Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì
3 Nígbà kan, Pétérù àti Jòhánù ń lọ sí tẹ́ńpìlì lákòókò àdúrà, ní wákàtí kẹsàn-án,* 2 àwọn kan sì ń gbé ọkùnrin kan tó ti yarọ láti ìgbà tí wọ́n ti bí i kọjá. Ojoojúmọ́ ni wọ́n máa ń gbé e sí tòsí ẹnu ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì tí wọ́n ń pè ní Ẹlẹ́wà, kó lè máa gba ọrẹ àánú lọ́wọ́ àwọn tó ń wọ tẹ́ńpìlì. 3 Nígbà tí ọkùnrin náà tajú kán rí Pétérù àti Jòhánù tí wọ́n fẹ́ wọ tẹ́ńpìlì, ó bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè ọrẹ àánú lọ́wọ́ wọn. 4 Àmọ́, Pétérù àti Jòhánù tẹjú mọ́ ọn, wọ́n sì sọ pé: “Wò wá.” 5 Ló bá ń wò wọ́n, ó sì ń retí pé òun máa rí nǹkan gbà lọ́wọ́ wọn. 6 Àmọ́ Pétérù sọ pé: “Mi ò ní fàdákà àti wúrà, àmọ́ ohun tí mo ní ni màá fún ọ. Ní orúkọ Jésù Kristi ará Násárẹ́tì, máa rìn!”+ 7 Ló bá di ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú, ó sì gbé e dìde.+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹsẹ̀ rẹ̀ àti ọrùn ẹsẹ̀ rẹ̀ le gírígírí;+ 8 ó fò sókè,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn, ó tẹ̀ lé wọn wọ tẹ́ńpìlì, ó ń rìn, ó ń fò sókè, ó sì ń yin Ọlọ́run. 9 Gbogbo èèyàn sì rí i tó ń rìn, tó sì ń yin Ọlọ́run. 10 Wọ́n dá a mọ̀ pé òun ni ọkùnrin tó máa ń jókòó síbi Ẹnubodè Ẹlẹ́wà tó wà ní tẹ́ńpìlì+ láti máa gba ọrẹ àánú, ẹnu yà wọ́n gidigidi, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i sì múnú wọn dùn gan-an.
11 Nígbà tí ọkùnrin náà ṣì di Pétérù àti Jòhánù mú, gbogbo èèyàn sáré lọ bá wọn níbi tí wọ́n ń pè ní Ọ̀dẹ̀dẹ̀* Sólómọ́nì,+ ẹnu yà wọ́n gidigidi. 12 Nígbà tí Pétérù rí ohun tó ṣẹlẹ̀, ọ́ sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ̀yin èèyàn Ísírẹ́lì, kí ló dé tọ́rọ̀ yìí fi ń yà yín lẹ́nu? Kí ló dé tí ẹ fi ń wò wá bíi pé agbára wa ló tó bẹ́ẹ̀, àbí torí pé ìfọkànsin Ọlọ́run tí a ní la fi mú kí ọkùnrin yìí máa rìn? 13 Ọlọ́run Ábúráhámù àti ti Ísákì àti ti Jékọ́bù,+ Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa, ti ṣe Jésù,+ Ìránṣẹ́ rẹ̀ lógo,+ ẹni tí ẹ fà lé àwọn èèyàn lọ́wọ́,+ tí ẹ sì sọ níwájú Pílátù pé ẹ ò mọ̀ rí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti pinnu pé òun máa dá a sílẹ̀. 14 Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ sọ pé ẹ ò mọ ẹni mímọ́ àti olódodo yẹn rí, ẹ sì ní kí wọ́n fún yín ní ọkùnrin tó jẹ́ apààyàn,+ 15 ẹ wá pa Olórí Aṣojú ìyè.+ Àmọ́ Ọlọ́run gbé e dìde kúrò nínú ikú, òtítọ́ yìí ni àwa ń jẹ́rìí sí.+ 16 Nípasẹ̀ orúkọ rẹ̀ àti nípa ìgbàgbọ́ tí a ní nínú orúkọ rẹ̀, ni ara ọkùnrin tí ẹ rí, tí ẹ sì mọ̀ yìí fi yá. Ìgbàgbọ́ tí a ní nípasẹ̀ rẹ̀ ló mú ara ọkùnrin yìí dá ṣáṣá níṣojú gbogbo yín. 17 Ní báyìí, ẹ̀yin ará, mo mọ̀ pé àìmọ̀kan ló sún yín ṣe é,+ bí àwọn alákòóso yín náà ti ṣe.+ 18 Àmọ́ ọ̀nà yìí ni Ọlọ́run gbà mú àwọn ohun tó ti kéde tẹ́lẹ̀ látẹnu gbogbo àwọn wòlíì ṣẹ, pé Kristi òun máa jìyà.+
19 “Nítorí náà, ẹ ronú pìwà dà,+ kí ẹ sì yí pa dà,+ kí Ọlọ́run lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́,+ kí àwọn àsìkò ìtura lè wá látọ̀dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀,* 20 kí ó sì lè rán Kristi tí ó ti yàn nítorí yín, ìyẹn Jésù. 21 Ọ̀run gbọ́dọ̀ gba ẹni yìí sínú ara rẹ̀ títí di àwọn àkókò ìmúbọ̀sípò gbogbo ohun tí Ọlọ́run sọ látẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ ti ìgbà àtijọ́. 22 Kódà, Mósè sọ pé: ‘Jèhófà* Ọlọ́run yín máa gbé wòlíì kan bí èmi dìde fún yín láàárín àwọn arákùnrin yín.+ Ẹ gbọ́dọ̀ fetí sí ohun tó bá sọ fún yín.+ 23 Ní tòótọ́, ẹni* tí kò bá fetí sí Wòlíì yẹn ni a ó pa run pátápátá kúrò láàárín àwọn èèyàn.’+ 24 Gbogbo àwọn wòlíì, látorí Sámúẹ́lì àti àwọn tó tẹ̀ lé e, gbogbo wọn ti sọ̀rọ̀, wọ́n sì kéde àwọn ọjọ́ yìí lọ́nà tó ṣe kedere.+ 25 Ẹ̀yin ni ọmọ àwọn wòlíì àti ti májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá àwọn baba ńlá yín dá,+ tí ó sọ fún Ábúráhámù pé: ‘Gbogbo ìdílé tó wà láyé yóò rí ìbùkún nípasẹ̀ ọmọ* rẹ.’+ 26 Ẹ̀yin ni Ọlọ́run kọ́kọ́ rán Ìránṣẹ́ rẹ̀ sí,+ lẹ́yìn tí ó gbé e dìde, kí ó lè bù kún yín láti mú kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín yí pa dà kúrò nínú àwọn iṣẹ́ ibi rẹ̀.”