‘Ẹ Yan Àwọn Ọ̀rẹ́ Nípasẹ̀ Ọrọ̀ Àìṣòdodo’
“Ẹ yan awọn ọ̀rẹ́ fún ara yín nípasẹ̀ ọrọ̀ àìṣòdodo . . . Ẹni tí ó bá jẹ́ olùṣòtítọ́ ninu ohun tí ó kéré jùlọ jẹ́ olùṣòtítọ́ ninu ohun tí ó pọ̀ pẹlu.”—LUKU 16:9, 10, NW.
1. Báwo ni Mose àti àwọn ọmọ Israeli ṣe yin Jehofa lẹ́yìn àsálà wọn kúrò ní ilẹ̀ Egipti?
AYỌ wọ́n nínú ewu nípasẹ̀ iṣẹ́-ìyanu—ìrírí tí ń fún ìgbàgbọ́ lókun gbáà ni èyí jẹ́! Ìjádelọ àwọn ọmọ Israeli kúrò ní Egipti ni a kò lè sọ pé ó ti ọwọ́ ẹlòmíràn wá yàtọ̀ sí Jehofa, Olódùmarè. Abájọ nígbà náà tí Mose àti àwọn ọmọ Israeli fi kọrin pé: “OLUWA ni agbára àti orin mi, òun ni ó sì di ìgbàlà mi: èyí ni Ọlọrun mi, èmi ó sì fi ìyìn fún un; Ọlọrun bàbá mi, èmi óò gbé e lékè.”—Eksodu 15:1, 2; Deuteronomi 29:2.
2. Kí ni àwọn ènìyàn Jehofa mú lọ́wọ́ lọ bí wọ́n tí ń fi Egipti sílẹ̀?
2 Ẹ wo bí òmìnira tí àwọn ọmọ Israeli ṣẹ̀ṣẹ̀ rí gbà ṣe yàtọ̀ sí ipò tí wọ́n wà ní Egipti tó! Nísinsìnyí wọ́n lè sin Jehofa láìsí ìdílọ́wọ́. Wọn kò sì fi Egipti sílẹ̀ lọ́wọ́ òfo. Mose ròyìn pé: “Àwọn ọmọ Israeli sì . . . béèrè ohun èèlò fàdákà, àti ohun èèlò wúrà, àti aṣọ lọ́wọ́ àwọn ará Egipti. OLUWA sì fún àwọn ènìyàn náà ní ojúrere ní ojú àwọn ará Egipti, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè. Wọ́n sì kó ẹrù àwọn ará Egipti.” (Eksodu 12:35, 36) Ṣùgbọ́n báwo ni wọ́n ṣe lo àwọn ọ̀rọ̀ Egipti wọ̀nyí? Ó ha yọrísí ‘gbígbé Jehofa lékè bí’? Kí ni a rí kọ́ láti inú àpẹẹrẹ wọn?—Fiwé 1 Korinti 10:11.
“Ọrẹ fún Oluwa”
3. Báwo ni lílò ti orílẹ̀-èdè Israeli lo wúrà nínú ìjọsìn èké ṣe sún Jehofa láti hùwàpadà?
3 Ní àkókò tí Mose fi gbé 40 ọjọ́ lórí Òkè Sinai láti gba àwọn ìtọ́ni Ọlọrun fún àwọn ọmọ Israeli, ara àwọn ènìyàn tí wọ́n ń dúró dè é ní ìsàlẹ̀ kò lélẹ̀ mọ́. Ní bíbọ́ yẹrí wúrà tí ó wà ní etí wọn, wọ́n mú kí Aaroni ṣe ère kan fún wọn láti jọ́sìn. Aaroni tún tẹ́ pẹ́pẹ́ kan, àti ní kùtùkùtù ọjọ́ kejì, wọ́n rú ẹbọ níbẹ̀. Ọ̀nà tí wọ́n gbà lo wúrà wọn yìí ha sọ wọ́n di ẹni ọ̀wọ́n fún Olùdáǹdè wọn bí? Àgbẹdọ̀! Jehofa sọ fún Mose pé, “Ǹjẹ́ nísinsìnyí jọ̀wọ́ mi jẹ́ẹ́, kí ìbínú mi kí ó gbóná sí wọn, kí èmi kí ó lè pa wọ́n run.” Kìkì nígbà tí Mose tó bẹ̀bẹ̀ ní Jehofa dá orílẹ̀-èdè náà sí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọlọ̀tẹ̀ tí wọ́n jẹ́ aṣáájú nínú ìwà búburú náà ni Ọlọrun fi àjàkálẹ̀ àrùn pa.—Eksodu 32:1-6, 10-14, 30-35.
4. Kí ni “ọrẹ fún Oluwa,” ta ni ó sì rú u?
4 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Israeli ní àǹfààní láti lo àwọn ọrọ̀ tí ń bẹ ní ìkáwọ́ wọn ní ọ̀nà kan tí ó mu inú Jehofa dùn. Wọ́n gba “ọrẹ fún Oluwa.”a Wúrà, fàdákà, idẹ, aṣọ-aláró, onírúurú ohun èèlò tí a pa láró, awọ àgbò, awọ seali, àti igi ṣittimu wà lára àwọn ọrẹ fún kíkọ́ àti ṣíṣe àgọ́-ìsìn lọ́sọ̀ọ́. Àkọsílẹ̀ náà darí àfiyèsí sí ìṣarasíhùwà àwọn olùṣètọrẹ náà. “Ẹnikẹ́ni tí ọkàn rẹ̀ fẹ́, kí ó mú un wá, ní ọrẹ fún OLUWA.” (Eksodu 35:5-9) Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ọmọ Israeli dáhùnpadà. Nípa báyìí, àgọ́-ìsìn náà jẹ́ ohun ìgbékalẹ̀ tí “ẹwà àti ìtóbilọ́lá rẹ̀ galógo,” bí a bá ni kí a fa ọ̀rọ̀ ọ̀mọ̀wèé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan yọ.
Ọrẹ fún Tẹ́ḿpìlì
5, 6. Ní ìsopọ̀ pẹ̀lú tẹ́ḿpìlì, báwo ni Dafidi ṣe lo ọrọ̀ rẹ̀, báwo sì ni àwọn mìíràn ṣe dáhùnpadà?
5 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọba Solomoni ti Israeli ni ó darí kíkọ́ ilé wíwà títílọ kan fún ìjọsìn Jehofa, Dafidi, bàbá rẹ̀, ṣe ìmúrasílẹ̀ rẹpẹtẹ fún un. Dafidi gba ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ wúrà, fàdákà, idẹ, irin, igi, àti àwọn òkúta iyebíye. Dafidi sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: “Nítorí ní dídùn inú mi sí ilé Ọlọrun mi, mo fi ohun ìní mi, èyíinì ni wúrà àti fàdákà, fún ilé Ọlọrun mi, ju gbogbo èyí tí mo ti pèsè sílẹ̀ fún ilé mímọ́ náà, ẹgbẹ̀ẹ́dógún tálẹ́ǹtì wúrà . . . àti ọ̀ọ́dẹ́gbàárin tálẹ́ǹtì fàdákà dídára, láti fi bo ògiri ilé náà.” Dafidi fún àwọn yòókù pẹ̀lú ní ìṣírí láti jẹ́ ọ̀làwọ́. Ìdáhùnpadà náà pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀: wúrà, fàdákà, idẹ, àti àwọn òkúta iyebiye púpọ̀ sí i. “Pẹ̀lú ọkàn pípé,” àwọn ènìyàn náà “fi tinútinú ṣe ìrànlọ́wọ́ fún Oluwa.”—1 Kronika 22:5; 29:1-9.
6 Nípasẹ̀ àwọn ọrẹ àtinúwá wọ̀nyí, àwọn ọmọ Israeli fi ìmọrírì jíjinlẹ̀ hàn fún ìjọsìn Jehofa. Dafidi fi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn gbàdúrà pé: “Ṣùgbọ́n ta ni èmi, àti kí ni àwọn ènìyàn mi, ti a fi lè ṣe ìrànlọ́wọ́ tinútinú bí irú èyí?” Èéṣe? “Nítorí ohun gbogbo ọ̀dọ̀ rẹ ní tií wá, àti nínú ohun ọwọ́ rẹ ni àwa ti fi fún ọ. . . . Bí ó ṣe ti èmi, nínú òdodo ọkàn mi ni èmi ti fi tinútinú ṣe ìrànlọ́wọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí.”—1 Kronika 29:14, 17.
7. Ẹ̀kọ́ akininílọ̀ wo ni a rí kọ́ láti inú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ Amosi?
7 Síbẹ̀, àwọn ẹ̀yà Israeli kùnà láti máa bá a nìṣó ní fífi ìjọsìn Jehofa sí ipò àkọ́kọ́ jùlọ nínú èrò-inú àti ọkàn-àyà wọn. Nígbà tí ó fi máa di ọ̀rúndún kẹsàn án B.C.E., orílẹ̀-èdè Israeli tí ó ti pínyà jẹ̀bi àìnáání nǹkan tẹ̀mí. Níti ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Israeli tí ń bẹ ní ìhà àríwá, Jehofa polongo nípasẹ̀ Amosi pé: “Ègbé ni fún ẹni tí ara rọ̀ ní Sioni, àti àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé òkè ńlá Samaria!” Ó ṣàpèjúwe wọn gẹ́gẹ́ bí àwọn ọkùnrin “tí . . . ń dùbúlẹ̀ lórí àkéte eyín erin, tí . . . n na ara wọn lórí ìrọ̀gbọ̀kú wọn, tí . . . ń jẹ ọ̀dọ́-àgùtàn inú agbo, ati ẹgbọrọ màlúù inú agbo; . . . tí ń mutí nínú ọpọ́n wáìnì.” Ṣùgbọ́n ọrọ̀ wọn kìí ṣe ààbò. Ọlọrun kìlọ̀ pé: ‘Wọn óò lọ sí ìgbèkùn pẹ̀lú àwọn tí ó ti kọ́ lọ sí ìgbèkùn; àsè àwọn tí ń ṣe àṣelékè ni a óò mú kúrò.’ Ní 740 B.C.E., orílẹ̀-èdè Israeli jìyà lọ́wọ́ àwọn ará Assiria. (Amosi 6:1, 4, 6, 7) Bí àkókò sì ti ń lọ ìjọba Juda ti ìhà gúúsù pẹ̀lú ṣubú gẹ́gẹ́ bí ẹran-ìjẹ sínú ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì.—Jeremiah 5:26-29.
Lílo Àwọn Ohun Àmúṣọrọ̀ Lọ́nà Yíyẹ ní Àkókò Àwọn Kristian
8. Àpẹẹrẹ rere wo ni Josefu àti Maria fifún wa níti lílo àwọn ohun àmúṣọrọ̀?
8 Ní ìyàtọ̀, ipò tálákà tí ó dàbí ẹni pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun wà lẹ́yìnwá ìgbà náà kò ṣèdíwọ́ fún wọn láti fi ìtara wọn hàn fún ìjọsìn tòótọ́. Àpẹẹrẹ kan ni ti Maria àti Josefu jẹ́. Ní ìgbọràn sí àṣẹ Kesari Augustu, wọ́n rìnrìn-àjò lọ sí ìlú ìbílẹ̀ ìdílé wọn, Betlehemu. (Luku 2:4, 5) Níbẹ̀ ni a bí Jesu sí. Ní 40 ọjọ́ lẹ́yìn náà, Josefu àti Maria lọ sí tẹ́ḿpìlì ní Jerusalemu tí ó wà nítòsí láti lọ ṣe ìtọrẹ ẹbọ ìwẹ̀nùmọ́ tí a fi lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí tí ó fihàn pé wọn kò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ nípa ti ohun-ìní, Maria fi ẹyẹ kékeré méjì rúbọ. Obìnrin náà tàbí Josefu kò fi ipò àìní wọn kẹ́wọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọn fi ìgbọràn lo ohun àmúṣọrọ̀ wọn tí ó mọníwọ̀n.—Lefitiku 12:8; Luku 2:22-24.
9-11. (a) Ìtọ́sọ́nà wo ni àwọn ọ̀rọ̀ Jesu nínú Matteu 22:21 pèsè níti bí a ṣe lè lo owó? (b) Èéṣe tí ọrẹ táṣẹ́rẹ́ ti opó náà kò fi jásí asán?
9 Lẹ́yìn náà, àwọn Farisi àti àwọn ọmọlẹ́yìn àjọ-ẹgbẹ́ Herodu gbìyànjú láti fi ìwà àgálámàṣà mú Jesu, ní wíwí pé: “Nitori naa, sọ fún wa, Kí ni iwọ rò? Ó ha bófinmu lati san owó-orí fún Kesari tabi bẹ́ẹ̀ kọ́?” Ìdáhùn Jesu ṣípayá ìfòyeronú rẹ̀. Ní títọ́ka sí ẹyọ-owó tí wọ́n fún un, Jesu béèrè pé: “Àwòrán ati àkọlé ta ni èyí?” Wọ́n fèsì pé: “Ti Kesari.” Lọ́nà ọgbọ́n, ó wá sí ìparí èrò náà pé: “Nitori naa, ẹ san awọn ohun ti Kesari padà fún Kesari, ṣugbọn awọn ohun ti Ọlọrun fún Ọlọrun.” (Matteu 22:17-21, NW) Jesu mọ̀ pé àwọn aláṣẹ tí ń ṣe ẹyọ-owó náà jáde retí pé kí a san owó-orí. Ṣùgbọ́n níbẹ̀ ni ó ti ran àwọn ọmọlẹ́yìn àti àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́ láti mọ̀ pé Kristian tòótọ́ kan tún máa ń sakun láti san àwọn ohun ti “Ọlọrun fún Ọlọrun.” Èyí ní nínú lílo àwọn dúkìá ohun-ìní ẹni lọ́nà yíyẹ.
10 Ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ó ṣojú Jesu nínú tẹ́ḿpìlì fúnni ní àpẹẹrẹ èyí. Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dá àwọn akọ̀wé oníwọra tí wọ́n “ń jẹ ilé awọn opó run” lẹ́bi tán ni. Luku ròyìn pé: “Bí ó ti gbé ojú sókè ó rí awọn ọlọ́rọ̀ tí wọ́n ń sọ ẹ̀bùn wọn sínú awọn àpótí ìṣúra. Nígbà naa ni [Jesu] rí opó aláìní kan tí ó sọ ẹyọ-owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí wọ́n kéré gan-an síbẹ̀, ó sì wí pé: ‘Lótìítọ́ ni mo sọ fún yín, Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé opó yii jẹ́ òtòṣì, ó sọ sínú rẹ̀ ju gbogbo wọn lọ. Nitori gbogbo awọn wọnyi sọ ẹ̀bùn sílẹ̀ lati inú àṣẹ́kùsílẹ̀ wọn, ṣugbọn obìnrin yii lati inú àìní rẹ̀ sọ gbogbo àlùmọ́ọ́nì ìgbésí-ayé tí ó ní sínú rẹ̀.’” (Luku 20:46, 47, NW; 21:1-4, NW) Àwọn kan lára àwọn ènìyàn náà mẹ́nukàn án pé àwọn òkúta ìyebíye ni a fi ṣe tẹ́ḿpìlì náà lọ́ṣọ̀ọ́. Jesu dáhùnpadà pé: “Níti awọn nǹkan wọnyi tí ẹ ń wò, awọn ọjọ́ yoo dé ninu èyí tí a kì yoo fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta kan níhìn-ín tí a kì yoo sì wó palẹ̀.” (Luku 21:5, 6, NW) Ọrẹ kékeré tí opó náà mú wá ha ti jásí asán bí? Dájúdájú bẹ́ẹ̀kọ́. Ó ṣètìlẹ́yìn fún ìṣètò tí Jehofa fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nígbà náà.
11 Jesu sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tòótọ́ pé: “Kò sí ìránṣẹ́ ilé tí ó lè jẹ́ ẹrú fún ọ̀gá méjì; nitori pé, yálà oun yoo kórìíra ọ̀kan tí yoo sì nífẹ̀ẹ́ èkejì, tabi oun yoo fàmọ́ ọ̀kan tí yoo sì tẹ́ḿbẹ́lú èkejì. Ẹ̀yin kò lè jẹ́ ẹrú fún Ọlọrun ati fún ọrọ̀.” (Luku 16:13, NW) Nípa báyìí, báwo ni a ṣe lè fi ìwàdéédéé títọ́ hàn nínú lílo owó àmúṣọrọ̀ wa?
Ìríjú Olùṣòtítọ́
12-14. (a) Àwọn ohun àmúsọrọ̀ wo ni àwọn Kristian jẹ́ ìríjú fún? (b) Ní àwọn ọ̀nà títayọ wo ni àwọn ènìyàn Jehofa lónìí fi ń ṣe iṣẹ́ ìríjú wọn pẹ̀lú ìṣòtítọ́? (d) Níbo ni owó ìṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ Ọlọrun lónìí ti ń wá?
12 Nígbà tí a ya ìgbésí-ayé wa sí mímọ́ fún Jehofa, a sọ níti gidi pé gbogbo ohun tí a ní, gbogbo àwọn ohun àmúṣọrọ̀ wa, jẹ́ tirẹ̀. Báwo, nígbà náà, ni a ṣe níláti lo ohun tí a ní? Nígbà tí ó ń jíròrò iṣẹ́-ìsìn Kristian nínú ìjọ, Arákùnrin C. T. Russell, ààrẹ àkọ́kọ́ fún Watch Tower Society, kọ̀wé pé: “Ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan ka araarẹ̀ sí ẹni tí Oluwa yàn láti jẹ́ ìríjú fún àkókò, agbára ìdarí, owó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí ó jẹ́ tirẹ̀, ẹnì kọ̀ọ̀kan sì níláti máa wá ọ̀nà láti lo àwọn tálẹ́ǹtì wọ̀nyí dé ibi tí agbára rẹ̀ bá mọ, sí ògo Ọ̀gá náà.”—The New Creation, ojú-ìwé 345.
13 “Ohun tí a ń wá ninu awọn ìríjú ni pé kí a rí ènìyàn kan ní olùṣòtítọ́,” ni 1 Korinti 4:2 (NW) sọ. Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kárí ayé kan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń làkàkà láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú àpèjúwe yẹn, ní lílo púpọ̀ nínú àkókò wọn bí ó bá ti lè ṣeéṣe tó nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ Kristian, ní fífi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ mú agbára ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wọn dàgbà. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọ̀wọ́ àwọn alájọṣiṣẹ́ tí wọ́n jẹ́ olùyọ̀ǹda ara-ẹni lábẹ́ ìdarí Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùn-Jẹkùn ń fi pẹ̀lú ìmúratán yọ̀ǹda àkókò, okun, àti òye-ìṣiṣẹ́ wọn láti kọ́ àwọn gbọ̀ngàn ìpàdé dídára fún ìjọsìn. Pẹ̀lú gbogbo èyí, a ń mú inú Jehofa dùn gidigidi.
14 Níbo ni owó tí a ń lò láti ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìgbétáásì ìkọ́ni àti ìkọ́lé gbígbòòrò yìí ti ń wá? Láti ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n ní ọkàn ìmúratán ni, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní àwọn ọjọ́ tí a fi kọ́ àgọ́-ìsìn. Lẹ́nìkọ̀ọ̀kan, àwa ha ń kópa nínú rẹ̀ bí? Ọ̀nà tí a gbà ń lo owó àmúṣọrọ̀ wa ha fihàn pé iṣẹ́-ìsìn Jehofa ní ìjẹ́pàtàkì tí ó gba iwájú jùlọ fún wa bí? Nínú àwọn ọ̀ràn tí ó jẹ mọ́ owó, ẹ jẹ́ kí a jẹ́ ìríjú olùṣòtítọ́.
Ọ̀nà Ìgbàhùwà Ọ̀làwọ́
15, 16. (a) Báwo ni àwọn Kristian ní ọjọ́ Paulu ṣe fi ìwà ọ̀làwọ́ hàn? (b) Ojú wo ni ó yẹ kí a fi wo ohun tí a ń jíròrò rẹ̀ yìí?
15 Aposteli Paulu kọ̀wé nípa ẹ̀mí ọ̀làwọ́ àwọn Kristian ní Makedonia àti Akaia. (Romu 15:26) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ń pọ́n àwọn fúnraawọn lójú, wọ́n fi ìmúratán ṣètọrẹ láti ran àwọn arákùnrin wọn lọ́wọ́. Bákan náà ni Paulu fún àwọn Kristian ará Korinti ní ìṣírí láti fífúnni lọ́nà ọ̀làwọ́, ní fífi àwọn ohun tí ó bá ṣẹ́kù sílẹ̀ fún wọ́n ṣètọrẹ láti lè dí àìnító àwọn ẹlòmíràn. Kò sí ẹni tí ó lè fi pẹ̀lú ẹ̀tọ́ fi ẹ̀sùn ìlọ́nilọ́wọ́gbà kan Paulu. Ó kọ̀wé pé: “Ẹni tí ó bá ń fúnrúgbìn kín-ún yoo ká kín-ún pẹlu; ẹni tí ó bá sì ń fúnrúgbìn yanturu yoo ká yanturu pẹlu. Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí oun ti gbèrò pinnu ninu ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹlu ìlọ́tìkọ̀ tabi lábẹ́ àfipáṣe, nitori Ọlọrun nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.”—2 Korinti 8:1-3, 14, NW; 9:5-7, 13, NW.
16 Ìtọrẹ ọlọ́làwọ́ tí àwọn arákùnrin wa àti àwọn olùfìfẹ́hàn ń ṣe fún iṣẹ́ Ìjọba káríayé lónìí fúnni ní ẹ̀rí nípa bí wọ́n ti fi ọ̀wọ̀ gíga hàn fún àǹfààní yìí tó. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí Paulu ti rán àwọn ará Korinti létí, àwa yóò ṣe dáradára láti ka ìjíròrò yìí sí ìránnilétí.
17. Ọ̀nà ìgbà fúnni wo ni Paulu fún ní ìṣírí, a ha sì lè fi èyí sílò lónìí bí?
17 Paulu rọ àwọn ará láti tẹ̀lé ọ̀nà àfilélẹ̀ kan níti ọ̀nà ìgbàfúnni wọn. Ó wí pé: “Ní gbogbo ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀ kí olúkúlùkù yín ní ilé ara rẹ̀ ya ohun kan sọ́tọ̀ gédégbé ní ìtọ́júpamọ́ gẹ́gẹ́ bí oun ti lè máa láásìkí.” (1 Korinti 16:1, 2, NW) Ìyẹn lè ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ kan fún àwa àti àwọn ọmọ wa nígbà tí a bá ń ṣètọrẹ, yálà a ṣe é nípasẹ̀ ìjọ tàbí ní tààràtà sí ọ́fíìsì ẹ̀ka Watch Tower Society tí ó súnmọ́ wa jùlọ. Tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì tí a yanṣẹ́ fún láti wàásù ní ìlú kan ní Ìlà-Oòrùn Africa késí àwọn olùfìfẹ́hàn láti darapọ̀ mọ́ wọn fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Ní ìparí ìpàdé àkọ́kọ́ yìí, àwọn míṣọ́nnárì náà fi pẹ̀lú ọgbọ́n-inú fi àwọn ẹyọ-owó díẹ̀ sínú àpótí kan tí a ṣe àmì “Ọrẹ fún iṣẹ́ Ìjọba náà” sí. Àwọn mìíràn tí wọ́n wá síbẹ̀ ṣe bákan náà pẹ̀lú. Lẹ́yìn náà, nígbà tí a ti ṣètò àwọn ẹni titun wọ̀nyí sí ìjọ Kristian kan, alábòójútó àyíká bẹ̀ wọ́n wò ó sì sọ̀rọ̀ àkíyèsí lórí ìṣedéédéé ọrẹ wọn.—Orin Dafidi 50:10, 14, 23.
18. Báwo ni a ṣe lè ran àwọn arákùnrin wa tí wọ́n wà nínú ìdààmú lọ́wọ́?
18 Àwa pẹ̀lú ní àǹfààní láti lo àwọn ohun àmúṣọrọ̀ wa láti ran àwọn ti ìjábá ti ìṣẹ̀dá dé bá àti àwọn wọnnì tí wọ́n ń gbé ní àwọn agbègbè tí ogun ti fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Ẹ wo bí a ti láyọ̀ tó láti kà nípa àwọn ìpèsè ìrànlọ́wọ́ tí a fi ránṣẹ́ sí Ìlà-Oòrùn Europe bí ìrugùdùsókè ti ọ̀ràn ìnáwó àti ti ìṣèlú ti ń jà rànyìn ní apá ibẹ̀ nínú ayé! Ọrẹ àwọn ohun tí ẹnu ń jẹ àti owó fi ìwà ọ̀làwọ́ àwọn arákùnrin wa àti ìsowọ́pọ̀ṣọ̀kan tí wọ́n ní fún àwọn Kristian tí nǹkan kò dánmọ́rán fún hàn.b—2 Korinti 8:13, 14.
19. Àwọn ohun gbígbéṣẹ́ wo ni a lè ṣe láti ran àwọn wọnnì tí ń bẹ nínú iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún lọ́wọ́?
19 A ní ìmọrírì gíga fún iṣẹ́ àwọn arákùnrin wa tí wọ́n ń kópa nínú iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà, alábòójútó arìnrìn-àjò, míṣọ́nnárì, àti olùyọ̀ǹda ara-ẹni ní Beteli, àbí a kò mọrírì rẹ̀? Bí àwọn àyíká ipò wa bá ti yọ̀ǹda sí, ó lè ṣeéṣe fún wa láti fún wọn ní àwọn ìrànlọ́wọ́ tààràtà díẹ̀ nípa ti ara. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí alábòójútó àyíká bá bẹ ìjọ yín wò, ó lè ṣeéṣe fún yín láti pèsè ilé ibùwọ̀, oúnjẹ, tàbí ìrànlọ́wọ́ nípa àwọn ìnáwó ìrìn-àjò rẹ̀. Bàbá wa ọ̀run ẹni tí ó fẹ́ kí a bójútó àwọn ìránṣẹ́ òun, ń pe àfiyèsí sí irú ìwà-ọ̀làwọ́ bẹ́ẹ̀. (Orin Dafidi 37:25) Ní àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn arákùnrin kan tí ó ṣeéṣe fún láti pèsè ìpápánu díẹ̀ késí alábòójútó arìnrìn-àjò kan pẹ̀lú aya rẹ̀ wá sí ilé rẹ̀. Nígbà tí tọkọtaya náà ń fi ibẹ̀ sílẹ̀ fún iṣẹ́-ìsìn pápá ti ìrọ̀lẹ́, arákùnrin náà nawọ́ àpòòwé kan sí àwọn àlejò rẹ̀. Sọ̀wédowó kan (tí ó dọ́gba pẹ̀lú dollar kan owó U.S.) wà nínú rẹ̀ pẹ̀lú ìwé kúkúrú kan tí ó fi ọwọ́ kọ pé: “Fún ife tìí kan tàbí gálọ́ọ̀nù epo bẹtiróò kan.” Ẹ wo bí èyí ti jẹ́ ìmọrírì rere tí a fihàn pẹ̀lú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tó!
20. Àǹfààní àti ẹrù-iṣẹ́ wo ni a kì yóò fẹ́ láti fi ojú tín-ín-rín?
20 Nípa tẹ̀mí, a ń bùkún fún àwọn ènìyàn Jehofa! A ń gbádùn àwọn àsè-ńlá nípa tẹ̀mí ní àwọn àpéjọ àti àpéjọpọ̀ wa, níbi tí a ti ń rí àwọn ìwé titun, ẹ̀kọ́ àtàtà, àti ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ gbà. Pẹ̀lú ọkàn-àyà tí ó kún fún ìmọrírì fún àwọn ìbùkún tẹ̀mí wa, àwa kò gbàgbé àǹfààní àti ẹrù-iṣẹ́ wa láti fi owó ṣètọrẹ fún lílò láti mú àǹfààní ire Ìjọba Ọlọrun gbòòrò sí i kárí-ayé.
‘Yan Àwọn Ọ̀rẹ́ Nípasẹ̀ Ọrọ̀ Àìṣòdodo’
21, 22. Kì ni yóò ṣẹlẹ̀ sí “ọrọ̀ àìṣòdodo” láìpẹ́, kí sì ni èyí ń béèrè pé kí a ṣe ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí?
21 Nítòótọ́, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀nà wà nípa èyí tí a ti lè fihàn pé ìjọsìn Jehofa ní ó wà ní ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí-ayé wa, ọ̀nà pàtàkì kan tí a lè gbà fi èyí hàn wémọ́ kíkọbiara sí ìmọ̀ràn Jesu pé: “Ẹ yan awọn ọ̀rẹ́ fún ara yín nípasẹ̀ ọrọ̀ àìṣòdodo, kí ó baà lè jẹ́ pé, nígbà tí irúfẹ́ bẹ́ẹ̀ bá kùnà, wọn yoo lè gbà yín sínú awọn ibi gbígbé àìnípẹ̀kun.”—Luku 16:9, NW.
22 Ṣàkíyèsí pe Jesu sọ̀rọ̀ nípa ìkùnà àwọn ọrọ̀ àìṣòdodo. Bẹ́ẹ̀ni, ọjọ́ náà yóò dé nígbà tí owó ètò-ìgbékalẹ̀ yìí yóò di aláìníláárí. Wòlíì Esekieli sọtẹ́lẹ̀ pé: “Wọn ó sọ fàdákà wọn sí ìgboro, wúrà wọn ni a óò sì mú kúrò; fàdákà wọn àti wúrà wọn kì yóò sì lè gbà wọ́n là ní ọjọ́ ìbínú Oluwa.” (Esekieli 7:19) Títí tí èyí yóò fi ṣẹlẹ̀, a gbọ́dọ̀ lo ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ nínú ọ̀nà tí a gba ń lo ọrọ̀-ìní wa nípa ti ara. Nípa báyìí àwa kì yóò bojúwẹ̀yìn kí a sì kábàámọ̀ nípa ìkìlọ̀ Jesu pé: “Bí ẹ̀yin kò bá tí ì fi ara yín hàn ní olùṣòtítọ́ ní ìsopọ̀ pẹlu ọrọ̀ àìṣòdodo, ta ni yoo fi ohun tí ó jẹ́ òótọ́ sí ìkáwọ́ yín? . . . Ẹ̀yin kò lè jẹ́ ẹrú fún Ọlọrun ati fún ọrọ̀.”—Luku 16:11-13, NW.
23. Kí ni a níláti lo pẹ̀lú ọgbọ́n, kí sì ni yóò jẹ́ èrè wa?
23 Nígbà náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa fi pẹ̀lú ìṣòtítọ́ kọbiara sí àwọn ìránnilétí wọ̀nyí láti fi ìjọsìn Jehofa sí ipò kìn-ín-ní nínú ìgbésí-ayé wa àti láti lo gbogbo ọrọ̀-ìní wa lọ́nà ọgbọ́n. Nípa báyìí yóò lè ṣeéṣe fún wa láti di ipò ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wa mú pẹ̀lú Jehofa àti Jesu, tí wọ́n ṣèlérí pé nígbà tí owó bá kùnà àwọn yóò gbà wá sínú “awọn ibi gbígbé àìnípẹ̀kun,” pẹ̀lú ìfojúsọ́nà fún ìye àyérayé yálà nínú Ìjọba tí òkè ọ̀run tàbí nínú paradise orí ilẹ̀-ayé.—Luku 16:9, NW.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀rọ̀ Heberu náà tí a túmọ̀ sí “ọrẹ” wá láti inú ọ̀rọ̀ìṣe kan tí ó túmọ̀ sí “ga; gbéga; gbé sókè” ní olówuuru.
b Wo ìwé Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom, ojú-ìwé 307 sí 315, tí a tẹ̀jáde ní 1993 láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Báwo ni àwọn ọmọ Israeli ṣe dáhùnpadà sí ìkésíni Jehofa láti ṣètọrẹ fún kíkọ́ àgọ́-ìsìn?
◻ Èéṣe tí ọrẹ opó náà kò fi jásí asán?
◻ Ẹrù iṣẹ́ wo ni ó já lé àwọn Kristian lórí níti ọ̀nà tí wọ́n ń gba lo àwọn ohun àmúsọrọ̀ wọn?
◻ Báwo ni a ṣe lè yẹra fún kíkábàámọ̀ nípa ọ̀nà tí a gba ń lo owó?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kéré, ọrẹ opó náà kò jásí asán
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Àwọn ọrẹ wa ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ Ìjọba náà kárí-ayé