Ǹjẹ́ a Sún Ọ Láti Ṣe Bíi Ti Jésù?
“Ó rí ogunlọ́gọ̀ ńlá, ṣùgbọ́n àánú wọ́n ṣe é, nítorí wọ́n dà bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ohun púpọ̀.”—MÁÀKÙ 6:34.
1. Èé ṣe tó fi bọ́gbọ́n mu pé àwọn kan ń fi ànímọ́ tó dáa gan-an hàn?
JÁLẸ̀ ìtàn aráyé, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti fi àwọn ànímọ́ tó dáa gan-an hàn. O ṣeé ṣe kóo mọ ohun tó fà á. Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́, tó ń fi ìfẹ́, inú rere, ọ̀làwọ́, àti àwọn ànímọ́ rere mìíràn hàn. A sì dá àwa èèyàn ní àwòrán Ọlọ́run. Nítorí náà, a lè mọ̀dí tó fi yẹ kí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ìfẹ́, inú rere, àánú, àti àwọn ànímọ́ mìíràn tó jẹ́ ti Ọlọ́run hàn, pàápàá jù lọ níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn ti fi hàn pé àwọn lẹ́rìí-ọkàn. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26; Róòmù 2:14, 15) Ṣùgbọ́n, o lè ti ṣàkíyèsí pé àwọn kan ń fi àwọn ànímọ́ yìí hàn ju àwọn ẹlòmíràn lọ.
2. Kí ni díẹ̀ lára iṣẹ́ rere táwọn èèyàn lè ṣe, tó lè mú kí wọ́n rò pé àwọn ń fara wé Kristi?
2 Ó ṣeé ṣe kóo mọ àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin kan tí wọ́n máa ń bẹ àwọn aláìsàn wò lóòrèkóòrè tàbí tí wọ́n máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́, tí wọ́n ń ṣoore fún àwọn aláàbọ̀ ara, tàbí tí wọ́n lawọ́ sí àwọn tálákà. Tún ronú nípa àwọn kan tí àánú sún wọn láti máa fi gbogbo ìgbésí ayé wọn ṣiṣẹ́ ní ibùdó àwọn adẹ́tẹ̀ tàbí ti àwọn ọmọ òrukàn, àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti ṣiṣẹ́ ní ilé ìwòsàn tàbí ní ilé ìtọ́jú àwọn ọmọ wẹ́wẹ́, tàbí àwọn tí ń làkàkà láti ran àwọn aláìnílélórí tàbí àwọn tí ogun lé kúrò nílùú lọ́wọ́. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé, àwọn kan lára wọn rò pé àwọn ń fara wé Jésù, ẹni tó fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún àwọn Kristẹni láti tẹ̀ lé. A kà nínú ìwé Ìhìn Rere pé Kristi wo àwọn aláìsàn sàn, ó sì bọ́ àwọn tí ebi ń pa. (Máàkù 1:34; 8:1-9; Lúùkù 4:40) Fífi tí Jésù fi ìfẹ́, ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn, àti àánú hàn fi “èrò inú Kristi” hàn, ẹni tó jẹ́ pé baba rẹ̀ ọ̀run ni òun náà ń fara wé.—1 Kọ́ríńtì 2:16.
3. Láti lè ní èrò tí kò fì síbì kan nípa àwọn iṣẹ́ rere tí Jésù ṣe, kí la ní láti gbé yẹ̀ wò?
3 Ǹjẹ́ o ti ṣàkíyèsí pé lóde òní, ọ̀pọ̀ àwọn tí ìfẹ́ àti àánú tí Jésù ní wọ̀ lọ́kàn ń gbójú fo apá pàtàkì kan nínú èrò inú Kristi dá? A lè lóye ohun tó fà á, báa bá fara balẹ̀ gbé Máàkù orí kẹfà yẹ̀ wò. A kà níbẹ̀ pé, àwọn ènìyàn ń gbé àwọn aláìsàn wá sọ́dọ̀ Jésù, kó lè wò wọ́n sàn. Nínú àyíká ọ̀rọ̀ náà, a tún gbọ́ pé nígbà tí Jésù rí i pé ebi ń pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tó wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó bọ́ wọn lọ́nà ìyanu. (Máàkù 6:35-44, 54-56) Lóòótọ́, wíwo àwọn aláìsàn sàn àti bíbọ́ àwọn tí ebi ń pa jẹ́ ọ̀nà títayọ tí Jésù gbà fi àánú onífẹ̀ẹ́ hàn, ṣùgbọ́n, ṣé ìwọ̀nyí ni ọ̀nà pàtàkì tó gbà ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ ni? Báwo la sì ṣe lè fara wé àpẹẹrẹ pípé tó fi lélẹ̀ ní ti ìfẹ́, inú rere, àti àánú, àní gẹ́gẹ́ bó ti fara wé Jèhófà?
A Sún Un Láti Wá Nǹkan Ṣe sí Àìní Tẹ̀mí
4. Báwo ni ìtàn tó wà nínú Máàkù orí kẹfà, ẹsẹ ọgbọ̀n sí ìkẹrìnlélọ́gbọ̀n ṣe wáyé?
4 Jésù ṣàánú àwọn tó wà nítòsí rẹ̀, ní pàtàkì, nítorí àìní wọn nípa tẹ̀mí. Àwọn àìní yẹn ṣe pàtàkì gidigidi, kódà, wọ́n ṣe pàtàkì ju àìní nípa tara lọ. Gbé àkọsílẹ̀ tó wà nínú Máàkù orí kẹfà, ẹsẹ ọgbọ̀n sí ìkẹrìnlélọ́gbọ̀n yẹ̀ wò. Ìtàn táa kọ síbẹ̀ ṣẹlẹ̀ ní etí Òkun Gálílì, nígbà tó kù díẹ̀ kí Ìrékọjá ọdún 32 Sànmánì Tiwa wáyé. Inú àwọn àpọ́sítélì náà dùn gan-an, ó sì nídìí tó fi rí bẹ́ẹ̀. Wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ìrìn àjò gígùn kan dé, wọ́n wá sọ́dọ̀ Jésù, kò sì sí àní-àní pé wọ́n ń hára gàgà láti sọ ìrírí wọn fún un. Ṣùgbọ́n, èrò pọ̀ lọ bí omi. Wọ́n pọ̀ débi pé Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ kò ráyè jẹun, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò ráyè sinmi. Ni Jésù bá sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Ẹ máa bọ̀, ẹ̀yin fúnra yín, ní ẹ̀yin nìkan sí ibi tí ó dá, kí ẹ sì sinmi díẹ̀.” (Máàkù 6:31) Ni wọ́n bá wọkọ̀ ojú omi, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ lẹ́bàá Kápánáúmù, wọ́n tukọ̀ kọjá Òkun Gálílì, wọ́n lọ sí ibi tó parọ́rọ́. Ṣùgbọ́n àwọn èrò náà tún ń gba etíkun náà sáré lọ, kí ọkọ̀ ojú omi náà tó gúnlẹ̀, wọ́n ti ṣáájú rẹ̀ débẹ̀. Kí ni Jésù yóò wá ṣe báyìí? Ǹjẹ́ inú bí i nítorí pé wọn ò jẹ́ kó sinmi? Rárá o!
5. Báwo ló ti rí lára Jésù nígbà tí àwọn èrò wá sọ́dọ̀ rẹ̀, kí ló sì ṣe?
5 Rírí tí Jésù rí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn tí wọ́n ń hára gàgà láti rí i, títí kan àwọn aláìsàn, àánú wọn ṣe é. (Mátíù 14:14; Máàkù 6:44) Nígbà tí Máàkù ń sọ̀rọ̀ lórí ohun tó jẹ́ kí Jésù fi irú àánú bẹ́ẹ̀ hàn àti ohun tí Ó ṣe, ó kọ̀wé pé: “Ó rí ogunlọ́gọ̀ ńlá, ṣùgbọ́n àánú wọ́n ṣe é, nítorí wọ́n dà bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ohun púpọ̀.” (Máàkù 6:34.) Ohun tí Jésù rí ju èrò rẹpẹtẹ lọ. Ó rí àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìní nípa tẹ̀mí. Wọ́n dà bí àwọn àgùntàn tó ń rìn gbéregbère kiri láìlólùṣọ́ tí yóò darí wọn sí pápá oko tútù tàbí tí yóò dáàbò bò wọn. Jésù mọ̀ pé àwọn ìkà aṣáájú ìsìn, tó yẹ kí wọ́n jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tó ń bójú tó agbo wọn, ń fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn gbáàtúù, wọn kò sì bìkítà nípa àìní wọn nípa tẹ̀mí rárá. (Ísíkíẹ́lì 34:2-4; Jòhánù 7:47-49) Jésù ò jẹ́ hùwà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni yóò ṣe oore tó bá lè ṣe fún wọn. Ló wá bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn nípa Ìjọba Ọlọ́run.
6, 7. (a) Kí ni àwọn ìwé Ìhìn Rere fi hàn nípa ohun tí Jésù ṣe láti tán àìní àwọn ènìyàn? (b) Kí ló sún Jésù láti wàásù kí ó sì kọ́ni?
6 Nínú àkọsílẹ̀ mìíràn tó fara jọ èyí táa sọ tán yìí, ṣàkíyèsí bí nǹkan náà ṣe ṣẹlẹ̀ àti nǹkan tó ṣáájú. Lúùkù, oníṣègùn, ẹni tó jẹ́ pé olórí àníyàn rẹ̀ ni pé kí ara àwọn èèyàn le, ló kọ ọ́. “Àwọn ogunlọ́gọ̀ tẹ̀ lé [Jésù]. Ó sì fi inú rere gbà wọ́n, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ fún wọn nípa ìjọba Ọlọ́run, ó sì mú àwọn tí wọ́n nílò ìwòsàn lára dá.” (Lúùkù 9:11; Kólósè 4:14) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àkọsílẹ̀ tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ìyanu, nínú èyí, kí ni àkọsílẹ̀ ìwé Lúùkù táa mí sí kọ́kọ́ kíyè sí? Ohun ni pé Jésù kọ́ àwọn ènìyàn náà lẹ́kọ̀ọ́.
7 Ká sòótọ́, èyí bá ohun táa tẹnu mọ́ nínú Máàkù orí kẹfà, ẹsẹ ìkẹrìnlélọ́gbọ̀n mu. Ẹsẹ yẹn fi hàn ní kedere ìdí pàtàkì tí àánú fi ṣe Jésù. Ó kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, ó tán àìní wọn nípa tẹ̀mí. Jésù ti sọ ṣáájú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ pé: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú ńlá mìíràn pẹ̀lú, nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.” (Lúùkù 4:43) Síbẹ̀, yóò jẹ́ èrò òdì gbáà, táa bá ń rò pé Jésù polongo iṣẹ́ Ìjọba náà nítorí pé ó kàn kà á sí iṣẹ́ tí òun ò ríbi yẹ̀ ẹ́ sí, bí ẹni pé ó kàn ń fara ṣe é, tí kò fọkàn ṣe é. Rárá o, ìfẹ́ tó kún fún àánú, èyí tó ní sí àwọn ènìyàn ni olórí ohun tó sún un láti máa bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ìhìn rere náà. Ohun rere títóbi jù lọ tí Jésù lè ṣe fún àwọn aláìsàn, àwọn tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu, àwọn òtòṣì, tàbí àwọn tí ebi ń pa ni pé, kó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run, kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kí wọ́n sì tẹ́wọ́ gbà á. Òtítọ́ yẹn ṣe pàtàkì gan-an nítorí ipa tí Ìjọba náà ń kó nínú dídá ipò ọba aláṣẹ Jèhófà láre àti láti rọ̀jò ìbùkún sórí aráyé títí láé.
8. Ojú wo ni Jésù fi wo iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ àti ẹ̀kọ́ tó fi ń kọ́ni?
8 Ìtara tí Jésù fi wàásù nípa Ìjọba náà ló jẹ́ ká mọ ìdí pàtàkì tó fi wá sáyé. Nígbà tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ń parí lọ, Jésù wí fún Pílátù pé: “Nítorí èyí ni a ṣe bí mi, nítorí èyí sì ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́. Olúkúlùkù ẹni tí ó bá wà ní ìhà ọ̀dọ̀ òtítọ́ ń fetí sí ohùn mi.” (Jòhánù 18:37) A ti ṣàkíyèsí nínú àpilẹ̀kọ méjèèjì tó ṣáájú pé Jésù jẹ́ ẹni tó lẹ́mìí ìbánikẹ́dùn—ó bìkítà nípa ẹni, ó ṣeé sún mọ́, ó ń gba tẹni rò, ó ń fọkàn tánni, ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó nífẹ̀ẹ́. Ó yẹ ká mọrírì àwọn ànímọ́ rẹ̀ wọ̀nyí bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ la fẹ́ mọ èrò inú Kristi. Bákan náà, ó tún ṣe pàtàkì láti mọ̀ pé èrò inú Kristi ní í ṣe pẹ̀lú bó ṣe fi iṣẹ́ ìwàásù àti ti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ sí ipò kìíní.
Ó Rọ Àwọn Ẹlòmíràn Láti Jẹ́rìí
9. Àwọn wo ló yẹ kó fi iṣẹ́ ìwàásù àti ìkọ́ni sí ipò kìíní?
9 Kí Jésù lè fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀dá àti pé òun jẹ́ aláàánú, kì í ṣe òun nìkan ló yẹ ko fi iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni sí ipò àkọ́kọ́. Ó rọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa fara wé ète òun, góńgó òun, àti ìgbésẹ̀ òun. Fún àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Jésù yan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá, iṣẹ́ wo ni wọ́n fẹ́ ṣe? Máàkù orí kẹta, ẹsẹ ìkẹrìnlá àti ìkẹẹ̀ẹ́dógún sọ fún wa pé: “Ó sì kó àwùjọ àwọn méjìlá jọ, àwọn tí ó pè ní ‘àpọ́sítélì’ pẹ̀lú, kí wọ́n lè máa bá a lọ ní wíwà pẹ̀lú òun, kí ó sì lè rán wọn jáde láti wàásù àti láti ní ọlá àṣẹ láti máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.” Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí ohun táwọn àpọ́sítélì fi sí ipò kìíní?
10, 11. (a) Nígbà tí Jésù ń rán àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ jáde, kí ló sọ pé kí wọ́n máa ṣe? (b) Nígbà tó ń rán àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ jáde, kí ló darí àfiyèsí wọn sí?
10 Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, Jésù fún àwọn méjìlá náà lágbára láti wo àwọn ẹlòmíràn sàn, kí wọ́n sì lé ẹ̀mí èṣù jáde. (Mátíù 10:1; Lúùkù 9:1) Ó wá rán wọn lọ́ sí ọ̀dọ̀ “àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tí wọ́n sọnù.” Láti ṣe kí ni? Jésù pàṣẹ fún wọn pé: “Bí ẹ ti ń lọ, ẹ máa wàásù, pé, ‘Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.’ Ẹ wo àwọn aláìsàn sàn, ẹ gbé àwọn ẹni tí ó ti kú dìde, ẹ mú kí àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́, ẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.” (Mátíù 10:5-8; Lúùkù 9:2) Kí ni wọ́n ṣe lóòótọ́? “Nítorí náà, wọ́n mú ọ̀nà wọn pọ̀n, [1] wọ́n sì wàásù kí àwọn ènìyàn bàa lè ronú pìwà dà; [2] wọn a sì máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù púpọ̀ jáde, wọn a sì fi òróró pa àwọn aláìsàn, wọn a sì wò wọ́n sàn.”—Máàkù 6:12, 13.
11 Níwọ̀n bí kì í ti í ṣe gbogbo ìgbésẹ̀ táa mẹ́nu kàn pé wọ́n gbé la ti gbọ́ pé wọ́n kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, ǹjẹ́ kíkíyèsí bí àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe ṣẹlẹ̀ kò ha fi hàn pé mímọ àwọn ohun tó yẹ ká fi sí ipò kìíní tàbí mímọ ète táa ní lọ́kàn, ló ṣe pàtàkì jù? (Lúùkù 10:1-8) Ṣùgbọ́n, kò yẹ ká fojú di iye ìgbà táa mẹ́nu kan iṣẹ́ kíkọ́ni, ká tó wá mẹ́nu kan iṣẹ́ ìwòsàn o. Gbé ohun tó yí ọ̀ràn yìí ká yẹ̀ wò. Kó tó di pé Jésù rán àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá jáde, ipò tí àwọn ogunlọ́gọ̀ náà wà ká a lára. A kà pé: “Jésù sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n nínú ìrìn àjò ìbẹ̀wò sí gbogbo àwọn ìlú ńlá àti àwọn abúlé, ó ń kọ́ni nínú àwọn sínágọ́gù wọn, ó sì ń wàásù ìhìn rere ìjọba náà, ó sì ń ṣe ìwòsàn gbogbo onírúurú òkùnrùn àti gbogbo onírúurú àìlera ara. Nígbà tí ó rí àwọn ogunlọ́gọ̀, àánú wọn ṣe é, nítorí a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn. Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: ‘Bẹ́ẹ̀ ni, ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.’”—Mátíù 9:35-38.
12. Ète mìíràn wo ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù àti àwọn àpọ́sítélì ṣe ṣiṣẹ́ fún?
12 Wíwà tí àwọn àpọ́sítélì wà pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́ kí wọ́n lè fara mọ́ èrò inú Kristi. Wọ́n lè rí i pé tí àwọn bá fẹ́ jẹ́ ẹni tó nífẹ̀ẹ́, tó sì láàánú àwọn ènìyàn, iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni nípa Ìjọba náà yóò jẹ́ apá pàtàkì nínú iṣẹ́ rere tí wọn yóò máa ṣe. Ní ìbámu pẹ̀lú ìyẹn, àǹfààní tí àwọn iṣẹ́ rere tó jẹ mọ́ pípèsè ohun ti ara mú wá, bíi ká woni sàn, kọjá pé ká kàn ṣèrànwọ́ fún àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́. Bí ìwọ náà ti lè fojú inú wò ó, a lè ru ìfẹ́ àwọn kan sókè nípa wíwoni sàn àti nípa pípèsè oúnjẹ lọ́nà ìyanu. (Mátíù 4:24, 25; 8:16; 9:32, 33; 14:35, 36; Jòhánù 6:26) Ṣùgbọ́n o, yàtọ̀ sí pé àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyẹn ranni lọ́wọ́ nípa ti ara, wọ́n tún sún àwọn tó kíyè sí i láti gbà pé Jésù ni Ọmọ Ọlọ́run àti “wòlíì” tí Mósè ti sọ tẹ́lẹ̀.—Jòhánù 6:14; Diutarónómì 18:15.
13. Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ tí Diutarónómì orí kejìdínlógún, ẹsẹ ìkejìdínlógún tẹnu mọ́ nípa “wòlíì” tó ń bọ̀?
13 Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé Jésù ni “wòlíì” náà? Ó dára, kí ni ipa pàtàkì tí a sọ tẹ́lẹ̀ pé ẹni yẹn yóò kó? Ṣé òkìkí “wòlíì” náà yóò kàn káàkiri kìkì nítorí pé ó ń ṣe iṣẹ́ ìwòsàn tàbí nítorí pé ó ń ṣàánú fún àwọn ènìyàn láti pèsè oúnjẹ fún àwọn ti ebi ń pa ni? Diutarónómì orí kejìdínlógún, ẹsẹ ìkejìdínlógún sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Wòlíì kan ni èmi yóò gbé dìde fún wọn ní àárín àwọn arákùnrin wọn, bí ìwọ [Mósè]; ní tòótọ́, èmi yóò sì fi àwọn ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ̀, dájúdájú, òun yóò sì sọ gbogbo ohun tí èmi yóò pa láṣẹ fún un fún wọn.” Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àpọ́sítélì ti kọ́ bí a ṣe ń gba tẹni rò àti báa ṣe ń fi ẹ̀mí náà hàn, wọ́n lè parí èrò sí pé èrò inú Kristi yóò tún hàn nínú ìgbòkègbodò ìwàásù àti ìkọ́ni wọn. Ìyẹn ni yóò jẹ́ ohun tó dára jù lọ tí wọ́n lè ṣe fáwọn èèyàn. Nípa ìyẹn ni àwọn aláìsàn àti òtòṣì fi lè rí àǹfààní tí yóò wà pẹ́ títí gbà, kò ní jẹ́ àwọn àǹfààní tó wà fún kìkì ìgbà ìwàláàyè kúkúrú tí ènìyàn ń lò tàbí oúnjẹ ìjókòó ẹ̀ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀méjì.—Jòhánù 6:26-30.
Mú Èrò Inú Kristi Dàgbà Lónìí
14. Báwo ni níní èrò inú Kristi ṣe wé mọ́ wíwàásù?
14 Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tó gbọ́dọ̀ lérò pé èrò inú Kristi pin sí ọ̀rúndún kìíní, pé ó pin sọ́dọ̀ Jésù àti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ìjímìjí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa wọn pé: “Ṣùgbọ́n àwa ní èrò inú ti Kristi.” (1 Kọ́ríńtì 2:16) Ó sì dájú pé gbogbo wa la ó gbà pé ó di dandan fún wa láti wàásù ìhìn rere, kí a sì sọni di ọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Síbẹ̀, ó ṣàǹfààní láti ronú lórí ohun tó ń sún wa ṣe iṣẹ́ yẹn. Kò yẹ kó jẹ́ pé ẹ̀mí iṣẹ́-yìí-ò-ṣeé-yẹ̀-sílẹ̀ la fi ń ṣe é. Ìfẹ́ táa ní sí Ọlọ́run ni ìdí pàtàkì táa fi ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, òótọ́ sì ni, táa bá fẹ́ dà bí Jésù, ó ń béèrè pé kí àánú tá a ní sáwọn èèyàn sún wa láti wàásù, ká sì kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́.—Mátíù 22:37-39.
15. Èé ṣe tí àánú fi jẹ́ apá yíyẹ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí à ń mú tọ gbogbo ènìyàn lọ?
15 Lóòótọ́, kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti máa ṣàánú fún àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn yàtọ̀ sí tiwa, ní pàtàkì, nígbà táwọn èèyàn ò bá bìkítà, tí wọn ò gba tiwa, tàbí tí wọ́n ń takò wá ṣáá. Síbẹ̀, bí a kò bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ènìyàn mọ́, tí àánú wọn ò sì ṣe wá mọ́, a lè di ẹni tí kò lóhun tó ń sún un láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Nígbà náà, báwo la ṣe lè ní àánú lójú? A lè gbìyànjú láti fojú tí Jésù fi wo àwọn ènìyàn wò wọ́n, ìyẹn ni ‘bí ẹni tí a bó láwọ, tí a sì fọ́n ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.’ (Mátíù 9:36) Ǹjẹ́ ìyẹn ò ṣàpèjúwe bí ọ̀pọ̀ ti rí lónìí? Àwọn olùṣọ́ àgùntàn ẹ̀sìn èké ti pa wọ́n tì, wọ́n sì ti fọ́ wọn lójú nípa tẹ̀mí. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, wọn kò mọ̀ nípa ìtọ́sọ́nà tó yè kooro táa rí nínú Bíbélì tàbí nípa ipò Párádísè tí Ìjọba Ọlọ́run yóò mú wá sórí ilẹ̀ ayé láìpẹ́. Pẹ̀lú pé wọn ò ní ìrètí Ìjọba náà, wọ́n ń dojú kọ àwọn ìṣòro ìgbésí ayé ojoojúmọ́—títí kan òṣì, èdè-àìyédè nínú ìdílé, àìsàn, àti ikú. A ní ohun tí wọ́n nílò: ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run táa ti gbé kalẹ̀ ní ọ̀run báyìí, èyí tó lè gbẹ̀mí là!
16. Èé ṣe táa fi fẹ́ láti máa sọ ìhìn rere náà fún àwọn ẹlòmíràn?
16 Nígbà tóo bá ronú lórí àwọn ohun tẹ̀mí tí àwọn tó yí ọ ká ṣaláìní, ǹjẹ́ ọkàn rẹ̀ kò ha sún ọ láti fẹ́ ṣe gbogbo ohun tóo lè ṣe láti rí i pé o sọ fún wọn nípa ète onífẹ̀ẹ́ tí Ọlọ́run ní nípa wọn? Bẹ́ẹ̀ ni, iṣẹ́ aláàánú niṣẹ́ wa. Nígbà tí àánú àwọn ènìyàn bá ṣe wá, gẹ́gẹ́ bó ti ṣe Jésù, kíá ló máa hàn nínú ohùn wa, yóò hàn lójú wa, yóò sì hàn nínú ọ̀nà táa gbà ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. Gbogbo ìyẹn ni yóò mú kí iṣẹ́ wa túbọ̀ wu àwọn tí “wọ́n . . . ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun.”—Ìṣe 13:48.
17. (a) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà táa lè gbà fi ìfẹ́ àti àánú hàn fún àwọn ẹlòmíràn? (b) Èé ṣe tí kì í fi í ṣe ọ̀ràn ṣíṣe iṣẹ́ rere nìkan ṣoṣo tàbí ṣíṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ nìkan ṣoṣo?
17 Àmọ́ ṣá o, ìfẹ́ àti àánú táa ní yóò hàn nínú ìgbésí ayé wa. Èyí kan ṣíṣoore fún àwọn tí kò rí já jẹ, àwọn tó ń ṣàìsàn, àwọn òtòṣì—ká máa ṣe ohun tí agbára wa bá ká láti gbọn ìyà dà nù lára wọn. Ó tún kan ìsapá wa nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe láti tu àwọn tí èèyàn wọn kú nínú. (Lúùkù 7:11-15; Jòhánù 11:33-35) Síbẹ̀, a kò gbọ́dọ̀ gbà pé irú fífi ìfẹ́, inú rere, àti àánú hàn lọ́nà bẹ́ẹ̀ nìkan ni iṣẹ́ rere tó yẹ ká ṣe, gẹ́gẹ́ bí èrò àwọn kan tó jẹ́ òṣìṣẹ́ afẹ́dàáfẹ́re. Tó bá jẹ́ pé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run ló súnni ṣe irú ìsapá bẹ́ẹ̀, tó sì wá hàn nínú nínípìn-ín nínú iṣẹ́ ìwàásù àti ti kíkọ́ni tí àwọn Kristẹni ń ṣe, ìjẹ́pàtàkì rẹ̀ yóò wà pẹ́ títí. Rántí ohun tí Jésù sọ nípa àwọn aṣáájú ìsìn àwọn Júù pé: “Ẹ ń fúnni ní ìdá mẹ́wàá efinrin àti ewéko dílì àti ewéko kúmínì, ṣùgbọ́n ẹ ṣàìka àwọn ọ̀ràn wíwúwo jù lọ nínú Òfin sí, èyíinì ni, ìdájọ́ òdodo àti àánú àti ìṣòtítọ́. Àwọn ohun wọ̀nyí pọndandan ní ṣíṣe, síbẹ̀ àwọn ohun yòókù ni kí ẹ má ṣàìkà sí.” (Mátíù 23:23) Jésù kò ṣèkan kó wá fi ìkejì sílẹ̀, kó ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ nípa ti ara, kó wá gbójú fo àìní wọn nípa tẹ̀mí. Méjèèjì ni Jésù ṣe. Síbẹ̀, ó ṣe kedere pé iṣẹ́ ìkọ́ni tó ń ṣe ló mú ní ọ̀kúnkúndùn nítorí pé rere tí ó ń tibẹ̀ jáde lè ranni lọ́wọ́ títí láé.—Jòhánù 20:16.
18. Táa bá gbé èrò inú Kristi yẹ̀ wò, kí ni yóò sún wa láti ṣe?
18 Ó mà yẹ ká kún fún ọpẹ́ o, pé Jèhófà jẹ́ ká mọ èrò inú Kristi! Nípasẹ̀ àwọn ìwé Ìhìn Rere, a lè túbọ̀ wá mọ̀ nípa èrò, ìmọ̀lára, ànímọ́, ìgbòkègbodò, àti àwọn ohun tó gba ipò kìíní nínú ìgbésí ayé ọkùnrin atóbilọ́lá jù lọ tó tíì gbé ayé rí. Ó wá kù sọ́wọ́ wa láti kà á, láti ṣàṣàrò lé e lórí, àti láti fi ohun tí Bíbélì bá ṣí payá nípa Jésù ṣèwà hù. Ẹ rántí pé, bí a óò bá máa hùwà bíi ti Jésù, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ kọ́ bí a ó ṣe máa ronú bíi tirẹ̀, báa ṣe máa ní irú ojú ìwòye tó ní, tá ó sì máa gbé ọ̀ràn yẹ̀ wò bó ṣe máa ń gbé e yẹ̀ wò, a ó ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí débi tí agbára wa bá gbé e dé gẹ́gẹ́ bí ènìyàn aláìpé. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu láti ní èrò inú Kristi, kí a sì fi í hàn. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, kò sí ọ̀nà míì táa lè gbà gbé ìgbésí ayé, kò sí ọ̀nà míì táa lè gbà bá àwọn èèyàn lò, kò sì sí ọ̀nà mìíràn tí àwa àti àwọn ẹlòmíràn lè gbà sún mọ́ ẹni náà tí Jésù jọ láìkù síbì kan, ìyẹn ni Ọlọ́run tó ń gba tẹni rò, Jèhófà.—2 Kọ́ríńtì 1:3; Hébérù 1:3.
Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?
• Òye wo ni Bíbélì fún wa láti mọ bí Jésù ṣe bójú tó àìní àwọn ènìyàn?
• Kí ni Jésù tẹnu mọ́ nígbà tó ń pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀?
• Báwo la ṣe lè fi “èrò inú Kristi” hàn nínú gbogbo ìgbòkègbodò wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ohun rere tó dára jù lọ wo ni àwọn Kristẹni lè ṣe fún àwọn ẹlòmíràn?