ORÍ 47
Jésù Jí Ọmọbìnrin Kan Dìde!
MÁTÍÙ 9:18, 23-26 MÁÀKÙ 5:22-24, 35-43 LÚÙKÙ 8:40-42, 49-56
JÉSÙ JÍ ỌMỌBÌNRIN JÁÍRÙ DÌDE
Nígbà tí Jáírù rí i pé Jésù ti wo obìnrin tó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ náà sàn, ó ṣeé ṣe kó gbà pé Jésù á wo ọmọ òun náà sàn. Síbẹ̀, ó tún ń ronú pé ó ṣeé ṣe kí ‘ọmọbìnrin òun ti kú báyìí.’ (Mátíù 9:18) Ṣé Jésù ṣì lè rí nǹkan ṣe sí i?
Bí Jésù ṣe ń bá obìnrin tó mú lára dá náà sọ̀rọ̀, àwọn ọkùnrin kan dé láti ilé Jáírù, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ọmọbìnrin rẹ ti kú! Kí ló dé tí o ṣì ń yọ Olùkọ́ lẹ́nu?”—Máàkù 5:35.
Ẹ ò rí i pé ìròyìn burúkú ni wọ́n mú wá fún ọkùnrin táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún yìí, kò sì sóhun tó lè ṣe nípa ẹ̀. Ọmọbìnrin kan ṣoṣo tó ní ti kú. Àmọ́, Jésù gbọ́ ohun tí wọ́n sọ, ó wá yíjú sí Jáírù, ó sì sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, ṣáà ti ní ìgbàgbọ́.”—Máàkù 5:36.
Jésù wá tẹ̀ lé Jáírù pa dà sílé. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, wọ́n rí i táwọn èèyàn ń kígbe bí wọ́n ṣe ń ṣọ̀fọ̀, tí wọ́n ń sunkún, tí wọ́n sì ń kérora. Bí Jésù ṣe wọlé, ó sọ ohun kan tó ya gbogbo wọn lẹ́nu, ó ní: “Ọmọ náà ò tíì kú, ó ń sùn ni.” (Máàkù 5:39) Nígbà táwọn èèyàn gbọ́ ohun tí Jésù sọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi ṣe yẹ̀yẹ́ torí wọ́n mọ̀ pé ọmọ náà ti kú. Àmọ́, Jésù máa jẹ́ kí wọ́n rí i pé Ọlọ́run ti fún òun lágbára láti jí òkú dìde bí ìgbà téèyàn jí ẹni tó ń sùn dìde.
Jésù wá ní kí àwọn èèyàn bọ́ síta àfi Pétérù, Jémíìsì, Jòhánù àti àwọn òbí ọmọ náà. Jésù mú àwọn márààrún lọ síbi tí wọ́n tẹ́ ọmọ náà sí. Ó di ọwọ́ rẹ̀ mú, ó wá sọ pé: “‘Tàlítà kumì,’ tó túmọ̀ sí: ‘Ọmọbìnrin, mo sọ fún ọ, “Dìde!”’” (Máàkù 5:41) Ọmọ náà dìde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn. Ẹ wo bí inú Jáírù àtìyàwó rẹ̀ ṣe máa dùn tó nígbà tí wọ́n rí ohun tó ṣẹlẹ̀! Kó lè túbọ̀ dá wọn lójú pé ọmọ náà ti jíǹde, Jésù ní kí wọ́n fún un lóúnjẹ.
Jésù sábà máa ń sọ fáwọn tó wò sàn pé kí wọ́n má sọ fún ẹnikẹ́ni nípa ẹ̀, ohun tó sì sọ fáwọn òbí ọmọ náà nìyẹn. Àmọ́ torí pé wọn ò lè pa ayọ̀ náà mọ́ra, ṣe ni wọ́n tan ọ̀rọ̀ náà ká “gbogbo agbègbè yẹn.” (Mátíù 9:26) Tó bá jẹ́ pé ẹnì kan tó sún mọ́ ẹ ni Jésù jí dìde, ṣé wàá lè pa á mọ́ra? Àjíǹde kejì tí Jésù ṣe nìyí.