Ìbéèrè Látọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
• Báwo la ṣe lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, nígbà tí kì í ṣe ẹni gidi kan?
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe máa kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run.” (Éfésù 4:30) Àwọn kan rò pé gbólóhùn yìí fi hàn pé ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ ẹni gidi kan. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ìwé “olóòótọ́ ìríjú náà” ti fi ẹ̀rí tó dájú hàn látinú Ìwé Mímọ́ àti látinú ohun tí ìtàn sọ pé àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní kò gbà pé ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ ẹni gidi kan. Bákan náà, wọn kò wò ó pé ó jẹ́ ọlọ́run kan tó bá Ẹni Gíga Jù Lọ dọ́gba, gẹ́gẹ́ bí apá kan ohun tí àwọn èèyàn ń pè ní Mẹ́talọ́kan.a (Lúùkù 12:42) Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù kò sọ pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run jẹ́ ẹni gidi kan.
Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ni ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀ tí kò ṣeé fojú rí. (Jẹ́nẹ́sísì 1:2) A sọ tẹ́lẹ̀ pé Jésù yóò “fi ẹ̀mí mímọ́” batisí àwọn èèyàn, gẹ́gẹ́ bí Jòhánù ṣe ń fomi batisí àwọn èèyàn. (Lúùkù 3:16) Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, nǹkan bí ọgọ́fà ọmọ ẹ̀yìn “kún fún ẹ̀mí mímọ́.” Ó dájú pé wọn ò lè kún fún ẹni gidi kan. (Ìṣe 1:5, 8; 2:4, 33) Àwọn ẹni àmì òróró wọ̀nyí ní ìrètí láti lọ sí ọ̀run, ẹ̀mí Ọlọ́run sì ń darí wọn láti jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ìgbésí ayé wọn. (Róòmù 8:14-17; 2 Kọ́ríńtì 1:22) Ẹ̀mí náà jẹ́ kí wọ́n lè máa so èso tí Ọlọ́run fẹ́, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yẹra fún “àwọn iṣẹ́ ti ara” tó jẹ́ iṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, èyí tó lè fa ìbínú Ọlọ́run.—Gálátíà 5:19-25.
Bí a bá jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó nírètí láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé, á jẹ́ pé a kò fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wá nìyẹn. Síbẹ̀, a lè ní ẹ̀mí Ọlọ́run bíi ti àwọn tó ń lọ sí ọ̀run. Nítorí náà, àwa náà lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́. Àmọ́, báwo lèyí ṣe lè ṣẹlẹ̀?
Bí a kò bá kọbi ara sí ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́, tí a kọ lábẹ́ ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí mímọ́, a lè máa hu àwọn ìwà tó lè yọrí sí mímọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́, rírí ìbínú Jèhófà àti ìparun lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. (Mátíù 12:31, 32) Ó lè jẹ́ pé a ò tíì máa dá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo báyìí, àmọ́ a lè ti bẹ̀rẹ̀ sí rìn ní ọ̀nà búburú, èyí tó lè mú ká ṣe ohun tó lòdì sí ìdarí ẹ̀mí mímọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Bá a bá ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́.
Nígbà náà, kí la lè ṣe tá ò fi ní máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ̀mí Ọlọ́run? Dájúdájú, a ní láti ṣàkóso èrò ọkàn wa àti ìwà wa. Ní orí kẹrin lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Éfésù, ó sọ pé ó yẹ ká yẹra fún àwọn àṣà burúkú, irú bí irọ́ pípa, bíbínú rangbandan, ìwà ọ̀lẹ àti sísọ ọ̀rọ̀ tí kò dára. Bá a bá ti gbé “àkópọ̀ ìwà titun” wọ̀, síbẹ̀ tá a ṣì tún ń padà hu irú àwọn ìwà burúkú bẹ́ẹ̀, kí là ń ṣe yẹn? Ńṣe là ń tàpá sí ìmọ̀ràn Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ mí sí. Bá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́.
Nínú Éfésù orí karùn-ún, Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú pé ká yẹra fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó ń múni ṣàgbèrè. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn tí wọ́n jọ jẹ onígbàgbọ́ pé kí wọ́n yẹra fún ìwà tí ń tini lójú àti fífi ọ̀rọ̀ rírùn ṣàwàdà. Bí a kò bá fẹ́ kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, ó yẹ ká máa rántí ìmọ̀ràn yìí nígbà tá a bá fẹ́ ṣe eré ìnàjú. Kí nìdí tá a ó fi máa nífẹ̀ẹ́ sí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ nípa fífi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ sọ, kíkàwé nípa wọn, àti wíwò wọ́n lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí lọ́nà mìíràn?
Ká sòótọ́, àwọn ọ̀nà mìíràn wà tá a lè gbà kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́. Ẹ̀mí Jèhófà ló ń mú kí ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ, àmọ́ tó bá jẹ́ pé ńṣe là ń ṣe òfófó tó lè pani lára tàbí à ń dá ẹgbẹ́ sílẹ̀ nínú ìjọ ńkọ́? Ǹjẹ́ kì í ṣe pé à ń tàpá sí ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí mímọ́ tó ní ká wà ní ìṣọ̀kan nìyẹn? Láìsí tàbí ṣùgbọ́n, ńṣe la óò máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́, bíi ti àwọn tó fa ìyapa nínú ìjọ Kọ́ríńtì. (1 Kọ́ríńtì 1:10; 3:1-4, 16, 17) Síwájú sí i, a óò máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ bá a bá mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìbọ̀wọ̀ fún àwọn tí a fi ẹ̀mí mímọ́ yàn sípò nínú ìjọ.—Ìṣe 20:28; Júúdà 8.
Nígbà náà, ó yẹ ká máa bi ara wa bóyá ìwà àti ìṣe wa wà ní ìbámu pẹ̀lú bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí a ti rí ẹ̀rí rẹ̀ nínú Bíbélì àti nínú ìjọ Kristẹni. Ẹ jẹ́ ká tún máa ‘gbàdúrà pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́,’ ká jẹ́ kó máa darí wa, ká sì máa hùwà tó bá Ọ̀rọ̀ onímìísí Ọlọ́run mu. (Júúdà 20) Ẹ jẹ́ ká pinnu pé a ò ní kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, a óò jẹ́ kó máa darí wa ká lè bọlá fún orúkọ mímọ́ Jèhófà.
• Jésù Kristi fi bó ṣe máa ṣòro tó fún ọlọ́rọ̀ láti wọ Ìjọba Ọlọ́run wé bó ṣe ṣòro fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá. Ṣé ràkúnmí gidi àti abẹ́rẹ́ ìránṣọ ni Jésù ní lọ́kàn?
Méjì lára àkọsílẹ̀ mẹ́ta tó wà nínú Ìwé Mímọ́ nípa ọ̀rọ̀ yìí jọra wọn gan-an. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ Mátíù ti sọ, Jésù sọ pé: “Ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá jù fún ọlọ́rọ̀ láti dé inú ìjọba Ọlọ́run.” (Mátíù 19:24) Lọ́nà kan náà, Máàkù 10:25 kà pé: “Ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run.”
Àwọn ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú wọn sọ pé “ojú abẹ́rẹ́” náà jẹ́ ẹnubodè kékeré kan tó wà lára àwọn ẹnubodè ńlá ìlú Jerúsálẹ́mù. Bí wọ́n bá ti ẹnubodè ńlá ní òru, wọ́n lè ṣí kékeré sílẹ̀. Wọ́n sọ pé ràkúnmí lè gba ibẹ̀ kọjá. Ǹjẹ́ ohun tí Jésù ní lọ́kàn nìyí?
Ó hàn gbangba pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Ó ṣe kedere pé abẹ́rẹ́ ìránṣọ ni Jésù ń sọ. Níwọ̀n bí àwọn olùṣèwádìí ti ṣàwárí àwọn abẹ́rẹ́ tí wọ́n fi egungun àti irin ṣe ní àgbègbè Jerúsálẹ́mù, ó dájú pé wọ́n jẹ́ àwọn ohun èlò tí àwọn èèyàn sábà máa ń lò nínú ilé. Lúùkù 18:25 mú iyèméjì kúrò nípa ohun tí ọ̀rọ̀ Jésù jẹ́ gan-an, nítorí ó fa ọ̀rọ̀ Jésù yọ pé: “Ní ti tòótọ́, ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ ìránṣọ kọjá jù fún ọlọ́rọ̀ láti dé inú ìjọba Ọlọ́run.”
Ọ̀pọ̀ àwọn atúmọ̀ èdè ló gbà pé ọ̀rọ̀ náà, “abẹ́rẹ́ ìránṣọ” tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tọ̀nà. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò fún ‘abẹ́rẹ́’ nínú Mátíù 19:24 àti Máàkù 10:25 (rha·phisʹ) wá látinú ọ̀rọ̀ ìṣe kan tó túmọ̀ sí “rán.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n sì lò nínú Lúùkù 18:25 (be·loʹne) tọ́ka sí abẹ́rẹ́ tí àwọn oníṣẹ́ abẹ máa ń lò. Ìwé náà Vine’s Expository Dictionary of Old and New Testament Words sọ pé: “Ó dà bíi pé láyé òde òní làwọn èèyàn ní èrò pé ‘ojú abẹ́rẹ́’ túmọ̀ sí ẹnubodè kékeré; kò sí ẹ̀rí èyíkéyìí tó fi hàn pé wọ́n gbà bẹ́ẹ̀ láyé àtijọ́. Kókó tí Jésù ní lọ́kàn nínú ọ̀rọ̀ tó sọ ni pé àwọn ohun kan ò ṣeé ṣe fún ẹ̀dá èèyàn. Nítorí náà, kò yẹ kí a rọ gbólóhùn yìí lójú nípa sísọ pé ohun mìíràn ni abẹ́rẹ́ náà túmọ̀ sí, pé kì í ṣe abẹ́rẹ́ gan-gan.”—1981, Apá 3, ojú ìwé 106.
Àwọn kan sọ pé nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí, “okùn” ló yẹ kí wọ́n pe “ràkúnmí.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò fún okùn (kaʹmi·los) àti ràkúnmí (kaʹme·los) jọra. Àmọ́ o, àwọn ìwé àfọwọ́kọ èdè Gíríìkì ti Ìhìn Rere Mátíù tó tíì pẹ́ jù lọ (ìyẹn Sinaitic, Vatican No. 1209, àti Alexandrine) fi hàn pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì fún “ràkúnmí” ni wọ́n lò nínú Mátíù 19:24 kì í ṣe ọ̀rọ̀ tó wà fún “okùn.” Ìtàn fi hàn pé Mátíù kọ́kọ́ kọ Ìhìn Rere rẹ̀ lédè Hébérù, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun fúnra rẹ̀ ló tú u sí èdè Gíríìkì. Ó mọ ohun náà gan-an tí Jésù sọ, ó sì lo ọ̀rọ̀ tó yẹ láti fi gbé èrò yìí yọ.
Nítorí náà, abẹ́rẹ́ ìránṣọ àti ràkúnmí gan-gan ni Jésù ní lọ́kàn. Ńṣe ni ó lo àwọn nǹkan yìí láti fi tẹnu mọ́ ọn pé àwọn ohun kan wà tí ò ṣeé ṣe. Àmọ́, ṣé ohun tí Jésù ní lọ́kàn ni pé kò sí ọlọ́rọ̀ èyíkéyìí tó lè dénú Ìjọba Ọlọ́run? Rárá o, nítorí pé ọ̀rọ̀ Jésù kì í ṣe ohun tó yẹ ká lóye lóréfèé bẹ́ẹ̀. Ńṣe ni ó lo àbùmọ́ láti fi ṣe àkàwé pé bí kò ti ṣeé ṣe fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá, bẹ́ẹ̀ náà ni kò lè ṣeé ṣe fún ọlọ́rọ̀ èyíkéyìí láti wọ Ìjọba Ọlọ́run bó bá jẹ́ pé ọrọ̀ rẹ̀ ló gbọ́kàn lé tí kò sì fi Jèhófà sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ̀.—Lúùkù 13:24; 1 Tímótì 6:17-19.
Jésù sọ gbólóhùn yìí kété lẹ́yìn tí ọ̀dọ́kùnrin olùṣàkóso kan tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ kọ àǹfààní ńlá kan tí Jésù fún un láti di ọmọ ẹ̀yìn òun. (Lúùkù 18:18-24) Ọlọ́rọ̀ tó bá nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ohun ìní rẹ̀ ju àwọn nǹkan tẹ̀mí lọ kò gbọ́dọ̀ retí pé òun á ní ìyè àìnípẹ̀kun lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Síbẹ̀, àwọn ọlọ́rọ̀ kan di ọmọlẹ́yìn Jésù. (Mátíù 27:57; Lúùkù 19:2, 9) Nítorí náà, ọlọ́rọ̀ èyíkéyìí tí àwọn nǹkan tẹ̀mí bá jẹ lọ́kàn, tó sì ń wá ìrànwọ́ Ọlọ́run lè rí ìgbàlà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.—Mátíù 5:3; 19:16-26.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìwé pẹlẹbẹ náà, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí? tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.