Ìwòsàn Ìyanu Aráyé Ti Sún Mọ́lé
“ÀWA kò tí ì rí ohun tí ó dà bí i rẹ̀ rí.” Ohun tí àwọn tí wọ́n fojú rí ìwòsàn ojú ẹsẹ̀ tí Jésù ṣe fún ọkùnrin alárùn ẹ̀gbà kan sọ nìyẹn. (Máàkù 2:12) Jésù tún wo àwọn afọ́jú, odi, àti àwọn arọ sàn, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sì ṣe ohun kan náà. Agbára ta ni Jésù fi ṣe é? Ipa wo ni ìgbàgbọ́ kó? Ìmọ́lẹ̀ wo ni àwọn ìrírí ọ̀rúndún kìíní wọ̀nyí tàn sórí ìwòsàn ìyanu òde òní?—Mátíù 15:30, 31.
“Ìgbàgbọ́ Rẹ Ti Mú Ọ Lára Dá”
Ó máa ń dùn mọ́ àwọn onígbàgbọ́ wò-ó-sàn òde òní lẹ́nu láti sọ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún obìnrin kan tí ó ti ń jìyà lọ́wọ́ ìṣàn ẹ̀jẹ̀ fún ọdún 12, tí ó wá gba ìwòsàn lọ́dọ̀ rẹ̀, pé: “Ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá.” (Lúùkù 8:43-48) Gbólóhùn Jésù ha túmọ̀ sí pé, rírí ìwòsàn rẹ̀ gbà sinmi lórí ìgbàgbọ́ rẹ̀? Ìyẹn ha jẹ́ àpẹẹrẹ “ìgbàgbọ́ wò-ó-sàn” tí a ń ṣe lónìí bí?
Nígbà tí a fara balẹ̀ ka àkọsílẹ̀ Bíbélì, a rí i pé, ní ìgbà tí ó pọ̀ jù lọ, Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kò sọ pé kí àwọn aláìsàn jẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ wọn kí a tó wò wọ́n sàn. Obìnrin tí a mẹ́nu kàn lókè wá, láìsì sọ ohunkóhun fún Jésù, ó rọra fọwọ́ kan ẹ̀wù rẹ̀ láti ẹ̀yìn, “ní ìṣẹ́jú akàn ìṣàn ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì dúró.” Ní àkókò míràn, Jésù mú ọkùnrin kan tí ó wà lára àwọn tí ó wá láti fàṣẹ ọba mú un lára dá. Ó tilẹ̀ mú ọkùnrin kan tí kò mọ ẹni tí Jésù jẹ́ rárá lára dá.—Lúùkù 22:50, 51; Jòhánù 5:5-9, 13; 9:24-34.
Nígbà náà, ipa wo ni ìgbàgbọ́ kó? Nígbà tí Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wà ní àgbègbè Tírè àti Sídónì, obìnrin ará Fòníṣíà kan wá ó sì lọgun pé: “Ṣàánú fún mi, Olúwa, Ọmọkùnrin Dáfídì. Ẹ̀mí èṣù gbé ọmọbìnrin mi dè burúkú burúkú.” Finú wòye àìnírètí rẹ̀, bí ó ti bẹ̀bẹ̀ pé: “Olúwa, ràn mí lọ́wọ́!” Àánú ṣe Jésù, ó sì fèsì pé: “Óò obìnrin, títóbi ni ìgbàgbọ́ rẹ; kí ó ṣẹlẹ̀ sí ọ gẹ́gẹ́ bí o ti dàníyàn.” A sì mú ọmọbìnrin rẹ̀ lára dá “láti wákàtí yẹn lọ.” (Mátíù 15:21-28) Ó ṣe kedere pé, ìgbàgbọ́ wé mọ́ ọn, ṣùgbọ́n, ìgbàgbọ́ ti ta ni? Kíyè sí i pé ìgbàgbọ́ ìyá ni Jésù gbóríyìn fún, kì í ṣe ìgbàgbọ́ ọmọ tí ń ṣàìsàn. Ìgbàgbọ́ nínú kí sì ni? Nípa pípe Jésù ní “Olúwa, Ọmọkùnrin Dáfídì,” obìnrin náà ń jẹ́wọ́ ní gbangba pé Jésù ni Mèsáyà tí a ṣèlérí náà. Kì í wulẹ̀ ṣe fífi ìgbàgbọ́ hàn nínú Ọlọ́run tàbí níní ìgbàgbọ́ nínú agbára amúniláradá náà. Nígbà tí Jésù sọ pé, “Ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá,” ó ń sọ pé, láìjẹ́ pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú òun gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà, àwọn tí ìyà ń pọ́n lójú kì bá má ti tọ̀ ọ́ wá fún ìwòsàn.
Láti inú àwọn àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí, a lè rí i pé àwọn ìmúláradá tí Jésù ṣe yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ohun tí a sábà máa ń rí tàbí tí àwọn ènìyàn sọ pé àwọn ń ṣe lónìí. Àwọn èrò kò fi ìmọ̀lára lílágbára hàn—pípariwo, kíkọrin, pípohùn réré ẹkún, lílọ nínú ẹ̀mí, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ—Jésù kò sì mẹ́mìí wọn gbóná láti mú wọn jí gìrì. Ní àfikún sí i, Jésù kò kùnà láé láti mú àwọn aláìsàn lára dá ní ṣíṣàwáwí pé wọn kò ní ìgbàgbọ́ tàbí pé owó tí wọ́n ń dá kò pọ̀ tó.
Ìwòsàn Nípa Agbára Ọlọ́run
Báwo ni ìmúláradá tí Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe ṣe ṣẹlẹ̀? Bíbélì dáhùn pé: “Agbára Jèhófà sì wà níbẹ̀ fún un láti ṣe ìmúláradá.” (Lúùkù 5:17) Lẹ́yìn tí ó ti ṣe ìmúláradá kan, Lúùkù 9:43 sọ pé, “háà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe gbogbo wọn sí agbára gíga lọ́lá ti Ọlọ́run.” Lọ́nà tí ó bá a mu wẹ́kú, Jésù kò darí àfiyèsí sí ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ṣe ìmúláradá náà. Ní àkókò kan, ó sọ fún ọkùnrin kan tí ó lé ẹ̀mí èṣù tí ń yọ ọ́ lẹ́nu jáde pé: “Lọ sí ilé lọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, kí o sì ròyìn fún wọn gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún ọ àti àánú tí ó ní fún ọ.”—Máàkù 5:19.
Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé agbára Ọlọ́run ni Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lò láti fi mú àwọn ènìyàn lára dá, ó rọrùn láti rí ìdí tí kò fi pọn dandan fún ẹni tí a ń wò sàn láti lo ìgbàgbọ́ kí ó tó lè rí ìwòsàn. Ṣùgbọ́n, ó pọn dandan fún amúniláradá láti ní ìgbàgbọ́ lílágbára. Nítorí náà, nígbà tí kò ṣeé ṣe fún àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù láti lé ẹ̀mí èṣù kan báyìí tí ó lágbára jáde, Jésù sọ ìdí rẹ̀ fún wọn pé: “Nítorí ìgbàgbọ́ yín tí ó kéré ni.”—Mátíù 17:20.
Ohun Tí Ìwòsàn Ìyanu Ń Ṣiṣẹ́ Fún
Bí Jésù tilẹ̀ ṣe ọ̀pọ̀ ìmúláradá jálẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, kì í ṣe ‘iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìmúláradá’ ni ohun àkọ́kọ́ tí ó ń lépa. Ìwòsàn ìyanu tí ó ṣe—tí kò gba kọ́bọ̀ rí lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tàbí kí ó ní kí wọn ṣèdáwó—wà ní ipò kejì sí àníyàn rẹ̀ àkọ́kọ́, ìyẹn ni ‘wíwàásù ìhìn rere ìjọba náà.’ (Mátíù 9:35) Àkọsílẹ̀ náà sọ pé, ní àkókò kan, ‘o fi inú rere gbà wọ́n ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ fún wọn nípa ìjọba Ọlọ́run, ó sì mú àwọn wọnnì tí wọ́n nílò ìwòsàn lára dá.’ (Lúùkù 9:11) Nínú àwọn àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere, lemọ́lemọ́ ni a máa ń tọ́ka sí Jésù gẹ́gẹ́ bí “Olùkọ́” ṣùgbọ́n a kò tọ́ka sí i rí gẹ́gẹ́ bí “Amúniláradá.”
Nígbà náà, èé ṣe tí Jésù fi ṣe ìwòsàn ìyanu? Ní pàtàkì, ó jẹ́ láti fìdí jíjẹ́ tí ó jẹ́ Mèsáyà tí a ṣèlérí múlẹ̀. Nígbà tí a fi Jòhánù Olùbatisí sẹ́wọ̀n láìyẹ, ó fẹ́ ìdánilójú pé òun ti ṣàṣeparí ohun ti Ọlọ́run rán òun wá láti ṣe. Ó rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Jésù láti bi í pé: “Ṣé ìwọ ni Ẹni Tí Ń Bọ̀ náà, tàbí kí a máa fojú sọ́nà fún ẹni kan tí ó yàtọ̀?” Kíyè si ohun tí Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù: “Ẹ máa bá ọ̀nà yín lọ kí ẹ sì ròyìn fún Jòhánù ohun tí ẹ ń gbọ́ tí ẹ sì ń rí: Àwọn afọ́jú tún ń ríran, àwọn arọ sì ń rìn káàkiri, a ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́ àwọn adití sì ń gbọ́ràn, a sì ń gbé àwọn òkú dìde, a sì ń polongo ìhìn rere fún àwọn òtòṣì.”—Mátíù 11:2-5.
Bẹ́ẹ̀ ni, òtítọ́ náà pé kì í ṣe iṣẹ́ ìmúláradá nìkan ni Jésù ṣe, ṣùgbọ́n ó tún ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu mìíràn tí a ṣàkọsílẹ̀ nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-ingbọn-in pé òun ni “Ẹni Tí Ń Bọ̀ náà,” Mèsáyà tí a ṣèlérí. Kò sí ìdí fún ẹnikẹ́ni láti “fojú sọ́nà fún ẹni kan tí ó yàtọ̀.”
Ìwòsàn Ìyanu Ha Wà Lónìí Bí?
Nígbà náà, ó ha yẹ kí a retí pé kí Ọlọ́run fẹ̀rí agbára rẹ̀ hàn lónìí nípa ìwòsàn bí? Rárá. Pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe nípasẹ̀ agbára Ọlọ́run, Jésù ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ láìsí àní-àní pé òun ní Mèsáyà tí Ọlọ́run ti ṣèlérí pé yóò wá. A ṣàkọsílẹ̀ àwọn iṣẹ́ agbára tí Jésù ṣe sínú Bíbélì fún gbogbo ènìyàn láti kà. Kò sí ìdí kankan fún Ọlọ́run láti fẹ̀rí agbára rẹ̀ hàn nípa ṣíṣe irú àwọn iṣẹ́ agbára bẹ́ẹ̀ fún gbogbo ìran ènìyàn.
Lọ́nà tí ó dùn mọ́ni, ìwọ̀nba ni ìwòsàn àti àwọn iṣẹ́ ìyanu mìíràn ń mú nǹkan dáni lójú mọ. Àní àwọn kan tí wọ́n fojú rí àwọn iṣẹ́ ìyanu Jésù pàápàá kò gbà gbọ́ pé ó ní ìtìlẹ́yìn Bàbá rẹ̀ ọ̀run. “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì níwájú wọn, wọn kì í lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.” (Jòhánù 12:37) Ìdí nìyẹn tí ó fi jẹ́ pé, lẹ́yìn jíjíròrò onírúurú ẹ̀bùn ìyanu—sísọtẹ́lẹ̀, sísọ̀rọ̀ ní ahọ́n àjèjì, mímúniláradá, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ—tí Ọlọ́run ti fún onírúurú mẹ́ńbà ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, a mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé pé: “Yálà àwọn ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀ wà, a óò mú wọn wá sí òpin; yálà àwọn ahọ́n àjèjì wà, wọn yóò ṣíwọ́; yálà ìmọ̀ wà, a óò mú un wá sí òpin. Nítorí àwa ní ìmọ̀ lápá kan a sì ń sọ tẹ́lẹ̀ lápá kan; ṣùgbọ́n nígbà tí èyíinì tí ó pé pérépéré bá dé, èyíinì tí ó jẹ́ ti apá kan ni a óò mú wá sí òpin.”—Kọ́ríńtì Kíní 12:28-31; 13:8-10.
Dájúdájú, níní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ṣe kókó fún ire wa. Ṣùgbọ́n, gbígbé ìgbàgbọ́ wa karí àwọn ìlérí asán ti ìwòsàn yóò wulẹ̀ já wa kulẹ̀ ni. Síwájú sí i, Jésù kìlọ̀ nípa àwọn àkókò ìkẹyìn pé: “Àwọn èké Kristi àti àwọn èké wòlíì yóò dìde wọn yóò sì fúnni ní àwọn àmì ńláǹlà àti àwọn iṣẹ́ àgbàyanu láti ṣi àwọn àyànfẹ́ pàápàá lọ́nà, bí ó bá ṣeé ṣe.” (Mátíù 24:24) Yàtọ̀ sí màgòmágó àti ẹ̀tàn, wọn yóò tún máa lo agbára ẹ̀mí èṣù. Nítorí èyí, kò yẹ kí sísọ tí wọ́n ń sọ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò ṣeé ṣàlàyé ń wáyé yà wá lẹ́nu, ìwọ̀nyí kì í sì í ṣe ìdí rárá fún níní ojúlówó ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run.
Níwọ̀n bí kò ti sí ẹnikẹ́ni lónìí tí ń ṣe ìwòsàn gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe, èyí ha ń pa wá lára bí? Rárá ó. Ní ti gidi, àwọn tí Jésù mú lára dá lè pa dà ṣàìsàn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Gbogbo wọn darúgbó, wọ́n sì kú. Àǹfààní ìmúláradá tí wọ́n rí gbà kò wà pẹ́ títí. Síbẹ̀, ìwòsàn ìyanu tí Jésù ṣe ní ìtumọ̀ wíwà pẹ́ títí ní ti pé wọ́n ṣàpẹẹrẹ àwọn ìbùkún ọjọ́ iwájú.
Nítorí náà, lẹ́yìn ṣíṣàyẹ̀wò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, Alexandre àti Benedita, tí a mẹ́nu kàn ṣáájú, kò gbé ìgbàgbọ́ wọn ka ìgbàgbọ́ wò-ó-sàn àti ìwòsàn mẹ́mìímẹ́mìí ti òde òní mọ́. Lẹ́sẹ̀ kan náà, wọ́n ní ìdánilójú pé ìwòsàn ìyanu kì í ṣe ìṣẹ̀lẹ̀ àtijọ́ lásán. Èé ṣe tí wọ́n fi ní irú ìdánilójú bẹ́ẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ kárí ayé, wọ́n ń fojú sọ́nà fún àwọn ìbùkún ìmúláradá lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.—Mátíù 6:10.
Kò Sí Àìsàn àti Ikú Mọ́
Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣáájú, ète iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù gan-an kì í ṣe láti mú àwọn aláìsàn lára dá àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu mìíràn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ṣe olórí iṣẹ́ rẹ̀. (Mátíù 9:35; Lúùkù 4:43; 8:1) Nípasẹ̀ Ìjọba yẹn ni Ọlọ́run yóò gbà ṣàṣeparí ìwòsàn ìyanu aráyé, tí yóò sì ṣàtúnṣe gbogbo ìbàjẹ́ tí ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé ti mú wá bá ìdílé ẹ̀dá ènìyàn. Báwo ni òun yóò ṣe ṣàṣeparí èyí, ìgbà wo sì ni yóò ṣe bẹ́ẹ̀?
Ní wíwo àwọn ọ̀rúndún tí ó wà níwájú, Kristi Jésù fi ìran alásọtẹ́lẹ̀ kan han àpọ́sítélì rẹ̀ Jòhánù: “Nísinsìnyí ni ìgbàlà dé àti agbára àti ìjọba Ọlọ́run wa àti ọlá àṣẹ Kristi rẹ̀!” (Ìṣípayá 12:10) Gbogbo ẹ̀rí fi hàn pé a ti lé aṣòdì tí ó burú jù lọ tí Ọlọ́run ní, Sátánì, dà sí sàkáání ilẹ̀ ayé láti ọdún 1914, Ìjọba náà sì ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ní ti gidi! A ti fi Jésù jẹ Ọba Ìjọba Mèsáyà náà, ó sì ti ṣe tán nísinsìnyí láti ṣe ìyípadà tegbò tigaga lórí ilẹ̀ ayé.
Ní ọjọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́, ìjọba ọ̀run ti Jésù yóò ṣàkóso lórí ẹgbẹ́ àwùjọ tuntun ti ẹ̀dá ènìyàn olódodo, ìyẹn ni “ilẹ̀ ayé tuntun.” (Pétérù Kejì 3:13) Báwo ni àwọn ipò nǹkan yóò ṣe rí nígbà yẹn? Ìwòfìrí ológo kan nìyí: “Mo sì rí ọ̀run tuntun kan àti ilẹ̀ ayé tuntun kan; nítorí ọ̀run ti ìṣáájú àti ilẹ̀ ayé ti ìṣáájú ti kọjá lọ . . . [Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:1, 4.
O ha lè finú wòye bí ìgbésí ayé yóò ṣe rí nígbà tí ìwòsàn ìyanu aráyé bá wáyé? “Kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’ Àwọn ènìyàn tí ń gbé ilẹ̀ náà yóò jẹ́ àwọn tí a ti dárí ìṣìnà wọn jì wọ́n.” Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run yóò ṣàṣeparí ohun tí àwọn onígbàgbọ́ wò-ó-sàn kò lè ṣe láé. “Òun yóò gbé ikú mì láéláé.” Ní tòótọ́, “Olúwa Jèhófà yóò nu omijé nù kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.”—Aísáyà 25:8; 33:24, NW.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, a óò mú aráyé lára dá lọ́nà ìyanu