Ẹ̀KỌ́ 38
Fi Hàn Pé O Mọyì Ẹ̀mí
Ọ̀pọ̀ nǹkan ló mú kí ayé dùn láti gbé. Kódà tá a bá tiẹ̀ láwọn ìṣòro kan, a ṣì lè gbádùn ayé wa níwọ̀nba. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ẹ̀mí wa? Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká mọyì ẹ̀mí wa?
1. Kí nìdí tó fi yẹ ká mọyì ẹ̀mí?
Ó yẹ ká mọyì ẹ̀mí wa torí pé ó jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà Baba wa onífẹ̀ẹ́. Òun ni “orísun ìyè,” ìyẹn ni pé òun ló dá gbogbo nǹkan. (Sáàmù 36:9) “Òun fúnra rẹ̀ ló ń fún gbogbo èèyàn ní ìyè àti èémí.” (Ìṣe 17:25, 28) Gbogbo nǹkan tó lè gbé ẹ̀mí wa ró ni Jèhófà ń fún wa. Bákan náà, ó tún ń fún wa láwọn nǹkan tó lè jẹ́ ká gbádùn ayé wa.—Ka Ìṣe 14:17.
2. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ẹ̀mí tí Jèhófà fún wa?
Àtìgbà tó o ti wà nínú oyún ni Jèhófà ti ń tọ́jú ẹ. Dáfídì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùjọ́sìn Jèhófà sọ nínú àdúrà rẹ̀ pé: “Ojú rẹ rí mi nígbà tí mo ṣì wà nínú ikùn.” (Sáàmù 139:16) Torí náà, ẹ̀mí rẹ ṣe pàtàkì gan-an sí Jèhófà. (Ka Mátíù 10:29-31.) Ó máa ń dun Jèhófà gan-an tẹ́nì kan bá mọ̀ọ́mọ̀ pa ẹlòmíì. Bákan náà, inú Jèhófà kì í dùn tẹ́nì kan bá pa ara ẹ̀.a (Ẹkísódù 20:13) Ó tún máa ń dun Jèhófà tá a bá fẹ̀mí ara wa tàbí ti àwọn míì sínú ewu torí pé a ò fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ ààbò. Tá a bá ń tọ́jú ara wa, tá ò sì fi ẹ̀mí àwọn ẹlòmíì sínú ewu, ńṣe là ń fi hàn pé a mọyì ẹ̀mí wa tó jẹ́ ẹ̀bùn pàtàkì látọ̀dọ̀ Jèhófà.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Jẹ́ ká wo àwọn ọ̀nà bíi mélòó kan tá a lè gbà fi hàn pé a mọyì ẹ̀mí tí Jèhófà fún wa.
3. Máa tọ́jú ara ẹ
Àwọn Kristẹni tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà máa ń lo gbogbo àkókò àti okun wọn láti sin Jèhófà. Ńṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n fi ara wọn rúbọ sí i. Ka Róòmù 12:1, 2, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí nìdí pàtàkì tó fi yẹ kó o máa tọ́jú ara ẹ?
Àwọn ọ̀nà wo lo lè máa gbà tọ́jú ara ẹ?
4. Máa sá fún ohun tó lè pa ẹ́ lára tàbí tó lè gbẹ̀mí ẹ
Bíbélì sọ pé ká máa sá fún àwọn àṣà tó léwu. Wo FÍDÍÒ yìí kó o lè mọ àwọn nǹkan tó o lè máa ṣe láti dáàbò bo ara rẹ.
Ka Òwe 22:3, lẹ́yìn náà kó o sọ bí ìwọ àtàwọn ẹlòmíì ṣe lè máa sá fún ewu . . .
nínú ilé.
níbi iṣẹ́.
tá a bá ń ṣeré ìdárayá.
tá a bá ń wa mọ́tò àtàwọn ohun ìrìnnà míì tàbí tẹ́nì kan bá fi gbé wa.
5. Má ṣe ohun tó máa pa ọmọ inú oyún lára
Dáfídì sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan tó jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ń kíyè sí gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sí ọmọ tó ṣì wà nínú oyún. Ka Sáàmù 139:13-17, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Lójú Jèhófà, ṣé látìgbà tí wọ́n ti lóyún ọmọ kan ni ìwàláàyè ẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ni àbí ìgbà tí wọ́n bá bí i?
Nílẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́, Jèhófà ṣe àwọn òfin kan láti dáàbò bo àwọn aboyún àtàwọn ọmọ inú wọn. Ka Ẹ́kísódù 21:22, 23, kó o sì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Tí ẹnì kan bá ṣèèṣì pa ọmọ inú oyún, kí ni Jèhófà ní kí wọ́n ṣe fún ẹni náà?
Tó bá wá jẹ́ pé ńṣe lẹnì kan mọ̀ọ́mọ̀ pa ọmọ inú oyún, báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára Jèhófà?b
Kí lèrò ẹ nípa ọwọ́ tí Ọlọ́run fi mú ọ̀rọ̀ yìí?
Nígbà míì, tí obìnrin kan tó lóyún bá tiẹ̀ mọyì ẹ̀mí, ó lè láwọn ìṣòro kan táá mú kó gbà pé àfi kóun ṣẹ́ oyún náà. Ka Àìsáyà 41:10, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Tí obìnrin kan bá láwọn ìṣòro kan nínú oyún, táwọn kan sì sọ pé ohun tó máa dáa jù ni pé kó ṣẹ́ oyún náà, ọ̀dọ̀ ta ló yẹ kó wá ìrànlọ́wọ́ lọ? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Obìnrin kan lè pinnu bóyá òun máa ṣẹ́yún àbí òun ò ní ṣẹ́ ẹ. Ṣebí òun ló ni ara ẹ̀?”
Kí ló mú kó dá ẹ lójú pé Jèhófà ka ẹ̀mí aboyún àti tọmọ inú ẹ̀ sí pàtàkì?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Bíbélì kọ́ wa pé Jèhófà ló fún wa ní ẹ̀mí. Torí náà, ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ ẹ̀mí wa àti tàwọn ẹlòmíì, ká fi hàn pé a mọyì ẹ̀, ká sì máa sá fún ohun tó lè fi ẹ̀mí wa àti tàwọn ẹlòmíì sínú ewu.
Kí lo rí kọ́?
Kí nìdí tí Jèhófà fi ka ẹ̀mí èèyàn sí pàtàkì gan-an?
Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà tẹ́nì kan bá mọ̀ọ́mọ̀ pa èèyàn?
Kí nìdí tó o fi mọyì ẹ̀mí tí Jèhófà fún wa?
ṢÈWÁDÌÍ
Wo fídíò orin yìí kó o lè rí bá a ṣe lè fi hàn pé a mọyì ẹ̀mí wa àtàwọn nǹkan míì tí Jèhófà dá fún ìgbádùn wa.
Ka ìwé yìí kó o lè mọ̀ bóyá Ọlọ́run lè dárí ji àwọn tó ti ṣẹ́yún rí.
Ka ìwé yìí kó o lè mọ ìdí tó fi yẹ kó o máa ronú nípa ọwọ́ tí Ọlọ́run fi mú ọ̀rọ̀ ẹ̀mí tó o bá ń ṣeré ìdárayá.
“‘Eré Ìdárayá Àṣejù’ Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí O Fara Rẹ Wewu?” (Jí!, October 8, 2000)
Ka ìwé yìí kó o lè rí ìmọ̀ràn tó wúlò gan-an tí Bíbélì fún àwọn tó bá ń ronú àtigbẹ̀mí ara wọn.
“Ṣé Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Tí Mo Bá Ń Ronú Àtipa Ara Mi?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)
a Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn, ó sì máa ń ṣìkẹ́ wọn gan-an. (Sáàmù 34:18) Jèhófà mọ̀ pé àwọn kan wà tí ìdààmú ọkàn wọ́n le débi pé wọ́n máa ń ronú àtigbẹ̀mí ara wọn, ó sì ṣe tán láti ran àwọn tó bá nírú ìṣòro yìí lọ́wọ́. Kó o lè rí ohun tó máa ran ẹni tó bá ń ronú láti gbẹ̀mí ara ẹ̀ lọ́wọ́, ka àpilẹ̀kọ tó wà ní apá Ṣèwádìí nínú ẹ̀kọ́ yìí, tí àkòrí ẹ̀ sọ pé “Ṣé Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Tí Mo Bá Ń Ronú Àtipa Ara Mi?”
b Tí ẹnì kan tó ti ṣẹ́yún rí bá ronú pìwà dà, kò yẹ kó máa banú jẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ torí pé Jèhófà máa dárí jì í. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ọ̀rọ̀ yìí, ka àpilẹ̀kọ tó wà ní apá Ṣèwádíì nínú ẹ̀kọ́ yìí, tí àkòrì ẹ̀ sọ pé “Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìṣẹ́yún?”