1-4. Ikú: Isaiah 25:8; Iṣe 24:15. Àwọn ohun tí ó yẹ kí ó gbapò kìn-ín-ní: Matteu 6:19-34; Luku 12:16-21; 1 Timoteu 6:6-12.
b Fún àpẹẹrẹ irú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ àti ìmúṣẹ wọn, wo ìwé náà The Bible—God’s Word or Man’s?, ojú-ìwé 117 sí 161; àti Reasoning From the Scriptures, ojú-ìwé 60 sí 62, 225 sí 232, 234 sí 240. A tẹ méjèèjì jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Ní dídá ìsìn tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀, ojú ìwòye ta ni ó ṣe pàtàkì jù?
◻ Àwọn ẹ̀rí mẹ́rin wo tí ń pèsè ìsọfúnni ni ó tọ́ka sí Bibeli gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun?
◻ Èéṣe tí ó fi jẹ́ pé kìí ṣe gbogbo ìsìn tí ń lo Bibeli ni Ọlọrun tẹ́wọ́gbà?
◻ Kí ni àwọn àmì mẹ́fà tí a fi lè dá ìsìn tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa . . .
◆ Gbé gbogbo ẹ̀kọ́ wọn ka orí Bibeli.
◆ Ń jọ́sìn Ọlọrun tòótọ́ kanṣoṣo, Jehofa.
◆ Ń gbé ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìgbàgbọ́ wọn nínú Jesu Kristi.
◆ Kò lọ́wọ́ nínú òṣèlú àti ìforígbárí ayé.
◆ Ń gbìyànjú láti fi ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan hàn nínú ìgbésí-ayé ojoojúmọ́.
◆ Ń ṣalágbàwí Ìjọba Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ojútùú pípẹ́títí sí ìṣòro aráyé.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
BIBELI—kí ni ó fihàn pé ó ní ìhìn-iṣẹ́ Ọlọrun nínú fún aráyé?