ORÍ 111
Àwọn Àpọ́sítélì Ní Kí Jésù Fún Àwọn Ní Àmì
MÁTÍÙ 24:3-51 MÁÀKÙ 13:3-37 LÚÙKÙ 21:7-38
MẸ́RIN NÍNÚ ÀWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN NÍ KÍ JÉSÙ FÚN ÀWỌN NÍ ÀMÌ
ÀSỌTẸ́LẸ̀ JÉSÙ ṢẸ NÍ ỌGỌ́RÙN-ÚN ỌDÚN KÌÍNÍ, Ó TÚN MÁA ṢẸ LỌ́JỌ́ IWÁJÚ
A GBỌ́DỌ̀ WÀ LÓJÚFÒ
Ọ̀sán ti pọ́n, ọjọ́ Tuesday Nísàn 11 ti ń parí lọ, díẹ̀ ló sì kù kí Jésù parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé. Láwọn ọjọ́ tó ṣáájú ìgbà yẹn, Jésù máa ń kọ́ àwọn èèyàn nínú tẹ́ńpìlì lọ́wọ́ ọ̀sán, ó sì máa ń sùn mọ́jú láwọn ìlú tó wà nítòsí Jerúsálẹ́mù. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ Jésù, wọ́n sì máa ń “wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní àárọ̀ kùtù kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì.” (Lúùkù 21:37, 38) Ní báyìí, Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wà lórí Òkè Ólífì, ó sì jókòó pẹ̀lú mẹ́rin lára wọn, ìyẹn Pétérù, Áńdérù, Jémíìsì àti Jòhánù.
Ṣe làwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn dọ́gbọ́n wá bá Jésù lóun nìkan. Ohun tí Jésù sọ nípa tẹ́ńpìlì ló ká wọn lára, torí ó sọ pé wọn ò ní fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta míì níbẹ̀. Yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ tẹ́ńpìlì yẹn, àwọn nǹkan míì tún wà tí wọ́n fẹ́ bi í. Ṣáájú ìgbà yẹn, Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ múra sílẹ̀, torí pé wákàtí tí ẹ ò rò pé ó lè jẹ́ ni Ọmọ èèyàn ń bọ̀.” (Lúùkù 12:40) Bákan náà, Jésù sọ̀rọ̀ nípa ‘ọjọ́ tí a máa ṣí Ọmọ èèyàn payá.’ (Lúùkù 17:30) Torí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn lè máa rò ó pé ṣé àwọn ohun tí Jésù sọ yẹn jọra pẹ̀lú ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ nípa tẹ́ńpìlì yìí? Wọ́n wá bi í pé: “Sọ fún wa, ìgbà wo ni àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀, kí ló sì máa jẹ́ àmì pé o ti wà níhìn-ín àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?”—Mátíù 24:3.
Ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa ronú nípa bí tẹ́ńpìlì tó wà níwájú wọn ṣe máa pa run. Bákan náà, bí wọ́n ṣe béèrè nípa ìgbà tí Ọmọ èèyàn máa dé, ó ṣeé ṣe kí wọ́n rántí ohun tí Jésù sọ ṣáájú ìgbà yẹn nípa “ọkùnrin kan tí wọ́n bí ní ilé ọlá” tó “rìnrìn àjò . . . kó lè lọ gba agbára láti jọba, kó sì pa dà.” (Lúùkù 19:11, 12) Ó tún ṣeé ṣe kí wọ́n máa ronú nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní “ìparí ètò àwọn nǹkan.”
Nígbà tí Jésù ń dá wọn lóhùn, ó ṣàlàyé ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí ètò àwọn Júù bá fẹ́ wá sópin àti bí tẹ́ńpìlì tó wà níbẹ̀ ṣe máa pa run. Àmọ́, àmì tó fún wọn tún kọjá ìyẹn, torí ó wúlò fáwọn tó di Kristẹni lẹ́yìn wọn. Àmì yẹn ló máa jẹ́ kí wọ́n mọ ohun táá ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù bá “wà níhìn-ín,” táá sì tún jẹ́ kí wọ́n mọ̀ tí wọ́n bá ti ń sún mọ́ ìparí ètò àwọn nǹkan yìí.
Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń rí i bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe ń ṣẹ. Ọ̀pọ̀ nǹkan tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ lójú wọn. Torí náà, ó dájú pé ọkàn àwọn Kristẹni tó wà lójúfò máa balẹ̀ nígbà tí ètò àwọn Júù àti tẹ́ńpìlì wọn bá dópin lọ́dún mẹ́tàdínlógójì (37) lẹ́yìn náà, ìyẹn lọ́dún 70 S.K. Àmọ́ o, kì í ṣe gbogbo ohun tí Jésù sọ ló ṣẹlẹ̀ ṣáájú kí Jerúsálẹ́mù tó pa run àti nígbà tó pa run lọ́dún 70 S.K. Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù bá gba agbára láti ṣàkóso? Jésù jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ mọ ìdáhùn sí ìbéèrè yìí.
Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa ‘gbọ́ nípa àwọn ogun àti ìròyìn nípa àwọn ogun,’ bákan náà “orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba.” (Mátíù 24:6, 7) Ó tún sọ pé “ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára máa wáyé, àìtó oúnjẹ àti àjàkálẹ̀ àrùn sì máa wà láti ibì kan dé ibòmíì.” (Lúùkù 21:11) Jésù wá kìlọ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Àwọn èèyàn máa gbé ọwọ́ wọn lé yín, wọ́n á sì ṣe inúnibíni sí yín.” (Lúùkù 21:12) Ó tún sọ pé àwọn wòlíì èké máa wà, wọ́n sì máa ṣi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà. Àti pé ìwà tí kò bófin mu máa pọ̀ sí i, ìfẹ́ ọ̀pọ̀ èèyàn sì máa tutù. Jésù fi kún un pé a máa “wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.”—Mátíù 24:14.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ohun tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ ló ṣẹ káwọn ará Róòmù tó pa Jerúsálẹ́mù run àti nígbà tí wọ́n pa á run, ṣé ó ṣeé ṣe káwọn ọ̀rọ̀ Jésù yẹn ṣẹ lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ lọ́jọ́ iwájú? Ṣé ìwọ náà ń rí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù sọ yẹn ń ṣẹ lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ lákòókò wa yìí?
Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa àmì tó máa fi hàn pé ó ti wà níhìn-ín, ó tún mẹ́nu ba ohun míì. Ó sọ pé wọ́n máa rí “ohun ìríra tó ń fa ìsọdahoro.” (Mátíù 24:15) Lọ́dún 66 S.K., ohun ìríra yẹn fara hàn nígbà táwọn abọ̀rìṣà, ìyẹn àwọn “ọmọ ogun [Róòmù] pàgọ́ yí Jerúsálẹ́mù ká,” tí wọ́n sì gbé àsíá wọn wá síbẹ̀. Wọ́n yí ìlú náà ká, wọ́n sì wó apá kan lára ògiri rẹ̀. (Lúùkù 21:20) Àwọn ni “ohun ìríra” tó dúró síbi táwọn Júù gbà pé ó jẹ́ “ibi mímọ́.”
Jésù tún sọ nǹkan míì tó máa ṣẹlẹ̀, ó ní: “Ìpọ́njú ńlá máa wà nígbà náà, irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé títí di báyìí, àní, irú rẹ̀ kò ní ṣẹlẹ̀ mọ́.” Lọ́dún 70 S.K., àwọn ọmọ ogun Róòmù pa Jerúsálẹ́mù run. Ìpọ́njú ńlá ló wáyé nígbà yẹn torí ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ló kú, wọ́n ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù táwọn Júù kà sí ‘ìlú mímọ́,’ wọ́n sì run tẹ́ńpìlì rẹ̀. (Mátíù 4:5; 24:21) Ìparun yẹn burú gan-an torí pé irú ẹ̀ ò ṣẹlẹ̀ rí nínú ìtàn àwọn Júù, ìyẹn ló sì fòpin sí ọ̀nà táwọn Júù ń gbà jọ́sìn Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ ọdún. Tí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù bá ṣẹ lọ́nà tó lágbára nígbà yẹn, ó dájú pé bó ṣe máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú máa bani lẹ́rù gan-an.
JÉSÙ FI WỌ́N LỌ́KÀN BALẸ̀ NÍPA OHUN TÓ MÁA ṢẸLẸ̀ LỌ́JỌ́ IWÁJÚ
Jésù ò tíì parí ọ̀rọ̀ tó ń bá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sọ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà tó bá gba agbára láti ṣàkóso àti bí nǹkan ṣe máa rí ní ìparí ètò àwọn nǹkan. Ó wá kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n ṣọ́ra nítorí “àwọn èké Kristi àti àwọn wòlíì èké.” Jésù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn wòlíì yẹn máa gbìyànjú “láti ṣi àwọn àyànfẹ́ pàápàá lọ́nà, tó bá ṣeé ṣe.” (Mátíù 24:24) Àmọ́ wọn ò ní lè ṣì wọ́n lọ́nà. Àwọn èké Kristi á fẹ́ káwọn èèyàn gbà pé àwọn máa rí Jésù lójúkojú. Àmọ́ ọ̀rọ̀ Jésù ò ní rí bẹ́ẹ̀, torí àwọn èèyàn ò ní rí i sójú nígbà tó bá dé.
Nígbà tí Jésù ń ṣàlàyé bí ìpọ́njú ńlá tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ṣe máa rí, ó sọ pé: “Oòrùn máa ṣókùnkùn, òṣùpá ò sì ní mọ́lẹ̀, àwọn ìràwọ̀ máa já bọ́ láti ọ̀run, a sì máa mi àwọn agbára ọ̀run.” (Mátíù 24:29) Ohun tí Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì yẹn bà wọ́n lẹ́rù, bí wọn ò tiẹ̀ lóye bí nǹkan ṣe máa rí, ó dájú pé nǹkan máa le gan-an nígbà yẹn.
Kí làwọn èèyàn máa ṣe nígbà táwọn nǹkan yẹn bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀? Jésù sọ pé: “Àwọn èèyàn máa kú sára nítorí ìbẹ̀rù àti àwọn ohun tí wọ́n ń retí pé ó máa ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, torí a máa mi àwọn agbára ọ̀run.” (Lúùkù 21:26) Ká sòótọ́, àsìkò yẹn ló máa ṣókùnkùn jù lọ nínú ìtàn ẹ̀dá èèyàn.
Inú wa dùn bí Jésù ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo èèyàn láá máa kérora nígbà tí ‘ọmọ èèyàn bá ń bọ̀ pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.’ (Mátíù 24:30) Ó sọ pé Ọlọ́run máa dá sí ọ̀rọ̀ náà “nítorí àwọn àyànfẹ́.” (Mátíù 24:22) Torí náà, kí ló yẹ káwọn ọmọ ẹ̀yìn tó bá jẹ́ olóòótọ́ ṣe nígbà tí wọ́n bá rí i tí gbogbo nǹkan yìí ń ṣẹlẹ̀? Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Tí àwọn nǹkan yìí bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀, ẹ nàró ṣánṣán, kí ẹ sì gbé orí yín sókè, torí ìdáǹdè yín ń sún mọ́lé.”—Lúùkù 21:28.
Kí ló máa wá jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà láyé nígbà yẹn mọ bí òpin ṣe sún mọ́lé tó? Jésù sọ àpèjúwe igi ọ̀pọ̀tọ́, ó ní: “Gbàrà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ ọ̀mùnú, tó sì rúwé, ẹ mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti sún mọ́lé. Bákan náà, tí ẹ bá rí gbogbo nǹkan yìí, kí ẹ mọ̀ pé ó ti sún mọ́ ẹnu ọ̀nà. Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé, ó dájú pé ìran yìí ò ní kọjá lọ títí gbogbo nǹkan yìí fi máa ṣẹlẹ̀.”—Mátíù 24:32-34.
Torí náà, táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bá ti ń rí oríṣiríṣi àmì tí Jésù sọ, wọ́n máa mọ̀ pé òpin ti sún mọ́lé. Jésù wá sọ ohun kan tó yẹ káwọn ọmọ ẹ̀yìn tó bá wà láyé nígbà yẹn fi sọ́kàn, ó ní:
“Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹni tó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run àti Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, àfi Baba nìkan. Torí bí àwọn ọjọ́ Nóà ṣe rí gẹ́lẹ́ ló máa rí tí Ọmọ èèyàn bá ti wà níhìn-ín. Torí bó ṣe rí ní àwọn ọjọ́ yẹn ṣáájú Ìkún Omi, wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a sì ń fa àwọn obìnrin fún ọkọ, títí di ọjọ́ tí Nóà wọ ọkọ̀ áàkì, wọn ò fiyè sí i títí Ìkún Omi fi dé, tó sì gbá gbogbo wọn lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ èèyàn máa rí.” (Mátíù 24:36-39) Ìkún Omi tó wáyé nígbà ayé Nóà dé ibi gbogbo láyé, torí náà, Jésù fi ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn wé ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.
Ó dájú pé àwọn àpọ́sítélì tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀ lórí Òkè Ólífì yẹn máa rí i pé ó ṣe pàtàkì káwọn wà lójúfò. Jésù sọ pé: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí àjẹjù, ọtí àmujù àti àníyàn ìgbésí ayé má bàa di ẹrù pa ọkàn yín, láìròtẹ́lẹ̀ kí ọjọ́ yẹn sì dé bá yín lójijì bí ìdẹkùn. Torí ó máa dé bá gbogbo àwọn tó ń gbé ní gbogbo ayé. Torí náà, ẹ máa wà lójúfò, kí ẹ máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ nígbà gbogbo, kí ẹ lè bọ́ nínú gbogbo nǹkan tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ yìí, kí ẹ sì lè dúró níwájú Ọmọ èèyàn.”—Lúùkù 21:34-36.
Ohun tí Jésù sọ yìí túbọ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́ wọn lọ́kàn pé ọ̀rọ̀ yẹn máa lágbára gan-an. Kì í ṣe ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní ọdún bíi mélòó kan sígbà yẹn nìkan ni Jésù ń sọ, ìyẹn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù tó sì máa kan àwọn Júù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó “máa dé bá gbogbo àwọn tó ń gbé ní gbogbo ayé” ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.
Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa ṣọ́nà, kí wọ́n wà lójúfò, kí wọ́n sì múra sílẹ̀. Jésù tún fi àpèjúwe míì ṣàlàyé bí ìyẹn ṣe ṣe pàtàkì tó, ó sọ pé: “Ẹ mọ ohun kan: Ká ní baálé ilé mọ ìṣọ́ tí olè ń bọ̀ ni, ì bá má sùn, kò sì ní jẹ́ kí wọ́n ráyè wọ ilé òun. Torí èyí, kí ẹ̀yin náà múra sílẹ̀, torí wákàtí tí ẹ kò ronú pé ó máa jẹ́ ni Ọmọ èèyàn ń bọ̀.”—Mátíù 24:43, 44.
Jésù sọ ohun kan tó máa fi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀. Ó jẹ́ kó dá wọn lójú pé “ẹrú” kan máa wà nígbà tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn bá ń ṣẹ, ẹrú yẹn máa mọṣẹ́ ẹ̀ níṣẹ́, á sì wà lójúfò. Jésù lo àpèjúwe kan tó máa tètè yé wọn, ó ní: “Ní tòótọ́, ta ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye tí ọ̀gá rẹ̀ yàn pé kó máa bójú tó àwọn ará ilé rẹ̀, kó máa fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tó yẹ? Aláyọ̀ ni ẹrú yẹn tí ọ̀gá rẹ̀ bá dé, tó sì rí i tó ń ṣe bẹ́ẹ̀! Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ó máa yàn án pé kó máa bójú tó gbogbo ohun ìní rẹ̀.” Àmọ́ tí “ẹrú” yẹn bá lọ yíwà pa dà, tó sì ń fìyà jẹ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ẹrú, ọ̀gá rẹ̀ “máa fi ìyà tó le jù lọ jẹ ẹ́.”—Mátíù 24:45-51; fi wé Lúùkù 12:45, 46.
Jésù ò sọ pé àwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa di ẹni burúkú. Kí ni Jésù wá fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ̀? Ó fẹ́ kí wọ́n wà lójúfò, kí wọ́n sì mọṣẹ́ wọn níṣẹ́. Jésù ṣàlàyé ìyẹn nínú àpèjúwe míì tó tẹ̀ lé e.