Jésù—Olùṣàkóso “Tí Orírun Rẹ̀ Jẹ́ Láti Àwọn Àkókò Ìjímìjí”
OJÚ rẹ wà lọ́nà bí o ti ń dúró kí ìbátan rẹ tí ẹ kò tíì fojú kanra fún ìgbà pípẹ́ dé. Níkẹyìn, o pàdé rẹ̀, o sì fi tayọ̀tayọ̀ kí i. O tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ bí ó ti ń sọ ìdí tí bàbá rẹ̀ fi rán an sí ọ. Kò sì pẹ́ tí ó fi tó àkókò kí ó padà sílé. Pẹ̀lú ìbànújẹ́, o juwọ́ sí i pé ó dìgbòóṣe. Àárò tí ó ń sọ ọ́ lẹ́yìn tí ó lọ yóò bẹ̀rẹ̀ sí dínkù nígbà tí o bá gbọ́ròyìn pé ó ti délé láyọ̀.
Lẹ́yìn náà, nígbà tí o ń ṣàyẹ̀wò àwọn lẹ́tà àtijọ́, ó rí àwọn lẹ́tà tí ó sọ ní ṣókí nípa ìwà akin tí ìbátan rẹ̀ ti hù kí ó tó bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ sọ́dọ̀ rẹ. Ohun tí o rí kà nínú àwọn lẹ́tà yẹn jẹ́ kí o lóye ipò àtilẹ̀wá rẹ̀ lọ́nà jíjinlẹ̀, ó sì mú kí o túbọ̀ mọrírì ìbẹ̀wò rẹ̀ àti iṣẹ́ tí ó ń ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́.
“Láti Àwọn Àkókò Ìjímìjí”
Lára àwọn lẹ́tà àtijọ́ tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní ni àwọn àkọsílẹ̀ Míkà, wòlíì Ọlọ́run, tí ó kọ ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún méje sẹ́yìn. Èyí sọ ibi pàtó tí a óò bí Mèsáyà sí. “Ìwọ, Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Éfúrátà, ẹni tí ó kéré jù láti wà lára àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún Júdà, inú rẹ ni ẹni tí yóò di olùṣàkóso Ísírẹ́lì yóò ti jáde tọ̀ mí wá, ẹni tí orírun rẹ̀ jẹ́ láti àwọn àkókò ìjímìjí, láti àwọn ọjọ́ tí ó jẹ́ àkókò tí ó lọ kánrin.” (Míkà 5:2) Ní ìmúṣẹ sí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, a bí Jésù sí ìletò Jùdíà kan ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ní àkókò tí a wá ń pè ní ọdún 2 ṣááju Sànmánì Tiwa nísinsìnyí. Ṣùgbọ́n báwo ni orírun rẹ̀ ṣe lè jẹ́ “láti àwọn àkókò ìjímìjí”?
Jésù ti wà kí a tó bí i gẹ́gẹ́ bí ènìyàn. Nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn Kristẹni ní Kólósè, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe Jésù gẹ́gẹ́ bí “àwòrán Ọlọ́run tí a kò lè rí, àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá.”—Kólósè 1:15.
Ní lílo ọ̀rọ̀ tí a mí sí tí Sólómọ́nì Ọba kọ sílẹ̀ nínú ìwé Òwe, Jèhófà, Orísun ọgbọ́n, dá Ọmọ rẹ̀ àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí “ìbẹ̀rẹ̀pàá àwọn àṣeyọrí” rẹ̀. Lẹ́yìn tí Jésù gbé orí ilẹ̀ ayé fún ìgbà díẹ̀, tí ó sì padà lọ sí ọ̀run, ó jẹ́rìí sí i pé ní tòótọ́ òun ni “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá láti ọwọ́ Ọlọ́run.” Gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n tí a ṣàkàwé, Jésù tí a kò tí ì bí gẹ́gẹ́ bí ènìyàn polongo pé: “Nígbà tí [Jèhófà] pèsè ọ̀run, mo wà níbẹ̀.”—Òwe 8:22, 23, 27; Ìṣípayá 3:14.
Láti ìbẹ̀rẹ̀, Ọmọ Ọlọ́run gba iṣẹ́ àrà ọ̀tọ̀ kan, ìyẹn ni ti jíjẹ́ “àgbà òṣìṣẹ́” lọ́dọ̀ Baba rẹ̀. Èyí mà mú inú Jèhófà dùn jọjọ o! “Mo . . . wá jẹ́ ẹni tí [Jèhófà] ni ìfẹ́ni sí lọ́nà àkànṣe lójoojúmọ́,” ni Òwe 8:30 sọ, ó sì fi kún un pé: “Mo ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ níwájú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà.”
Lẹ́yìn náà, Jèhófà ké sí Ọmọ rẹ àkọ́bí láti nípìn-ín nínú dídá aráyé. Ó polongo pé: “Jẹ́ kí a ṣe ènìyàn ní àwòrán wa, ní ìrí wa.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, ìfẹ́ni mìíràn dìde. Jésù tí a kò tí ì bí gẹ́gẹ́ bí ènìyàn sọ pé: “Àwọn ohun tí mo sì ní ìfẹ́ni sí jẹ́ sípa àwọn ọmọ ènìyàn.” (Òwe 8:31) Ní ìbẹ̀rẹ̀ Ìhìn Rere rẹ̀, àpọ́sítélì Jòhánù sọ nípa ipa tí Jésù tí a kò tí ì bí gẹ́gẹ́ bí ènìyàn kó nínú ìṣẹ̀dá pé: “Ohun gbogbo di wíwà nípasẹ̀ rẹ̀, àti pé láìsí i, àní ohun kan kò di wíwà.”—Jòhánù 1:3.
Agbọ̀rọ̀sọ Jèhófà
Àwọn ọ̀rọ̀ Jòhánù darí àfiyèsí sí àǹfààní mìíràn tí Ọmọ Ọlọ́run gbádùn, ìyẹn ni, jíjẹ́ agbọ̀rọ̀sọ. Láti ìbẹ̀rẹ̀, ó sìn gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀. Nípa báyìí, nígbà tí Jèhófà bá Ádámù sọ̀rọ̀, àti lẹ́yìn náà nígbà tí ó bá Ádámù àti Éfà sọ̀rọ̀, ó ṣeé ṣe kí ó ti ṣe bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ náà. Ta sì ni ó tóótun láti sọ ìtọ́ni Ọlọ́run nípa ire aráyé bí kò ṣe ẹni tí ó ní ìfẹ́ni fún wọn?—Jòhánù 1:1, 2.
Ẹ wo bí yóò ti dun Ọ̀rọ̀ náà tó láti rí Éfà àti lẹ́yìn náà Ádámù tí wọ́n ṣàìgbọràn sí Ẹlẹ́dàá wọn! Ẹ sì wo bí yóò ti yán hànhàn tó láti wá ojútùú sí àbùkù tí àìgbọràn wọn ti mú wá bá irú ọmọ wọn! (Jẹ́nẹ́sísì 2:15-17; 3:6, 8; Róòmù 5:12) Ní bíbá Sátánì sọ̀rọ̀, ẹni tí ó ti fún Éfà níṣìírí láti ṣọ̀tẹ̀, Jèhófà polongo pé: “Èmi yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Níwọ̀n bí ó ti fojú rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní Édẹ́nì, Ọ̀rọ̀ náà mọ̀ pé gẹ́gẹ́ bí apá pàtàkì nínú “irú-ọmọ” obìnrin náà, òun yóò di ẹni ìkórìíra gidigidi. Ó mọ̀ pé apànìyàn ni Sátánì.—Jòhánù 8:44.
Nígbà tí Sátánì béèrè ìbéèrè nípa ìwà títọ́ Jóòbù lẹ́yìn náà, Ọ̀rọ̀ náà ti gbọ́dọ̀ bínú fún ẹ̀sùn ìbàlórúkọjẹ́ tí ó fi kan Bàbá rẹ̀. (Jóòbù 1:6-10; 2:1-4) Ní tòótọ́, nínú ipa iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olú-áńgẹ́lì, a mọ Ọ̀rọ̀ náà sí Máíkẹ́lì, ẹni tí orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí “Ta Ni Ó Dà Bí Ọlọ́run?” ó sì ń tọ́ka sí bí ó ṣe gbèjà Jèhófà lọ́dọ̀ gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ gba ipò ọba aláṣẹ Ọlọ́run.—Dáníẹ́lì 12:1; Ìṣípayá 12:7-10.
Bí ìtàn Ísírẹ́lì ṣe ń lọ, Ọ̀rọ̀ náà ṣàkíyèsí àwọn ìgbìdánwò Sátánì láti fa àwọn ènìyàn kúrò nínú ìjọsìn mímọ́ gaara. Lẹ́yìn Ìjádelọ wọn kúrò ní Íjíbítì, Ọlọ́run sọ fún Ísírẹ́lì nípasẹ̀ Mósè pé: “Kíyè sí i, èmi yóò rán áńgẹ́lì kan ṣáájú rẹ láti pa ọ́ mọ́ ní ojú ọ̀nà àti láti mú ọ wá sí ibi tí mo ti pèsè sílẹ̀. Ṣọ́ ara rẹ nítorí rẹ̀ kí o sì ṣègbọràn sí ohùn rẹ̀. Má ṣọ̀tẹ̀ sí i, nítorí kì yóò dárí ìrélànàkọjá yín jì; nítorí orúkọ mi wà lára rẹ̀.” (Ẹ́kísódù 23:20, 21) Ta ni áńgẹ́lì yìí? Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ Jésù tí a kò tí ì bí gẹ́gẹ́ bí ènìyàn.
Fífòótọ́ Tẹrí Ba
Mósè kú ní ọdún 1473 ṣááju Sànmánì Tiwa, a sì sin òkú rẹ̀ “sínú àfonífojì ní ilẹ̀ Móábù ní iwájú Bẹti-péórù.” (Diutarónómì 34:5, 6) Lọ́nà tí ó ṣe kedere, Sátánì fẹ́ lo òkú náà, bí ó bá ṣeé ṣe láti gbé ìbọ̀rìṣà lárugẹ. Máíkẹ́lì tako èyí ṣùgbọ́n ò fi ìtẹríba darí ọlá àṣẹ náà sí Baba rẹ̀, Jèhófà. ‘Láìfẹ́ dá a láṣà láti mú ìdájọ́ wá lòdì sí Sátánì ní àwọn ọ̀rọ̀ èébú,’ Máíkẹ́lì sọ fún Sátánì pé: “Kí Jèhófà bá ọ wí lọ́nà mímúná.”—Júúdà 9.
Lẹ́yìn èyí, Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí gba Kénáánì, Ilẹ̀ Ìlérí náà. Lẹ́bàá ìlú Jẹ́ríkò, Jóṣúà rí ẹ̀rí pé Ọ̀rọ̀ náà yóò máa bá a nìṣó láti bójú tó orílẹ̀-èdè náà. Níbẹ̀ ni ó ti rí ọkùnrin kan tí ó mú idà tí ó fà yọ̀ lọ́wọ́. Jóṣúà rìn tọ àjòjì náà lọ, ó sì bi í pé: “Ṣé àwa ni o wà fún tàbí fún àwọn elénìní wa?” Wo bí ẹnu yóò ti ya Jóṣúà tó nígbà tí àjòjì náà sọ ẹni tí ó jẹ́ fún un, ní sísọ pé: “Rárá, ṣùgbọ́n èmi—gẹ́gẹ́ bí olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jèhófà ni mo ṣe wá nísinsìnyí.” Abájọ tí Jóṣúà fi dojú bolẹ̀ níwájú aṣojú ńlá yìí láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, kò sí iyèméjì pé Jésù tí a kò tí ì bí gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ni yóò wá di “Mèsáyà Aṣáájú” nígbẹ̀yìngbẹ́yín.—Jóṣúà 5:13-15; Dáníẹ́lì 9:25.
Àkókò mìíràn tí Jésù àti Sátánì fojú kojú ni ní àwọn ọjọ́ Dáníẹ́lì, wòlíì Ọlọ́run. Ní àkókò yìí, Máíkẹ́lì ti àwọn áńgẹ́lì ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn nígbà tí ọmọ aládé ilẹ̀ ọba Páṣíà, tí í ṣe ọmọ èṣù ‘dúró ní ìlòdìsí i’ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta. Áńgẹ́lì náà ṣàlàyé pé: “Wò ó! Máíkẹ́lì, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ aládé tí ó wà ní ipò iwájú pátápátá, wá láti ràn mí lọ́wọ́; ní tèmi, mo wà níbẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ọba Páṣíà.—Dáníẹ́lì 10:13, 21.
Ògo Rẹ̀ Kí Ó Tó Di Ènìyàn àti Gẹ́gẹ́ Bí Ènìyàn
Ní ọdún 778 ṣááju Sànmánì Tiwa, ọdún tí Ùsáyà, Ọba Júúdà kú, Aísáyà, wòlíì Ọlọ́run, rí ìran kan nípa Jèhófà tí ó gúnwà sórí ìtẹ́ rẹ̀ gíga. Jèhófà béèrè pé: “Ta ni èmi yóò rán, ta sì ni yóò lọ fún wa?” Aísáyà yọ̀ǹda ara rẹ̀, ṣùgbọ́n Jèhófà kìlọ̀ fún un pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kò ní fetí sí ìpolongo rẹ̀. Àpọ́sítélì Jòhánù fi àwọn Júù aláìgbàgbọ́ ti ọ̀rúndún kìíní wé àwọn ènìyàn ọjọ́ Aísáyà, ó sì sọ pé: “Aísáyà sọ nǹkan wọ̀nyí nítorí ó rí ògo rẹ̀.” Ògo ta ni? Ti Jèhófà àti ti Jésù tí kò tí í di ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní àjùlé ọ̀run.—Aísáyà 6:1, 8-10; Jòhánù 12:37-41.
Ní ọ̀rúndún díẹ̀ lẹ́yìn náà, Jésù gba iṣẹ́ àyànfúnni tí ó tóbi jù lọ títí di ìgbà yẹn. Jèhófà tàtaré ìwàláàyè Ọmọ rẹ̀ olùfẹ́ ọ̀wọ́n láti ọ̀run sínú ilé ọlẹ̀ Màríà. Ní oṣù mẹ́sàn-án lẹ́yìn náà ó bí ọmọkùnrin kékeré jòjòló, Jésù. (Lúùkù 2:1-7, 21) Nínú àwọn ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù: “Nígbà tí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àkókò dé, Ọlọ́run rán Ọmọ rẹ̀ jáde, ẹni tí ó ti ara obìnrin jáde wá.” (Gálátíà 4:4) Bákan náà, àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ọ̀rọ̀ náà di ẹlẹ́ran ara, ó sì gbé láàárín wa, a sì rí ògo rẹ̀, ògo kan irú èyí tí ó jẹ́ ti ọmọ bíbí kan ṣoṣo láti ọ̀dọ̀ baba kan; ó sì kún fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti òtítọ́.”—Jòhánù 1:14.
Mèsáyà Fara Hàn
Ó kéré tán, nígbà tí ó fi tó ọmọ ọdún 12, ọ̀dọ́mọdé náà, Jésù ti wá mọ̀ pé ọwọ́ òun gbọ́dọ̀ dí fún ṣíṣe iṣẹ́ Baba òun ọ̀run. (Lúùkù 2:48, 49) Ní nǹkan bí ọdún 18 lẹ́yìn náà, Jésù wá sọ́dọ̀ Jòhánù Oníbatisí ní Odò Jọ́dánì, a sì batisí rẹ̀. Bí Jésù ti ń gbàdúrà, ọ̀run ṣí sílẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ sì bà lé e lórí. Fọkàn yàwòrán ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ohun tí yóò wá sí i lọ́kàn, bí ó ti ń rántí àìníye ẹgbẹ̀rúndún tí òun ti sìn ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú Bàbá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́, agbọ̀rọ̀sọ, olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ọlọ́run, àti Máíkẹ́lì, olórí áńgẹ́lì. Lẹ́yìn èyí ni ìdùnnú ti gbígbọ́ ohùn Baba rẹ̀ tí ń sọ fún Jòhánù Oníbatisí pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.”—Mátíù 3:16, 17; Lúùkù 3:21, 22.
Ó dájú pé, Jòhánù Oníbatisí kò ṣiyèméjì rárá pé Jésù ti wà kí a tó bí i gẹ́gẹ́ bí ènìyàn. Bí Jésù ti ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀, Jòhánù polongo pé: “Wò ó, Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ!” Ó sì fi kún un pé: “Èyí ni ẹni náà nípa ẹni tí mo wí pé, Lẹ́yìn mi, ọkùnrin kan ń bọ̀ tí ó ti lọ jìnnà níwájú mi, nítorí tí ó wà ṣáájú mi.” (Jòhánù 1:15, 29, 30) Àpọ́sítélì Jòhánù pẹ̀lú mọ̀ pé Jésù ti wà kí ó tó di ènìyàn. Ò kọ̀wé pé: “Ẹni tí ó ti òkè wá ga ju gbogbo àwọn yòókù lọ,” àti pé: “Ẹni tí ó ti ọ̀run wá ga ju gbogbo àwọn yòókù lọ. Ohun tí ó ti rí, tí ó sì ti gbọ́, nípa èyí ni ó ń jẹ́rìí.”—Jòhánù 3:31, 32.
Ní nǹkan bí ọdún 61 Sànmánì Tiwa, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni tí í ṣe Hébérù láti mọrírì ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìjẹ́pàtàkì dídé Mèsáyà sórí ilẹ̀ ayé àti iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà. Ní pípe àfiyèsí sí ipa tí Jésù kó gẹ́gẹ́ bí Agbọ̀rọ̀sọ, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ọlọ́run . . . ti tipasẹ̀ Ọmọ kan bá wa sọ̀rọ̀ ní òpin ọjọ́ wọ̀nyí . . . nípasẹ̀ ẹni tí òun dá àwọn ètò àwọn nǹkan.” Yálà èyí ń tọ́ka sí ipa Jésù gẹ́gẹ́ bí “àgbà òṣìṣẹ́” nígbà ìṣẹ̀dá tàbí sí ipa tí ó kó nínú àwọn ìṣètò oníṣísẹ̀ntẹ̀lé tí Ọlọ́run ṣe fún mímú ènìyàn padà bá òun rẹ́, níhìn-ín Pọ́ọ̀lù fi ẹ̀rí rẹ̀ kún un pé Jésù ti wà kí ó tó di ènìyàn.—Hébérù 1:1-6; 2:9.
Ìdúróṣinṣin Láti “Àwọn Àkókò Ìjímìjí”
Pọ́ọ̀lù sọ ọ̀rọ̀ ìyànjú yìí fún àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ní Fílípì pé: “Ẹ pa ẹ̀mí ìrònú yìí mọ́ nínú yín, èyí tí ó wà nínú Kristi Jésù pẹ̀lú, ẹni tí ó jẹ́ pé, bí ó tilẹ̀ wà ní ìrísí Ọlọ́run, kò ronú rárá nípa ìjá-nǹkan-gbà, èyíinì ni, pé kí òun bá Ọlọ́run dọ́gba. Ó tì o, ṣùgbọ́n ó sọ ara rẹ̀ di òfìfo, ó sì gbé ìrísí ẹrú wọ̀, ó sì wá wà ní ìrí ènìyàn. Ju èyíinì lọ, nígbà tí ó rí ara rẹ̀ ní àwọ̀ ènìyàn, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di onígbọràn títí dé ikú, bẹ́ẹ̀ ni, ikú lórí òpó igi oró.” (Fílípì 2:5-8) Jèhófà fi ìfẹ́ dáhùn padà sí ìgbésí ayé adúróṣinṣin tí Jésù gbé nípa jíjí i dìde àti fífi ayọ̀ gbà á padà sí ilé lókè ọ̀run. Àpẹẹrẹ títayọlọ́lá ti ìwà títọ́ jálẹ̀ àìníye ọdún ni Jésù mà fi lélẹ̀ fún wa o!—1 Pétérù 2:21.
A mà dúpẹ́ o fún ìmọ́lẹ̀ fìrí tí Bíbélì pèsè nípa ìwàláàyè Jésù kí a tó bí i gẹ́gẹ́ bí ènìyàn! Dájúdájú, wọ́n fi kún ìpinnu wa láti fara wé àpẹẹrẹ iṣẹ́ ìsìn adúróṣinṣin tí ó ṣe, ní pàtàkì nísinsìnyí tí ó ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Mèsáyà Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ kí a kókìkí “Ọmọ Aládé Àlàáfíà,” Kristi Jésù, Gómìnà àti Olùṣàkóso wa “ẹni tí orírun rẹ̀ jẹ́ láti àwọn àkókò ìjímìjí”!—Aísáyà 9:6; Míkà 5:2.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]
Ẹ̀rí Pé Ó Ti Wà Kí A Tó Bí I Gẹ́gẹ́ Bí Ènìyàn
Àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù fúnra rẹ̀ sọ, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sísàlẹ̀ yìí, jẹ́rìí sí i lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ pé ó ti wà kí a tó bí i gẹ́gẹ́ bí ènìyàn:
◻ “Kò sí ènìyàn kankan tí ó ti gòkè re ọ̀run bí kò ṣe ẹni tí ó sọ kalẹ̀ láti ọ̀run, Ọmọ ènìyàn.”—Jòhánù 3:13.
◻ “Mósè kò fún yín ní oúnjẹ láti ọ̀run, ṣùgbọ́n Baba mi ni ó fún yín ní oúnjẹ tòótọ́ láti ọ̀run. Nítorí pé oúnjẹ Ọlọ́run ni ẹni tí ó sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run tí ó sì fi ìyè fún ayé.” . . . èmi sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run, kì í ṣe láti ṣe ìfẹ́ mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi.”—Jòhánù 6:32, 33, 38.
◻ “Èyí ni oúnjẹ tí ó sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run, kí ẹnikẹ́ni lè jẹ nínú rẹ̀, kí ó má sì kú. Èmi ni oúnjẹ ààyè tí ó sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run; bí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, yóò wà láàyè títí láé.”—Jòhánù 6:50, 51.
◻ “Bí ẹ bá wá rí Ọmọ ènìyàn ń kọ́, tí ó ń gòkè lọ sí ibi tí ó wà tẹ́lẹ̀ rí?”—Jòhánù 6:62.
◻ “Òótọ́ ni ẹ̀rí mi, nítorí mo mọ ibi tí mo ti wá àti ibi tí mo ń lọ. . . . Ẹ̀yin wá láti àwọn ilẹ̀ àkóso ìsàlẹ̀; èmi wá láti àwọn ilẹ̀ àkóso òkè. Ẹ̀yin wá láti inú ayé yìí; èmi kò wá láti inú ayé yìí.”—Jòhánù 8:14, 23.
◻ “Bí ó bá jẹ́ pé Ọlọ́run ni Baba yín, ẹ̀yin ì bá nífẹ̀ẹ́ mi, nítorí pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni mo ti jáde wá, mo sì wà níhìn-ín. Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò wá rárá ní ìdánúṣe ara mi, ṣùgbọ́n Ẹni yẹn ni ó rán mi jáde.”—Jòhánù 8:42.
◻ “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Kí Ábúráhámù tó wà, èmi ti wà.”—Jòhánù 8:58.
◻ “Baba, ṣe mí lógo lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara rẹ pẹ̀lú ògo tí mo ti ní lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ kí ayé tó wà. Baba, ní ti ohun tí ìwọ ti fi fún mi, mo dàníyàn pé, níbi tí mo bá wà, kí àwọn náà lè wà pẹ̀lú mi, láti lè rí ògo mi tí ìwọ ti fi fún mi, nítorí pé ìwọ nífẹ̀ẹ́ mi ṣáájú ìgbà pípilẹ̀ ayé.”—Jòhánù 17:5, 24.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Jóṣúà pàdé olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jèhófà