Fi Ọwọ́ Pàtàkì Mú “Ohun Tí Ọlọ́run Ti So Pọ̀”
“Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” —MÁÀKÙ 10:9.
1, 2. Kí ni Hébérù 13:4 ń rọ̀ wá pé ká ṣe?
ṢÉ Ó máa ń wù ẹ́ láti bọlá fún Jèhófà? Kò sí àní-àní pé ó máa ń wù ẹ́! Jèhófà yẹ lẹ́ni tá à ń bọlá fún, ó sì ṣèlérí pé òun á bọlá fún ẹni tó bá ń bọlá fún òun. (1 Sám. 2:30; Òwe 3:9; Ìṣí. 4:11) Ó tún sọ pé ká máa bọlá fún àwọn aláṣẹ. (Róòmù 12:10; 13:7) Àmọ́ o, ohun míì wà tí Jèhófà fẹ́ ká máa bọlá fún tàbí ká fọwọ́ pàtàkì mú, ìyẹn ìgbéyàwó.
2 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó sì wà láìní ẹ̀gbin.” (Héb. 13:4) Kì í ṣe ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbéyàwó ni Pọ́ọ̀lù ń sọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n fọwọ́ pàtàkì mú ìgbéyàwó, kí wọ́n kà á sí ohun iyebíye. Ṣé ojú tíwọ náà fi ń wo ìgbéyàwó nìyẹn, pàápàá ìgbéyàwó rẹ tó bá jẹ́ pé o ti ṣègbéyàwó?
3. Ìmọ̀ràn pàtàkì wo ni Jésù fún wa lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
3 Tó o bá ka ìgbéyàwó sí ohun iyebíye, a jẹ́ pé o rẹ́ni fi jọ torí ojú tí Jésù náà fi wò ó nìyẹn. Nígbà táwọn Farisí béèrè lọ́wọ́ Jésù nípa ìkọ̀sílẹ̀, Jésù tọ́ka wọn sí ohun tí Ọlọ́run sọ nípa ìgbéyàwó àkọ́kọ́, pé: “Ní tìtorí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.” Jésù wá fi kún un pé: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.”—Ka Máàkù 10:2-12; Jẹ́n. 2:24.
4. Ìlànà wo ni Jèhófà fi lélẹ̀ nípa ìgbéyàwó?
4 Jésù tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kó ṣe kedere pé Ọlọ́run ló dá ìgbéyàwó sílẹ̀ àti pé kò fẹ́ káwọn tọkọtaya máa kọ ara wọn sílẹ̀. Ọlọ́run ò sọ fún Ádámù àti Éfà pé wọ́n lè fòpin sí ìgbéyàwó wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìlànà ọkọ kan aya kan ni Jèhófà fi lélẹ̀ nígbà tó so wọ́n pọ̀, ó sì fẹ́ kí “àwọn méjèèjì” wà pa pọ̀ títí lọ gbére.
NǸKAN YÍ PA DÀ FÚNGBÀ DÍẸ̀ NÍNÚ ÌGBÉYÀWÓ
5. Àkóbá wo ni ikú ń ṣe fún ìgbéyàwó?
5 Bí ẹ̀yin náà ṣe mọ̀, ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ló mú kí nǹkan yí pa dà. Bí àpẹẹrẹ, àtìgbà tọ́mọ aráyé ti ń kú ni ikú ti ń ṣàkóbá fún ìgbéyàwó. Èyí ṣe kedere nínú ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nígbà tó ń ṣàlàyé fún àwọn Kristẹni pé wọn ò sí lábẹ́ Òfin Mósè. Ó sọ fún wọn pé ikú ló máa ń fòpin sí ìgbéyàwó, tí ẹnì kejì á sì làǹfààní láti fẹ́ ẹlòmíì.—Róòmù 7:1-3.
6. Báwo ni Òfin Mósè ṣe jẹ́ ká mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo ìgbéyàwó?
6 Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe àlàyé kíkún nípa ìgbéyàwó. Ó fàyè gba àwọn tó ní ju ìyàwó kan lọ, ó ṣe tán àwọn èèyàn ti ń fẹ́ ju ìyàwó kan lọ kí Ọlọ́run tó fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin. Bó ti wù kó rí, ó fún irú àwọn bẹ́ẹ̀ lófin, ó pàṣẹ pé àwọn ọkọ ò gbọ́dọ̀ fìyà jẹ àwọn ìyàwó wọn. Bí àpẹẹrẹ, bí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá fẹ́ ẹrú kan níyàwó, tó sì tún wá fẹ́ obìnrin míì, kò gbọ́dọ̀ fi ẹ̀tọ́ ìyàwó àkọ́kọ́ dù ú, ó ṣì gbọ́dọ̀ máa pèsè ohun tó nílò fún un, bí oúnjẹ àti aṣọ. Kódà, Ọlọ́run sọ pé ó gbọ́dọ̀ máa dáàbò bò ó, kó sì máa fìfẹ́ hàn sí i. (Ẹ́kís. 21:9, 10) Àwa ò sí lábẹ́ Òfin Mósè, àmọ́ òfin yẹn jẹ́ ká rí i pé ojú pàtàkì ni Jèhófà fi ń wo ìgbéyàwó. Ǹjẹ́ kò yẹ káwa náà máa firú ojú yẹn wo ìgbéyàwó?
7, 8. (a) Kí ni Òfin Mósè sọ nípa ìkọ̀sílẹ̀ bó ṣe wà nínú Diutarónómì 24:1? (b) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ìkọ̀sílẹ̀?
7 Kí ni Òfin Mósè sọ nípa ìkọ̀sílẹ̀? Jèhófà kò yí ìlànà rẹ̀ pa dà lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó, àmọ́ fún ìdí kan, ó fàyè gba ìkọ̀sílẹ̀. (Ka Diutarónómì 24:1.) Òfin yẹn gbà pé ọmọ Ísírẹ́lì kan lè kọ ìyàwó ẹ̀ sílẹ̀ tó bá “rí ohun àìbójúmu kan níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” Òfin yẹn ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó pè ní “ohun àìbójúmu.” Ó ní láti jẹ́ ohun tó lè fa ìtìjú tàbí ohun tó burú gan-an, kì í ṣe àwọn ẹ̀sùn pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. (Diu. 23:14) Ó bani nínú jẹ́ pé nígbà ayé Jésù, ńṣe làwọn Júù ń kọ ìyàwó wọn sílẹ̀ lórí gbogbo ẹ̀sùn. (Mát. 19:3) Ó dájú pé àwa ò ní fẹ́ ṣe irú ẹ̀ láé.
8 Wòlíì Málákì jẹ́ ká mọ ojú tí Jèhófà fi wo ìkọ̀sílẹ̀. Lásìkò tó gbé láyé, ńṣe làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń hùwà àìṣòótọ́ sáwọn ‘aya ìgbà èwe wọn,’ tí wọ́n sì ń kọ̀ wọ́n sílẹ̀ bóyá torí àtifẹ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tí ò fi bẹ́ẹ̀ dàgbà. Málákì wá sọ ojú tí Ọlọ́run fi wo ìwà yẹn, ó sọ pé Ọlọ́run “kórìíra ìkọ̀sílẹ̀.” (Mál. 2:14-16) Ohun tó sọ yìí bá ohun tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì mu, níbi tí Jèhófà ti sọ pé: ‘Ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.’ (Jẹ́n. 2:24) Ojú kan náà ni Jésù fi wo ìgbéyàwó nígbà tóun náà sọ pé: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.”—Mát. 19:6.
ÌDÍ KAN ṢOṢO TÍ TỌKỌTAYA FI LÈ KỌ ARA WỌN SÍLẸ̀
9. Kí lọ̀rọ̀ Jésù nínú Máàkù 10:11, 12 túmọ̀ sí?
9 Ẹnì kan lè béèrè pé, ‘Ṣé ohun tá à ń sọ ni pé Kristẹni kan kò lè kọ ẹnì kejì rẹ̀ sílẹ̀ kó sì fẹ́ ẹlòmíì?’ Jésù sọ ojú tó fi wo ìkọ̀sílẹ̀ nígbà tó sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì gbé òmíràn níyàwó ṣe panṣágà lòdì sí i, bí obìnrin kan, lẹ́yìn kíkọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, bá sì ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú òmíràn pẹ́nrẹ́n, ó ṣe panṣágà.” (Máàkù 10:11, 12; Lúùkù 16:18) Ó ṣe kedere pé ojú pàtàkì ni Jésù fi wo ìgbéyàwó, irú ojú yìí kan náà ló sì fẹ́ káwọn míì fi wò ó. Tí ọkùnrin kan bá kọ ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́ sílẹ̀ (tàbí tí obìnrin kan bá kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ láìṣẹ̀ láìrò) torí ẹ̀sùn pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, tó wá lọ fẹ́ ẹlòmíì, àgbèrè ló ṣe. Òótọ́ sì lọ̀rọ̀ yìí, ti pé wọ́n kọ ara wọn sílẹ̀ kò fòpin sí ìgbéyàwó náà. Lójú Ọlọ́run, wọ́n ṣì jẹ́ “ara kan.” Bákan náà, Jésù sọ pé tí ọkùnrin kan bá kọ ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́ sílẹ̀, ó lè mú kí obìnrin náà ṣe àgbèrè. Lọ́nà wo? Láyé ìgbà yẹn, ó lè wu obìnrin kan tí wọ́n kọ̀ sílẹ̀ láti ní ọkọ míì torí àtirí owó gbọ́ bùkátà. Tírú obìnrin bẹ́ẹ̀ bá fẹ́ ọkọ míì, àgbèrè ló ṣe.
10. Kí ni ìdí kan ṣoṣo tí Kristẹni fi lè kọ ẹnì kejì rẹ̀ sílẹ̀, kó sì fẹ́ ẹlòmíì?
10 Jésù sọ ìdí kan ṣoṣo tó lè mú kí ẹnì kan kọ ẹnì kejì rẹ̀ sílẹ̀, ó ní: “Mo wí fún yín pé ẹnì yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, bí kò ṣe lórí ìpìlẹ̀ àgbèrè, [por·neiʹa lédè Gíríìkì] tí ó sì gbé òmíràn níyàwó, ṣe panṣágà.” (Mát. 19:9) Ó ti sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí rí nínú Ìwàásù Lórí Òkè. (Mát. 5:31, 32) Ìgbà méjèèjì ló mẹ́nu kan àgbèrè tàbí panṣágà. Ọ̀rọ̀ míì tá a lè lò ni ìṣekúṣe, onírúurú nǹkan lọ̀rọ̀ yìí sì túmọ̀ sí. Ó kan gbogbo ìbálòpọ̀ tí kì í ṣe láàárín ọkọ àti aya, bí àgbèrè, ṣíṣe aṣẹ́wó, ìbálòpọ̀ láàárín àwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó, ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ àti bíbá ẹranko lòpọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ọkùnrin kan ṣe ìṣekúṣe, ìyàwó rẹ̀ lè pinnu pé òun á kọ̀ ọ́ sílẹ̀ tàbí òun ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Tó bá kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, ìyẹn ti fòpin sí ìgbéyàwó wọn lójú Ọlọ́run nìyẹn.
11. Kí ló lè mú kí Kristẹni kan pinnu pé òun ò ní kọ ẹnì kejì òun sílẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìwé Mímọ́ fàyè gbà á láti ṣe bẹ́ẹ̀?
11 Àmọ́ ẹ kíyè sí i pé Jésù ò sọ pé tí ẹnì kan bá ṣe ìṣekúṣe (ìyẹn por·neiʹa), dandan ni kí ẹnì kejì rẹ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìyàwó lè pinnu pé òun ò ní fi ọkọ òun sílẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkọ náà ṣèṣekúṣe. Ó ṣì lè nífẹ̀ẹ́ ọkọ rẹ̀, ó lè pinnu láti dárí jì í kí wọ́n sì jọ sapá láti mú kí ìgbéyàwó wọn kẹ́sẹ járí. Òótọ́ kan ni pé, tó bá kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ tó sì wà láìlọ́kọ, ó máa ní àwọn ìṣòro kan. Lára ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ìṣúnná owó àti ìbálòpọ̀. Ó lè máa ṣe é bíi pé kò rẹ́ni fojú jọ. Ìṣòro àtibójú tó àwọn ọmọ ńkọ́? Ní báyìí tó ti fi ọkọ ẹ̀ sílẹ̀, ṣó máa rọrùn fún un láti tọ́ wọn dàgbà nínú òtítọ́? (1 Kọ́r. 7:14) Bí ìyàwó náà bá tiẹ̀ jẹ́ olóòótọ́, ó máa kojú àwọn ìṣòro kan tó bá pinnu láti kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.
12, 13. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ìgbéyàwó Hóséà? (b) Kí nìdí tí Hóséà fi gba Gómérì pa dà, kí la sì rí kọ́ tó bá kan ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó?
12 Ẹ̀kọ́ ńlá la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wòlíì Hóséà. Ọlọ́run sọ fún un pé kó fẹ́ Gómérì, ó sọ pé Gómérì máa jẹ́ oníṣekúṣe, ó sì máa ní àwọn ọmọ àlè. Ìgbà tó yá, Gómérì ‘lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún’ Hóséà. (Hós. 1:2, 3) Nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèṣekúṣe, ó sì bí ọmọbìnrin kan àti ọmọkùnrin kan fáwọn míì. Láìka iye ìgbà tí Gómérì ṣèṣekúṣe, Hóséà kò kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Níkẹyìn, Gómérì fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di ẹrú. Àmọ́ Hóséà lọ rà á pa dà. (Hós. 3:1, 2) Jèhófà fi ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Hóséà ṣàpẹẹrẹ bí Òun ṣe ń dárí ji àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn náà ń ṣàgbèrè nípa tẹ̀mí. Kí la rí kọ́ nínú àkọsílẹ̀ yìí?
13 Tí Kristẹni kan bá ṣèṣekúṣe, á di pé kí ẹnì kejì rẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́ ṣèpinnu. Jésù sọ pé ẹni tó jẹ́ olóòótọ́ lè pinnu pé òun á kọ̀ ọ́ sílẹ̀ kóun sì fẹ́ ẹlòmíì. Lọ́wọ́ kejì, ẹni náà lè pinnu pé òun á dárí jì í. Kò sí ohun tó burú ńbẹ̀. Ẹ rántí pé Hóséà gba Gómérì pa dà. Lẹ́yìn tí Gómérì pa dà sọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀, Hóséà sọ fún un pé kò gbọ́dọ̀ ní àjọṣe pẹ̀lú ọkùnrin míì mọ́. Hóséà alára kò sún mọ́ Gómérì fúngbà díẹ̀. (Hós. 3:3) Àmọ́ nígbà tó yá, ó dájú pé Hóséà bẹ̀rẹ̀ sí í ní àjọṣe pẹ̀lú rẹ̀. Ohun tó ṣe yẹn jẹ́ ká rí bí Jèhófà ṣe gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa dà tí wọ́n sì tún ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀. (Hós. 1:11; 3:3-5) Kí la rí kọ́ nínú ìtàn yìí tó bá dọ̀rọ̀ ìgbéyàwó? Tí Kristẹni kan tó jẹ́ olóòótọ́ bá pinnu pé òun ò ní fi ẹnì kejì òun sílẹ̀, tó sì ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ìyẹn ló máa fi hàn pé ó ti dárí jì í. (1 Kọ́r. 7:3, 5) Ìbálòpọ̀ tó wáyé láàárín wọn fi hàn pé kò tún ní lè kọ̀ ọ́ sílẹ̀ mọ́. Ohun tó kù ni pé káwọn méjèèjì wá bí wọ́n ṣe máa ṣera wọn lọ́kan, kí wọ́n sì máa fojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìgbéyàwó wò ó.
Ẹ MÁ ṢE JẸ́ KÍ ÌṢÒRO TÚ ÌGBÉYÀWÓ YÍN KÁ
14. Bó ṣe wà nínú 1 Kọ́ríńtì 7:10, 11, kí ló lè ṣẹlẹ̀ nínú ìgbéyàwó?
14 Àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ sapá ká lè máa fojú tí Jèhófà àti Jésù fi ń wo ìgbéyàwó wò ó. Àmọ́, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ torí àìpé tá a jogún. (Róòmù 7:18-23) Torí náà, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé àwọn Kristẹni kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní níṣòro nínú ìgbéyàwó wọn. Pọ́ọ̀lù sọ pé ‘kí aya má ṣe kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀.’ Síbẹ̀, ẹ̀rí fi hàn pé àwọn kan pínyà.—Ka 1 Kọ́ríńtì 7:10, 11.
15, 16. (a) Kí ló yẹ kó jẹ́ àfojúsùn àwọn tí ìgbéyàwó wọn níṣòro, kí sì nìdí? (b) Tí ọ̀kan nínú wọn bá jẹ́ aláìgbàgbọ́ ńkọ́?
15 Pọ́ọ̀lù ò sọ ohun tó mú kí wọ́n pínyà. Ó ṣe kedere pé kì í ṣe torí pé ọkọ kan ṣèṣekúṣe, èyí tó lè mú kí ìyàwó pinnu pé òun á kọ̀ ọ́ sílẹ̀, òun á sì fẹ́ ẹlòmíì. Pọ́ọ̀lù sọ pé kí aya kan tó ti pínyà pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ “wà láìlọ́kọ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kí ó parí aáwọ̀ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀.” Ìdí ni pé tọkọtaya ṣì làwọn méjèèjì lójú Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù gbà wọ́n níyànjú pé ìṣòro yòówù kí wọ́n ní, tí kò bá ti jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe, ṣe ni kí wọ́n yanjú ẹ̀. Àwọn méjèèjì lè tọ àwọn alàgbà lọ pé kí wọ́n ran àwọn lọ́wọ́. Àwọn alàgbà máa fún wọn nímọ̀ràn látinú Ìwé Mímọ́, láìsí pé wọ́n ń gbè sẹ́yìn ẹnì kankan nínú wọn.
16 Ìṣòro tún máa ń légbá kan nínú ìdílé tó bá jẹ́ pé ọkọ tàbí aya kan kò sin Jèhófà. Ká wá sọ pé ìṣòro yọjú, ṣé ohun tó kàn ni pé kí wọ́n pínyà? Bá a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ìṣekúṣe nìkan ni Bíbélì sọ pé ó lè mú kí tọkọtaya kọ ara wọn sílẹ̀, àmọ́ kò sọ onírúurú nǹkan tó lè fa ìpínyà. Pọ́ọ̀lù sọ pé: ‘Tí obìnrin kan bá ní ọkọ tí kò gbà gbọ́, síbẹ̀ tí ọkùnrin náà fara mọ́ bíbá a gbé, kí ó má fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.’ (1 Kọ́r. 7:12, 13) Ìlànà yìí kan náà là ń tẹ̀ lé lónìí.
17, 18. Kí nìdí táwọn Kristẹni kan fi pinnu pé àwọn ò ní fi ẹnì kejì wọn sílẹ̀ bí wọ́n tiẹ̀ láwọn ìṣòro kan?
17 Síbẹ̀, àwọn ipò kan wà tó jẹ́ pé “ọkọ tí kò gbà gbọ́” lè máa ṣe àwọn ohun tó fi hàn pé kò ṣeé bá gbé. Ó lè máa lu ìyàwó rẹ̀ nílùkulù débi tí ìyàwó náà fi gbà pé ọkọ òun lè ṣe òun léṣe tàbí kó gbẹ̀mí òun. Ó lè kọ̀ láti pèsè fún ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọ tàbí kó mú kó ṣòro fún un gan-an láti sin Jèhófà. Nírú àwọn ipò yìí, àwọn Kristẹni kan ti pinnu pé àwọn á pínyà, wọ́n gbà pé onítọ̀hún kò ṣeé bá gbé láìka ohun yòówù kó sọ. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, a ráwọn Kristẹni míì tí wọ́n níṣòro tó le gan-an, síbẹ̀ tí wọ́n ń fara dà á, tí wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí ìgbéyàwó wọn má bàa dà rú. Kí nìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀?
18 Bí àwọn méjèèjì bá tiẹ̀ pínyà, tọkọtaya ni wọ́n ṣì jẹ́. Ohun kan ni pé tí wọ́n bá ń gbé lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n máa ní àwọn ìṣòro kan bá a ṣe sọ ṣáájú. Bó ti wù kó rí, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ìdí míì tó fi dáa káwọn méjèèjì wà pa pọ̀, nígbà tó sọ pé: “Ọkọ tí kò gbà gbọ́ ni a sọ di mímọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú aya rẹ̀, aya tí kò sì gbà gbọ́ ni a sọ di mímọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú arákùnrin náà; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwọn ọmọ yín ì bá jẹ́ aláìmọ́ ní ti gidi, ṣùgbọ́n nísinsìnyí wọ́n jẹ́ mímọ́.” (1 Kọ́r. 7:14) Ọ̀pọ̀ Kristẹni ló pinnu pé àwọn ò ní fi ẹnì kejì wọn tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ sílẹ̀ láìka àwọn ìṣòro tó lágbára tí wọ́n ní sí. Wọ́n gbà pé ìfaradà àwọn lérè gan-an, pàápàá nígbà tí ẹnì kejì náà di onígbàgbọ́ bíi tiwọn.—Ka 1 Kọ́ríńtì 7:16; 1 Pét. 3:1, 2.
19. Kí nìdí tá a fi ní ọ̀pọ̀ tọkọtaya tó ṣera wọn lọ́kan láàárín àwa èèyàn Jèhófà?
19 Jésù jẹ́ ká túbọ̀ lóye ojú tí Jèhófà fi ń wo ìkọ̀sílẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà sì sọ ojú tí Jèhófà fi ń wo ìpínyà. Ó ṣe kedere pé àwọn méjèèjì fẹ́ káwa ìránṣẹ́ Jèhófà fọwọ́ pàtàkì mú ìgbéyàwó. Kárí ayé, pàápàá nínú ìjọ àwa èèyàn Jèhófà, ọ̀pọ̀ tọkọtaya ló ṣe ara wọn lọ́kan. Kò sí àní-àní pé àwọn tọkọtaya bẹ́ẹ̀ wà ní ìjọ yín. Àpẹẹrẹ àtàtà làwọn tọkọtaya yìí jẹ́ torí pé àwọn ọkọ nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn dénú, bẹ́ẹ̀ sì làwọn aya ń bọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún àwọn ọkọ wọn. Wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé àwọn fọwọ́ pàtàkì mú ìgbéyàwó àwọn. Inú wa dùn pé ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ará wa yìí ń fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ Bíbélì tó sọ pé: “Fún ìdí yìí, ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.”—Éfé. 5:31, 33.