Kí Nìdí Tí Wọ́n Fi Kọ Mèsáyà Sílẹ̀?
NÍGBÀ tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ohun tó sọ wọ àwọn èèyàn lọ́kàn, àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe sì jọ wọ́n lójú gan-an. Èyí mú kí ọ̀pọ̀ “ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀,” wọ́n sì gbà pé òun ni Mèsáyà tàbí Kristi tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀. Wọ́n sọ pé: “Nígbà tí Kristi bá dé, kì yóò ṣe àwọn iṣẹ́ àmì tí ó ju èyí tí ọkùnrin yìí ti ṣe, àbí yóò ṣe bẹ́ẹ̀?”—Jòhánù 7:31.
Láìka ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹ̀rí tó fi hàn pé Jésù ni Mèsáyà sí, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tó rí Jésù, tí wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni kò di onígbàgbọ́. Ó bani nínú jẹ́ pé, àwọn kan tó gbà á gbọ́ tẹ́lẹ̀ pa dà lẹ́yìn rẹ̀ nígbà tó yá. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi sọ pé Jésù kọ́ ni Mèsáyà láìka gbogbo ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ sí? Jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìdí náà, bá a sì ti ń gbé e yẹ̀ wò, máa bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ èmi náà lè ṣe irú àṣìṣe yìí lónìí?’
Wọn Kò Rí Ohun Tí Wọ́n Ń Retí
Nígbà tí wọ́n bí Jésù, àwọn Júù ti ń retí ìgbà tí Mèsáyà máa fara hàn. Àwọn tó “ń dúró de ìdáǹdè Jerúsálẹ́mù” látọwọ́ Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí, rí Jésù nígbà tí wọ́n gbé e wá sí tẹ́ńpìlì nígbà tó wà lọ́mọ ọwọ́. (Lúùkù 2:38) Nígbà tó yá, ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń kíyè sí àwọn iṣẹ́ tí Jòhánù Olùbatisí ń ṣe, sọ pé: “Àbí òun ni Kristi náà ni?” (Lúùkù 3:15) Kí làwọn Júù ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ń retí pé kí Mèsáyà ṣe?
Èrò tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn Júù nígbà yẹn ni pé, Mèsáyà máa wá dá wọn sílẹ̀ kúrò lábẹ́ àjàgà àti ìnilára àwọn alákòóso Róòmù, á sì dá ìjọba pa dà fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Kí Jésù tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, àwọn aṣáájú kan tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́nu-dún-juyọ̀ dìde, wọ́n sì ń rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n máa gbéjà ko àwọn olóṣèlú tó ń ṣàkóso wọn. Ó ṣeé ṣe kí ohun tí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ṣe mú kí àwọn èèyàn náà ní èrò tí kò tọ́ nípa ohun tí wọ́n ń retí lọ́dọ̀ Mèsáyà.
Jésù yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ayédèrú Mèsáyà yẹn. Kò sọ pé kí àwọn èèyàn máa hùwà ipá, àmọ́, ó kọ́ àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn, kí wọ́n sì máa tẹrí bá fún àwọn aláṣẹ. (Mátíù 5:41-44) Kò gbà kí àwọn èèyàn sọ òun di ọba. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń kọ́ni pé ìjọba òun kì í ṣe “apá kan ayé yìí.” (Jòhánù 6:15; 18:36) Síbẹ̀, èròkérò tí àwọn èèyàn náà ti ní tẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà ló ṣì jọba lọ́kàn wọn.
Jòhánù Olùbatisí fojú ara rẹ̀ rí iṣẹ́ ìyanu tó fi ẹ̀rí hàn pé Jésù ni Ọmọ Ọlọ́run, ó sì tún gbọ́ ohùn tó jẹ́rìí sí i. Síbẹ̀ náà, nígbà tí Jòhánù wà lẹ́wọ̀n, ó tún rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n lọ béèrè lọ́wọ́ Jésù pé: “Ṣé ìwọ ni Ẹni Tí Ń Bọ̀, tàbí kí a máa fojú sọ́nà fún ẹnì kan tí ó yàtọ̀?” (Mátíù 11:3) Ó lè jẹ́ pé Jòhánù ń ṣe iyè méjì bóyá Jésù ni Olùdáǹdè náà tí Ọlọ́run ṣèlérí, èyí tó máa ṣe ohun tí àwọn Júù ń retí.
Ó ṣòro fún àwọn àpọ́sítélì Jésù láti gbà pé wọ́n máa pa Jésù, pé ó sì máa jíǹde. Nígbà kan tí Jésù ṣàlàyé pé, Mèsáyà ní láti jìyà kó sì kú, Pétérù “mú un lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a wí lọ́nà mímúná.” (Máàkù 8:31, 32) Ìdí tí Jésù tó jẹ́ Mèsáyà fi ní láti kú kò tíì yé Pétérù.
Nígbà tí Jésù wọ Jerúsálẹ́mù ní kété ṣáájú Ìrékọjá ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àwọn èèyàn rẹpẹtẹ ń fìtara kí i káàbọ̀, wọ́n sì yìn ín gẹ́gẹ́ bí Ọba. (Jòhánù 12:12, 13) Ẹ wá wo bí ọ̀ràn ṣe wá yí pa dà bìrí! Láàárín ọ̀sẹ̀ yẹn náà, wọ́n fòfin mú Jésù, wọ́n sì pa á. Lẹ́yìn tí Jésù ti kú, méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kédàárò pé: “Àwa ń retí pé ọkùnrin yìí ni ẹni tí a yàn tẹ́lẹ̀ láti dá Ísírẹ́lì nídè.” (Lúùkù 24:21) Lẹ́yìn tí Jésù ti jíǹde tó sì fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pàápàá, èrò wọn ni pé, Mèsáyà ṣì máa fìdí ìjọba kan múlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé níbí. Wọ́n bí i pé: “Olúwa, ìwọ ha ń mú ìjọba padà bọ̀ sípò fún Ísírẹ́lì ní àkókò yìí bí?” Ó ṣe kedere pé, èrò òdì nípa Mèsáyà jinlẹ̀ lọ́kàn àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù.—Ìṣe 1:6.
Lẹ́yìn tí Jésù ti gòkè re ọ̀run, tá a sì ti tú ẹ̀mí mímọ́ jáde, ìgbà yẹn làwọn ọmọ ẹ̀yìn wá lóye lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ pé, ọ̀run ni Mèsáyà á ti máa ṣàkóso bí Ọba. (Ìṣe 2:1-4, 32-36) Àpọ́sítélì Pétérù àti Jòhánù ń fi ìgboyà wàásù pé Jésù ti jíǹde, wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìyanu láti fi ẹ̀rí hàn pé Ọlọ́run ń ti àwọn lẹ́yìn. (Ìṣe 3:1-9, 13-15) Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ní Jerúsálẹ́mù ló fetí sílẹ̀, wọ́n sì di onígbàgbọ́. Àmọ́, èyí kò dùn mọ́ àwọn aláṣẹ Júù nínú rárá. Bí wọ́n ti ṣe ta ko Jésù, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n wá ń ta ko àwọn àpọ́sítélì àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ báyìí. Kí nìdí tí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù fi kọ Jésù sílẹ̀ pátápátá?
Àwọn Aṣáájú Ẹ̀sìn Kọ̀ Ọ́ Sílẹ̀
Nígbà tí Jésù wá sí ayé, èrò àwọn Júù nípa ẹ̀sìn àti ìwà wọn ti yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí Ìwé Mímọ́ kọ́ni. Àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ làwọn Farisí, Sadusí àtàwọn akọ̀wé òfin tí wọ́n jẹ́ aṣáájú ẹ̀sìn nígbà yẹn ń tẹ̀ lé, wọ́n sì kà á sí ju Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ. Léraléra ni wọ́n fẹ̀sùn kan Jésù pé ó rú Òfin nítorí pé ó ṣe iṣẹ́ ìyanu lọ́jọ́ Sábáàtì. Nígbà tí Jésù kò wọ́n lójú pé, ẹ̀kọ́ wọn kò bá Ìwé Mímọ́ mu, ó tipa bẹ́ẹ̀ ta ko ọlá àṣẹ wọn, ó sì fi hàn pé irọ́ ni wọ́n ń pa pé àwọn ní orúkọ rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Jésù yàtọ̀ sí wọn gan-an, àwọn òbí tí kò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ ni wọ́n tọ́ ọ dàgbà, kò sì lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn táwọn èèyàn kà sí. Abájọ tó fi ṣòro fún àwọn ọkùnrin agbéraga yìí láti gbà pé Jésù ni Mèsáyà náà! Bó ṣe kò wọ́n lójú yìí mú kí inú bí wọn tí wọ́n fi “gbìmọ̀ pọ̀ lòdì sí [Jésù], kí wọ́n lè pa á run.”—Mátíù 12:1-8, 14; 15:1-9.
Báwo ni àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ṣe tẹ́ńbẹ́lú agbára tí Jésù fi ṣiṣẹ́ ìyanu? Wọn kò sọ pé kò ṣe iṣẹ́ ìyanu. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n fẹ́ ba ìgbàgbọ́ táwọn èèyàn ní nínú Jésù jẹ́, nípa sísọ ọ̀rọ̀ òdì pé agbára Sátánì ló fi ń ṣe iṣẹ́ ìyanu náà, wọ́n ní: “Àwé yìí kò lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde bí kò ṣe nípasẹ̀ Béélísébúbù, olùṣàkóso àwọn ẹ̀mí èṣù.”—Mátíù 12:24.
Ìdí míì tún wà lọ́kàn wọn tó mú kí wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti gbà pé Jésù ni Mèsáyà. Lẹ́yìn tí Jésù jí Lásárù dìde, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n sì sọ pé: “Kí ni kí a ṣe, nítorí ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì? Bí a bá jọ̀wọ́ rẹ̀ jẹ́ẹ́ lọ́nà yìí, gbogbo wọn yóò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, àwọn ará Róòmù yóò wá, wọn yóò sì gba àyè wa àti orílẹ̀-èdè wa.” Ẹ̀rù ń ba àwọn aṣáájú ẹ̀sìn pé àwọn máa pàdánù ipò àti àṣẹ táwọn ní, nítorí náà, wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Jésù àti Lásárù!—Jòhánù 11:45-53; 12:9-11.
Ẹ̀tanú àti Inúnibíni Látọ̀dọ̀ Àwọn Júù
Ìwà àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní mú kí nǹkan le fún ẹnikẹ́ni tó bá gbà pé Jésù ni Mèsáyà. Wọ́n ń fi ipò ńlá tí wọ́n wà yangàn, wọ́n sì ń tẹ́ńbẹ́lú ẹnikẹ́ni tó bá gba Jésù gbọ́, wọ́n sọ pé: “Kò sí ọ̀kan nínú àwọn olùṣàkóso tàbí àwọn Farisí tí ó ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, àbí ó wà?” (Jòhánù 7:13, 48) Àwọn kan lára àwọn aṣáájú Júù, àwọn bíi Nikodémù àti Jósẹ́fù ará Arimatíà di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, àmọ́ wọn kò jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ nítorí pé ẹ̀rù ń bà wọ́n. (Jòhánù 3:1, 2; 12:42; 19:38, 39) Àwọn aṣáájú Júù ti pàṣẹ pé, “bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́wọ́ [Jésù] ní Kristi, lílé ni wọn yóò lé e jáde kúrò nínú sínágọ́gù.” (Jòhánù 9:22) Wọ́n á pa irú ẹni bẹ́ẹ̀ tì, wọ́n á máa fojú ẹ̀gàn wò ó, wọ́n kò sì ní bá a kẹ́gbẹ́ mọ́.
Nígbà tó yá, àtakò tí wọ́n ń ṣe sí àwọn àpọ́sítélì àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù wá yọrí sí inúnibíni rírorò. Nítorí pé àwọn àpọ́sítélì ń fi ìgboyà wàásù, Sànhẹ́dírìn, ìyẹn ilé ẹjọ́ àwọn Júù tó ga jù fìyà jẹ wọ́n. (Ìṣe 5:40) Àwọn alátakò fẹ̀sùn èké kan Sítéfánù pé ó sọ̀rọ̀ òdì. Sànhẹ́dírìn dá a lẹ́bi, wọ́n sì sọ ọ́ lókùúta pa. Nítorí náà, “inúnibíni ńlá dìde sí ìjọ tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù; gbogbo wọn àyàfi àwọn àpọ́sítélì ni a tú ká jákèjádò àwọn ẹkùn ilẹ̀ Jùdíà àti Samáríà.” (Ìṣe 6:8-14; 7:54–8:1) Sọ́ọ̀lù, tó wá di àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ nínú inúnibíni tí àlùfáà àgbà àti “gbogbo àjọ àgbààgbà ọkùnrin” dá sílẹ̀.—Ìṣe 9:1, 2; 22:4, 5.
Kódà ní irú ipò líle koko yìí, ẹ̀sìn Kristẹni yára gbèrú lẹ́yìn ikú Kristi. Òótọ́ ni pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló di onígbàgbọ́, àmọ́, àwọn Kristẹni ṣì kéré láàárín àwọn èèyàn tó wà ní ìlú Palẹ́sìnì ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Téèyàn kan bá sọ ní gbangba pé ọmọlẹ́yìn Kristi lòun, wọ́n lè máà bá a kẹ́gbẹ́ mọ́, wọ́n sì lè hùwà ìkà sí i pàápàá.
Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Tí Wọ́n Kọ Jésù Sílẹ̀
Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i, èrò tí kò tọ̀nà, fífúngun mọ́ni àti inúnibíni ni kò jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn gba Jésù gbọ́ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Lóde òní, èrò tí kò tọ̀nà nípa Jésù àti ẹ̀kọ́ rẹ̀ lè mú káwọn èèyàn má ṣe gbà á gbọ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ti kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn pé inú ọkàn wọn ni Ìjọba Ọlọ́run wà tàbí pé ìsapá àwọn èèyàn ló máa mú kí ìjọba náà ṣeé ṣe. Wọ́n ti mú kí àwọn míì máa rò pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tàbí ìmọ̀ ẹ̀rọ ló máa yanjú ìṣòro aráyé, nípa bẹ́ẹ̀, wọn kò rí ìdí kankan láti gbà pé àwọn nílò Mèsáyà. Ọ̀pọ̀ àwọn alárìíwísí lóde òní sọ pé àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù tó wà nínú Bíbélì kì í ṣe òótọ́, àwọn ọkùnrin yìí sì tipa báyìí ba ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn jẹ́ pé Jésù kì í ṣe Mèsáyà.
Gbogbo èrò àti àbá wọ̀nyẹn ti mú kí àwọn èèyàn má mọ ipa tí Mèsáyà máa kó tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ rí ìdí kankan láti ronú nípa ọ̀ràn náà. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ẹ̀rí tó ju ti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní lọ ló wà lónìí pé Jésù ni Mèsáyà, èyí tí àwọn tó ń fẹ́ ẹ̀rí lè ṣàyẹ̀wò wọn. A ní odindi Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tó sọ ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn nǹkan tí Mèsáyà máa ṣe, a sì tún ní àkọ́sílẹ̀ ìwé Ìhìn Rere mẹ́rin nínú Bíbélì tó sọ nípa àwọn nǹkan tí Jésù ṣe láti mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ.a
Ní ti tòótọ́, ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló wà fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa láti ṣe ìpinnu tó dára lórí ọ̀ràn yìí. A sì ní láti ṣe ìpinnu náà ní kíákíá. Kí nìdí? Ìdí ni pé Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé láìpẹ́ Jésù tó jẹ́ Mèsáyà Ọba Ìjọba Ọlọ́run yóò gbé ìgbésẹ̀ láti pa gbogbo àwọn tó ń run ilẹ̀ ayé, tí yóò sì mú àkóso òdodo wá, èyí tí yóò mú káwọn onígbọràn máa gbé títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Dáníẹ́lì 2:44; Ìṣípayá 11:15, 18; 21:3-5) Ìwọ náà lè ní àǹfààní àgbàyanu tó wà lọ́jọ́ ọ̀la yìí tó o bá sapá láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù tó o sì gbà á gbọ́ nísinsìnyí. Fi ọ̀rọ̀ Jésù sọ́kàn, ó ní: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àtẹ náà, “Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Mèsáyà” lójú ìwé 200 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 20]
Ṣé wàá dá Mèsáyà mọ̀ ká ní o gbé láyé lọ́jọ́ Jésù?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Má ṣe jẹ́ kí èrò òdì dí ẹ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Jésù