Ǹjẹ́ Ọlọrun a Maa Fetisilẹ Nigba Ti Iwọ Bá Gbadura Bi?
Ọ̀GÁ PATAPATA kan a maa pinnu boya oun yoo yàn aṣoju fun ọ̀ràn kan tabi oun yoo bojuto o funra oun. Bakan naa, Oluṣakoso Ọba-Alaṣẹ agbaye ní anfaani yíyàn lati pinnu iwọn ti oun gbọdọ kówọnú ọ̀ràn eyikeyii mọ. Iwe Mimọ kọni pe Ọlọrun fúnraarẹ̀ ti yàn lati dásí awọn adura wa ati nitori naa ó paṣẹ fun wa lati dari iwọnyi si oun.—Saamu 66:19; 69:13.
Yíyàn Ọlọrun ninu ọ̀ràn yii ṣipaya ifẹ-ọkan oun fúnraarẹ̀ ninu adura awọn eniyan ti wọn jẹ́ iranṣẹ rẹ̀. Dipo kíkó irẹwẹsi bá awọn eniyan rẹ̀ lati maṣe wá sọdọ rẹ̀ pẹlu gbogbo èrò ati aniyan, ó gbà wọn niyanju pe: “Ẹ maa gbadura laisinmi,” “ẹ ni iforiti ninu adura,” “gbé ẹrù inira rẹ̀ ka Jehofa fúnraarẹ̀,” “kó gbogbo aniyan yin lé [Ọlọrun].”—1 Tẹsalonika 5:17; Roomu 12:12; Saamu 55:22; 1 Peteru 5:7, New World Translation (Gẹẹsi).
Bi Ọlọrun kò bá fẹ́ lati fi afiyesi sí adura awọn iranṣẹ rẹ̀, oun kì bá tí ṣeto fun iru ọ̀nà bẹẹ lati dé ọdọ rẹ̀ ki o sì tun funni niṣiiri lati lò ó ní fàlàlà. Nigba naa, yíyàn ti Ọlọrun yàn lati mú araarẹ̀ jẹ́ ẹni ti awọn eniyan rẹ̀ lè tọ̀ wá tobẹẹ yii, jẹ́ idi kan fun igbọkanle pe ó ń fetisilẹ niti tootọ. Bẹẹni, ó ń fun adura ọkọọkan ninu awọn iranṣẹ rẹ̀ ni afiyesi.
Ohun tí kò yẹ ní gbígbójú fòdá ni otitọ naa pe Bibeli sọ ni kedere pe Ọlọrun a maa fetisilẹ si adura. Fun apẹẹrẹ, apọsiteli Johanu, kọwe pe: “Eyi sì ni ìgboyà ti awa ni niwaju rẹ̀, pe bi awa bá beere ohunkohun gẹgẹ bi ifẹ rẹ̀, o ń gbọ́ tiwa.” (1 Johanu 5:14) Ọba Dafidi tọka si Jehofa Ọlọrun gẹgẹ bi ‘Olùgbọ́ adura’ ó sì fi igbọkanle tẹnumọ ọn pe: “Oun yoo sì gbóhùn mi.”—Saamu 55:17; 65:2.
Nitori naa nigba ti kò sí iyemeji pe gbigbadura ní awọn anfaani ninu araarẹ̀, Iwe Mimọ fihan pe ohun pupọ sii ni ó wémọ́ ọn nigba ti olododo kan bá gbadura. Ẹnikan ń fetisilẹ. Olufetisilẹ yẹn ni Ọlọrun.—Jakobu 5:16-18.
Awọn Adura Ti A Gbọ́
Bibeli kún fọ́fọ́ fun akọsilẹ awọn eniyan, ti a gbọ́ ti a sì dahun awọn adura wọn, lati ọdọ Ọlọrun nitootọ. Iriri wọn jẹ́rìí sí i kedere pe awọn anfaani adura lọ rekọja iyọrisi itọju iṣegun ti yíyọ̀rọ̀ ati sisọ awọn èrò ẹni jade. Wọn lọ rekọja awọn isapa àdáṣe ẹnikan ni ibamu pẹlu awọn adura rẹ̀.
Fun apẹẹrẹ, nigba ti ó dojukọ tẹmbẹlẹkun Abusalomu lati fi ipá gba ipo ọba Isirẹli, Ọba Dafidi gbadura pe: “Oluwa [“Jehofa,” NW], emi bẹ̀ ọ́, sọ ìmọ̀ Ahitofeli [agbani nimọran Abusalomu] di asan!” Kì í ṣe ibeere kekere, gẹgẹ bi o ti jẹ́ pe “ìmọ̀ Ahitofeli . . . dabi ẹni pe eniyan ń beere nǹkan ni ọwọ́ Ọlọrun: bẹẹ ni gbogbo ìmọ̀ Ahitofeli . . . rí.” Abusalomu lẹhin naa kọ amọran ọgbọn ìgbógun Ahitofeli fun gbigbajọba lọwọ Ọba Dafidi silẹ. Eeṣe? “Nitori Oluwa [“Jehofa,” NW] fẹ́ lati yí ìmọ̀ rere ti Ahitofeli po, nitori ki Oluwa [“Jehofa,” NW] kí ó lè mú ibi wá sori Abusalomu.” Ni kedere, adura Dafidi ni a gbọ́.—2 Samuẹli 15:31; 16:23; 17:14.
Lọna ti ó farajọra, lẹhin ti Hesekaya gbadura ẹ̀bẹ̀ si Ọlọrun fun idande kuro ninu ailera ti ó lè fa iku, ara rẹ̀ yá pada. Eyi ha wulẹ jẹ́ nitori awọn anfaani ti èrò-ọpọlọ fun Hesekaya gẹgẹ bi iyọrisi pe o ti gbadura bi? Bẹẹkọ, niti gidi! Ihin-iṣẹ Jehofa si Hesekaya, gẹgẹ bi wolii Aisaya ti fi jiṣẹ, ni pe: “Emi ti gbọ́ adura rẹ, emi sì ti rí omije rẹ: kiyesi i, emi yoo wò ọ́ sàn.”—2 Ọba 20:1-6.
Daniẹli, ẹni ti a dahun adura rẹ̀ lẹhin akoko ti oun ti lè reti, ni angẹli Jehofa mú ọrọ dá loju pe: “A gbọ́ ọrọ rẹ.” Adura awọn miiran, iru awọn wọnni bii ti Hannah, awọn ọmọ-ẹhin Jesu, ati Kọneliu ijoye ologun, ni a dahun ni awọn ọ̀nà ti a kò lè kà sí agbara òye eniyan nikan. Bibeli, nigba naa, kọni kedere pe awọn adura ti wọn wà ni ibamu pẹlu ifẹ-inu Ọlọrun ni Ọlọrun yoo gbà, gbọ́, tí yoo sì dahun.—Daniẹli 10:2-14; 1 Samuẹli 1:1-20; Iṣe 4:24-31; 10:1-7.
Ṣugbọn bawo ni Ọlọrun ṣe ń dahun adura awọn iranṣẹ rẹ̀ oluṣotitọ lonii?
Idahun si Awọn Adura
Awọn adura ti a tọka sí loke yii ni a dahun ni awọn ọ̀nà amúnijígìrì, ati oniṣẹ iyanu. Bi o ti wu ki o ri, jọwọ fi sọkan, pe ni awọn akoko ti a kọ Bibeli paapaa, awọn idahun lemọlemọ julọ si adura ni kò rọrun lati foye mọ. Eyi jẹ́ nitori pe wọn tan mọ fifun awọn iranṣẹ Ọlọrun ni okun nipa ilana iwahihu ati ilaloye, ti ń jẹ ki ó ṣeeṣe fun wọn lati dìrọ̀ mọ́ ipa-ọna ododo. Ni pataki fun awọn Kristẹni, idahun si awọn adura wémọ́ awọn ọ̀ràn ti ó jẹmọ tẹmi ni pataki, kì í ṣe awọn iṣarasihuwa ti ó jẹ́ mérìíyìírí tabi alagbara.—Kolose 1:9.
Nitori naa, maṣe jẹ ki a já ọ kulẹ bi a kìí bá dahun awọn adura rẹ̀ ni gbogbo ìgbà ni ọ̀nà ti o reti tabi fẹ́. Fun apẹẹrẹ, dipo ki ó mú adanwo naa kuro, Ọlọrun lè yàn lati fun ọ́ ni “agbara ti ó rekọja ohun ti ó wà níwọ̀n” lati faradà á. (2 Kọrinti 4:7, NW; 2 Timoti 4:17) Awa kò gbọdọ foju tín-ín-rín iniyelori iru agbara bẹẹ lae, bẹẹ ni a kò sì gbọdọ pari ero pe Jehofa kò dahun adura wa rárá niti gidi.
Gbé ọ̀ràn tí kì í ṣe ti ẹlomiran bikoṣe Ọmọkunrin Ọlọrun, Jesu Kristi yẹwo. Ninu aniyan rẹ̀ lati maṣe kú lọna ti yoo fi í han gẹgẹ bi abanilórúkọjẹ́, Jesu gbadura pe: “Baba, bi iwọ bá fẹ́, gba ago yìí lọwọ mi.” Njẹ adura yii ni Ọlọrun ha fi ojurere gbọ́ bi? Bẹẹni, gẹgẹ bi a ti jẹrii si i ni Heberu 5:7. Jehofa kò yọ Ọmọkunrin rẹ̀ kuro ninu aini naa lati kú lori òpó-igi ìdálóró. Kaka bẹẹ, “angẹli kan sì yọ sí i lati ọrun wá, ó ń gbà á niyanju.”—Luuku 22:42, 43.
Idahun amunijigiri, oniṣẹ iyanu ha ni bi? Fun ẹnikẹni ninu wa, bẹẹ ni yoo jẹ́! Ṣugbọn fun Jehofa Ọlọrun, orisun irú agbara bẹẹ, eyi kì í ṣe iṣẹ iyanu kankan. Jesu sì ti, dojulumọ pẹlu awọn apẹẹrẹ iṣẹlẹ ti ó ti kọja, lati ìgbà igbesi-aye rẹ̀ ijimiji ni ọrun nigba ti awọn angẹli farahan fun awọn eniyan. Nitori naa ifarahan angẹli kan kò lè ni ipa amunijigiri ti yoo ni lori wa lori rẹ̀. Sibẹ, angẹli yii, ẹni ti Jesu lọna ti o han gbangba mọ̀ fúnraarẹ̀ lati inu iwalaaye Rẹ̀ ṣaaju ki ó tó di eniyan, ṣeranwọ lati fun Un lokun fún adanwo ti o wà niwaju gan-an.
Ni didahun adura awọn iranṣẹ rẹ̀ oluṣotitọ lonii, leralera ni Jehofa ń funni ni okun ti a nilo lati farada. Itilẹhin yii lè jẹ́ lọ́nà ifunni niṣiiri lati ọdọ awọn olujọsin ẹlẹgbẹ ẹni ti a jọ mọwọ́ araawa daradara. Ẹnikẹni ninu wa yoo ha fẹ lati kọ iru iṣiri bẹẹ silẹ, boya ni pipari ero si pe niwọn bi o ti jẹ́ pe awọn iranṣẹ ẹlẹgbẹ wa kò tíì niriiri awọn adanwo ti ó farajọ tiwa, wọn kò sí ni ipo lati fun wa lokun bi? Jesu ìbá ti ni iru oju-iwoye bẹẹ gẹlẹ si angẹli ti ó farahan an. Kaka bẹẹ, ó tẹwọgba iṣiri naa gẹgẹ bi idahun Jehofa si adura rẹ̀ ó sì lè mú ifẹ-inu Baba rẹ̀ ṣẹ pẹlu iṣotitọ. Awa pẹlu yoo fẹ́ lati fi inurere tẹwọgba okun ti Ọlọrun fi funni ni idahun si awọn adura wa. Ranti, pẹlu, pe iru awọn sáà akoko ifarada onisuuru bẹẹ ni awọn ibukun ailonka maa ń tẹle niye ìgbà.—Oniwaasu 11:6; Jakobu 5:11.
Ni Igbọkanle Pe Ọlọrun Ń Fetisilẹ
Maṣe sọ igbọkanle ninu ìgbéṣẹ́ adura nù lae bi a kò bá dá ọ lohun loju ẹsẹ. Idahun si awọn adura kan, bi iru awọn wọnni ti wọn wà fun itura ti ara-ẹni kuro ninu inira tabi fun ìmúpọ̀ sii ẹru-iṣẹ ninu iṣẹ-isin ẹni si Ọlọrun, lè nilati duro di akoko ti Ọlọrun mọ̀ pe ó tọ́ ti ó sì dara julọ. (Luuku 18:7, 8; 1 Peteru 5:6) Bi iwọ bá ń gbadura nipa ọ̀ràn ara-ẹni kan ti ó jinlẹ, fi han Ọlọrun nipa itẹpẹlẹmọ rẹ pe ifẹ-ọkan rẹ múná, isunniṣe rẹ mọgaara ó sì jẹ́ ojulowo. Jakọbu fi ẹmi yii hàn nigba ti, lẹhin wíwọ̀jàkadì fun akoko kan pẹlu angẹli kan, ó sọ pe: “Emi kì yoo jẹ́ ki iwọ ki o lọ, bi kò ṣe pe iwọ bá súre fun mi.” (Jẹnẹsisi 32:24-32) A gbọdọ ni igbọkanle ti ó rí bakan naa pe bi a bá ń baa lọ ni bibeere, awa yoo rí ibukun gbà ni akoko ti ó yẹ.—Luuku 11:9.
Èrò kan ti ó gbẹhin. Lati rí etíìgbọ́ gbà lati ọdọ Ọba-Alaṣẹ agbaye jẹ́ anfaani ṣiṣeyebiye. Nitori eyi, awa ha ń fi tiṣọratiṣọra fetisilẹ nigba ti Jehofa Ọlọrun, nipasẹ Ọrọ rẹ̀, bá ń sọ awọn ohun abeerefun rẹ̀ fun wa bi? Bi awọn adura wa ti ń mú wa sunmọ Ẹlẹdaa wa pẹkipẹki sii, awa yoo fẹ́ lati fi afiyesi pataki si ohun gbogbo ti ó ní lati sọ fun wa.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ọlọrun ń fetisilẹ si awọn adura. Awa ha ń fetisilẹ sí i nipasẹ Ọrọ rẹ̀ bi?