Ẹ̀KỌ́ 21
Báwo La Ṣe Ń Wàásù Ìhìn Rere?
Láìpẹ́, Jèhófà máa mú gbogbo ìṣòro wa kúrò nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀. Ìròyìn ayọ̀ tó yẹ kí gbogbo èèyàn gbọ́ ni. Jésù fẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn òun sọ ìròyìn náà fún gbogbo èèyàn! (Mátíù 28:19, 20) Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ṣe ohun tí Jésù sọ yìí?
1. Báwo ni ohun tó wà ní Mátíù 24:14 ṣe ń ṣẹ lóde òní?
Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.” (Mátíù 24:14) Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń dùn láti máa ṣe iṣẹ́ pàtàkì yìí. À ń wàásù ìhìn rere yìí kárí ayé ní èdè tó ju ẹgbẹ̀rún kan (1,000) lọ! Iṣẹ́ ńlá ni iṣẹ́ yìí o! Ó gba àkókò àti okun, ó sì gba pé ká ṣètò ẹ̀ dáadáa. A ò lè ṣe iṣẹ́ náà láìsí ìrànlọ́wọ́ Jèhófà.
2. Àwọn nǹkan wo là ń ṣe ká lè rí i pé a ń wàásù ìhìn rere fún gbogbo èèyàn?
A máa ń wàásù níbikíbi tá a bá ti lè rí àwọn èèyàn. Bíi ti àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, a máa ń wàásù “láti ilé dé ilé.” (Ìṣe 5:42) Ọ̀nà tá à ń gbà wàásù yìí ń jẹ́ ká lè wàásù fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lọ́dọọdún. Nítorí pé àwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ sí nílé, a tún máa ń wàásù láwọn ibòmíì tá a ti lè rí wọn. A máa ń lo gbogbo àǹfààní tá a bá rí láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà àtàwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe fáráyé.
3. Ojúṣe àwọn wo ni láti máa wàásù ìhìn rere?
Ojúṣe gbogbo àwọn Kristẹni tòótọ́ ni láti máa wàásù ìhìn rere fún àwọn èèyàn. Ọwọ́ pàtàkì la fi mú iṣẹ́ yìí. A máa ń ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti wàásù fáwọn èèyàn torí a fẹ́ kí wọ́n rí ìgbàlà. (Ka 1 Tímótì 4:16.) A kì í gba owó nídìí iṣẹ́ yìí nítorí Bíbélì sọ pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ gbà á, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.” (Mátíù 10:7,8) Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa ń fẹ́ gbọ́ ìhìn rere tá à ń wàásù. Àmọ́, a kì í jẹ́ kó sú wa, torí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe jẹ́ ara ọ̀nà tá à ń gbà jọ́sìn Jèhófà, ó sì ń múnú rẹ̀ dùn.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Kẹ́kọ̀ọ́ sí i kó o lè mọ bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ṣiṣẹ́ kára láti wàásù kárí ayé àti bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́.
4. À ń ṣiṣẹ́ kára láti dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣiṣẹ́ kára gan-an láti wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn níbi gbogbo. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Kí ló wú ẹ lórí nípa ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe láti rí i pé àwọn wàásù fáwọn èèyàn?
Ka Mátíù 22:39 àti Róòmù 10:13-15, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù wa ṣe ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wa?
Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tó ń wàásù ìhìn rere?—Wo ẹsẹ 15.
5. À ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run
Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń ṣẹlẹ̀ tó fi hàn pé Jèhófà ló ń darí iṣẹ́ wa. Bí àpẹẹrẹ, nílẹ̀ New Zealand arákùnrin kan tó ń jẹ́ Paul bá obìnrin kan sọ̀rọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé lọ́sàn-án ọjọ́ kan. Láàárọ̀ ọjọ́ yẹn, obìnrin náà ti gbàdúrà pé kí ẹnì kan wá sọ́dọ̀ òun, ó sì lo Jèhófà tó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run nínú àdúrà rẹ̀. Paul sọ pé, “Wákàtí mẹ́ta lẹ́yìn náà, mo dé ẹnu ọ̀nà ilé obìnrin náà.”
Ka 1 Kọ́ríńtì 3:9, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Báwo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ nílẹ̀ New Zealand ṣe fi hàn pé Jèhófà ló ń darí iṣẹ́ ìwàásù wa?
Ka Ìṣe 1:8, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká wá ìrànlọ́wọ́ Jèhófà tá a bá fẹ́ ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa?
Ǹjẹ́ o mọ̀?
Ní ìpàdé tá a máa ń ṣe láàárín ọ̀sẹ̀, a máa ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó ń jẹ́ ká lè wàásù. Tó bá jẹ́ pé o ti lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìpàdé náà, kí lo lè sọ nípa ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá à ń gbà níbẹ̀?
6. Àṣẹ Ọlọ́run là ń tẹ̀ lé bá a ṣe ń wàásù
Nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, àwọn alátakò gbìyànjú láti dá iṣẹ́ ìwàásù táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ń ṣe dúró. Àmọ́, àwọn Kristẹni yẹn ‘fìdí ìhìn rere múlẹ̀ lọ́nà tó bófin mu’ kí wọ́n lè jà fún ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti wàásù. (Fílípì 1:7) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe ohun kan náà lónìí.a
Ka Ìṣe 5:27-42, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
ẸNÌ KAN LÈ BÉÈRÈ PÉ: “Kí nìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa ń wàásù láti ilé dé ilé?”
Kí lo máa sọ?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa wàásù ní gbogbo orílẹ̀-èdè. Jèhófà ń fún àwọn èèyàn rẹ̀ lókun láti máa ṣe iṣẹ́ yìí.
Kí lo rí kọ́?
Àwọn wo ló ń wàásù ìhìn rere kárí ayé?
Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù wa ṣe ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn?
Ṣé o rò pé iṣẹ́ ìwàásù lè fúnni láyọ̀? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
ṢÈWÁDÌÍ
Wo fídíò yìí kó o lè rí bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń wàásù fáwọn èèyàn láwọn ìlú ńlá.
Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe kí wọ́n lè wàásù fún àwọn tí ogun tàbí àwọn ìṣòro míì lé kúrò nílùú wọn.
Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun tó ń mú kí obìnrin kan láyọ̀ bó ṣe ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù.
Ka ìwé yìí kó o lè rí báwọn ilé ẹjọ́ ṣe dá wa láre, tí ìyẹn sì ti mú kí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà tẹ̀ síwájú.
“Àwọn Akéde Ìjọba Ọlọ́run Gbé Ọ̀rọ̀ Lọ Sílé Ẹjọ́” (Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!, orí 13)
a Ọlọ́run ló pàṣẹ pé ká máa wàásù. Torí náà, kò sídìí fáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti gba àṣẹ lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ ayé ká tó lè wàásù ìhìn rere.