Ìwọ Yóò Ha Ti Dá Mèsáyà náà Mọ̀ Bí?
JÉSÙ KRISTI lo ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ ní wíwàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ṣùgbọ́n nígbà tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní orí ilẹ̀ ayé yóò fi parí, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn alájọgbáyé rẹ̀ ti kọ̀ ọ́ gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà, tàbí gẹ́gẹ́ bí “Ẹni Àmì Òróró” tí Ọlọ́run ṣèlérí. Èé ṣe?
Bíbélì ràn wá lọ́wọ́ láti mọ àwọn ìdí díẹ̀ tí àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní kò fi gba Jésù gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà. Mẹ́ta nínú àwọn ìdí wọ̀nyí ń dènà jíjẹ́ kí ọ̀pọ̀ tẹ́wọ́ gba ipò tí Jésù wà lónìí gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà Ọba tí ń ṣàkóso.
“Àwá Fẹ́ Rí Àmì”
Ìdí kan tí àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní kò fi dá Mèsáyà náà mọ̀ ni pé wọ́n kọ̀ láti tẹ́wọ́ gba àwọn àmì Ìwé Mímọ́ tí ń tọ́ka sí ipò jíjẹ́ Mèsáyà rẹ̀. Látìgbàdégbà, àwọn ènìyàn tí ń tẹ́tí sí Jésù béèrè pé kí ó ṣiṣẹ́ àmì láti fẹ̀rí hàn pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ó ti wá. Fún àpẹẹrẹ, Mátíù 12:38 ròyìn pé àwọn kan lára àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí wí pé: “Olùkọ́, àwá fẹ́ rí àmì kan láti ọ̀dọ̀ rẹ.” Jésù kò ha ti fi àmì hàn wọ́n tẹ́lẹ̀ bí? Dájúdájú, ó ti ṣe bẹ́ẹ̀.
Ní àkókò yẹn, Jésù ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu mélòó kan sẹ́yìn. Ó ti sọ omi di ọtí wáìnì, ó ti mú ọmọkùnrin kan tí ń kú lọ lára dá, ó ti wo ìyá ìyàwó Pétérù tí ń ṣàìsàn sàn, ó ti sọ ọkùnrin kan tí ó jẹ́ adẹ́tẹ̀ di mímọ́, ó ti mú kí ọkùnrin kan tí ó jẹ́ alárùn ẹ̀gbà rìn, ó ti dá ìlera ọkùnrin kan tí ó ti ṣàìsàn fún ọdún 38 padà, ó ti mú kí apá ọkùnrin kan, tí ó ti rọ padà sípò, ó ti tú ọ̀pọ̀ ènìyàn sílẹ̀ kúrò nínú àrùn wọn tí ń roni lára, ó ti mú ẹrú olóyè ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan lára dá, ó ti mú ọmọkùnrin opó kan padà láti inú ikú, ó sì ti wo ọkùnrin kan tí ó fọ́jú, tí kò sì lè sọ̀rọ̀ sàn. Àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ ní Kánà, Kápánáúmù, Jerúsálẹ́mù, àti Náínì. Ní àfikún sí i, ìròyìn nípa irú àwọn iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀ tàn kálẹ̀ jákèjádò Jùdíà àti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí i ká.—Jòhánù 2:1-12; 4:46-54; Mátíù 8:14-17; 8:1-4; 9:1-8; Jòhánù 5:1-9; Mátíù 12:9-14; Máàkù 3:7-12; Lúùkù 7:1-10; 7:11-17; Mátíù 12:22.
Ní kedere, kò sí pé àmì kò tó láti fẹ̀rí hàn pé Jésù ni Mèsáyà náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó ṣe ọ̀pọ̀ jaburata iṣẹ́ àmì níwájú àwọn ènìyàn náà, wọn kò lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. Àwọn tí ó rí ẹ̀rí náà pé Ọlọ́run ni ó rán Jésù, ṣùgbọ́n tí wọn kò tẹ́wọ́ gbà á gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà fọ́jú nípa tẹ̀mí. Ọkàn-àyà wọn yigbì, kò sì lè gba òtítọ́ wọlé.—Jòhánù 12:37-41.
Ọjọ́ wa ńkọ́? Àwọn kan máa ń pòkìkí pé, “Ohun tí ojú mi bá rí nìkan ni mo gbà gbọ́.” Ṣùgbọ́n, ìyẹ́n ha jẹ́ ọ̀nà ọgbọ́n láti tọ̀ bí? Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé a ti gbé Jésù gorí ìtẹ́ ná, gẹ́gẹ́ bí Ọba ti ọ̀run nínú Ìjọba Mèsáyà. Níwọ̀n bí òún ti jẹ́ àìleèrí, a nílò àmì tí yóò jẹ́ kí a fòye mọ ìṣàkóso rẹ̀, tí ó sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú yìí. Ìwọ́ ha mọ àmì náà bí?—Mátíù 24:3.
Ní ìbámu pẹ̀lú Bíbélì, ìbẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso Kristi gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà Ọba ni ogun, ìmìtìtì ilẹ̀, àìtó oúnjẹ, àti àjàkálẹ̀ àrùn lọ́nà tí irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí, yóò sàmì sí. Ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” àjọṣepọ̀ ẹ̀dá ènìyàn ní a óò fi ìmọtara-ẹni-nìkan, ojú kòkòrò, àti àìní ìkóra-ẹni-níjàánu dá mọ̀. (Tímótì Kejì 3:1-5; Mátíù 24:6, 7; Lúùkù 21:10, 11) Yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀rí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀, èyí tí ó ju apá 20 ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nípa ọjọ́ ìkẹyìn ń tọ́ka sí ìbẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso Mèsáyà ní 1914.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà, March 1, 1993, ojú ìwé 5.
“Olùfẹ́ Owó”
Ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì ni ìdí mìíràn tí àwọn Júù fi kọ Jésù gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà náà. Kíka ọrọ̀ sí bàbàrà ṣèdíwọ́ fún ọ̀pọ̀ láti tẹ̀ lé Jésù. Fún àpẹẹrẹ, a mọ àwọn Farisí fún jíjẹ́ “olùfẹ́ owó.” (Lúùkù 16:14) Ronú ná nípa ọ̀ràn ọ̀dọ́mọdé alákòóso kan, tí ó jẹ́ ọlọ́rọ̀, tí ó tọ Jésù lọ tí ó sì béèrè bí òún ṣe lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. Jésù fèsì pé: “Máa pa àwọn àṣẹ mọ́ nígbà gbogbo.” Ọ̀dọ́kùnrin náà béèrè pé: “Mo ti pa gbogbo ìwọ̀nyí mọ́; kí ni mo ṣaláìní síbẹ̀?” ìbéèrè rẹ̀ fi hàn pé ó mọ̀ pé a nílò ju pípa àwọn òfin kan mọ́. Jésù wí fún un pé: “Ta àwọn nǹkan ìní rẹ kí o sì fi fún àwọn òtòṣì ìwọ yóò sì ní ìṣúra ní ọ̀run, sì wá di ọmọlẹ́yìn mi.” Ẹ wo àǹfààní tí ó jẹ́—láti jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Mèsáyà náà! Síbẹ̀, alákòóso náà bá tirẹ̀ lọ, ẹ̀dùn ọkàn sì bá a. Èé ṣe? Nítorí pé ìṣúra lórí ilẹ̀ ayé ṣe pàtàkì fún un ju ìṣúra ní ọ̀run.—Mátíù 19:16-22.
Ipò náà kò tí ì yí padà. Dídi ojúlówó ọmọlẹ́yìn Mèsáyà Ọba náà túmọ̀ sí fífi àwọn ire tẹ̀mí ṣáájú ohun gbogbo mìíràn, títí kan àwọn ohun ìní ti orí ilẹ̀ ayé. Fún ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, ìpèníjà kan nì èyí jẹ́. Fún àpẹẹrẹ, tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì ní ilẹ̀ Ìlà Oòrùn kan bá obìnrin kan sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Níwọ̀n bí wọ́n ti gbà gbọ́ pé yóò fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọkùnrin rẹ̀, Jésù Kristi, tọkọtaya náà fi Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọ̀ ọ́. Báwo ni ó ṣe hùwà padà? Ó béèrè pé: “Ṣé àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí yóò ràn mí lọ́wọ́ láti ní owó sí i?” Obìnrin náà lọ́kàn ìfẹ́ nínú ọrọ̀ àlùmọ́nì ju àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí.
Tọkọtaya yìí kan náà bá ọ̀dọ́kùnrin kan kẹ́kọ̀ọ́ láti inú Bíbélì, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn òbí rẹ̀ sọ fún un pé: “O ń fi àkókò rẹ ṣòfò. Ó yẹ kí o wá iṣẹ́ kejì ṣe ní ìrọ̀lẹ́, kí o sì lówó sí i.” Ẹ wo bí ó ti ń bani nínú jẹ́ tó nígbà tí àwọn òbí bá ń fún àwọn ọmọ wọn níṣìírí láti fi ọrọ̀ àlùmọ́nì ṣáájú kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa Mèsáyà Ọba náà! Òwe àwọn ara China kan sọ pé: “Bí ó ti wù kí alákòóso kan lọ́rọ̀ tó kò lè fi owó ra ìwàláàyè ẹgbẹ̀rúndún mẹ́wàá.”
Ọ̀pọ̀ ti wá rí i pé kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa Mèsáyà Ọba àti títẹ̀ lé e kò fàyè gba ìfẹ́ owó. Ẹlẹ́rìí kan fún Jèhófà, tí ó ń pawó gọbọi nídìí iṣẹ́ ajé rẹ̀ sọ pé: “Níní owó púpọ̀ ń gbádùn mọ́ni gan-an ṣùgbọ́n kò pọn dandan. Kì í ṣe owó ni ó ń mú kí ènìyàn láyọ̀.” Ní báyìí, ó jẹ́ mẹ́ḿbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní ẹ̀ka Watch Tower Society ní Europe.
“Ìbẹ̀rù Àwọn Júù”
Ìbẹ̀rù ènìyàn tún jẹ́ ìdí mìíràn tí àwọn Júù kò fi tẹ́wọ́ gba Jésù gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà náà. Jíjẹ́wọ́ ipò jíjẹ́ Mèsáyà rẹ̀ ní gbangba túmọ̀ sí wíwu ìfùsì wọn léwu. Fún àwọn kan, ohun tí ń náni ti ga jù. Ronú ná nípa Nikodémù, mẹ́ḿbà ilé ẹjọ́ gíga ti àwọn Júù tí a ń pè ní Sànhẹ́dírìn. Níwọ̀n bí àwọn iṣẹ́ àmì àti ẹ̀kọ́ Jésù tí wú u lórí, ó wí pé: “Rábì, àwá mọ̀ pé ìwọ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ kan ti wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run; nítorí kò sí ẹnì kan tí ó lè ṣe àwọn iṣẹ́ àmì wọ̀nyí tí ìwọ́ ń ṣe láìjẹ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.” Síbẹ̀ Nikodémù jẹ́ kí ilẹ̀ ṣú kí ó tó kàn sí Jésù, bóyá nítorí kí àwọn Júù yòó kù má baà mọ̀ ọ́n.—Jòhánù 3:1, 2.
Fún ọ̀pọ̀ tí wọ́n gbọ́ nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀, ìtẹ́wọ́gbà ènìyàn ṣe pàtàkì fún wọn ju ti Ọlọ́run. (Jòhánù 5:44) Nígbà tí Jésù fi wà ní Jerúsálẹ́mù fún Àjọyọ̀ Àwọn Àgọ́ ní ọdún 32 Sànmánì Tiwa, “ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ . . . wà nípa rẹ̀ láàárín àwọn ogunlọ́gọ̀ náà.” Kò sí ẹni tí ó sọ̀rọ̀ ní gbangba nípa Jésù “nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù.” (Jòhánù 7:10-13) Kódà, àwọn òbí ọkùnrin kan tí Jésù wo ìfọ́jú rẹ̀ sàn kò múra tán láti sọ pé iṣẹ́ ìyanu náà wá láti ọ̀dọ̀ aṣojú Ọlọ́run. Àwọn pẹ̀lú ní “ìbẹ̀rù àwọn Júù.”—Jòhánù 9:13-23.
Lónìí, àwọn kan mọ̀ pé Jésù ti ń ṣàkóso nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà Ọba nínú ọ̀run, ṣùgbọ́n wọ́n ń bẹ̀rù láti sọ òtítọ́ yìí ní gbangba. Lójú tiwọn, ohun tí pípàdánù àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn yóò ná wọn ti ga jù. Fún àpẹẹrẹ, ní Germany, ẹnì kan tí ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà ní ìjíròrò Bíbélì pẹ̀lú ọkùnrin kan tí ó sọ pé: “Òtítọ́ ni ohun tí ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí ń wàásù nípa Bíbélì. Ṣùgbọ́n, tí mo bá di Ẹlẹ́rìí lónìí, nígbà tí yóò bá fi dọ̀la, gbogbo ènìyàn yóò ti gbọ́ nípa rẹ̀. Kí ni wọ́n yóò máa rò níbi iṣẹ́, ládùúgbò, àti nínú ẹgbẹ́ tí èmi àti ìdílé mi wà? N kò lè fara da ìyẹn.”
Kí ni ó ń fa ìbẹ̀rù ènìyàn? Ìgbéraga, ìfẹ́ àtigbajúmọ̀ láàárín ìdílé àti ọ̀rẹ́, ìbẹ̀rù ìfiniṣẹlẹ́yà àti ìtẹ́nilógo, àníyàn nítorí àìbẹ́gbẹ́jọ. Irú àwọn ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìdánwò ní pàtàkì fún àwọn tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí i kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́bìnrin kan yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Párádísè tí Ìjọba Mèsáyà yóò gbé kalẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ ìṣàkóso Jésù Kristi. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ olùfìtaranífẹ̀ẹ́ orin dísíkò, ìbẹ̀rù ènìyàn sì ṣèdíwọ́ fún un láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ìrètí yìí. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ó lo ìgbóyà láti sọ̀rọ̀ fàlàlà nípa Bíbélì. Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ nídìí orin dísíkò kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n ọkọ rẹ̀ àti àwọn òbí rẹ̀ fi ọkàn-ìfẹ́ hàn. A batisí obìnrin náà àti ìyá rẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ọkọ rẹ̀ àti bàbá rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ wo èrè tí ó jẹ nítorí ṣíṣẹ́pá ìbẹ̀rù ènìyàn!
Ìwọ́ Ha Mọ Mèsáyà Náà Ní Ti Gidi Bí?
Nígbà tí Jésù ń kú lọ lórí òpó igi ìdálóró, díẹ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wà níbẹ̀. Wọ́n ti mọ̀ ọ́n gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà tí a sọ tẹ́lẹ̀. Àwọn alákòóso Júù tún wà níbẹ̀ pẹ̀lú, àwọn tí wọ́n ṣì ń béèrè àmì, kí a sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀. “Kí ó gba ara rẹ̀ là, bí ó bá jẹ́ ẹni yìí ni Kristi [tàbí Mèsáyà] ti Ọlọ́run, Àyànfẹ́.” (Lúùkù 23:35) Wọn kì yóò ha ṣíwọ́ bíbéèrè fún àmì bí? Jésù ti ṣe ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu. Ní àfikún sí i, ìbí rẹ̀, iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ìgbẹ́jọ́ rẹ̀, ìfìyà-ikú-jẹ ẹ́, àti àjíǹde rẹ̀, mú ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ṣẹ.—Wo ìwé náà, “All Scripture Is Inspired of God and Beneficial,” tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ojú ìwé 343 àti 344.
Àwọn tí ń kọjá lọ bú Jésù, níwọ̀n bí wọ́n ti kọ ẹ̀rí jíjẹ́ Mèsáyà rẹ̀. (Mátíù 27:39, 40) Ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì mú kí awọn sójà pín aṣọ Jésù láàárín ara wọn, ní ṣíṣẹ́ kèké lórí ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀. (Jòhánù 19:23, 24) Ìbẹ̀rù ènìyàn jẹ́ apá kan ìdí tí àwọn kan fi kọ ẹ̀rí náà. Fún àpẹẹrẹ, ronú ná nípa Jósẹ́fù ará Arimatíà, mẹ́ḿbà Sànhẹ́dírìn. Òún “jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣùgbọ́n ọ̀kan tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀ nítorí ìbẹ̀rù rẹ̀ fún àwọn Júù.” Lẹ́yìn ikú Mèsáyà, Jósẹ́fù àti Nikodémù bójú tó òkú Jésù. Jósẹ́fù tipa báyìí ṣẹ́pá ìbẹ̀rù ènìyàn tí ó ní.—Jòhánù 19:38-40.
Ká ní o wà láàyè ní ọ̀rúndún kìíní, ìwọ yóò ha ti dá Jésù mọ̀ gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà náà bí? Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò ti béèrè pé kí o tẹ́wọ́ gba ẹ̀rí Ìwé Mímọ́, kí o kọ èrò tí ó jẹ́ ti onífẹ̀ẹ́-ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì sílẹ̀, kí o má sì ṣe juwọ́ sílẹ̀ fún ìbẹ̀rù ènìyàn. Ní àwọn ọjọ́ ìkẹ́yìn wọ̀nyí, ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bi ara rẹ̀ léèrè pé, ‘Mo ha dá Jésù mọ̀ nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà Ọba ti ọ̀run bí?’ Láìpẹ́, òun yóò gba àkóso àwọn àlámọ̀rí ilẹ̀ ayé. Nígbà tí ìyẹ́n bá ṣẹlẹ̀, ìwọ yóò ha wà lára àwọn tí wọ́n dá Jésù Kristi mọ̀ ní ti gidi gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà tí a ṣèlérí bí?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Má ṣe dágunlá sí ẹ̀rí náà pé Jésù ni Mèsáyà Ọba
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa Mèsáyà náà sábà máa ń túmọ̀ sí ṣíṣẹ́pá ìbẹ̀rù ohun tí àwọn ẹlòmíràn lè sọ