Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí
17 Ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì méje tó ní abọ́ méje+ náà wá, ó sì sọ fún mi pé: “Wá, màá fi ìdájọ́ aṣẹ́wó ńlá tó jókòó lórí omi púpọ̀ hàn ọ́,+ 2 ẹni tí àwọn ọba ayé bá ṣe ìṣekúṣe,*+ tí a sì mú kí àwọn tó ń gbé ayé mu wáìnì ìṣekúṣe* rẹ̀ ní àmupara.”+
3 Ó fi agbára ẹ̀mí gbé mi lọ sínú aginjù kan. Mo sì rí obìnrin kan tó jókòó lórí ẹranko aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tó kún fún àwọn orúkọ tó jẹ́ ọ̀rọ̀ òdì, ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá. 4 Obìnrin náà wọ aṣọ aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aláwọ̀ pọ́pù,+ a sì fi wúrà, àwọn òkúta iyebíye àti péálì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́,+ ó mú ife tí wọ́n fi wúrà ṣe dání, àwọn ohun ìríra àti àwọn ohun àìmọ́ ìṣekúṣe* rẹ̀ ló kún inú ife náà. 5 Wọ́n kọ orúkọ kan sí iwájú orí rẹ̀, ó jẹ́ àdììtú: “Bábílónì Ńlá, ìyá àwọn aṣẹ́wó+ àti àwọn ohun ìríra ayé.”+ 6 Mo rí i pé obìnrin náà ti mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹni mímọ́ àti ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹlẹ́rìí Jésù ní àmupara.+
Tóò, nígbà tí mo rí i, ó yà mí lẹ́nu gan-an. 7 Áńgẹ́lì náà wá sọ fún mi pé: “Kí nìdí tó fi yà ọ́ lẹ́nu? Màá sọ ohun tó jẹ́ àdììtú nípa obìnrin náà+ fún ọ àti nípa ẹranko tó ń gbé e, èyí tó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá:+ 8 Ẹranko tí ìwọ rí ti wà tẹ́lẹ̀, àmọ́ kò sí, síbẹ̀ ó máa tó jáde látinú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀,+ ó sì máa lọ sí ìparun. Nígbà tí àwọn tó ń gbé ayé, ìyẹn àwọn tí a kò kọ orúkọ wọn sínú àkájọ ìwé ìyè+ látìgbà ìpìlẹ̀ ayé, bá sì rí bí ẹranko náà ṣe wà tẹ́lẹ̀, àmọ́ tí kò sí, síbẹ̀ tó tún máa wà, ó máa yà wọ́n lẹ́nu.
9 “Èyí gba pé kí èèyàn ní ọgbọ́n, kó sì lo làákàyè:* Orí méje+ náà túmọ̀ sí òkè méje, níbi tí obìnrin náà jókòó lé. 10 Ọba méje ló wà: Márùn-ún ti ṣubú, ọ̀kan wà, ọ̀kan yòókù kò tíì dé; àmọ́ nígbà tó bá dé, ó gbọ́dọ̀ wà fúngbà díẹ̀. 11 Ẹranko tó wà tẹ́lẹ̀ àmọ́ tí kò sí,+ òun náà ni ọba kẹjọ, àmọ́ ó wá látinú àwọn méje náà, ó sì lọ sí ìparun.
12 “Ìwo mẹ́wàá tí o rí túmọ̀ sí ọba mẹ́wàá, tí kò tíì gba ìjọba, àmọ́ wọ́n gba àṣẹ láti jọba pẹ̀lú ẹranko náà fún wákàtí kan. 13 Èrò kan náà ló wà lọ́kàn wọn, torí náà, wọ́n fún ẹranko náà ní agbára àti àṣẹ wọn. 14 Wọ́n máa bá Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà jà,+ àmọ́, torí òun ni Olúwa àwọn olúwa àti Ọba àwọn ọba,+ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà máa ṣẹ́gun wọn.+ Bákan náà, àwọn tí a pè tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ àyànfẹ́ àti olóòótọ́ máa ṣẹ́gun pẹ̀lú.”+
15 Ó sọ fún mi pé: “Àwọn omi tí o rí, níbi tí aṣẹ́wó náà jókòó sí, túmọ̀ sí àwọn èèyàn àti èrò rẹpẹtẹ àti àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ahọ́n.*+ 16 Ìwo mẹ́wàá+ tí o rí àti ẹranko náà,+ máa kórìíra aṣẹ́wó náà,+ wọ́n máa sọ ọ́ di ahoro, wọ́n á tú u sí ìhòòhò, wọ́n máa jẹ ẹran ara rẹ̀, wọ́n sì máa fi iná sun ún pátápátá.+ 17 Torí Ọlọ́run ti fi sí ọkàn wọn láti ṣe ohun tí òun fẹ́,+ àní láti ṣe ohun kan ṣoṣo tí wọ́n ń rò láti fún ẹranko náà ní ìjọba wọn,+ títí ìgbà tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ṣẹ délẹ̀délẹ̀. 18 Obìnrin+ tí o rí túmọ̀ sí ìlú ńlá tó ní ìjọba kan tó ń jọba lórí àwọn ọba ayé.”