‘Ẹ Dúró Nínú Ọ̀rọ̀ Mi’
“Bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin jẹ́ ní ti tòótọ́.”—JÒHÁNÙ 8:31.
1. (a) Nígbà tí Jésù padà sí ọ̀run, kí ló fi sílẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?
NÍGBÀ tí Jésù Kristi, tó jẹ́ Olùdásílẹ̀ Ẹ̀sìn Kristẹni, ń padà sí ọ̀run, kò fi àwọn ìwé tóun fúnra rẹ̀ kọ sílẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, kò kọ́ ilé sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun ìrántí bẹ́ẹ̀ ni kò fi ọrọ̀ sílẹ̀. Àmọ́ ó fi àwọn ọmọ ẹ̀yìn sílẹ̀ àtàwọn ohun kan téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe láti di ọmọ ẹ̀yìn. Kódà, nínú Ìhìn Rere Jòhánù, Jésù mẹ́nu ba àwọn ohun pàtàkì mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe láti di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Kí làwọn ohun pàtàkì yìí? Kí la lè ṣe kọ́wọ́ wa bàa lè tẹ àwọn ohun pàtàkì náà? Ọ̀nà wo la lè gbé e gbà láti rí i dájú pé a tóótun gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn Kristi lónìí?a
2. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ìhìn Rere Jòhánù, kí ni ohun tó pọn dandan láti ṣe téèyàn bá fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn?
2 Nígbà tó ku nǹkan bí oṣù mẹ́fà kí Jésù kú, ó lọ sí Jerúsálẹ́mù ó sì wàásù fáwọn èrò tó pé jọ síbẹ̀ láti ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà ọlọ́sẹ̀ kan gbáko. Ohun tó wá ṣẹlẹ̀ ni pé nígbà tí àjọyọ̀ náà dé ìdajì, “ọ̀pọ̀ nínú ogunlọ́gọ̀ náà ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.” Jésù ò dá ìwàásù rẹ̀ dúró, tó fi di pé ní ọjọ́ tó kẹ́yìn àjọyọ̀ náà, “ọ̀pọ̀lọpọ̀ [ló tún] ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.” (Jòhánù 7:10, 14, 31, 37; 8:30) Ìgbà náà ni Jésù wá yíjú sáwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́, tó sì sọ àwọn ohun tó pọn dandan téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe tó bá fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn fún wọn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ pé: “Bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin jẹ́ ní ti tòótọ́.”—Jòhánù 8:31.
3. Ànímọ́ wo lẹnì kan gbọ́dọ̀ ní tó bá fẹ́ “dúró nínú ọ̀rọ̀ [Jésù]”?
3 Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí kò túmọ̀ sí pé àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn náà kò nígbàgbọ́ tó pọ̀ tó o. Dípò ìyẹn, òun tó ń sọ ni pé wọ́n láǹfààní láti di ọmọ ẹ̀yìn òun tòótọ́—tí wọ́n bá sáà ti lè dúró nínú ọ̀rọ̀ òun, tí wọ́n ní ìfaradà. Wọ́n ti fara mọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àmọ́ wọ́n ní láti máa bá a lọ bẹ́ẹ̀, láìdáwọ́dúró. (Jòhánù 4:34; Hébérù 3:14) Àní, Jésù ka ìfaradà sí ànímọ́ pàtàkì táwọn ọmọ ẹ̀yìn òun gbọ́dọ̀ ní débi pé nínú ìjíròrò tó wáyé kẹ́yìn láàárín òun àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀, èyí tá a kọ sínú Ìhìn Rere Jòhánù, ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló rọ̀ wọ́n pé: “[Ẹ] máa bá a lọ ní títọ̀ mí lẹ́yìn.” (Jòhánù 21:19, 22) Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ìjímìjí ló ṣe bẹ́ẹ̀. (2 Jòhánù 4) Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní ìfaradà?
4. Kí ló ran àwọn Kristẹni ìjímìjí lọ́wọ́ láti ní ìfaradà?
4 Àpọ́sítélì Jòhánù, tó jẹ́ olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi fún nǹkan bí àádọ́rin ọdún, sọ kókó pàtàkì kan tó ràn wọ́n lọ́wọ́. Ó gbóríyìn fáwọn Kristẹni olóòótọ́ pé: “Alágbára [ni yín] àti pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dúró nínú yín, ẹ sì ti ṣẹ́gun ẹni burúkú náà.” Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi wọ̀nyí ní ìfaradà, wọn ò yà kúrò nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nítorí pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dúró nínú wọn. Wọ́n kà á sí ohun tó ṣeyebíye gan-an. (1 Jòhánù 2:14, 24) Bákan náà lọ̀ràn rí lóde òní, tá a bá fẹ́ ‘fara dà á títí dópin,’ a ní láti rí i dájú pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò kúrò nínú wa. (Mátíù 24:13) Báwo la ṣe lè ṣe èyí? Àkàwé kan tí Jésù ṣe dáhùn ìbéèrè yìí.
‘Gbígbọ́ Ọ̀rọ̀ Náà’
5. (a) Oríṣi erùpẹ̀ wo ni Jésù mẹ́nu bà nínú ọ̀kan nínú àwọn àkàwé tó ṣe? (b) Kí ni irúgbìn àti erùpẹ̀ inú àkàwé Jésù ṣàpẹẹrẹ?
5 Jésù sọ àkàwé afúnrúgbìn kan tó lọ fúnrúgbìn, a sì kọ ọ́ sínú ìwé Ìhìn Rere Mátíù, Máàkù àti Lúùkù. (Mátíù 13:1-9, 18-23; Máàkù 4:1-9, 14-20; Lúùkù 8:4-8, 11-15) Bó o ṣe ń ka àkọsílẹ̀ yìí, wà á rí i pé kókó inú àkàwé náà ni pé oríṣi irúgbìn kan náà ló bọ́ sórí onírúurú ilẹ̀, àbájáde wọn sì yàtọ̀ síra. Ilẹ̀ àkọ́kọ́ le koránkorán, èkejì kò ní erùpẹ̀ púpọ̀, ẹ̀gún ló sì kúnnú ẹ̀kẹta. Àmọ́ oríṣi ilẹ̀ kẹrin yàtọ̀ sí gbogbo àwọn tó kù, “erùpẹ̀ àtàtà” lòun. Gẹ́gẹ́ bí Jésù fúnra rẹ̀ ṣe ṣàlàyé, ìhìn Ìjọba náà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni irúgbìn náà dúró fún, erùpẹ̀ sì dúró fún àwọn èèyàn tó jẹ́ pé ọkàn àyà wọn yàtọ̀ síra. Òótọ́ ni pé àwọn èèyàn tá a fi oríṣiríṣi erùpẹ̀ ṣàpèjúwe láwọn ànímọ́ kan tó jọra wọn, àmọ́ àwọn tá a fi erùpẹ̀ àtàtà ṣàpèjúwe ní àwọn ànímọ́ kan tó mú kí wọ́n yàtọ̀ sáwọn tó kù.
6. (a) Báwo ni oríṣi erùpẹ̀ kẹrin nínú àkàwé Jésù ṣe yàtọ̀ sí oríṣi mẹ́ta tó kù, kí ló sì túmọ̀ sí? (b) Kí lohun náà tó ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ ní ìfaradà gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn Kristi?
6 Àkọsílẹ̀ inú Lúùkù 8:12-15, fi hàn pé nínú àpèjúwe mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà làwọn èèyàn ti ‘gbọ́ ọ̀rọ̀ náà.’ Àmọ́ ṣá, àwọn tó ní “ọkàn-àyà àtàtà àti rere” kò kàn wulẹ̀ ‘gbọ́ ọ̀rọ̀ náà’ lásán. Wọ́n “dì í mú ṣinṣin, wọ́n sì so èso pẹ̀lú ìfaradà.” Erùpẹ̀ àtàtà yìí, tó rọ̀ dáadáa jẹ́ kí irúgbìn náà lè fi gbòǹgbò múlẹ̀ dáadáa, èyí ló wá jẹ́ kí irúgbìn náà hù tó sì so èso. (Lúùkù 8:8) Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀ràn àwọn tó ní ọkàn rere ṣe rí, wọ́n lóye ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n mọyì rẹ̀, wọ́n sì ń jẹ́ kó wọ̀ wọ́n lọ́kàn ṣinṣin. (Róòmù 10:10; 2 Tímótì 2:7) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà nínú wọn. Èyí ló mú kí wọ́n máa fi ìfaradà so èso. Nítorí náà, fífi tọkàntọkàn mọrírì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe kókó láti ní ìfaradà gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn Kristi. (1 Tímótì 4:15) Nígbà náà, báwo la ṣe lè ní irú ìmọrírì àtọkànwá bẹ́ẹ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
Bí Ọkàn Ṣe Rí àti Ríronú Jinlẹ̀
7. Kí lohun tí ọkàn rere máa ń ṣe?
7 Kíyè sí ohun tí Bíbélì sọ léraléra pé ọkàn rere máa ń ṣe. “Ọkàn-àyà olódodo máa ń ṣe àṣàrò láti lè dáhùn.” (Òwe 15:28) “Kí àwọn àsọjáde ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn-àyà mi dùn mọ́ ọ, ìwọ Jèhófà.” (Sáàmù 19:14) “Àṣàrò inú ọkàn-àyà mi yóò sì jẹ́ ti àwọn ohun òye.”—Sáàmù 49:3.
8. (a) Kí la gbọ́dọ̀ yẹra fún nígbà tá a bá ń ka Bíbélì, kí la sì gbọ́dọ̀ ṣe? (b) Àǹfààní wo ló wà nínú ṣíṣàṣàrò tàdúràtàdúrà lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? (Fi ohun tó wà nínú àpótí náà “Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Gbọn-in Gbọn-in Nínú Òtítọ́” kún un.)
8 Gẹ́gẹ́ bíi tàwọn òǹkọ̀wé Bíbélì yìí, àwa náà gbọ́dọ̀ máa fi ìmọrírì ṣàṣàrò tàdúràtàdúrà lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti iṣẹ́ rẹ̀. Tá a bá ń ka Bíbélì tàbí àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn tá a gbé karí Bíbélì, a ò gbọ́dọ̀ ṣe bíi ti arìnrìn àjò afẹ́, tó kàn ń ya fọ́tò àwọn ohun mèremère tó ń rí àmọ́ tí ò lè fara balẹ̀ wò wọ́n kó sì gbádùn wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, tá a bá ń ka Bíbélì, ó yẹ ká fara balẹ̀ dáadáa, ká sì gbádùn àwọn ẹsẹ Bíbélì tá à ń kà.b Bá a ṣe ń baralẹ̀ ronú lórí àwọn ohun tá a kà ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run á ṣe máa nípa lórí ọkàn wa. Á máa nípa lórí èrò wa àti ọ̀nà tá a gbà ń ronú. Á tún máa jẹ́ ká sọ àwọn ọ̀rọ̀ àṣírí wa fún Ọlọ́run nínú àdúrà. Èyí á wá jẹ́ kí àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà túbọ̀ lágbára sí i, ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run kò ní jẹ́ ká jáwọ́ títẹ̀lé Jésù kódà lákòókò tí nǹkan bá le koko pàápàá. (Mátíù 10:22) Ó wá ṣe kedere pé ṣíṣàṣàrò lórí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ jẹ́ olóòótọ́ títí dópin.—Lúùkù 21:19.
9. Báwo la ṣe lè mú kí ọkàn wa fàyè gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
9 Àkàwé Jésù tún fi hàn pé àwọn ohun kan wà tí kì í jẹ́ kí irúgbìn náà, ìyẹn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dàgbà. Fún ìdí yìí, tá a bá fẹ́ jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn olóòótọ́, a gbọ́dọ̀ (1) mọ àwọn ohun ìdènà tí ilẹ̀ tí kò dára nínú àpèjúwe Jésù dúró fún, ká sì (2) gbé ìgbésẹ̀ tó bá yẹ láti ṣàtúnṣe tàbí yẹra fún wọn. Lọ́nà yìí, àá lè rí i dájú pé ọkàn wa jẹ́ èyí tó ń mú kí irúgbìn Ìjọba náà hù bó ṣe yẹ a ò sì ní ṣíwọ́ síso èso.
Ti “Ẹ̀bá Ọ̀nà” —Ìyẹn Àwọn Tọ́wọ́ Wọn Dí
10. Sọ ilẹ̀ àkọ́kọ́ nínú àpèjúwe Jésù, kó o sì ṣàlàyé ìtumọ̀ rẹ̀.
10 Oríṣi ilẹ̀ àkọ́kọ́ tí irúgbìn náà bọ́ sí ni “ẹ̀bá ọ̀nà,” níbi táwọn èèyàn ti “tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀.” (Lúùkù 8:5) Ilẹ̀ tó bá wà lẹ́bàá ọ̀nà oko tí wọ́n gbin ọkà sí kì í nísinmi rárá, títẹ̀ làwọn èèyàn máa ń tẹ̀ ẹ́ ní àtẹ̀lọ àtẹ̀bọ̀. (Máàkù 2:23) Lọ́nà kan náà, àwọn tó bá jẹ́ kí kòókòó jàn-ánjàn-án ilé ayé yìí máa gba àkókò wọn àti okun wọn bí ò ṣe yẹ lè rí i pé ọwọ́ àwọn dí débi pé àwọn ò lè ní ìmọrírì kankan fún ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, àmọ́ wọn ò ṣàṣàrò lé e lórí. Ìdí nìyẹn tí ọ̀rọ̀ náà ò fi wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Kó tó di pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, “Èṣù [ti] wá, ó sì mú ọ̀rọ̀ náà kúrò nínú ọkàn-àyà wọn, kí wọ́n má bàa gbà gbọ́, kí a sì gbà wọ́n là.” (Lúùkù 8:12) Ǹjẹ́ ohun kan wà tá a lè ṣe kí èyí má bàa ṣẹlẹ̀?
11. Báwo la ṣe lè ṣe é tí ọkàn àyà wa ò fi ní dà bí ilẹ̀ líle?
11 Ọ̀pọ̀ nǹkan la lè ṣe kí ọkàn wa má bàa dà bí ilẹ̀ ẹ̀bá ọ̀nà tí ò dára fún irúgbìn. Ilẹ̀ táwọn èèyàn ti tẹ̀ lọ tẹ̀ bọ̀ tó ti wá le koránkorán lè padà di èyí tó rọ̀ mùpẹ̀mupẹ tó sì dára fún irúgbìn, téèyàn bá fi ohun èlò ìtúlẹ̀ tú u táwọn èèyàn ò sì gbabẹ̀ kọjá mọ́. Lọ́nà kan náà, wíwá àkókò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ṣíṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè mú kí ọkàn dà bí ilẹ̀ dáradára, tó ń méso jáde. Kókó ibẹ̀ ni pé ká má ṣe jẹ́ káwọn nǹkan tí ò ní láárí nínú ayé dí wa lọ́wọ́. (Lúùkù 12:13-15) Kàkà bẹ́ẹ̀, rí i dájú pé o ṣètò àkókò láti ṣàṣàrò lórí “àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù” nínú ìgbésí ayé.—Fílípì 1:9-11.
‘Ti Orí Àpáta Ràbàtà’ —Ìyẹn Àwọn Tó Ń Bẹ̀rù
12. Kí lohun náà gan-an tó mú kí èèhù inú ilẹ̀ kejì nínú àkàwé Jésù gbẹ?
12 Nígbà tí irúgbìn bọ́ sórí ilẹ̀ kejì, kò kàn bọ́ síbẹ̀ lásán bíi ti ilẹ̀ àkọ́kọ́. Ó ta gbòǹgbò ó sì hù jáde. Àmọ́ nígbà tí oòrùn ganrínganrín dé, ooru mú èèhù irúgbìn náà ó sì gbẹ. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká kíyè sí kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ yìí. Kì í ṣe ooru lásán ló mú kí irúgbìn náà gbẹ o. Ó ṣe tán, ooru mú irúgbìn tó hù nínú ilẹ̀ dáradára náà kò sì gbẹ, kódà, ńṣe ló so jìngbìnnì. Kí ló fa ìyàtọ̀ yìí? Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ, “ṣíṣàìní erùpẹ̀ jíjinlẹ̀,” àti “ṣíṣàìní ọ̀rinrin” ló mú kí èèhù náà gbẹ. (Mátíù 13:5, 6; Lúùkù 8:6) “Àpáta ràbàtà” tó wà lábẹ́ ilẹ̀ náà kò jẹ́ kí gbòǹgbò irúgbìn yìí ríbi wọlẹ̀ débi tá á fi rí ọ̀rinrin táá sì fìdí múlẹ̀ dáadáa. Tìtorí pé ilẹ̀ náà kò ní erùpẹ̀ jíjinlẹ̀ ló mú kí èèhù náà gbẹ.
13. Irú àwọn èèyàn wo ló dà bí ilẹ̀ tí kò ní erùpẹ̀ jíjinlẹ̀, kí sì ni olórí ohun tó mú kí wọ́n hùwà lọ́nà tí wọ́n gbà hùwà yẹn?
13 Àwọn tí apá yìí ń tọ́ka sí nínú àkàwé Jésù làwọn tí wọ́n “fi ìdùnnú gba ọ̀rọ̀ náà” tí wọ́n sì fi ìtara tẹ̀ lé Jésù “fún àsìkò kan.” (Lúùkù 8:13) Tí oòrùn ganrínganrín, ìyẹn “ìpọ́njú tàbí inúnibíni” bá dé, ẹ̀rù á bà wọ́n débi pé wọn ò ní ní ayọ̀ àti okun mọ́, wọ́n ò sì ní tọ Kristi lẹ́yìn mọ́. (Mátíù 13:21) Àmọ́ ṣá, kì í ṣe àtakò lohun náà gan-an tó fa ìbẹ̀rù wọn yìí. Ó ṣe tán ọ̀kẹ́ àìmọye ọmọ ẹ̀yìn Kristi ló ti fara da onírúurú ìpọ́njú, síbẹ̀ ìṣòtítọ́ wọn ò yingin. (2 Kọ́ríńtì 2:4; 7:5) Ohun náà gan-an tó ń mú káwọn kan bẹ̀rù kí wọ́n sì fi òtítọ́ sílẹ̀ ni pé ọkàn wọn tó dà bí àpáta kò jẹ́ kí wọ́n lè ṣàṣàrò dáadáa lórí àwọn ohun tó ń gbéni ró àtàwọn ohun tẹ̀mí. Nítorí èyí, ìmọrírì tí wọ́n ní fún Jèhófà àti fún ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ju bíńtín lọ kò sì lágbára páàpáà láti kojú inúnibíni. Báwo la ṣe lè dènà èyí?
14. Àwọn ìgbésẹ̀ wo lẹnì kan gbọ́dọ̀ gbé kí ọkàn rẹ̀ má bàa dà bí ilẹ̀ tí ò ní erùpẹ̀ jíjinlẹ̀?
14 Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ rí i dájú pé kò sí ohun ìdènà kankan tó dà bí òkúta, irú bí ìbínú tó ti wà nínú ẹni tipẹ́tipẹ́, ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan tàbí àwọn ìwà burúkú mìíràn nínú ọkàn wa. Tó bá sì ṣẹlẹ̀ pé irú àwọn ohun ìdènà bẹ́ẹ̀ ti wà lọ́kàn wa, agbára tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní lè mú wọn kúrò. (Jeremáyà 23:29; Éfésù 4:22; Hébérù 4:12) Lẹ́yìn náà, ṣíṣàṣàrò tàdúràtàdúrà yóò mú kí “gbígbin ọ̀rọ̀ náà sínú” ọkàn ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣeé ṣe. (Jákọ́bù 1:21) Èyí á pèsè okun láti borí ìrẹ̀wẹ̀sì á sì tún fúnni nígboyà láti jẹ́ olóòótọ́ láìfí àdánwò pè.
‘Ti Àárín Àwọn Ẹ̀gún’ —Ìyẹn Àwọn Tó Ní Ìpínyà Ọkàn
15. (a) Èé ṣe tí ilẹ̀ kẹta tí Jésù mẹ́nu bà fi yẹ lóhun tá à ń dìídì gbé yẹ̀ wò? (b) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ kẹta nígbẹ̀yìngbẹ́yín, kí ló sì fà á?
15 Ilẹ̀ kẹta, ìyẹn èyí tí ẹ̀gún wà nínú rẹ̀, dìídì yẹ lóhun tá à ń gbé yẹ̀ wò nítorí pé ó fara jọ erùpẹ̀ rere láwọn ọ̀nà kan. Ilẹ̀ ẹlẹ́gùn-ún yìí jẹ́ kí irúgbìn náà hù kó sì ta gbòǹgbò gẹ́gẹ́ bíi ti erùpẹ̀ rere. Lákọ̀ọ́kọ́, kò sí ìyàtọ̀ kankan láàárín báwọn irúgbìn náà ṣe ń dàgbà nínú erùpẹ̀ méjì yìí. Àmọ́ bí àkókò ti ń lọ, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó fún irúgbìn náà pa nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Ilẹ̀ yìí ní tiẹ̀ ò dà bí ilẹ̀ rere, ńṣe ni ẹ̀gún gbalẹ̀ nínú rẹ̀. Bí irúgbìn náà ṣe ń yọrí jáde látinú ilẹ̀ báyìí, làwọn ‘ẹ̀gún tí wọ́n ń bá a dàgbà sókè’ bẹ̀rẹ̀ sí hàn án léèmọ̀. Irúgbìn náà àti ẹ̀gún bẹ̀rẹ̀ sí du oúnjẹ, oòrùn àti àyè mọ́ra wọn lọ́wọ́, àmọ́ nígbà tó yá ọwọ́ ẹ̀gún le ju ti irúgbìn náà lọ ó sì “fún un pa.”—Lúùkù 8:7.
16. (a) Irú àwọn èèyàn wo ló dà bí ilẹ̀ ẹlẹ́gùn-ún? (b) Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣe sọ, kí ni ẹ̀gún náà dúró fún?—Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.
16 Irú àwọn èèyàn wo ló dà bí ilẹ̀ ẹlẹ́gùn-ún yìí? Jésù ṣàlàyé pé: “Ìwọ̀nyí ni àwọn tí ó ti gbọ́, ṣùgbọ́n, nípa dídi ẹni tí àwọn àníyàn àti ọrọ̀ àti adùn ìgbésí ayé yìí gbé lọ, a fún wọn pa pátápátá, wọn kò sì mú nǹkan kan wá sí ìjẹ́pípé.” (Lúùkù 8:14) Bí irúgbìn tí afúnrúgbìn náà gbìn àti ẹ̀gún ṣe ń dàgbà pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà làwọn èèyàn kan wà tí wọ́n fẹ́ máa kó irin méjì bọná lẹ́ẹ̀kan náà, ìyẹn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti “adùn ìgbésí ayé yìí.” A gbin òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí ọkàn wọn, àmọ́ irúgbìn yìí ní láti figagbága pẹ̀lú àwọn ohun mìíràn táwọn èèyàn yìí tún ń lépa. Ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wọn ti pín sí oríṣiríṣi ọ̀nà. (Lúùkù 9:57-62) Èyí ni kì í jẹ́ kí wọ́n ráyè tó pọ̀ tó láti ṣàṣàrò lórí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàdúràtàdúrà. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò wọnú ọkàn wọn dáadáa, ìdí rèé tí wọn ò fi ní ìmọrírì àtọkànwá láti ní ìfaradà. Díẹ̀díẹ̀ ni àwọn nǹkan tara á bẹ̀rẹ̀ sí borí nǹkan tẹ̀mí mọ́ wọn lọ́wọ́ títí tí wọ́n á fi “fún [un] pa pátápátá.”c Ẹ ò rí i pé àbájáde búburú gbáà lèyí jẹ́ fáwọn tí ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn!—Mátíù 6:24; 22:37.
17. Àwọn ohun wo ló yẹ ká yàn nínú ìgbésí ayé kí ẹ̀gún ìṣàpẹẹrẹ tá a mẹ́nu bà nínú àkàwé Jésù má bà a fún wa pa?
17 Tá a bá fi àwọn ohun tẹ̀mí ṣáájú ohun ti ara, ìrora àti adùn ìgbésí ayé yìí ò ní lè hàn wá léèmọ̀. (Mátíù 6:31-33; Lúùkù 21:34-36) A ò gbọ́dọ̀ kóyán Bíbélì kíkà àti ṣíṣe àṣàrò lórí ohun tá a kà kéré láé. Tá ò bá walé ayé máyà, àá lè rí àyè tó pọ̀ sí i láti pọkàn pọ̀ sórí ṣíṣàṣàrò tàdúràtàdúrà. (1 Tímótì 6:6-8) Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí ò walé ayé máyà—ìyẹn àwọn tá a lè sọ pé wọ́n ti hú àwọn ẹ̀gún inú ilẹ̀ kúrò kí ilẹ̀ náà lè ráwọn èròjà aṣaralóore tó nílò, kó sì lè rí oòrùn àti àyè tó pọ̀ tó fún irúgbìn tó ń so èso—ń rí ìbùkún Jèhófà. Sandra, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n sọ pé: “Tí mo bá ronú lórí àǹfààní tí mo ti ní nínú òtítọ́, mo máa ń rí i pé kò sóhun náà tí ayé yìí lè fúnni tá a lè fi wé e!”—Sáàmù 84:11.
18. Báwo la ṣe lè dúró nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ká sì máa forí tì í gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni?
18 Nígbà náà, ó ṣe kedere pé tí gbogbo wa, lọ́mọdé lágbà, bá jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dúró nínú wa, àá lè gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sínú àá sì lè forí tì í gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé a ò jẹ́ kí ilẹ̀ ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa di èyí tó le koránkorán, tí ò jinlẹ̀ tàbí tí koríko tí ò dára hù sínú rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ká jẹ́ kó rọ̀ kó sì jinlẹ̀. Lọ́nà yìí, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run á lè wọ̀ wá lọ́kàn dáadáa àá sì lè “so èso pẹ̀lú ìfaradà.”—Lúùkù 8:15.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a óò jíròrò èyí tó jẹ́ àkọ́kọ́ lára àwọn ohun pàtàkì tí Jésù là sílẹ̀ yìí. A óò jíròrò méjì tó kù nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó kù.
b Láti ṣàṣàrò tàdúràtàdúrà lórí ibi tó o kà nínú Bíbélì, o lè béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ ibí yìí sọ ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ànímọ́ Jèhófà fún mi? Báwo ló ṣe bá àkòrí Bíbélì mu? Báwo ni mo ṣe lè lò ó nínú ìgbésí ayé mi tàbí kí n fi ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́?’
c Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sọ nípa àkàwé Jésù, ìrora àti adùn inú ayé yìí ló fún irúgbìn náà pa: “Àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí,” “agbára ìtannijẹ ọrọ̀,” “àwọn ìfẹ́-ọkàn fún àwọn nǹkan yòókù” àti “adùn ìgbésí ayé yìí.”—Máàkù 4:19; Mátíù 13:22; Lúùkù 8:14; Jeremáyà 4:3, 4.
Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
• Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ ‘dúró nínú ọ̀rọ̀ Jésù’?
• Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dúró nínú ọkàn wa?
• Irú àwọn èèyàn wo ni oríṣi erùpẹ̀ mẹ́rin tí Jésù mẹ́nu bà dúró fún?
• Báwo lo ṣe lè wá àkókò láti ṣàṣàrò lórí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé tó wà ní ojú ìwé 10]
“FẸSẸ̀ MÚLẸ̀ GBỌN-IN GBỌN-IN NÍNÚ ÒTÍTỌ́”
Ọ̀PỌ̀ àwọn tó ti jẹ ọmọ ẹ̀yìn Kristi tipẹ́ ló ń fi hàn bí ọdún ṣe ń gorí ọdún pé àwọn “fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in nínú òtítọ́.” (2 Pétérù 1:12) Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní ìforítì? Ẹ jẹ́ ká gbọ́ díẹ̀ lára ohun tí wọ́n sọ.
“Mo máa ń ka Bíbélì ní òpin ọjọ́ kọ̀ọ̀kan mo sì máa ń gbàdúrà. Màá wá ronú lórí nǹkan tí mo kà.”—Jean, ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1939.
“Ṣíṣe àṣàrò lórí bí Jèhófà, tó jẹ́ ẹni gíga ṣe nífẹ̀ẹ́ wa gan-an jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀ pé kò séwu ó sì fún mi lókun láti jẹ́ olóòótọ́.—Patricia, ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1946.
“Bí mo ṣe sọ ọ́ dàṣà láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé tí mo sì máa ń ronú lórí ‘àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run’ ló ń jẹ́ kí n lè máa sin Jèhófà nìṣó.”—1 Kọ́ríńtì 2:10; Anna, ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1939.
“Ìdí tí mo fi ń ka Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde wa tá a gbé karí Bíbélì ni kí n lè ṣàyẹ̀wò ọkàn mi àtàwọn ohun tí mo ń fẹ́.”—Zelda, ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1943.
“Àkókò ti mo máa ń gbádùn jù lọ ni ìgbà tí mo bá rìn jáde tí mo sì bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nínú àdúrà tí mo jẹ́ kó mọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn mi.”—Ralph, ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1947.
“Ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ lohun àkọ́kọ́ tí mo máa ń ṣe láràárọ̀ màá sì ka Bíbélì. Èyí máa ń jẹ́ kí n rí ohun tuntun kan tí màá ronú lé lórí ní gbogbo ọjọ́ náà.”—Marie, ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1935.
“Ní tèmi, jíjíròrò ìwé kọ̀ọ̀kan nínú Bíbélì lẹ́sẹẹsẹ máa ń fún mi lókun gan-an.”—Daniel, ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1946.
Ìgbà wo lo máa ń wáyè láti ṣàṣàrò lórí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàdúràtàdúrà?—Dáníẹ́lì 6:10b; Máàkù 1:35; Ìṣe 10:9.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Tá a bá ń fi àwọn ohun tẹ̀mí sípò àkọ́kọ́, a lè “so èso pẹ̀lú ìfaradà”