ORÍ 50
Wọ́n Ṣe Tán Láti Wàásù Láìka Àtakò Sí
MÁTÍÙ 10:16–11:1 MÁÀKÙ 6:12, 13 LÚÙKÙ 9:6
JÉSÙ DÁ ÀWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ RẸ̀ LẸ́KỌ̀Ọ́, Ó SÌ RÁN WỌN JÁDE
Jésù pín àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ní méjì-méjì, ó sì fún wọn láwọn ìtọ́ni tó ṣe kedere nípa bí wọ́n á ṣe wàásù. Àmọ́, kò fi mọ síbẹ̀ o. Ó tún kìlọ̀ fún wọn nípa àwọn alátakò, ó ní: “Ẹ wò ó! Mò ń rán yín jáde bí àgùntàn sáàárín àwọn ìkookò . . . Ẹ máa ṣọ́ra yín lọ́dọ̀ àwọn èèyàn; torí wọ́n máa fà yín lé àwọn ilé ẹjọ́ àdúgbò lọ́wọ́, wọ́n á sì nà yín nínú àwọn sínágọ́gù wọn. Wọ́n á tún mú yín lọ síwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba nítorí mi.”—Mátíù 10:16-18.
Ó ṣe kedere pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù máa kojú àtakò tó le gan-an, àmọ́ Jésù fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé: “Tí wọ́n bá ti fà yín lé wọn lọ́wọ́, ẹ má ṣàníyàn nípa bí ẹ ṣe máa sọ̀rọ̀ àti ohun tí ẹ máa sọ, torí a máa fún yín ní ohun tí ẹ máa sọ ní wákàtí yẹn; torí kì í kàn ṣe ẹ̀yin lẹ̀ ń sọ̀rọ̀, àmọ́ ẹ̀mí Baba yín ló ń gbẹnu yín sọ̀rọ̀.” Jésù tún sọ pé: “Arákùnrin máa fa arákùnrin lé ikú lọ́wọ́, bàbá máa ṣe bẹ́ẹ̀ sí ọmọ rẹ̀, àwọn ọmọ máa dìde sí àwọn òbí, wọ́n sì máa pa wọ́n. Gbogbo èèyàn sì máa kórìíra yín nítorí orúkọ mi, ṣùgbọ́n ẹni tó bá fara dà á dé òpin máa rí ìgbàlà.”—Mátíù 10:19-22.
Torí pé iṣẹ́ ìwàásù ló ṣe pàtàkì jù, Jésù jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rí ìdí tó fi yẹ kí wọ́n wà lójúfò kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà yanjú. Ó ní: “Tí wọ́n bá ṣe inúnibíni sí yín ní ìlú kan, ẹ sá lọ sí òmíràn; torí lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ó dájú pé ẹ ò lè lọ yí ká àwọn ìlú Ísírẹ́lì tán títí Ọmọ èèyàn fi máa dé.”—Mátíù 10:23.
Ẹ ò rí i pé àwọn ìtọ́ni, ìkìlọ̀ àti ìṣírí tí Jésù fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá (12) bọ́ sákòókò gan-an! Àmọ́, àwọn nìkan kọ́ làwọn ìtọ́ni yẹn kàn, ó tún kan àwọn tó máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù lẹ́yìn tí Jésù bá kú tó sì jíǹde. Jésù jẹ́ kí èyí ṣe kedere nígbà tó sọ pé “gbogbo èèyàn . . . máa kórìíra yín.” Lédè míì, kì í ṣe àwọn tí wọ́n wàásù fún nígbà yẹn nìkan ló máa kórìíra àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Bákan náà, Bíbélì ò sọ fún wa pé àwọn èèyàn fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sọ́dọ̀ gómìnà tàbí lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba láàárín ìwọ̀nba àkókò tí wọ́n fi wàásù ní Gálílì, bẹ́ẹ̀ la ò sì gbọ́ pé àwọn mọ̀lẹ́bí wọn pa èyíkéyìí lára wọn.
Ó ṣe kedere pé nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó ń bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nígbà tó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé wọn ò ní lè lọ yí ká gbogbo ìlú tí wọ́n ti máa wàásù “títí Ọmọ èèyàn fi máa dé,” ohun tó ń sọ ni pé wọn ò tíì ní parí ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run títí Jésù Kristi ọba fi máa wá ṣe ìdájọ́.
Kò yẹ kó ya àwọn àpọ́sítélì lẹ́nu tí wọ́n bá kojú àtakò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù torí Jésù fúnra ẹ̀ sọ pé: “Akẹ́kọ̀ọ́ ò ju olùkọ́ rẹ̀ lọ, ẹrú ò sì ju ọ̀gá rẹ̀ lọ.” Ohun tí Jésù ń sọ ṣe kedere. Àwọn èèyàn ta ko Jésù torí pé ó ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n sì ṣe inúnibíni sí i, ohun táwọn náà sì máa kojú nìyẹn. Síbẹ̀, Jésù gbà wọ́n níyànjú pé: “Ẹ má bẹ̀rù àwọn tó ń pa ara àmọ́ tí wọn ò lè pa ọkàn; kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ bẹ̀rù ẹni tó lè pa ọkàn àti ara run nínú Gẹ̀hẹ́nà.”—Mátíù 10:24, 28.
Jésù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí. Kò bẹ̀rù ikú, ó sì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà tó ní agbára jù lọ láyé àti lọ́run. Ọlọ́run Olódùmarè nìkan ló lè pa “ọkàn” (ìyẹn ìrètí ọjọ́ iwájú), òun nìkan ló sì lè jí ẹnì kan dìde láti wà láàyè títí láé. Ẹ wo bí ìyẹn ṣe máa fi àwọn àpọ́sítélì náà lọ́kàn balẹ̀ tó!
Jésù wá lo àkàwé kan láti jẹ́ kó dá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn, ó sọ pé: “Ẹyọ owó kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ níye lórí ni wọ́n ń ta ológoṣẹ́ méjì, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Síbẹ̀, ìkankan nínú wọn ò lè já bọ́ lulẹ̀ láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀. . . . Torí náà, ẹ má bẹ̀rù; ẹ níye lórí gan-an ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.”—Mátíù 10:29, 31.
Ìhìn rere táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń wàásù máa mú káwọn ìdílé kan pínyà torí àwọn kan lè tẹ́wọ́ gbà á, àwọn tó kù sì lè má ṣe bẹ́ẹ̀. Jésù ní: “Ẹ má rò pé mo wá láti mú àlàáfíà wá sí ayé.” Ó gba ìgboyà kí ẹnì kan tó gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó sì di ọmọ ẹ̀yìn. Jésù tún sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ bàbá tàbí ìyá jù mí lọ kò yẹ fún mi; ẹnikẹ́ni tó bá sì nífẹ̀ẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin jù mí lọ kò yẹ fún mi.”—Mátíù 10:34, 37.
Àmọ́ o, àwọn kan máa mọyì àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà. Torí náà, Jésù sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá fún ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré yìí ní ife omi tútù lásán pé kó mu ún, torí pé ó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn, lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ó dájú pé kò ní pàdánù èrè rẹ̀.”—Mátíù 10:42.
Ní báyìí tí Jésù ti dá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́, tó fún wọn níṣìírí tó sì kìlọ̀ fún wọn, wọ́n “bẹ̀rẹ̀ sí í lọ káàkiri agbègbè náà láti abúlé dé abúlé, wọ́n ń kéde ìhìn rere, wọ́n sì ń ṣe ìwòsàn níbi gbogbo.”—Lúùkù 9:6.