ORÍ 42
Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Ṣiṣẹ́
NÍNÚ kí o máa ṣiṣẹ́ tàbí kí o máa ṣeré, èwo lo fẹ́ràn jù lọ?— Ká sòótọ́, kò sí ohun tó burú nínú ká ṣeré. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa Jerúsálẹ́mù pé yóò “kún fún àwọn ọmọdékùnrin àti àwọn ọmọdébìnrin tí ń ṣeré ní àwọn ojúde rẹ̀.”—Sekaráyà 8:5.
Ó máa ń dùn mọ́ Olùkọ́ Ńlá náà láti máa wo àwọn ọmọdé bí wọ́n ti ń ṣeré. Kí ó tó wá sí orí ilẹ̀ ayé, ó sọ pé: ‘Mo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ [Ọlọ́run] gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́, tí mo ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ níwájú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà.’ Ṣàkíyèsí pé Jésù jẹ́ òṣìṣẹ́ lọ́dọ̀ Jèhófà ní ọ̀run. Nígbà tí ó ṣì wà lọ́hùn-ún, ó sọ pé: “Àwọn ohun tí mo sì ní ìfẹ́ni sí jẹ́ sípa àwọn ọmọ ènìyàn.” Dájúdájú, gẹ́gẹ́ bí a ṣe kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ṣáájú, Olùkọ́ Ńlá náà fẹ́ràn gbogbo èèyàn dáadáa, títí kan àwọn ọmọdé.—Òwe 8:30, 31.
Ǹjẹ́ o rò pé Jésù ṣeré nígbà tí ó wà lọ́mọdé?— Ó jọ pé ó ṣeré. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí òun ti jẹ́ “àgbà òṣìṣẹ́” nígbà tó wà ní ọ̀run, ǹjẹ́ ó ṣiṣẹ́ ní ayé pẹ̀lú?— Ó dára, ohun tí àwọn kan pe Jésù ní “ọmọkùnrin káfíńtà náà.” Àmọ́ wọ́n tún pè é ní “káfíńtà” pẹ̀lú. Kí ni èyí fi hàn?— Ó fi hàn pé ó ní láti jẹ́ pé Jósẹ́fù, tó tọ́ Jésù dàgbà gẹ́gẹ́ bí ọmọ, kọ́ Jésù níṣẹ́. Nítorí náà, Jésù alára di káfíńtà.—Mátíù 13:55; Máàkù 6:3.
Irú káfíńtà wo ni Jésù jẹ́?— Níwọ̀n bí òun ti jẹ́ àgbà òṣìṣẹ́ ní ọ̀run, ǹjẹ́ o kò rò pé yóò jẹ́ àgbà káfíńtà lórí ilẹ̀ ayé níhìn-ín pẹ̀lú?— Wo bí iṣẹ́ káfíńtà ṣe nira tó ní ayé ìgbà náà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jésù yóò ní láti wọnú igbó lọ láti gé igi lulẹ̀. Kí ó là á, kí ó wá ru apákó rẹ̀ wá sílé, kí ó sì wá fá a láti fi kan tábìlì, ìjókòó àti àwọn nǹkan mìíràn.
Ǹjẹ́ o rò pé iṣẹ́ yìí dùn mọ́ Jésù?— Ǹjẹ́ inú rẹ yóò dùn bí o bá lè ṣe àwọn tábìlì àti àga àti àwọn nǹkan dáradára mìíràn fún àwọn èèyàn láti máa lò?— Bíbélì sọ pé ó dára kí èèyàn “máa yọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” Iṣẹ́ ń fúnni ní ìdùnnú kan tí a kò lè rí látinú eré ṣíṣe.—Oníwàásù 3:22.
Ká sòótọ́ o, iṣẹ́ dára fún ọpọlọ wa àti ara wa. Ọ̀pọ̀ ọmọ ló máa ń jókòó tí wọ́n a máa wo tẹlifíṣọ̀n ṣáá tàbí kí wọ́n máa bá àwọn ọ̀rẹ́ wọn ṣeré. Wọ́n á wá sanra bọ̀kọ̀tọ̀, wọn ò ní lágbára, wọn ò sì ní fi bẹ́ẹ̀ láyọ̀. Inú àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú kì í dùn sí wọn. Kí ni ó yẹ kí á ṣe láti lè láyọ̀?—
A rí i kọ́ ní Orí 17 nínú ìwé yìí pé fífúnni ní nǹkan àti ṣíṣe nǹkan láti fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ máa ń múni láyọ̀. (Ìṣe 20:35) Bíbélì pe Jèhófà ní “Ọlọ́run aláyọ̀.” (1 Tímótì 1:11) Gẹ́gẹ́ bí a sì ṣe rí i kà nínú ìwé Òwe, ńṣe ni Jésù “ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ níwájú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà.” Kí ló ń mú inú Jésù dùn?— Ó sọ ọ̀kan nínú ohun tó fà á, nígbà tó sọ pé: “Baba mi ti ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyí, èmi náà sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́.”—Jòhánù 5:17.
Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, kò fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ ṣiṣẹ́ káfíńtà. Jèhófà Ọlọ́run ní iṣẹ́ àkànṣe kan tó fẹ́ kí ó ṣe ní ayé. Ǹjẹ́ o mọ iṣẹ́ náà?— Jésù sọ pé: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú ńlá mìíràn pẹ̀lú, nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.” (Lúùkù 4:43) Nígbà mìíràn, tí Jésù bá wàásù fún àwọn èèyàn, wọ́n máa ń gbà á gbọ́, wọ́n á sì tún sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa ohun tó bá wọn sọ, gẹ́gẹ́ bí obìnrin ará Samáríà tí o rí níbí yìí ti ṣe.— Jòhánù 4:7-15, 27-30.
Báwo ni iṣẹ́ yìí ṣe rí lára Jésù? Ǹjẹ́ o rò pé ó ń fẹ́ láti ṣe é?— Jésù sọ pé: “Oúnjẹ mi ni kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 4:34) Báwo ni oúnjẹ tí o fẹ́ràn jù lọ ṣe máa ń wù ọ́ jẹ tó?— Bẹ́ẹ̀ náà ni Jésù ṣe fẹ́ràn iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún un láti ṣe.
Ọlọ́run dá wa lọ́nà tó jẹ́ pé mímọ bí a ṣe ń ṣiṣẹ́ á máa mú wa láyọ̀. Ọlọ́run sọ pé ẹ̀bùn tí òun fún èèyàn ni pé kí ó “máa yọ̀ nínú iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.” Nítorí náà, tí o bá kọ́ bí a ti ń ṣiṣẹ́ nígbà ọmọdé, ìgbésí ayé rẹ yóò túbọ̀ lárinrin.—Oníwàásù 5:19.
Ìyẹn kò túmọ̀ sí pé ọmọdé kékeré lè ṣe iṣẹ́ àwọn àgbàlagbà o, ṣùgbọ́n gbogbo wa pátá ló lè ṣe iṣẹ́ kan tàbí òmíràn. Àwọn òbí rẹ lè máa lọ síbi iṣẹ́ lójoojúmọ́ láti lè rí owó tí ìdílé yín yóò fi jẹun àti ilé tí ẹ ó máa gbé. Ó sì ti yẹ kí o mọ̀ pé iṣẹ́ púpọ̀ wà láti ṣe nínú ilé, kí ó lè wà ní mímọ́ tónítóní.
Iṣẹ́ wo ló wà tí o lè ṣe tí yóò ṣàǹfààní fún gbogbo ìdílé yín?— O lè bá wọn gbé oúnjẹ sórí tábìlì, o lè fọ abọ́, o lè da ìdọ̀tí nù, o lè gbá ilẹ̀ ibi tí ò ń sùn, o sì lè pa àwọn ohun ìṣeré rẹ mọ́ kúrò nílẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí o tiẹ̀ ti máa ṣe díẹ̀ nínú nǹkan wọ̀nyí. Àwọn iṣẹ́ yẹn ń ṣe ìdílé láǹfààní gan-an ni.
Jẹ́ ká wo bí irú àwọn iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ṣe ṣàǹfààní. Ó yẹ kí o máa kó ohun ìṣeré kúrò nílẹ̀ tí o bá ti ṣeré tán. Kí nìdí tí o rò pé èyí fi ṣe pàtàkì?— Ó máa ń jẹ́ kí ilé wà ní mímọ́ tónítóní, kò sì ní jẹ́ kí jàǹbá ṣẹlẹ̀. Bí o kò bá kó àwọn ohun ìṣeré rẹ kúrò nílẹ̀, ìyá rẹ lè ti òde dé lọ́jọ́ kan, kí ẹrù pọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀, kí ó sì tẹ ọkàn lára ohun ìṣeré náà mọ́lẹ̀. Ó lè yọ̀ ṣubú kí ó sì fara pa. Wọ́n tiẹ̀ lè gbé e lọ sílé ìwòsàn. Ǹjẹ́ ìyẹn kò ní burú gan-an?— Nítorí náà, tí o bá kó ohun ìṣeré rẹ kúrò nílẹ̀ lẹ́yìn tí o bá ṣeré tán, gbogbo èèyàn ló máa ṣe láǹfààní.
Iṣẹ́ mìíràn tún wà fún àwọn ọmọdé láti ṣe. Bí àpẹẹrẹ, iṣẹ́ ilé ìwé. Ní ilé ìwé, ò ń kọ́ bí a ṣe ń kàwé. Àwọn ọmọ kan gbádùn ìwé kíkà, ṣùgbọ́n àwọn kan sọ pé ó nira. Kódà bí ó bá tiẹ̀ kọ́kọ́ dà bíi pé ó nira, inú rẹ yóò dùn bí o bá mọ ìwé kà dáadáa. Bí o bá ti mọ ìwé kà, ọ̀pọ̀ nǹkan alárinrin wà tí o máa lè mọ̀. Ìwọ yóò tiẹ̀ lè fúnra rẹ ka Bíbélì, tó jẹ́ ìwé Ọlọ́run fúnra rẹ̀. Nítorí náà, tí o bá ṣe iṣẹ́ ilé ìwé rẹ dáadáa, àǹfààní gidi ló jẹ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?—
Àwọn èèyàn kan wà tí wọn kì í fẹ́ ṣiṣẹ́. Bóyá o mọ ẹnì kan tó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ níwọ̀n bí Ọlọ́run ti dá wa láti máa ṣiṣẹ́, ó yẹ kí á kọ́ bí a ṣe lè gbádùn iṣẹ́ ṣíṣe. Báwo ni Olùkọ́ Ńlá náà ṣe gbádùn iṣẹ́ rẹ̀ tó?— Bí ìgbà tó bá ń jẹ oúnjẹ tó fẹ́ràn jù lọ ló ṣe máa ń rí lára rẹ̀. Iṣẹ́ wo ló sì ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?— Ìyẹn ni sísọ̀rọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run fún àwọn èèyàn, àti sísọ fún wọn nípa bí wọ́n ṣe lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.
Nítorí náà, ohun kan rèé tó lè mú ká gbádùn iṣẹ́ ṣíṣe. Bi ara rẹ léèrè, ‘Kí nìdí tí iṣẹ́ yìí fi yẹ ní ṣíṣe?’ Tí o bá ti mọ ìdí tí ohun kan fi ṣe pàtàkì, ó máa ń túbọ̀ rọrùn láti ṣe é. Yálà iṣẹ́ náà pọ̀ tàbí ó kéré, rí i pé o ṣe é dáadáa. Bí o bá ṣe é dáadáa, o lè rí ìdùnnú nínú iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, gẹ́gẹ́ bíi ti Olùkọ́ Ńlá wa.
Bíbélì lè ranni lọ́wọ́ láti di òṣìṣẹ́ dáadáa. Ka ohun tó sọ nínú Òwe 10:4; 22:29; Oníwàásù 3:12, 13; àti Kólósè 3:23.