Igbesi-aye ati Iṣẹ-ojiṣẹ Jesu
“Dájúdájú Ọmọkunrin Ọlọrun ni Eyi”
JESU ko tii pẹ lori opo-igi nigba ti, ni ọjọ́kanrí, abàmì okunkun oni wakati mẹta kan ṣú. Kii ṣe nitori imuṣokunkun oṣupa niwọnbi eyi ti maa nwaye kiki ni akoko oṣupa titun, oṣupa si ti yọ jade tan lakooko Irekọja. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìmúṣókùnkùn oṣupa kii pẹ ju iwọnba iṣẹju diẹ lọ. Nitori naa okunkun naa ní ipilẹṣẹ atọrunwa! O ṣeeṣe ki o mu ki isinmi ẹnu diẹ wa fun awọn wọnni ti nfi Jesu ṣẹlẹya, ani ki o tilẹ dá ipẹgan wọn duro.
Bí àrà meriyiiri akojinnijinni bani naa ba ṣẹlẹ ṣaaju ki oluṣe buburu naa tó ba ẹlẹgbẹ rẹ wi ti o si bẹ Jesu lati ranti oun, o le jẹ koko abajọ fun ironupiwada rẹ. O ṣeeṣe ki o jẹ pe laaarin okunkun naa ni awọn obinrin mẹrin, ti wọn jẹ, iya Jesu ati Salome arabinrin rẹ, Maria Magidaleni, ati Maria iya apọsteli Jakọbu Kekere ti wa ọna de ìtòsí opo-igi idaloro naa. Johanu, apọsteli aayo-olufẹ Jesu, wà pẹlu wọn nibẹ.
Bawo ni ọkan iya Jesu ti ‘gbọgbẹ́’ tó bi oun ti nwo ọmọkunrin rẹ ti oun tọ ti oun si bọ́ dagba ti a gbe kọ́ ninu irora! Sibẹ, Jesu ko ronu nipa irora tirẹ funraarẹ, ṣugbọn nipa ipo alaafia iya rẹ. Pẹlu isapa nlanla, o mi ori si Johanu o si wi fun iya rẹ pe: “Ìyá, wòó! Ọmọkunrin rẹ!” Lẹhin naa ni mimi ori siha-ọdọ Maria, o wi fun Johanu pe: “Wòó! Iya rẹ!”
Jesu tipa bayi gbe itọju iya rẹ, ẹni ti o jẹ opó lọna ti o han gbangba nisinsinyi le apọsteli rẹ ti oun nifẹẹ lọna akanṣe lọwọ. Oun ṣe eyi nitori pe awọn ọmọkunrin Maria miiran ko tii fi igbagbọ ninu rẹ han sibẹ. Oun tipa bayii fi apẹẹrẹ rere lelẹ ti ṣiṣe ipese kii ṣe kiki fun aini iya rẹ̀ nipa ti ara nikan ṣugbọn fun aini tẹmi rẹ̀ pẹlu.
Ni nnkan bi agogo mẹta ọsan, Jesu wipe: “Orungbẹ ngbẹ mi.” Lẹhin naa, pẹlu imọlara pe Baba rẹ ti, fa ọwọ́ aabo sẹhin kuro lọdọ rẹ̀, bii pe o ri bẹẹ nitootọ, ki a ba le dán iwatitọ rẹ̀ wò de gongo, oun ke jade pẹlu ohùn rara pe: “Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, eeṣe ti iwọ fi kọ mi silẹ?” Ni gbigbọ eyi awọn kan ti wọn duro nitosi kigbe soke pe: “Wòó! oun npe Elija.” Lọ́gán ọkan ninu wọn sare ati, ni mimu kàn-ìnkàn-ìn ti a ti rì bọnu ọti kikan si apa òkè ọpa hisopu kan, o fun un ni ohun mimu. Ṣugbọn awọn miiran wipe: “Ẹ jẹ ki o ku! Ẹ jẹ ki a ri boya Elija yoo wa lati sọ ọ kalẹ.”
Nigba ti Jesu gba ọti kikan naa, o kigbe jade pe: “O pari!” Bẹẹni, oun ti pari ohun gbogbo ti Baba rẹ ti ran an wa si ilẹ-aye lati ṣe. Nikẹhin, oun wipe: “Baba, ni ọwọ rẹ ni mo fi ẹmi mi le.” Jesu tipa bayi fi ipá iwalaaye rẹ̀ le Ọlọrun lọwọ pẹlu igbọkanle pe Ọlọrun yoo mú un pada bọsipo fun oun lẹẹkan sii. Lẹhin naa o tẹri ara rẹ ba o si ku.
Lakooko ti Jesu mi èémí rẹ ikẹhin, isẹlẹ buburu kan waye, ti o ṣi awọn apata ràbàtàràbàtà silẹ. Isẹlẹ naa lagbara tobẹẹ gẹẹ ti awọn iboji iranti lẹhin ode Jerusalẹmu fi fọ sita, ara awọn oku ni a si gbe sọ sita kuro ninu wọn. Awọn ti nkọja lọ, ti wọn ri awọn ara oku naa ti o wà ni gbangba, wọ inu ilu lọ wọn si rohin rẹ̀.
Siwaju sii pẹlu, ni akoko ti Jesu ku, ìkélé fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ ti o pin ibi Mimọ kuro lara ibi Mimọ Julọ ninu tẹmpili Ọlọrun ni o faya si meji, lati oke delẹ. Yoo fẹrẹẹ jẹ pe, ìkélé ti a ṣe lọṣọọ daradara yi jẹ nnkan bi ẹsẹ bata 60 lóòró o si wuwo gan-an! Kii ṣe kìkì pe àgbàyanu Iṣẹ-iyanu naa fi ibinu Ọlọrun han lodisi awọn ti o pa Ọmọkunrin Rẹ nikan ni, ṣugbọn o fihan pe wiwọle sinu ibi Mimọ Julọ naa, ọrun funraarẹ, ni a mu ki o ṣeeṣe nisinsinyi nipasẹ iku Jesu.
O dara, nigba ti awọn eniyan nimọlara isẹlẹ naa ti wọn si ri ohun ti nṣẹlẹ, ẹru ba wọn gidigidi. Ijoye-oṣiṣẹ ti o wa nidii ifiya-iku-jẹni naa fi ogo fun Ọlọrun. “Dajudaju Ọmọkunrin Ọlọrun ni eyi,” ni oun polongo. O ṣeeṣe ki oun ti wa nibẹ nigba ti a jiroro jijẹ ọmọkunrin atọrunwa naa nibi igbẹjọ Jesu niwaju Pilatu. Nisinsinyi oun ni idaniloju pe Jesu ni Ọmọkunrin Ọlọrun, bẹẹni, pe oun nitootọ ni ọkunrin titobi julọ naa ti o tíì gbe laye ri.
Awọn miiran pẹlu ni a jáláyà nipasẹ awọn iṣẹlẹ agbayanu wọnyi, wọn si bẹrẹ sí í pada si ile wọn ni lílu àyà wọn, gẹgẹ bi ifaraṣapejuwe ìbànújẹ́ ati ìtìjú mímúná. Ọpọlọpọ awọn obinrin ti wọn jẹ ọmọ-ẹhin Jesu ti a sun lọna jijinlẹ nipa awọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì wọnyi ni wọn nkiyesi iran apewo yii lati ọ̀kánkán. Apọsteli Johanu wà nibẹ pẹlu. Matiu 27:45-56, NW; Maaku 15:33-41; Luuku 23:44-49; 2:34, 35; Johanu 19:25-30.
◆ Eeṣe ti ìmúṣókùnkùn òṣùpá ko fi lè jẹ́ idi fun òkùnkùn oni wákàtí mẹta naa?
◆ Ní kete ṣaájú ikú rẹ̀, apẹẹrẹ rere wo ni Jesu pèsè fun awọn wọnni ti wọ́n ní awọn obi ọlọ́jọ́lórí?
◆ Ki ni gbólóhùn-ọ̀rọ̀ mẹrin ikẹhin ti Jesu sọ ṣaaju ki oun to ku?
◆ Ki ni ìsẹ̀lẹ̀ naa ṣàṣeparí rẹ̀, ki si ni ìjẹ́pàtàkì ìkélé tẹmpili ti o fàya si meji?
◆ Bawo ni awọn isẹlẹ-iyanu naa ṣe nípalórí ìjòyè òṣìṣẹ́ ologun ti o wa nidii ìfìyà-ikú-jẹni?