“Ọjọ́ Ńlá Jèhófà Sún Mọ́lé”
“Ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé. Ó sún mọ́lé, ìyára kánkán rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.” —SEFANÁYÀ 1:14.
1, 2. (a) Ọjọ́ pàtàkì wo làwa Kristẹni ń retí? (b) Ìbéèrè wo ló yẹ ká béèrè, kí sì nìdí?
Ọ̀DỌ́BÌNRIN kan ń yọ̀ ṣìnkìn bó ṣe ń fi tọkàntara retí ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀. Inú aláboyún kan ń dùn bó ṣe ń wọ̀nà fún ọjọ́ tó máa bímọ. Òṣìṣẹ́ kan tó ti ṣiṣẹ́ ṣiṣẹ́ ń yọ̀ bó ṣe ń wọ̀nà fún ìgbà tí ìsinmi tó ti ń retí tipẹ́ máa bẹ̀rẹ̀. Kí lọ̀rọ̀ àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí fi jọra? Ohun tọ́rọ̀ wọn fi jọra ni pé gbogbo wọn ló ń retí ọjọ́ pàtàkì kan tó máa nípa lórí ìgbésí ayé wọn. Gbogbo wọn ni inú wọn ń dùn gan-an, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló fa ayọ̀ wọn. Ó pẹ́ ó yá, ọjọ́ tí wọ́n ń retí á dé, wọn ò sì fẹ́ kó bá àwọn láìmúrasílẹ̀.
2 Bíi tàwọn tá a mẹ́nu kàn yìí, àwa Kristẹni tòótọ́ lónìí ń retí ọjọ́ pàtàkì kan lójú méjèèjì. Ọjọ́ wo nìyẹn? ‘Ọjọ́ ńlá Jèhófà’ ni. (Aísáyà 13:9; Jóẹ́lì 2:1; 2 Pétérù 3:12) Kí ni “ọjọ́ Jèhófà” tó ń bọ̀ yìí, ipa wo sì ni dídé rẹ̀ máa ní lórí aráyé? Báwo la ṣe lè rí i dájú pé a múra sílẹ̀ dè é? Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí nísinsìnyí nítorí ẹ̀rí fi hàn pé òótọ́ pọ́ńbélé lohun tí Bíbélì sọ pé: “Ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé. Ó sún mọ́lé, ìyára kánkán rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.”—Sefanáyà 1:14.
“Ọjọ́ Ńlá Jèhófà”
3. Kí ni “ọjọ́ ńlá Jèhófà”?
3 Kí ni “ọjọ́ ńlá Jèhófà”? Ní gbogbo ibi tí Bíbélì ti mẹ́nu kan gbólóhùn náà “ọjọ́ Jèhófà,” ohun tó tọ́ka sí ni àwọn àkókò pàtàkì tí Jèhófà mú ìdájọ́ rẹ̀ wá sórí àwọn ọ̀tá rẹ̀ tó sì mú ògo bá orúkọ ńlá rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, “ọjọ́ Jèhófà” dé bá àwọn èèyàn Júdà àti Jerúsálẹ́mù tó di aláìṣòótọ́, ó dé bá àwọn ará Bábílónì tí wọ́n ń ni àwọn ẹlòmíì lára àtàwọn èèyàn Íjíbítì. Ọjọ́ náà dé bá wọn nígbà tí Jèhófà mú ìdájọ́ rẹ̀ wá sórí wọn, tó pa wọ́n run. (Aísáyà 2:1, 10-12; 13:1-6; Jeremáyà 46:7-10) Àmọ́ ṣá o, “ọjọ́ Jèhófà” tó tóbi jù lọ ṣì ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ó jẹ́ “ọjọ́” tí Jèhófà yóò pa àwọn tó ń kó ẹ̀gàn bá orúkọ rẹ̀ run. Ohun tó máa bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ yẹn ni ìparun “Bábílónì Ńlá,” ìyẹn gbogbo ìsìn èké àgbáyé lápapọ̀, ohun tó sì máa parí rẹ̀ ni ìparun apá tó kù nínú ètò àwọn nǹkan búburú yìí ní ogun Amágẹ́dọ́nì.—Ìṣípayá 16:14, 16; 17:5, 15-17; 19:11-21.
4. Kí nìdí tó fi yẹ kí èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ọmọ aráyé máa bẹ̀rù ọjọ́ Jèhófà tó ń yára sún mọ́lé?
4 Ọjọ́ tó yẹ kí ọ̀pọ̀ jù lọ aráyé máa bẹ̀rù ni ọjọ́ Jèhófà tó ń yára sún mọ́lé yìí yálà wọ́n mọ̀ bẹ́ẹ̀ tàbí wọn ò mọ̀. Kí nìdí? Jèhófà gbẹnu wòlíì Sefanáyà sọ ìdí rẹ̀ fún wa, ó ní: “Ọjọ́ yẹn jẹ́ ọjọ́ ìbínú kíkan, ọjọ́ wàhálà àti làásìgbò, ọjọ́ ìjì àti ìsọdahoro, ọjọ́ òkùnkùn àti ìṣúdùdù, ọjọ́ àwọsánmà àti ìṣúdùdù tí ó nípọn.” Ẹ ò rí i pé ọjọ́ ẹ̀rù ni lóòótọ́! Jèhófà tún tipasẹ̀ wòlíì náà fi kún un pé: ‘Dájúdájú, èmi yóò fa wàhálà bá aráyé nítorí pé Jèhófà ni wọ́n ti ṣẹ̀ sí.’—Sefanáyà 1:15, 17.
5. Kí nìdí tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn fi ń fayọ̀ retí ọjọ́ Jèhófà?
5 Àmọ́ tàwọn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn kan yàtọ̀ o. Ńṣe làwọn ń fayọ̀ retí pé kí ọjọ́ Jèhófà dé. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n mọ̀ pé ọjọ́ náà jẹ́ àkókò ìgbàlà àti ìdáǹdè fáwọn olódodo, ọjọ́ tí a óò gbé Jèhófà ga tí a ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ológo di mímọ́. (Jóẹ́lì 3:16, 17; Sefanáyà 3:12-17) Ohun tẹ́nì kan bá ń fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe nísinsìnyí ló máa pinnu bóyá ńṣe lá máa bẹ̀rù ọjọ́ Jèhófà tàbí á máa fayọ̀ retí rẹ̀. Kí ni èrò rẹ nípa ọjọ́ Jèhófà tó sún mọ́lé yìí? Ǹjẹ́ o ti múra sílẹ̀ fún un? Ǹjẹ́ bí ọjọ́ Jèhófà ṣe sún mọ́lé yìí ń nípa lórí ọ̀nà tó o gbà ń gbé ìgbé ayé rẹ lójoojúmọ́?
“Àwọn Olùyọṣùtì Yóò Wá Pẹ̀lú Ìyọṣùtì Wọn”
6. Ọwọ́ wo ni ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn fi mú ọ̀rọ̀ “ọjọ́ Jèhófà” tó ń bọ̀, kí sì nìdí tí èyí ò fi ya àwa Kristẹni tòótọ́ lẹ́nu?
6 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe ni “ọjọ́ Jèhófà” ń yára sún mọ́lé, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tó ń gbé ayé ò ṣe bíi pé ó kan àwọn. Wọ́n tiẹ̀ tún ń pẹ̀gàn àwọn tó ń kìlọ̀ fún wọn pé ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé. Èyí ò ya àwa Kristẹni tòótọ́ lẹ́nu. A rántí ìkìlọ̀ tí àpọ́sítélì Pétérù ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀, pé: “Ẹ mọ èyí lákọ̀ọ́kọ́, pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn olùyọṣùtì yóò wá pẹ̀lú ìyọṣùtì wọn, wọn yóò máa rìn ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn wọn yóò sì máa wí pé: ‘Wíwàníhìn-ín rẹ̀ yìí tí a ti ṣèlérí dà? Họ́wù, láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá wa ti sùn nínú ikú, ohun gbogbo ń bá a lọ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá.’”—2 Pétérù 3:3, 4.
7. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa fi sọ́kàn pé ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé gan-an?
7 Kí ni ò ní jẹ́ ká ní irú èrò òdì tí wọ́n ní yìí ká lè máa fi sọ́kàn pé ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé gan-an? Pétérù sọ fún wa pé: “Èmi ń ru agbára ìrònú yín ṣíṣe kedere sókè gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìránnilétí, pé kí ẹ máa rántí àwọn àsọjáde tí àwọn wòlíì mímọ́ ti sọ ní ìṣáájú àti àṣẹ Olúwa àti Olùgbàlà nípasẹ̀ àwọn àpọ́sítélì yín.” (2 Pétérù 3:1, 2) Tá a bá ń fiyè sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó jẹ́ ìkìlọ̀, á ràn wá lọ́wọ́ láti ‘ru agbára ìrònú wa tó ṣe kedere sókè.’ Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti rán wa létí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìkìlọ̀ wọ̀nyí láìmọye ìgbà, àmọ́ ó ṣe pàtàkì pé ká máa fiyè sí wọn nísinsìnyí ju ti ìgbàkígbà rí lọ.—Aísáyà 34:1-4; Lúùkù 21:34-36.
8. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ ò fi ka ìránnilétí tó wà nínú Bíbélì sí?
8 Kí nìdí táwọn kan ò fi ka àwọn ìránnilétí wọ̀nyí sí? Pétérù sọ ìdí rẹ̀ bó ṣe ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ní ìbámu pẹ̀lú ìdàníyàn wọn, òtítọ́ yìí bọ́ lọ́wọ́ àfiyèsí wọn, pé àwọn ọ̀run wà láti ìgbà láéláé àti ilẹ̀ ayé kan tí ó dúró digbí-digbí láti inú omi àti ní àárín omi nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; àti nípasẹ̀ ohun wọnnì, ayé ìgbà yẹn jìyà ìparun nígbà tí a fi àkúnya omi bò ó mọ́lẹ̀.” (2 Pétérù 3:5, 6) Àbẹ́ ò rí nǹkan! Àwọn kan ò fẹ́ kí ọjọ́ Jèhófà dé. Wọn ò fẹ́ kí ohunkóhun dí wọn lọ́wọ́ ayé ìjẹkújẹ tí wọ́n ń jẹ. Wọn ò fẹ́ jíhìn fún Jèhófà fún bí wọ́n ṣe ń fi ìgbésí ayé wọn ṣe ìfẹ́ inú ara wọn nìkan! Bí Pétérù ṣe sọ, ńṣe ni wọ́n ń gbé ìgbé ayé wọn “ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn.”
9. Nígbà ayé Nóà àti Lọ́ọ̀tì, ọwọ́ wo làwọn èèyàn fi mú ìkìlọ̀ tí wọ́n gbọ́?
9 Àwọn ẹlẹ́gàn wọ̀nyí mọ̀ pé àwọn ìgbà kan wà tí Jèhófà mú ìdájọ́ rẹ̀ wá sórí àwọn ẹni ibi láyé àtijọ́ o, àmọ́ nítorí “ìdàníyàn wọn,” ìyẹn nítorí ìfẹ́ inú ara wọn, wọ́n yàn láti fi mímọ̀ ṣaláìmọ̀. Jésù Kristi àti àpọ́sítélì Pétérù mẹ́nu kan méjì lára irú àwọn ìgbà bẹ́ẹ̀, ìyẹn “àwọn ọjọ́ Nóà” àti “àwọn ọjọ́ Lọ́ọ̀tì.” (Lúùkù 17:26-30; 2 Pétérù 2:5-9) Kí Ìkún-omi tó wáyé, àwọn èèyàn ò fiyè sí ìkìlọ̀ tí Nóà ṣe fún wọn. Bákan náà, ṣáájú ìparun Sódómù àti Gòmórà, ńṣe ni Lọ́ọ̀tì “dà bí ọkùnrin tí ń ṣàwàdà” lójú àwọn àfẹ́sọ́nà àwọn ọmọbìnrin rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 19:14.
10. Kí ni Jèhófà sọ pé òun á ṣe fún àwọn tí kò fiyè sí ìkìlọ̀?
10 Báwọn èèyàn ṣe ń ṣe lónìí náà nìyẹn o. Àmọ́ ṣá, kíyè sí ohun tí Jèhófà sọ pé òun á ṣe fún àwọn tí kò fiyè sí ìkìlọ̀. Ó ní: “Èmi yóò sì fún àwọn ènìyàn tí ń dì lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ wọn ní àfiyèsí, tí wọ́n sì ń sọ ní ọkàn-àyà wọn pé, ‘Jèhófà kì yóò ṣe rere, kì yóò sì ṣe búburú.’ Ọlà wọn yóò sì wá jẹ́ fún ìkógun àti ilé wọn fún ahoro. Wọn yóò sì kọ́ ilé, ṣùgbọ́n wọn kì yóò gbé inú wọn; wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò mu wáìnì wọn.” (Sefanáyà 1:12, 13) Àwọn èèyàn lè máa bá a lọ láti fi gbogbo àkókò wọn gbọ́ tara wọn, àmọ́ wọn ò ní rí àǹfààní tó pẹ́ lọ títí nínú iṣẹ́ àṣekára tí wọ́n ń ṣe. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọjọ́ Jèhófà yóò dé lójijì, ọrọ̀ tí wọ́n sì ti kó jọ ò ní lè gbà wọ́n là.—Sefanáyà 1:18.
“Máa Bá A Nìṣó ní Fífojú Sọ́nà fún Un”
11. Ọ̀rọ̀ ìyànjú wo la gbọ́dọ̀ máa fi sọ́kàn?
11 Àwa ò gbọ́dọ̀ ṣe bíi tàwọn èèyàn búburú o, kàkà bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa fi ọ̀rọ̀ ìyànjú tí wòlíì Hábákúkù ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ sọ́kàn, pé: “Ìran náà ṣì jẹ́ fún àkókò tí a yàn kalẹ̀, ó sì ń sáré lọ ní mímí hẹlẹhẹlẹ sí òpin, kì yóò sì purọ́. Bí ó bá tilẹ̀ falẹ̀, máa bá a nìṣó ní fífojú sọ́nà fún un; nítorí yóò ṣẹ láìkùnà. Kì yóò pẹ́.” (Hábákúkù 2:3) Kódà bó bá dà bíi pé ọjọ́ náà ń pẹ́ jù lójú wa nítorí ẹ̀dá aláìpé tá a jẹ́, ó yẹ ká máa rántí pé Jèhófà kì í fi nǹkan falẹ̀. Àkókò tó là kalẹ̀ gan-an ni ọjọ́ rẹ̀ máa dé, nígbà tí ẹ̀dá èèyàn ò retí pé yóò jẹ́.—Máàkù 13:33; 2 Pétérù 3:9, 10.
12. Kí ni Jésù kìlọ̀ nípa rẹ̀, báwo lèyí sì ṣe yàtọ̀ sí ohun táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ń ṣe?
12 Nígbà tí Jésù ń sọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì láti máa retí ọjọ́ Jèhófà, ó kìlọ̀ pé àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun pàápàá ò ní fi sọ́kàn mọ́ pé ọjọ́ Jèhófà ti rọ̀ dẹ̀dẹ̀. Ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa wọn pé: “Bí ẹrú búburú yẹn bá lọ sọ nínú ọkàn-àyà rẹ̀ pẹ́nrẹ́n pé, ‘Ọ̀gá mi ń pẹ́,’ tí ó sì wá bẹ̀rẹ̀ sí lu àwọn ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó sì ń jẹ, tí ó sì ń mu pẹ̀lú àwọn ọ̀mùtí paraku, ọ̀gá ẹrú yẹn yóò dé ní ọjọ́ tí kò fojú sọ́nà fún àti ní wákàtí tí kò mọ̀, yóò sì fi ìyà mímúná jù lọ jẹ ẹ́.” (Mátíù 24:48-51) Àmọ́ ti ẹrú olóòótọ́ àti olóye yàtọ̀ o. Ẹrú yìí kò gbàgbé rí pé ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé gan-an. Kò yéé ṣọ́nà ó sì ń fi hàn pé òun ti múra sílẹ̀. Jésù sì ti yàn án pé kó máa bójú tó “gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀” tó wà lórí ilẹ̀ ayé.—Mátíù 24:42-47.
Ìjáfara Léwu!
13. Báwo ni Jésù ṣe tẹnu mọ́ ọn pé àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ò gbọ́dọ̀ jáfara?
13 Ó pọn dandan pé káwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní wà lójúfò. Wọ́n ní láti sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù kíákíá tí wọ́n bá rí i tí ‘àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini yí i ká.’ (Lúùkù 21:20, 21) Ọdún 66 Sànmánì Kristẹni làwọn ọmọ ogun yí Jerúsálẹ́mù ká. Kíyè sí bí Jésù ṣe tẹnu mọ́ ọn fáwọn Kristẹni wọ̀nyẹn pé wọn ò gbọ́dọ̀ jáfara, ó ní: “Kí ẹni tí ó wà ní orí ilé má ṣe sọ̀ kalẹ̀ láti kó àwọn ẹrù kúrò nínú ilé rẹ̀; kí ẹni tí ó wà ní pápá má sì padà sí ilé láti mú ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀.” (Mátíù 24:17, 18) Àmọ́ níwọ̀n bí ìtàn ti fi hàn pé ọdún mẹ́rin lẹ́yìn ọdún 66 Sànmánì Kristẹni ni Jerúsálẹ́mù tó pa run, kí wá nìdí táwọn Kristẹni fi gbọ́dọ̀ gbégbèésẹ̀ lórí ìkìlọ̀ Jésù láìjáfara lọ́dún 66 Sànmánì Kristẹni?
14, 15. Kí nìdí tó fi pọn dandan pé káwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù kíákíá nígbà tí wọ́n bá rí i táwọn ọmọ ogun yí i ká?
14 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọdún 70 Sànmánì Kristẹni làwọn ọmọ ogun Róòmù tó pa Jerúsálẹ́mù run, síbẹ̀, nǹkan ò fara rọ nílùú náà fún ọdún mẹ́rin yẹn. Ojú wọn rí màbo! Ńṣe làwọn aráàlú náà ń han ara wọn léèmọ̀ tí wọ́n sì ń para wọn nípakúpa. Òpìtàn kan sọ pé “ogun abẹ́lé tó gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn àti ìwà ìkà tó burú jáì” ló wáyé ni Jerúsálẹ́mù lákòókò yẹn. Wọ́n ń pe àwọn ọ̀dọ́kùnrin láti di ara àwọn tó ń dáàbò bo ìlú, wọ́n ní kí wọ́n máa gbé ohun ìjà, wọ́n sì ń pè wọ́n láti di ọmọ ogun. Ojoojúmọ́ ni wọ́n ń fi ogun jíjà dánra wò. Ojú ọ̀dàlẹ̀ ni wọ́n sì fi ń wo àwọn tí ò fọwọ́ sí ètò tí wọ́n ṣe. Ká ní àwọn Kristẹni ò tètè sá kúrò nílùú náà ni, inú ewu ńlá ni wọn ì bá wà.—Mátíù 26:52; Máàkù 12:17.
15 Nǹkan kan wà nínú ọ̀rọ̀ Jésù tó yẹ ká kíyè sí o. Kò sọ pé àwọn tó wà ní Jerúsálẹ́mù ni kí wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ, kàkà bẹ́ẹ̀, “àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà” ló pè é. Èyí ṣe pàtàkì nítorí pé àwọn ọmọ ogun Róòmù tún bẹ̀rẹ̀ ogun padà ní oṣù mélòó kan lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Jerúsálẹ́mù. Wọ́n kọ́kọ́ ṣẹ́gun Gálílì lọ́dún 67 Sànmánì Kristẹni, wọ́n sì rọra ń ṣẹ́gun Jùdíà díẹ̀díẹ̀ lọ́dún tó tẹ̀ lé e. Èyí fa ìpọ́njú ńlá fáwọn tó wà ní ìgbèríko. Bákan náà, ńṣe ló ń ṣòro sí i fáwọn tó wà ní Jerúsálẹ́mù láti sá lọ. Ṣíṣọ́ ni wọ́n ń ṣọ́ ẹnubodè ìlú náà, tẹ́nì kan bá sì fẹ́ sá lọ, wọ́n á rò pé ó fẹ́ lọ dara pọ̀ mọ́ àwọn ará Róòmù ni.
16. Kí làwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní gbọ́dọ̀ múra tán láti ṣe kí wọ́n tó lè la àkókò hílàhílo yẹn já?
16 Gbogbo ohun tá a gbé yẹ̀ wò yìí jẹ́ ká rí ìdí tí Jésù fi tẹnu mọ́ ọn pé àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní ò gbọ́dọ̀ jáfara. Wọ́n gbọ́dọ̀ múra tán láti yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan, wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn ohun ìní tara dí wọn lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó yẹ. Wọ́n gbọ́dọ̀ múra tán láti “sọ pé ó dìgbòóṣe fún gbogbo àwọn nǹkan ìní [wọn]” kí wọ́n bàa lè ṣe ohun tí Jésù kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n ṣe. (Lúùkù 14:33) Gbogbo àwọn tí wọ́n ṣègbọràn tí wọ́n sì sá lọ sí òdìkejì Jọ́dánì ló yè bọ́.
Bá A Ṣe Lè Máa Fi Sọ́kàn Pé Ọjọ́ Jèhófà Ti Sún Mọ́lé Gan-an
17. Kí nìdí tá a fi ní láti túbọ̀ máa fi sọ́kàn pé ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé gan-an?
17 Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn kedere pé ọjọ́ ìkẹyìn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dópin. Ju ti ìgbàkígbà rí lọ, a ní láti túbọ̀ máa fi sọ́kàn pé ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé gan-an, ká má sì jẹ́ kó kúrò lọ́kàn wa. Lákòókò tí kò bá sógun, kì í sí gìrìgìrì fún ọmọ ogun, kò sì ní sí nínú ewu ogun. Àmọ́ tó bá torí ìyẹn dẹra nù, tí wọ́n wá pè é lójijì pé ojú ogun yá, ó lè bá a lábo, ìyẹn sì lè mú kó bógun náà lọ. Bọ́rọ̀ ṣe rí nínú ogun tẹ̀mí tá à ń jà nìyẹn o. Táwa náà bá lọ dẹra nù, a lè má lè ṣẹ́gun nínú ogun tẹ̀mí tá à ń jà, ọjọ́ Jèhófà sì lè dé bá wa lójijì. (Lúùkù 21:36; 1 Tẹsalóníkà 5:4) Tá a bá rí ẹnikẹ́ni tó ti “fà sẹ́yìn kúrò ní títọ Jèhófà lẹ́yìn,” ìsinsìnyí ló yẹ kẹ́ni náà padà sọ́dọ̀ rẹ̀.—Sefanáyà 1:3-6; 2 Tẹsalóníkà 1:8, 9.
18, 19. Kí ló máa jẹ́ ká lè máa fi “wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà” sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí?
18 Nítorí pé ọjọ́ Jèhófà lè dé bá wa lójijì ni àpọ́sítélì Pétérù ṣe gbà wá níyànjú pé ká máa fi “wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà” sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí. Báwo la ṣe lè fi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí? Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa ṣe “ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run.” (2 Pétérù 3:11, 12) Tá a bá ń jẹ́ kí ọwọ́ wa dí lẹ́nu irú àwọn ìgbòkègbodò bẹ́ẹ̀, tayọ̀tayọ̀ la óò máa retí pé kí “ọjọ́ Jèhófà” dé. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí ‘fi sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí’ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí túmọ̀ sí “mú yára kánkán” ní ìtumọ̀ olówuuru. Ká sòótọ́, a ò lè mú kí àkókò tó kù kí ọjọ́ Jèhófà dé yá ju bí Jèhófà ṣe ṣètò rẹ̀ lọ. Àmọ́ bá a ṣe ń dúró de ọjọ́ yẹn, ńṣe ló máa dà bíi pé àkókò ń sáré tete tá a bá jẹ́ kí ọwọ́ wa dí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.—1 Kọ́ríńtì 15:58.
19 Tá a bá ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a sì ń ronú lórí àwọn ìránnilétí tá à ń rí nínú rẹ̀, ìyẹn náà á jẹ́ ká lè máa “fi tọkàntara fẹ́ kí ọjọ́ yẹn dé (ìyẹn ni pé ká máa retí rẹ̀ ká sì mú kí dídé rẹ̀ yára kánkán),” á sì tún mú ká “máa fojú sọ́nà fún un nígbà gbogbo.” (2 Pétérù 3:12, Bíbélì The Amplified Bible àti Bíbélì The New Testament, tí William Barclay ṣe) Ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ló wà nínú àwọn ìránnilétí tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ọ̀hún sọ pé ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀, yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún sọ ọ̀pọ̀ ìbùkún tí àwọn tó ń ‘wà ní ìfojúsọ́nà fún Jèhófà’ máa rí gbà.—Sefanáyà 3:8.
20. Àrọwà wo ló yẹ ká fi sọ́kàn?
20 Àkókò tá a wà yìí gan-an ló yẹ kí gbogbo wa fi àrọwà tí Jèhófà pa nípasẹ̀ wòlíì Sefanáyà sọ́kàn, pé: “Kí ìbínú jíjófòfò Jèhófà tó wá sórí yín, kí ọjọ́ ìbínú Jèhófà tó wá sórí yín, ẹ wá Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé, tí ń fi ìpinnu ìdájọ́ Tirẹ̀ ṣe ìwà hù. Ẹ wá òdodo, ẹ wá ọkàn-tútù. Bóyá a lè pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà.”—Sefanáyà 2:2, 3.
21. Kí ni ìpinnu àwa èèyàn Ọlọ́run ní ọdún 2007?
21 Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ pàtàkì tá a gbé yẹ̀ wò yìí, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2007 bá a mu gan-an ni. Ó ní: “Ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé.” Ó dá àwa èèyàn Ọlọ́run lójú pé ọjọ́ náà “sún mọ́lé, ìyára kánkán rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.” (Sefanáyà 1:14) “Kì yóò pẹ́.” (Hábákúkù 2:3) Nítorí náà, bá a ṣe ń retí ọjọ́ yẹn, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a ó máa fi àkókò tá a wà sọ́kàn, ká mọ̀ pé díẹ̀ báyìí ló kù káwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí ní ìmúṣẹ tó kẹ́yìn!
Ǹjẹ́ O Lè Dáhùn?
• Kí ni “ọjọ́ ńlá Jèhófà”?
• Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ ò fi fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ pé ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé gan-an?
• Kí nìdí táwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní ò fi gbọ́dọ̀ jáfara?
• Kí ló lè mú ká túbọ̀ máa fi sọ́kàn pé ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé gan-an?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 19]
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2007 ni: “Ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé.” —Sefanáyà 1:14.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Bíi tìgbà ayé Nóà, ọjọ́ Jèhófà yóò dé bá àwọn ẹlẹ́gàn lójijì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní sá lọ kíákíá nígbà tí wọ́n rí i tí ‘àwọn ọmọ ogun yí Jerúsálẹ́mù ká’