Ara-ilu Tabi Àlejò, Ọlọrun Tẹwọgba Ọ́!
“Ó . . . dá lati inu ọkunrin kan olukuluku orilẹ-ede eniyan, lati gbé lori gbogbo oju ilẹ̀-ayé.”—IṢE 17:26, NW.
1. Ipo iṣoro wo ni ó wà ni ọpọlọpọ awọn ibi lonii niti titẹwọgba awọn eniyan ti wọn ti inú ẹgbẹ́ awujọ àjèjì wá?
ÀKÓJỌPỌ̀ awọn irohin fihan pe aniyan ń ga nipa awọn àlejò ni ọpọlọpọ ilẹ, awọn tí wọn ṣí wa lati ilu miiran, ati awọn olùwá-ibi-ìsádi. Araadọta-ọkẹ ni wọn gbékútà lati ṣí kuro ni apakan Asia, Africa, Europe, ati awọn ilu America. Boya wọn ń wá itura kuro ninu ipo òṣì apanirun patapata, ogun abẹ́lé, tabi inunibini. Ṣugbọn a ha tẹwọgba wọn nibomiran bi? Iwe irohin Time sọ pe: “Bi ìdàpọ̀mọ́ra ẹ̀yà ni Europe ti bẹrẹ sii yipada, awọn orilẹ-ede kan wá mọ̀ pe awọn kò ni ẹmi ìgbàmọ́ra fun awọn aṣa àjèjì bi awọn ti rò pe awọn ní nigba kan rí.” Ninu 18,000,000 awọn olùwá-ibi-ìsádi “ti a kò fẹ́,” iwe irohin Time sọ pe: “Ipenija ti wọn gbekalẹ fun awọn orilẹ-ede ti wọn duro deedee kò ni kuro.”
2, 3. (a) Idaniloju atunilara wo ni Bibeli pese ni isopọ pẹlu itẹwọgba? (b) Eeṣe ti a fi lè janfaani lati inu ṣiṣayẹwo ohun ti Iwe Mimọ gbekalẹ nipa ibalo Ọlọrun pẹlu awọn eniyan?
2 Ohun yoowu ki ó jẹ jade ni ọ̀nà yii, Bibeli fihan pe Ọlọrun tẹwọgba awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede—yala ẹnikan jẹ́ ojulowo ọmọ ibilẹ, ẹni ti ó ṣí wá lati ilu miiran, tabi olùwá-ibi-ìsádi kan. (Iṣe 10:34, 35) ‘Sibẹ,’ awọn kan lè beere pe, ‘bawo ni iwọ ṣe lè sọ iyẹn? Ọlọrun kò ha yan kiki Isirẹli igbaani gẹgẹ bi awọn eniyan rẹ̀, ti o sì pa awọn miiran tì?’
3 Ó dara, ẹ jẹ ki a wo bi Ọlọrun ṣe ba awọn eniyan igbaani lò. A tun lè ṣayẹwo awọn asọtẹlẹ kan ti ó tan mọ́ awọn anfaani ti ó wà larọọwọto fun awọn olujọsin tootọ lonii. Ṣiṣatunyẹwo akojọpọ-ọrọ alasọtẹlẹ yii lè sọ òye ti o tubọ kunrẹrẹ sii ti iwọ lè rí pe ó ń funni niṣiiri di mímọ̀. Ó funni ni itọka, pẹlu, nipa bi Ọlọrun ṣe lè bá awọn ẹnikọọkan “lati inu orilẹ-ede gbogbo, ati ẹ̀yà, ati eniyan, ati lati inu ede gbogbo wá” lò lẹhin ipọnju ńlá naa.—Iṣipaya 7:9, 14-17.
‘Awọn Orilẹ-Ede Yoo Bukun Araawọn’
4. Bawo ni iṣoro jíjẹ́ ọmọ orilẹ-ede kan ní pàtó ṣe gbèrú, ṣugbọn awọn igbesẹ wo ni Ọlọrun gbé?
4 Lẹhin Ìkún-Omi, idile Noa gan-an ni ó papọ jẹ́ gbogbo araye, gbogbo wọn sì jẹ́ olujọsin tootọ. Ṣugbọn iṣọkan yẹn yipada laipẹ. Laipẹ laijinna, awọn eniyan kan, ni dídágunlá sí ifẹ-inu Ọlọrun, bẹrẹ sii kọ́ ilé-ìṣọ́ kan. Eyi jálẹ̀ sí pínpín sí awujọ èdè ti ó di awọn eniyan ati orilẹ-ede fífọ́nká ti iran eniyan. (Jẹnẹsisi 11:1-9) Sibẹ, ijọsin tootọ ń baa lọ ni ìlà ti ó dé ọdọ Aburahamu. Ọlọrun bukun Aburahamu oluṣotitọ ó sì ṣeleri pe iru-ọmọ rẹ̀ yoo di orilẹ-ede ńlá. (Jẹnẹsisi 12:1-3) Orilẹ-ede yẹn ni Isirẹli igbaani.
5. Eeṣe ti gbogbo wa fi lè jere iṣiri lati inu awọn ìbálò Ọlọrun pẹlu Aburahamu?
5 Bi o ti wu ki o ri, Jehofa kò pa awọn eniyan miiran yatọ si Isirẹli tì, nitori pe ète rẹ̀ gbooro dé ọ̀dọ̀ gbogbo araye. A ri eyi kedere lati inu ohun ti Ọlọrun ṣeleri fun Aburahamu pe: “Ati ninu iru-ọmọ rẹ ni a o bukun fun gbogbo orilẹ-ede ayé: nitori ti iwọ ti gba ohùn mi gbọ́.” (Jẹnẹsisi 22:18) Bi o ti wu ki o ri, fun ọpọ ọrundun, Ọlọrun bá Isirẹli lò lọna akanṣe, ni fifun wọn ni akojọ Ofin orilẹ-ede kan, ṣiṣeto fun awọn alufaa lati ṣe awọn irubọ ninu tẹmpili rẹ̀, ati pipese Ilẹ Ileri ti wọn yoo gbé.
6. Bawo ni awọn iṣeto Ọlọrun pẹlu Isirẹli yoo ṣe ṣanfaani fun gbogbo wa?
6 Ofin Ọlọrun fun Isirẹli dara fun awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede niti pe ó mú ipo ẹṣẹ eniyan han gbangba, ni fifi aini naa hàn fun ẹbọ pipe lati bo ẹṣẹ eniyan mọ́lẹ̀ lẹẹkan ati fun gbogbo ìgbà. (Galatia 3:19; Heberu 7:26-28; 9:9; 10:1-12) Sibẹ, idaniloju wo ni ó wà nibẹ pe Iru-Ọmọ Aburahamu—nipasẹ ẹni ti gbogbo orilẹ-ede yoo bukun araawọn—yoo dé ti yoo sì doju ìlà ìtóótun naa? Ofin Isirẹli ṣeranwọ nihin-in pẹlu. Ó ka ìjọṣègbéyàwó pẹlu awọn ara Kenani léèwọ̀, awọn eniyan ti wọn lókìkí buruku fun awọn àṣà ati ààtò isin oniwa palapala, iru bii àṣà jíjó awọn ọmọde lóòyẹ̀. (Lefitiku 18:6-24; 20:2, 3; Deutaronomi 12:29-31; 18:9-12) Ọlọrun paṣẹ pe awọn ati awọn àṣà wọn ni a nilati mú kuro patapata. Iyẹn wà fun anfaani alakooko pípẹ́ fun gbogbo eniyan, titikan àtìpó olùgbé, bi ó ti jẹ pe yoo ṣiṣẹ lati pa ìlà Iru-Ọmọ naa mọ́ kuro ninu didi eyi ti a sọ dibajẹ.—Lefitiku 18:24-28; Deutaronomi 7:1-5; 9:5; 20:15-18.
7. Itọka ijimiji wo ni ó wà pe Ọlọrun tẹwọgba awọn àlejò?
7 Kódà nigba ti Ofin wà lẹnu iṣẹ ti Ọlọrun sì wo Isirẹli gẹgẹ bi akanṣe, ó fi aanu han si awọn ti wọn kì í ṣe ọmọ Isirẹli. Imuratan rẹ̀ lati ṣe bẹẹ ni a ti fihan nigba ti Isirẹli yan jade kuro ninu ìdè ìsìnrú Ijibiti siha ilẹ tirẹ fúnraarẹ̀. “Ọpọ eniyan ti ó dàpọ̀ mọ wọn bá wọn goke lọ pẹlu.” (Ẹkisodu 12:38) Ọjọgbọn C. F. Keil fi awọn wọnni han gẹgẹ bi “ọ̀pọ̀ bí eṣú awọn àlejò . . . ìkójọpọ̀ oniruuru eniyan, tabi ogunlọgọ awọn eniyan orilẹ-ede ọtọọtọ.” (Lefitiku 24:10; Numeri 11:4) Ó ṣeeṣe ki ọpọlọpọ jẹ́ awọn ọmọ Ijibiti ti wọn gba Ọlọrun tootọ naa.
Ìtẹ́wọ́gbà fun Awọn Àlejò
8. Bawo ni awọn ará Gibioni ṣe ri àyè kan laaarin awọn eniyan Ọlọrun?
8 Bi Isirẹli ti ń mú aṣẹ Ọlọrun ṣẹ lati nu awọn orilẹ-ede oniwa ibajẹ nù kuro ni Ilẹ Ileri naa, ó daabobo awujọ awọn alejo kan, awọn ara Gibioni, ti wọn ń gbé ni ariwa Jerusalẹmu. Wọn rán awọn ikọ̀ ti wọn dọ́gbọ́n paradà sí Joṣua, ni bibẹbẹ fun ati jijere alaafia. Nigba ti wọn jádìí ọgbọn arúmọjẹ ti wọn lò, Joṣua paṣẹ pe awọn ará Gibioni yoo ṣiṣẹsin gẹgẹ bi “aṣẹ́gi ati apọnmi fun ìjọ, ati fun pẹpẹ Oluwa [“Jehofa,” NW].” (Joṣua 9:3-27) Lonii ọpọlọpọ awọn olùṣíwọnú ilu miiran gba ipo iṣẹ-isin rirẹlẹ pẹlu ki wọn baa lè di apakan awọn eniyan titun.
9. Bawo ni apẹẹrẹ Rahabu ati idile rẹ̀ ṣe jẹ́ eyi ti ń funni niṣiiri niti awọn àlejò ní Isirẹli?
9 Ó lè fun ọ niṣiiri lati mọ pe ìtẹ́wọ́gbà Ọlọrun ki i wulẹ ṣe fun awujọ awọn alejo nigba naa lọ́hùn-ún nikan; awọn eniyan ti ń dánìkan gbé ni a tẹwọgba pẹlu. Lonii awọn orilẹ-ede kan tẹwọgba kìkì awọn ti wọn ṣí wá lati ilu miiran ti wọn ni ipo lawujọ, ọrọ̀ lati fi dókòwò, tabi ìmọ̀-ẹ̀kọ́ giga ju. Kì í ṣe bẹẹ pẹlu Jehofa, gẹgẹ bi a ti rí i lati inu iṣẹlẹ kan ni kété ṣaaju apejuwe iṣẹlẹ ti o wáyé pẹlu awọn ará Gibioni. Eyi wémọ́ ará Kenani kan ti ó daju pe kì í ṣe onipo giga lawujọ. Bibeli pè é ni “Rahabu panṣaga.” Nitori igbagbọ rẹ̀ ninu Ọlọrun tootọ, oun ati agbo ile rẹ̀ ni a danide nigba ti Jẹriko ṣubu. Bi o tilẹ jẹ pe Rahabu jẹ́ alejo, awọn ọmọ Isirẹli gbà á. Ó jẹ́ awokọṣe igbagbọ ti o yẹ fun wa lati farawe. (Heberu 11:30, 31, 39, 40; Joṣua 2:1-21; 6:1-25) Ó tilẹ di ìyáńlá Mesaya naa.—Matiu 1:5, 16.
10. Gbígba awọn àlejò ni Isirẹli sinmi lori ki ni?
10 Awọn ti wọn kì í ṣe ọmọ Isirẹli ni a tẹwọgba ninu Ilẹ Ileri ni ibamu pẹlu isapa wọn lati tẹ́ Ọlọrun lọrun. Awọn ọmọ Isirẹli ni a sọ fun lati maṣe kẹgbẹpọ, ni pataki lọna ti isin, pẹlu awọn wọnni ti wọn kò ṣiṣẹsin Jehofa. (Joṣua 23:6, 7, 12, 13; 1 Ọba 11:1-8; Owe 6:23-28) Sibẹ ọpọ awọn olùṣe àtìpó ti wọn kì í ṣe ọmọ Isirẹli ṣegbọran si awọn ofin ipilẹ naa. Awọn miiran tilẹ di aláwọ̀ṣe ti a kọ nílà, Jehofa sì tẹwọgba wọn patapata gẹgẹ bi mẹmba ìjọ rẹ̀.—Lefitiku 20:2; 24:22; Numeri 15:14-16; Iṣe 8:27.a
11, 12. (a) Ki ni ìbálò awọn ọmọ Isirẹli nilati jẹ́ pẹlu awọn àlejò olùjọsìn? (b) Eeṣe ti aini fi lè wà pé ki a sunwọ̀n sii ninu titẹle apẹẹrẹ Jehofa?
11 Ọlọrun dari awọn ọmọ Isirẹli lati ṣafarawe iṣarasihuwa rẹ̀ siha awọn alejo olujọsin pe: “Ki àlejò ti ń bá yin gbé kí ó jasi fun yin bi ibilẹ, ki iwọ ki o sì fẹ́ ẹ bi ara rẹ; nitori pe ẹyin ti ṣe àlejò ni ilẹ Ijibiti.” (Lefitiku 19:33, 34; Deutaronomi 1:16; 10:12-19) Eyi pese ẹ̀kọ́ kan fun wa, ani bi o tilẹ jẹ pe a kò si labẹ Ofin. Ó rọrun lati juwọsilẹ fun ẹ̀tanú ati ẹmi àìbániṣọ̀rẹ́ siha awọn wọnni ti wọn wá lati inu iran, orilẹ-ede, tabi àṣà miiran. Nitori naa a ṣe daradara lati beere pe: ‘Mo ha ń gbiyanju lati mú iru awọn ẹ̀tanú bẹẹ kuro lara mi, ni titẹle apẹẹrẹ Jehofa bi?’
12 Awọn ọmọ Isirẹli ní ẹ̀rí ti ó ṣee fojuri ti itẹwọgba Ọlọrun. Ọba Solomọni gbadura pe: “Niti àlejò, ti kì í ṣe ti inu Isirẹli eniyan rẹ, ṣugbọn ti o ti ilẹ okeere jade wá nitori orukọ rẹ, . . . nigba ti oun yoo wa, ti yoo sì gbadura si ìhà ile yii; iwọ gbọ́ ni ọrun, . . . ki gbogbo ayé ki o lè mọ orukọ rẹ, ki wọn ki o lè maa bẹru rẹ.”—1 Ọba 8:41-43; 2 Kironika 6:32, 33.
13. Eeṣe ti Ọlọrun fi ṣeto lati yí awọn ìbálò rẹ̀ pẹlu Isirẹli pada?
13 Nigba ti Jehofa ṣì ń lo orilẹ-ede Isirẹli gẹgẹ bi awọn eniyan rẹ̀ tí ó sì ń tipa bẹẹ pa ìlà iran Mesaya mọ́, Ọlọrun sọ asọtẹlẹ awọn iyipada pataki. Ni iṣaaju, nigba ti Isirẹli gbà lati wà ninu majẹmu Ofin, Ọlọrun yọnda pe wọn lè jẹ́ orisun “ijọba alufaa . . . ati orilẹ-ede mimọ.” (Ẹkisodu 19:5, 6) Ṣugbọn Isirẹli fi aiṣotitọ hàn fun ọpọ ọrundun. Nitori naa Jehofa sọtẹlẹ pe oun yoo dá majẹmu titun kan labẹ eyi ti a o ti dárí aṣiṣe ati ẹṣẹ awọn wọnni ti wọn papọ jẹ́ “ile Isirẹli” jì wọn. (Jeremaya 31:33, 34) Majẹmu titun yẹn duro de Mesaya, irubọ ẹni ti yoo wẹ ọpọlọpọ nù kuro ninu ẹṣẹ niti gidi.—Aisaya 53:5-7, 10-12.
Awọn Ọmọ Isirẹli ni Ọrun
14. “Isirẹli” titun wo ni Jehofa tẹwọgba, Bawo sì ni?
14 Iwe Mimọ Kristẹni lede Giriiki ràn wá lọwọ lati loye bi a ṣe ṣaṣepari gbogbo eyi. Jesu ni Mesaya, ẹni ti iku rẹ̀ mú Ofin ṣẹ ti ó sì fi ipilẹ lélẹ̀ fun idariji ẹṣẹ ni kíkún. Lati jere anfaani yẹn, ẹnikan kò nilati jẹ́ Juu ti a kọ ní ilà ninu ara. Bẹẹkọ. Apọsiteli Pọọlu kọwe pe ninu majẹmu titun, “oun ni Juu ẹni ti o jẹ ọ̀kan ni inu lọhun-un, ìkọlà rẹ̀ sì jẹ ti ọkan-aya nipa ẹmi, ki i sii ṣe nipa iwe akojọ ofin.” (Roomu 2:28, 29, NW; 7:6) Awọn wọnni ti wọn ni igbagbọ ninu ẹbọ Jesu jere idariji, Ọlọrun sì tẹwọgba wọn gẹgẹ bii ‘Juu nipa ẹmi,’ ti o parapọ di orilẹ-ede tẹmi ti a ń pè ni “Isirẹli Ọlọrun.”—Galatia 6:16.
15. Eeṣe ti jijẹ ọmọ orilẹ-ede kan pàtó niti ara kò fi jẹ́ koko kan ninu jijẹ apakan Isirẹli tẹmi?
15 Bẹẹni, didi ẹni ti a tẹwọgba sinu Isirẹli tẹmi kò sinmi lori ipilẹ ti orilẹ-ede tabi ti ẹ̀yà iran kan bayii. Awọn kan, iru bii awọn apọsiteli Jesu, jẹ́ awọn Juu nipa ti ara. Awọn miiran, iru bii Kọneliu ijoye oṣiṣẹ ologun Roomu, jẹ́ awọn Keferi alaikọla. (Iṣe 10:34, 35, 44-48) Pọọlu sọ lọna ti ó tọna nipa Isirẹli tẹmi pe: “Kò lè sí Giriiki ati Juu, ìkọlà ati àìkọ̀là, aláìgbédè, ará Sikitia, ẹrú ati ominira.” (Kolose 3:11) Awọn wọnni ti a fẹmi Ọlọrun yàn di “iran ti a yàn, olú alufaa, orilẹ-ede mimọ, eniyan ọ̀tọ̀.”—1 Peteru 2:9; fiwe Ẹkisodu 19:5, 6.
16, 17. (a) Ipa wo ni awọn Isirẹli tẹmi ní ninu ète Ọlọrun? (b) Eeṣe ti o fi jẹ́ ohun yiyẹ lati gbé awọn wọnni ti wọn kì í ṣe ti Isirẹli Ọlọrun yẹwo?
16 Ọjọ-ọla wo ni Isirẹli tẹmi ní ninu ète Ọlọrun? Jesu dahun pe: “Má bẹru, agbo kekere; nitori didun inu Baba yin ni lati fi ijọba fun yin.” (Luuku 12:32) Awọn ẹni ami ororo, tí ‘ilu-ibilẹ wọn ń bẹ ni ọrun,’ yoo jẹ́ ajumọ jogun pẹlu Ọdọ-Agutan naa ninu iṣakoso Ijọba rẹ̀. (Filipi 3:20; Johanu 14:2, 3; Iṣipaya 5:9, 10) Bibeli tọka sii pe awọn wọnyi ni a ‘fi èdídí dí lati inu awọn ọmọkunrin Isirẹli wá’ ti a sì “rà . . . lati aarin araye bi awọn eso akọso fun Ọlọrun ati fun Ọdọ-Agutan naa.” Iye wọn jẹ́ 144,000. Bi o ti wu ki o ri, lẹhin fifunni ni akọsilẹ iye ti a fi èdídí dí yii, Johanu fi awujọ miiran hanni—“ogunlọgọ ńlá kan, ti eniyan kankan kò lè kaye, lati inu gbogbo awọn orilẹ-ede ati ẹ̀yà ati eniyan ati ahọ́n.”—Iṣipaya 7:4, 9; 14:1-4, NW.
17 Awọn kan lè ṣe kayefi pe: ‘Ki ni nipa araadọta-ọkẹ ti wọn kì í ṣe apakan Isirẹli tẹmi, bii iru awọn wọnni ti wọn lè la ipọnju ńlá já gẹgẹ bi ogunlọgọ ńlá? Ipa wo ni wọn ní lonii ní isopọ pẹlu iwọnba diẹ ti ó ṣẹ́kù ninu Isirẹli tẹmi?’b
Awọn Àlejò Ninu Asọtẹlẹ
18. Ki ni ó ṣamọna si pipada Isirẹli lati igbekun Babiloni?
18 Ni yiyiju pada si akoko naa nigba ti Isirẹli wà labẹ majẹmu Ofin ṣugbọn tí wọn jẹ́ alaiṣootọ si i, a ri i pe Ọlọrun pinnu lati jẹ́ ki awọn ará Babiloni sọ Isirẹli dahoro. Ni 607 B.C.E., Isirẹli ni a kó lọ sí oko-ẹrú fun 70 ọdun. Lẹhin naa Ọlọrun ra orilẹ-ede naa pada. Labẹ ipo aṣiwaju Gomina Serubabeli, aṣẹku Isirẹli ti ara kan ni a mú pada si ilẹ wọn. Awọn oluṣakoso awọn ará Mẹdia ati Paṣia, ti wọn ti gbàjọba Babiloni, tilẹ ṣetilẹhin fun awọn igbekun pẹlu awọn ipese. Iwe Aisaya sọ asọtẹlẹ awọn idagbasoke wọnyi. (Aisaya 1:1-9; 3:1-26; 14:1-5; 44:21-28; 47:1-4) Ẹsira sì fun wa ni awọn kulẹkulẹ onítàn nipa ipada yẹn.—Ẹsira 1:1-11; 2:1, 2.
19. Ni isopọ pẹlu ipada Isirẹli, itọka alasọtẹlẹ wo ni ó wà nibẹ pe yoo ní awọn àlejò ninu?
19 Sibẹ, ni sisọ asọtẹlẹ irapada ati ipada awọn eniyan Ọlọrun naa, Aisaya sọ asọtẹlẹ ayanilẹnu lojiji yii: “Awọn keferi [“orilẹ-ede,” NW] yoo wá sí imọlẹ rẹ, ati awọn ọba si títàn yiyọ rẹ.” (Aisaya 59:20; 60:3) Eyi tumọsi ju pe awọn àlejò kọọkan ni a tẹwọgba, ni ìlà pẹlu adura Solomọni. Aisaya ń tọka si iyipada ti ó ṣajeji kan ninu ipo. “Awọn orilẹ-ede” yoo ṣiṣẹsin pẹlu awọn ọmọkunrin Isirẹli: “Awọn ọmọ àlejò yoo sì mọ odi rẹ: awọn ọba wọn yoo ṣe iranṣẹ fun ọ: nitori ni ikannu mi ni mo lù ọ́, ṣugbọn ni inu rere mi ni mo sì ṣaanu fun ọ.”—Aisaya 60:10.
20, 21. (a) Ibaradọgba wo ni a rí ni akoko ode-oni pẹlu ipada Isirẹli lati oko-ẹrú? (b) Bawo ni a ṣe fi ‘awọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin’ kun Isirẹli tẹmi lẹhin-ọ-rẹhin?
20 Ni ọpọlọpọ ọ̀nà, lilọ si ati pipada Isirẹli lati igbekun ti wá ri ìbádọ́gba kan ninu Isirẹli tẹmi ni akoko ode-oni. Ṣaaju Ogun Agbaye I, aṣẹku awọn Kristẹni ẹni ami ororo ni wọn kò sí ni ìlà ní kikun pẹlu ifẹ-inu Ọlọrun; wọn di awọn oju-iwoye ati iṣe-aṣa ti wọn gbé wá lati inu ṣọọṣi Kristẹndọmu mú. Lẹhin naa, lakooko ìgbónára eléwèlè ogun ati lapakan nitori ti awujọ alufaa beere fun un, awọn aṣaaju laaarin aṣẹku Isirẹli tẹmi ni a fi sẹ́wọ̀n lọna ti kò bá idajọ ododo mu. Lẹhin ogun naa, ni 1919 C.E., awọn ẹni ami ororo wọnni ti wọn wà ninu ẹwọn niti gidi ni a dasilẹ ti a sì dalare. Eyi jẹrii si i pe awọn eniyan Ọlọrun ni a tusilẹ kuro ninu oko-ẹrú Babiloni Ńlá, ilẹ-ọba isin èké agbaye. Awọn eniyan rẹ̀ jade lọ lati kọ́ ki wọn sì gbé inu paradise tẹmi kan.—Aisaya 35:1-7; 65:13, 14.
21 Eyi ni a fihan ninu apejuwe Aisaya: “Gbogbo wọn ṣa ara wọn jọ pọ̀, wọn wá sọdọ rẹ: awọn ọmọ rẹ ọkunrin yoo ti ọ̀nà jijin wá, a o sì tọju awọn ọmọ rẹ obinrin ni ẹ̀gbẹ́ rẹ. Nigba naa ni iwọ yoo ri, oju rẹ yoo sì mọlẹ, ọkàn rẹ yoo si wariri, yoo sì di ńlá: nitori a o yi ọrọ̀ òkun pada si ọ, ipá awọn keferi [“orilẹ-ede,” NW] yoo wá sọdọ rẹ.” (Aisaya 60:4, 5) Ni awọn ẹ̀wádún ti ó tẹle e, ‘awọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin’ ń ba a lọ lati wọle, ni jíjẹ́ ẹni ti a fi ẹmi yàn lati kún àlàfo àyè ti o kẹhin ninu Isirẹli tẹmi.
22. Bawo ni “awọn àlejò” ṣe wá lati ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn Isirẹli tẹmi?
22 Ki ni nipa ti ‘awọn àlejò ti yoo mọ awọn odi rẹ’? Eyi pẹlu ti ṣẹlẹ ni akoko wa. Bi ìkésíni awọn 144,000 ti ń wá si opin, ogunlọgọ ńlá lati inu gbogbo awọn orilẹ-ede bẹrẹ sii rọ́ gìrìgìrì wá lati jọsin pẹlu Isirẹli tẹmi. Awọn ẹni titun wọnyi ní ireti ti a gbekari Bibeli ti ìyè ainipẹkun lori paradise ilẹ̀-ayé. Bi o tilẹ jẹ pe ọgangan àyè iṣẹ-isin oluṣotitọ wọn yoo yatọ, ó dùn mọ wọn ninu lati ran aṣẹku ẹni ami ororo lọwọ ninu wiwaasu ihinrere Ijọba naa.—Matiu 24:14.
23. Dé iwọn àyè wo ni “awọn àlejò” ti ran awọn ẹni ami ororo lọwọ?
23 Lonii, iye ti o ju 4,000,000 ti wọn jẹ́ “awọn àlejò,” papọ pẹlu awọn wọnni ti ‘ilu ibilẹ wọn wà ni ọ̀run,’ ń fi ẹ̀rí ifọkansin wọn si Jehofa han. Ọpọlọpọ ninu wọn, lọkunrin ati lobinrin, lọmọde ati lágbà, ń ṣiṣẹsin ninu iṣẹ-ojiṣẹ alakooko kikun gẹgẹ bi aṣaaju-ọna. Ni eyi ti o pọ julọ ninu iye awọn ìjọ ti o ju 66,000 lọ, iru awọn àlejò bẹẹ ń gbé ẹru-iṣẹ gẹgẹ bi alagba ati iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ. Awọn aṣẹku yọ̀ ninu eyi, ni rírí imuṣẹ awọn ọrọ Aisaya pe: “Awọn àlejò yoo sì duro, wọn ó sì bọ́ ọ̀wọ́ ẹran yin, awọn ọmọ àlejò yoo sì ṣe atúlẹ̀ yin, ati olùrẹ́ ọwọ́ àjàrà yin.”—Aisaya 61:5.
24. Eeṣe ti a fi lè fun wa niṣiiri nipa ìbálò Ọlọrun pẹlu Isirẹli ati awọn miiran ni ìgbà atijọ?
24 Nitori naa ninu orilẹ-ede yoowu lori ilẹ̀-ayé ti iwọ ti jẹ́ ọmọ-ibilẹ, ti wọn ṣí wá lati ilu miiran, tabi olùwá-ibi-ìsádi, iwọ ni anfaani ńláǹlà naa lati di àlejò tẹmi ẹni ti Olodumare fi tọkantọkan tẹwọgba. Itẹwọgba rẹ̀ ní ninu ṣiṣeeṣe naa lati gbadun awọn anfaani ninu iṣẹ-isin nisinsinyi ati wọnu ọjọ-ọla àìnípẹ̀kun.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Niti awọn iyatọ laaarin “àlejò olùgbé,” “àtìpó,” “àjèjì,” ati “àlejò,” wo Insight on the Scriptures, Idipọ 1, oju-iwe 72 si 75, 849 si 851, ti a tẹjade lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
b Iye ti o ju 10,600,000 wá si iṣe-iranti ọdọọdun ti Ounjẹ Alẹ́ Oluwa tí Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe ni 1991, ṣugbọn kiki 8,850 ni wọn jẹwọ jíjẹ́ ti aṣẹku Isirẹli tẹmi.
Iwọ Ha Ṣakiyesi Eyi Bi?
◻ Bawo ni Ọlọrun ṣe pese ireti pe awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede ni Oun yoo tẹwọgba?
◻ Ki ni o fihan pe awọn eniyan miiran yatọ si Isirẹli, awọn akanṣe eniyan fun Ọlọrun, lè wá sọdọ Rẹ̀?
◻ Ninu asọtẹlẹ, bawo ni Ọlọrun ṣe tọka pe awọn àlejò yoo da araawọn pọ mọ Isirẹli?
◻ Ki ni o ti baradọgba pẹlu ipada Isirẹli lati igbekun ni Babiloni, bawo sì ni o ṣe di eyi ti o ní “awọn àlejò” ninu?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ọba Solomọni gbadura nipa awọn àlejò ti wọn yoo wá lati jọsin Jehofa