ORÍ 38
Jòhánù Fẹ́ Gbọ́rọ̀ Látẹnu Jésù
JÒHÁNÙ ARINIBỌMI BÉÈRÈ IRÚ ẸNI TÍ JÉSÙ JẸ́
JÉSÙ GBÓRÍYÌN FÚN JÒHÁNÙ
Nǹkan bí ọdún kan ni Jòhánù Arinibọmi ti wà lẹ́wọ̀n báyìí, ó sì ń gbọ́ nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ń ṣe. Ẹ wo bó ṣe máa rí lára ẹ̀ nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ sọ fún un pé Jésù jí ọmọ opó Náínì dìde. Àmọ́, Jòhánù ṣì fẹ́ gbọ́rọ̀ látẹnu Jésù fúnra ẹ̀, kó lè mọ ohun tí gbogbo nǹkan yìí túmọ̀ sí. Torí náà, ó pe méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀. Kí nìdí tó fi pè wọ́n? Ó ní kí wọ́n bi Jésù pé: “Ṣé ìwọ ni Ẹni Tó Ń Bọ̀, àbí ká máa retí ẹlòmíì?”—Lúùkù 7:19.
Ṣé kò yà ẹ́ lẹ́nu pé Jòhánù béèrè irú ìbéèrè yẹn? Ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni Jòhánù, kódà ní nǹkan bí ọdún méjì sẹ́yìn nígbà tó ń ṣèrìbọmi fún Jésù, ó rí ẹ̀mí Ọlọ́run tó bà lé Jésù, ó sì gbọ́ tí Jèhófà sọ pé òun tẹ́wọ́ gba Jésù. Kò sídìí láti ronú pé ìgbàgbọ́ Jòhánù ti ń jó rẹ̀yìn. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, Jésù ò ní sọ̀rọ̀ ẹ̀ dáadáa. Tí Jòhánù ò bá ṣiyèméjì, kí wá ló dé tó fi béèrè irú ìbéèrè yìí?
Ó ṣeé ṣe kí Jòhánù fẹ́ kí Jésù fẹnu ara ẹ̀ sọ pé òun ni Mèsáyà. Tó bá mọ̀ pé Jésù ni Mèsáyà, ọkàn ẹ̀ máa túbọ̀ balẹ̀ bó ṣe ń kú lọ nínú ẹ̀wọ̀n. Ìdí pàtàkì míì tún wà tí Jòhánù fi béèrè ìbéèrè yẹn. Ó mọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó sọ pé Ẹni Àmì Òróró Ọlọ́run máa jẹ́ ọba àti olùdáǹdè. Ọ̀pọ̀ oṣù ti kọjá lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi, síbẹ̀ Jòhánù ṣì wà lẹ́wọ̀n. Ìdí nìyẹn tó fi ń béèrè pé ṣé ẹlòmíì ṣì ń bọ̀ lẹ́yìn Jésù tó máa mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yòókù nípa Mèsáyà ṣẹ.
Jésù ò kàn sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù pé ‘Èmi náà ni Ẹni tó ń bọ̀, kò sẹ́lòmíì.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló wo ọ̀pọ̀ èèyàn sàn, kó lè fi hàn pé Ọlọ́run ló rán òun. Ó wá sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù pé: “Ẹ lọ ròyìn ohun tí ẹ̀ ń gbọ́ àti ohun tí ẹ̀ ń rí fún Jòhánù: Àwọn afọ́jú ti ń ríran báyìí, àwọn arọ ń rìn, à ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́, àwọn adití ń gbọ́ràn, à ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń sọ ìhìn rere fún àwọn aláìní.”—Mátíù 11:4, 5.
Ó ṣeé ṣe kí Jòhánù máa retí pé Jésù á ṣe kọjá ohun tó ń ṣe báyìí, kó sì wá dá òun sílẹ̀ lẹ́wọ̀n. Àmọ́, ohun tí Jésù ń sọ fún Jòhánù ni pé kó má retí pé òun máa ṣe iṣẹ́ ìyanu tó ju èyí táwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn rí.
Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù lọ tán, Jésù sọ fáwọn tó wà níbẹ̀ pé wòlíì tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni Jòhánù. Ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun ni “ìránṣẹ́” Jèhófà tí Málákì 3:1 sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Òun náà ni wòlíì Èlíjà tí Málákì 4:5, 6 sọ tẹ́lẹ̀. Jésù ṣàlàyé pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé, nínú àwọn tí obìnrin bí, kò tíì sí ẹni tó tóbi ju Jòhánù Arinibọmi lọ, àmọ́ ẹni kékeré nínú Ìjọba ọ̀run tóbi jù ú lọ.”—Mátíù 11:11.
Nígbà tí Jésù sọ pé ẹni kékeré nínú Ìjọba ọ̀run tóbi ju Jòhánù lọ, ohun tó ń sọ ni pé Jòhánù ò ní sí lára àwọn tó máa jọba pẹ̀lú òun lọ́run. Jòhánù ló ṣètò ọ̀nà sílẹ̀ fún Jésù, àmọ́ ó kú kí Jésù tó ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fáwọn èèyàn láti lọ sọ́run. (Hébérù 10:19, 20) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wòlíì tó fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run ni Jòhánù, ayé ló máa gbé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.