ORÍ 131
Ọba Kan Ń Jìyà Láìṣẹ̀ Lórí Òpó Igi
MÁTÍÙ 27:33-44 MÁÀKÙ 15:22-32 LÚÙKÙ 23:32-43 JÒHÁNÙ 19:17-24
WỌ́N KAN JÉSÙ MỌ́ ÒPÓ IGI ORÓ
ÀWỌN ÈÈYÀN FI JÉSÙ ṢE YẸ̀YẸ́ TORÍ ÀKỌLÉ TÍ WỌ́N GBÉ SÓRÍ RẸ̀
JÉSÙ ṢÈLÉRÍ FÚN ỌKÙNRIN KAN PÉ Ó MÁA WÀ NÍNÚ PÁRÁDÍSÈ
Àwọn ọmọ ogun mú Jésù àtàwọn olè méjì tí wọ́n fẹ́ pa lọ síbì kan tó wà nítòsí ìlú tí wọ́n ti gbọ́ ẹjọ́ Jésù. Gọ́gọ́tà tàbí Ibi Agbárí ni wọ́n ń pe ibẹ̀, àwọn èèyàn sì lè máa wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ “láti ọ̀ọ́kán.”—Máàkù 15:40.
Wọ́n bọ́ aṣọ Jésù àtàwọn olè náà. Wọ́n wá fún wọn ní wáìnì tí wọ́n pò pọ̀ mọ́ òjíá àti òróòro. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn obìnrin kan ní Jerúsálẹ́mù ló ṣe wáìnì náà kí àwọn tí wọ́n fẹ́ pa má bàa mọ ìrora náà lára, àwọn ọmọ ogun Róòmù ò sì ní kí wọ́n má fún wọn. Àmọ́ nígbà tí Jésù tọ́ ọ wò, kò mu ún. Kí nìdí tí ò fi mu ún? Jésù fẹ́ kí ọpọlọ òun máa ṣiṣẹ́ dáadáa kóun lè fọkàn sí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lásìkò tó ń dojú kọ àdánwò tó le yìí. Ó fẹ́ jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà dójú ikú.
Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ ogun tẹ́ Jésù sórí òpó yẹn kí wọ́n lè kàn án. (Máàkù 15:25) Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í kan ìṣó mọ́ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀, bí ìṣó ṣe ń ya ẹran àti iṣan ara rẹ̀ ni ìrora rẹ̀ ń pọ̀ sí i. Ìrora yẹn wá lágbára sí i nígbà tí wọ́n gbé òpó náà sókè torí ìṣó nìkan ló gbé ara Jésù dúró, ìyẹn sì túbọ̀ ń ya ojú ọgbẹ́ táwọn ìṣó náà ti dá sí i lára. Síbẹ̀, Jésù ò bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ burúkú sáwọn ọmọ ogun náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbàdúrà pé: “Baba, dárí jì wọ́n, torí wọn ò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.”—Lúùkù 23:34.
Àwọn ará Róòmù sábà máa ń gbé àkọlé sórí ọ̀daràn tí wọ́n bá fẹ́ pa, káwọn èèyàn lè mọ ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́ni náà dá. Torí náà, Pílátù ní kí wọ́n gbé àkọlé kan sórí Jésù, ohun tó kọ síbẹ̀ ni: “Jésù Ará Násárẹ́tì Ọba Àwọn Júù.” Ó rọrùn fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti kà á torí pé ó kọ ọ́ ní èdè Hébérù, Látìn àti èdè Gíríìkì. Ohun tí Pílátù kọ yìí fi hàn pé kò fara mọ́ ohun táwọn Júù ní kó ṣe, pé àfi dandan kó pa Jésù. Àmọ́ ẹ̀rù ba àwọn olórí àlùfáà nígbà tí wọ́n rí ohun tí Pílátù kọ, wọ́n wá sọ fún un pé: “Má kọ ọ́ pé, ‘Ọba Àwọn Júù,’ àmọ́ pé ó sọ pé, ‘Èmi ni Ọba Àwọn Júù.’ ” Pílátù ò fẹ́ kí wọ́n darí òun mọ́, ló bá dá wọn lóhùn pé: “Ohun tí mo ti kọ, mo ti kọ ọ́.”—Jòhánù 19:19-22.
Inú tó sì ń bí àwọn àlùfáà yẹn ló mú kí wọ́n tún sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Jésù nígbà tí wọ́n gbọ́ ẹjọ́ ẹ̀ ní ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn. Àwọn tó ń kọjá lọ wá bẹ̀rẹ̀ sí í mi orí wọn nígbà tí wọ́n gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n sì ń fi Jésù ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n ń sọ pé: “Ṣíọ̀! Ìwọ tí o fẹ́ wó tẹ́ńpìlì palẹ̀, kí o sì fi ọjọ́ mẹ́ta kọ́ ọ, gba ara rẹ là, kí o sọ̀ kalẹ̀ kúrò lórí òpó igi oró.” Bákan náà, àwọn olórí àlùfáà àtàwọn akọ̀wé òfin ń sọ ọ́ láàárín ara wọn pé: “Kí Kristi, Ọba Ísírẹ́lì sọ̀ kalẹ̀ látorí òpó igi oró, ká lè rí i, ká sì gbà gbọ́.” (Máàkù 15:29-32) Àwọn olè tí wọ́n kàn mọ́gi sí ọ̀tún àti òsì Jésù pàápàá ń fi ṣe yẹ̀yẹ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ọ̀daràn bíi tiwọn.
Àwọn ọmọ ogun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó wà níbẹ̀ náà fi Jésù ṣe yẹ̀yẹ́. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé wáìnì kíkan tí wọ́n ń mu ni wọ́n gbé fún Jésù, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò lè nawọ́ gbà á. Wọ́n tún fi àkọlé tó wà lórí rẹ̀ bú u, wọ́n ní: “Tó bá jẹ́ ìwọ ni Ọba Àwọn Júù, gba ara rẹ là.” (Lúùkù 23:36, 37) Ẹ ò rí i pé ó yani lẹ́nu! Ọkùnrin tó sọ fáwọn èèyàn pé òun ni ọ̀nà, òtítọ́ àti ìyè ni wọ́n fìyà jẹ báyìí láìṣẹ̀ láìrò, tí wọ́n sì tún kàn án lábùkù. Síbẹ̀, ó mú gbogbo ẹ̀ mọ́ra, kò bú àwọn Júù tó ń wò ó, bẹ́ẹ̀ ni kò sọ̀rọ̀ sáwọn ọmọ ogun Róòmù tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́, kò sì dẹ́bi fáwọn ọ̀daràn méjèèjì tí wọ́n kàn mọ́gi sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.
Làwọn ọmọ ogun tó wà níbẹ̀ bá mú aṣọ àwọ̀lékè Jésù, wọ́n sì pín in sí ọ̀nà mẹ́rin. Wọ́n wá ṣẹ́ kèké kí wọ́n lè pinnu ẹni tó máa mú ọ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́ aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ Jésù ṣàrà ọ̀tọ̀, kò “ní ojú rírán, ṣe ni wọ́n hun ún látòkè délẹ̀.” Torí náà, àwọn ọmọ ogun yẹn sọ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ ká ya á, àmọ́ ẹ jẹ́ ká fi kèké pinnu ti ẹni tó máa jẹ́.” Ìyẹn sì mú ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ṣẹ pé: “Wọ́n pín ẹ̀wù mi láàárín ara wọn, wọ́n sì ṣẹ́ kèké nítorí aṣọ mi.”—Jòhánù 19:23, 24; Sáàmù 22:18.
Nígbà tó yá, ọ̀kan lára àwọn ọ̀daràn tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù gbà pé ọba ni Jésù máa jẹ́ lóòótọ́. Torí náà, ó bá ẹnì kejì rẹ̀ wí, ó sọ fún un pé: “Ṣé o ò bẹ̀rù Ọlọ́run rárá ni, ní báyìí tó jẹ́ pé ìdájọ́ kan náà nìwọ náà gbà? Ó tọ́ sí àwa, torí pé ohun tó yẹ wá là ń gbà yìí torí àwọn ohun tí a ṣe; àmọ́ ọkùnrin yìí ò ṣe nǹkan kan tó burú.” Ó wá bẹ Jésù pé: “Rántí mi tí o bá dé inú Ìjọba rẹ.”—Lúùkù 23:40-42.
Jésù dá a lóhùn pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, o máa wà pẹ̀lú mi ní Párádísè,” kì í ṣe ní Ìjọba ọ̀run. (Lúùkù 23:43) Ìlérí tó ṣe fún ọkùnrin yìí yàtọ̀ sí èyí tó ṣe fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé wọ́n máa jókòó sórí ìtẹ́ pẹ̀lú òun nínú Ìjọba ọ̀run. (Mátíù 19:28; Lúùkù 22:29, 30) Júù ni ọ̀daràn yìí, torí náà ó ṣeé ṣe kó ti gbọ́ nípa Párádísè tí Jèhófà fi Ádámù àti Éfà sí pé kí wọ́n máa gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Ní báyìí tí olè yẹn ti fẹ́ kú, ọkàn rẹ̀ máa balẹ̀ pé òun á wà nínú Párádísè yẹn lọ́jọ́ iwájú.