Ẹ Jẹ́ Onígboyà Kẹ́ Ẹ sì Máa Lo Ìfòyemọ̀ Bíi Ti Jésù
“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí i rí, ẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí i sójú nísinsìnyí, síbẹ̀ ẹ lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.”—1 PÉT. 1:8.
1, 2. (a) Báwo la ṣe lè rí ìgbàlà? (b) Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa rìn nìṣó lójú ọ̀nà ìgbàlà?
LỌ́JỌ́ tá a di ọmọlẹ́yìn Kristi, ńṣe ló dà bíi pé a bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò kan. Ìrìn àjò yẹn máa já sí ìyè fún wa, yálà lókè ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀ ayé. Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin [ìyẹn òpin ayé ẹni yẹn tàbí òpin ètò nǹkan búburú yìí] ni ẹni tí a ó gbà là.” (Mát. 24:13) A lè wà lára àwọn tó máa rí ìgbàlà tá a bá ń bá ìṣòtítọ́ wa nìṣó. Àmọ́, bá a ṣe ń bá ìrìn àjò yìí lọ, a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohunkóhun mú ká yà kúrò lójú ọ̀nà tàbí ká sọ nù. (1 Jòh. 2:15-17) Báwo la ṣe lè máa wà lójú ọ̀nà ìrìn àjò wa nìṣó?
2 Jésù tó jẹ́ Àwòfiṣàpẹẹrẹ wa fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún wa. Bó ṣe rìnrìn àjò rẹ̀ wà lákọsílẹ̀ nínú Bíbélì. Tá a bá yẹ àkọsílẹ̀ náà wò dáadáa, àá mọ irú ẹni tí Jésù jẹ́. Èyí máa jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an ká sì lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. (Ka 1 Pétérù 1:8, 9.) Ẹ rántí pé àpọ́sítélì Pétérù sọ pé Jésù fi àwòkọ́ṣe lélẹ̀ fún wa ká lè tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí. (1 Pét. 2:21) Tá a bá fara balẹ̀ tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ rẹ̀ bó ṣe yẹ, àá fara dà á dé “òpin,” ọwọ́ wa á sì tẹ ìgbàlà.a Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, a jíròrò bá a ṣe lè jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ bíi ti Jésù. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo bá a ṣe lè jẹ́ onígboyà àti ẹni tó ń lo ìfòyemọ̀ bíi ti Jésù.
JÉSÙ JẸ́ ONÍGBOYÀ
3. Kí ni ìgboyà, báwo la sì ṣe lè ní in?
3 Ìgboyà máa ń jẹ́ kéèyàn lókun, kó sì lè fara da ìṣòro. Onígboyà èèyàn ni wọ́n sọ pé ó máa ń “fàyà rán ìṣòro,” ó máa ń “dúró lórí òtítọ́,” ó sì máa ń “tìtorí ìgbàgbọ́ tàbí ọ̀wọ̀ ara ẹni forí ti ìpọ́njú.” Onígboyà èèyàn máa ń ní ìbẹ̀rù, ìrètí àti ìfẹ́. Lọ́nà wo? Ìbẹ̀rù Ọlọ́run máa jẹ́ ká ní ìgboyà láti borí ìbẹ̀rù èèyàn. (1 Sám. 11:7; Òwe 29:25) Ojúlówó ìrètí máa jẹ́ ká wò kọjá àwọn àdánwò tá à ń kojú báyìí, ó sì máa jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ pé ọ̀la máa dáa. (Sm. 27:14) Ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan máa ń jẹ́ ká ní ìgboyà kódà tá a bá tiẹ̀ mọ̀ pé ó léwu fún ẹ̀mí wa. (Jòh. 15:13) A máa ní ìgboyà tá a bá nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run tá a sì ń tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Ọmọ rẹ̀.—Sm. 28:7.
4. Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ onígboyà ‘láàárín àwọn olùkọ́’ nínú tẹ́ńpìlì? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
4 Kódà, nígbà tí Jésù wà lọ́mọ ọdún méjìlá, ó dúró lórí òtítọ́ torí pé ó jẹ́ onígboyà. Ẹ kíyè sí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù wà “nínú tẹ́ńpìlì, [tó] jókòó sáàárín àwọn olùkọ́.” (Ka Lúùkù 2:41-47.) Àwọn olùkọ́ yìí mọ Òfin Mósè dunjú, wọ́n tún mọ àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù tó mú kí Òfin náà nira láti tẹ̀ lé. Àmọ́ Jésù ò jẹ́ kíyẹn mú kó dákẹ́, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló “bi wọ́n ní ìbéèrè.” Ó dájú pé kì í ṣe àwọn ìbéèrè ọmọdé ni Jésù ń béèrè. Àwọn ìbéèrè gbankọgbì tó ń béèrè lọ́wọ́ àwọn olùkọ́ yìí mú kí wọ́n ronú jinlẹ̀, kí wọ́n sì tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ gbọ́ ohun tó ń sọ. Báwọn olùkọ́ yìí bá sì béèrè àwọn ìbéèrè tó lè fa àríyànjiyàn torí kí wọ́n lè mú Jésù nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, pàbó ni ìsapá wọn já sí. Torí pé gbogbo àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ títí kan àwọn olùkọ́ yìí ń ṣe “kàyéfì . . . nítorí òye rẹ̀ àti àwọn ìdáhùn rẹ̀.” Láìsí àní-àní, Jésù gbèjà òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run!
5. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun jẹ́ onígboyà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀?
5 Nígbà tí Jésù ń wàásù, ó fi hàn pé òun jẹ́ onígboyà lónírúurú ọ̀nà. Kò bẹ̀rù rárá láti túdìí àṣírí ẹ̀kọ́ èké táwọn aṣáájú ẹ̀sìn fi ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà. (Mát. 23:13-36) Kò gbà rárá kí ayé kó èèràn ran òun. (Jòh. 16:33) Ó ń bá iṣẹ́ ìwàásù nìṣó báwọn alátakò tiẹ̀ ṣe inúnibíni sí i. (Jòh. 5:15-18; 7:14) Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló gbé ìgbésẹ̀ akin kó lè fọ tẹ́ńpìlì mọ́, ó lé àwọn tó ń sọ ìjọsìn di ẹlẹ́gbin jáde níbẹ̀.—Mát. 21:12, 13; Jòh. 2:14-17.
6. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun jẹ́ onígboyà ní ọjọ́ tó lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé?
6 Ó máa túbọ̀ fún ìgbàgbọ́ wa lókun tá a bá ṣàyẹ̀wò bí Jésù ṣe jẹ́ onígboyà nígbà ìpọ́njú. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí bí Jésù ṣe fi hàn pé òun jẹ́ onígboyà lọ́jọ́ tó lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé. Ó mọ wàhálà ńlá tí ìwà ọ̀dàlẹ̀ Júdásì máa fà. Síbẹ̀, nígbà oúnjẹ Ìrékọjá, Jésù sọ fún Júdásì pé: “Ohun tí ìwọ ń ṣe túbọ̀ ṣe é kíákíá.” (Jòh. 13:21-27) Nínú ọgbà Gẹtisémánì, Jésù ò bẹ̀rù rárá nígbà tó sọ fáwọn sójà tó wá fi àṣẹ ọba mú un pé òun ni ẹni tí wọ́n ń wá. Ó gbèjà àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀mí òun fúnra rẹ̀ wà nínú ewu. (Jòh. 18:1-8) Nígbà tó wà níwájú ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn, ó fìgboyà sọ fún wọn pé òun ni Kristi àti Ọmọ Ọlọ́run, bó tiẹ̀ mọ̀ pé àlùfáà àgbà ń wá ẹ̀sùn tó lè kà sí òun lọ́rùn kó lè pa òun. (Máàkù 14:60-65) Jésù jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú lórí òpó igi oró. Bó ṣe fẹ́ mí èémí ìkẹyìn nínú ìnira tó wà, ó kígbe sókè pé: “A ti ṣe é parí!”—Jòh. 19:28-30.
Ẹ JẸ́ ONÍGBOYÀ BÍI TI JÉSÙ
7. Ẹ̀yin ọ̀dọ́, báwo ló ṣe rí lára yín pé ẹ̀ ń jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà, báwo lẹ sì ṣe lè fi hàn pé ẹ jẹ́ onígboyà?
7 Báwo la ṣe lè jẹ́ onígboyà bíi ti Jésù? Ní ilé ìwé. Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ máa fi hàn pé ẹ jẹ́ onígboyà tẹ́ ẹ bá jẹ́ kó mọ́ ọn yín lára láti máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni yín, báwọn ọmọ iléèwé yín tàbí àwọn míì tiẹ̀ ń fi yín ṣe yẹ̀yẹ́. Ìyẹn máa fi hàn pé ẹ ò tijú láti máa jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà. (Ka Sáàmù 86:12.) Àwọn èèyàn lè bẹ̀rẹ̀ sí í fúngun mọ́ ẹ kó o lè gbà pé òótọ́ ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n. Àmọ́ àwọn ẹ̀rí tó dájú wà nínú Bíbélì tó fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé Ọlọ́run ló ṣẹ̀dá àwọn nǹkan. O lè wo ìwé pẹlẹbẹ tó sọ nípa bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀, ìyẹn The Origin of Life—Five Questions Worth Asking kó o lè rí ìdáhùn tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ tó o máa sọ fún àwọn tó fẹ́ mọ “ìdí fún ìrètí tí ń bẹ” nínú rẹ. (1 Pét. 3:15) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọkàn rẹ máa balẹ̀ láti máa fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
8. Kí nìdí tá a fi lè wàásù tìgboyàtìgboyà?
8 Lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Torí pé a jẹ́ Kristẹni, a ní láti máa bá a nìṣó ní “sísọ̀rọ̀ pẹ̀lú àìṣojo nípasẹ̀ ọlá àṣẹ Jèhófà.” (Ìṣe 14:3) Àwọn ìdí wo ló máa jẹ́ ká lè máa wàásù láìṣojo tàbí pẹ̀lú ìgboyà? A mọ̀ pé òtítọ́ ni ohun tá à ń wàásù torí pé inú Bíbélì la ti mú un. (Jòh. 17:17) A mọ̀ pé “àwa jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run,” a sì mọ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run wà lẹ́yìn wa. (1 Kọ́r. 3:9; Ìṣe 4:31) A mọ̀ pé tá a bá ń fìtara wàásù, ńṣe là ń fi hàn pé tọkàntọkàn la fi ń sin Jèhófà, a sì nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa. (Mát. 22:37-39) Torí pé a jẹ́ onígboyà, a ò ní dákẹ́ láti máa sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ti pinnu láti máa túdìí àṣírí irọ́ tí àwọn ìsìn èké ń pa fáwọn èèyàn kí wọ́n má bàa mọ òtítọ́. (2 Kọ́r. 4:4) A ò sì ní ṣíwọ́ láti máa wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn kódà bí wọ́n tiẹ̀ ń dágunlá sí iṣẹ́ wa, tí wọ́n ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí wa.—1 Tẹs. 2:1, 2.
9. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ onígboyà bá a tiẹ̀ ń dojú kọ ìpọ́njú?
9 Tá a bá dojú kọ ìpọ́njú. Ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run máa jẹ́ ká ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà tó máa jẹ́ ká lè fara da onírúurú ìṣòro. Tí èèyàn wa kan bá kú, inú wa máa ń bà jẹ́, àmọ́ a ò sọ̀rètí nù. Ọkàn wa balẹ̀ pé “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo” máa fún wa lókun. (2 Kọ́r. 1:3, 4; 1 Tẹs. 4:13) Tá a bá ń ṣàìsàn tàbí tí jàǹbá kan ṣẹlẹ̀ sí wa, a lè máa jẹ̀rora, àmọ́ ìyẹn ò sọ pé ká ṣe ohun tínú Ọlọ́run ò dùn sí. A ò ní gba ìtọ́jú tó máa ta ko ìlànà Bíbélì. (Ìṣe 15:28, 29) Tí ohun kan bá mú ká sorí kọ́, ‘ọkàn wa lè dá wa lẹ́bi,’ àmọ́ a ò ní jẹ́ kí ìṣòro yẹn borí wa torí pé a gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run tó ‘sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn.’b—1 Jòh. 3:19, 20; Sm. 34:18.
JÉSÙ MÁA Ń LO ÌFÒYEMỌ̀
10. Ta ni a lè pè ní onífòyemọ̀, báwo sì ni ìwà àti ọ̀rọ̀ ẹnu ìránṣẹ́ Jèhófà tó bá jẹ́ onífòyemọ̀ ṣe máa rí?
10 Ẹni tó bá ń lo ìfòyemọ̀ máa mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, á sì lè ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu. (Héb. 5:14) Àwọn kan sọ pé ẹni tó “bá lè ṣe ìpinnu tó tọ̀nà lórí ọ̀ràn tó kan ìjọsìn Ọlọ́run” jẹ́ onífòyemọ̀. Ìwà àti ọ̀rọ̀ olùjọ́sìn Jèhófà tó bá ń lo ìfòyemọ̀ máa ń múnú Ọlọ́run dùn. Irú ẹni yìí á máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó máa gbé àwọn èèyàn ró dípò kó sọ èyí tó máa bà wọ́n nínú jẹ́. (Òwe 11:12, 13) Á máa “lọ́ra láti bínú.” (Òwe 14:29) Á sì máa “lọ tààrà,” ìyẹn ni pé ìpinnu tí ó tọ́ lá máa ṣe jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. (Òwe 15:21) Báwo la ṣe lè ní ìfòyemọ̀? A gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ká sì fi ohun tá a kọ́ sílò. (Òwe 2:1-5, 10, 11) Ó máa túbọ̀ ṣèrànwọ́ gan-an tá a bá gbé àpẹẹrẹ Jésù yẹ̀ wò, torí òun ni ìfòyemọ̀ rẹ̀ ga jù lọ nínú gbogbo èèyàn tó tíì gbé láyé rí.
11. Báwo ni Jésù ṣe lo ìfòyemọ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀?
11 Jésù lo ìfòyemọ̀ nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tó sọ àti ohun tó ṣe. Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó lo òye nígbà tó ń wàásù ìhìn rere, ó máa ń lo “àwọn ọ̀rọ̀ alárinrin” tó ya àwọn olùgbọ́ rẹ̀ lẹ́nu gan-an. (Lúùkù 4:22; Mát. 7:28) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Jésù sábà máa ń lò. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń kà á jáde ní tààràtà, ó máa ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú rẹ̀ tàbí kó tọ́ka sí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó máa gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ. (Mát. 4:4, 7, 10; 12:1-5; Lúùkù 4:16-21) Jésù tún máa ń ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó máa wọ àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ́kàn gan-an. Lẹ́yìn tó jíǹde, ó bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ méjì sọ̀rọ̀ lójú ọ̀nà tó lọ sí Ẹ́máọ́sì, ó “túmọ̀ àwọn nǹkan tí ó jẹ mọ́ ara rẹ̀ nínú gbogbo Ìwé Mímọ́ fún wọn.” Àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà sọ pé: “Ọkàn-àyà wa kò ha ń jó fòfò . . . bí ó ti ń ṣí Ìwé Mímọ́ payá fún wa lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́?”—Lúùkù 24:27, 32.
12, 13. Àwọn àpẹẹrẹ wo ló jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù máa ń lọ́ra láti bínú àti pé ó jẹ́ afòyebánilò?
12 Nínú bí nǹkan ṣe máa ń rí lára rẹ̀ àti ìwà rẹ̀. Ìfòyemọ̀ mú kí Jésù kóra rẹ̀ níjàánu, ó sì mú kó “lọ́ra láti bínú.” (Òwe 16:32) Jésù jẹ́ “onínú tútù.” (Mát. 11:29) Ó máa ń ṣe sùúrù fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bí wọ́n tiẹ̀ ń ṣàṣìṣe láìmọye ìgbà. (Máàkù 14:34-38; Lúùkù 22:24-27) Kò pariwo kó máa jà fẹ́tọ̀ọ́ rẹ̀ kódà nígbà tí wọ́n hùwà àìdáa sí i.—1 Pét. 2:23.
13 Ìfòyemọ̀ tún jẹ́ kí Jésù jẹ́ afòyebánilò. Ó mọ ìdí tí Ọlọ́run fi gbé Òfin Mósè kalẹ̀, ó mọ ìlànà tó so mọ́ Òfin náà, ó sì tẹ̀ lé e. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo ìtàn tó wà nínú Máàkù 5:25-34. (Kà á.) Obìnrin onísun ẹ̀jẹ̀ kan rápálá wọ àárín èrò, ó lọ fọwọ́ kan aṣọ Jésù, ó sì rí ìwòsàn. Lábẹ́ Òfin, aláìmọ́ ni, torí náà kó yẹ kó fọwọ́ kan ẹnikẹ́ni. (Léf. 15:25-27) Àmọ́, torí pé Jésù fòye mọ̀ pé “àánú àti ìṣòtítọ́” wà lára “àwọn ọ̀ràn wíwúwo jù lọ nínú Òfin,” kò bá a wí torí pé obìnrin náà fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀. (Mát. 23:23) Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù sọ fún un tìfẹ́tìfẹ́ pé: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní àlàáfíà, kí o sì ní ìlera kúrò lọ́wọ́ àìsàn burúkú tí ń ṣe ọ́.” Ó wúni lórí gan-an pé ìfòyemọ̀ ló mú kí Jésù ṣe inúure yìí!
14. Kí ni Jésù pinnu láti ṣe, báwo ló sì ṣe fi gbogbo ọkàn ṣe iṣẹ́ yìí?
14 Nínú ọ̀nà tó gbà gbé ìgbésí ayé rẹ̀. Jésù lo ìfòyemọ̀ nínú bó ṣe yan ohun tó máa fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe, ohun tó yàn yẹn náà ló sì gbájú mọ́. Jésù fi gbogbo àkókò tó lò lórí ilẹ̀ ayé ṣe iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere. (Lúùkù 4:43) Tọkàntọkàn ni Jésù fi ṣe iṣẹ́ yìí, ó sì ń ṣe àwọn ìpinnu tó jẹ́ kó lè pọkàn pọ̀ sorí rẹ̀ kó lè ṣe é láṣeyọrí. Ó yàn láti jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ òun lọ́rùn, kó lè lo gbogbo àkókò àti okun rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Lúùkù 9:58) Ó fòye mọ̀ pé ó yẹ kí òun dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ náà nìṣó lẹ́yìn ikú òun. (Lúùkù 10:1-12; Jòh. 14:12) Ó ṣèlérí fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé òun máa wà pẹ̀lú wọn lẹ́nu iṣẹ́ yìí “títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.”—Mát. 28:19, 20.
MÁA LO ÌFÒYEMỌ̀ BÍI TI JÉSÙ
15. Báwo la ṣe lè máa lo ìfòyemọ̀ tá a bá ń sọ̀rọ̀?
15 Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ọ̀nà míì tá a lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Nínú ọ̀rọ̀ wa. Tá a bá ń bá àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ sọ̀rọ̀, a máa ń sọ̀rọ̀ tó máa gbé wọn ró, a ò ní sọ èyí tó máa bà wọ́n lọ́kàn jẹ́. (Éfé. 4:29) Tá a bá ń sọ nípa Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn, a máa ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa dùn bí “iyọ̀.” (Kól. 4:6) A máa ń sapá láti mọ ohun tó ń jẹ àwọn tá à ń wàásù fún lọ́kàn àtohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí, a sì máa ń sọ ọ̀rọ̀ tó máa bá ipò wọn mu. A mọ̀ pé tá a bá sọ ọ̀rọ̀ tó kún fún oore ọ̀fẹ́, àwọn èèyàn lè ṣílẹ̀kùn ilé wọn fún wa, kí wọ́n sì tẹ́tí gbọ́ wa. Bákan náà, Bíbélì la máa fi ń ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́. Torí náà, a máa ń fa ọ̀rọ̀ inú Bíbélì yọ, a sì máa ń kà á torí a mọ̀ pé ohun tí Bíbélì sọ ló tọ̀nà. A mọ̀ pé àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì lágbára fíìfíì ju ohunkóhun táwa fúnra wa lè sọ.—Héb. 4:12.
16, 17. (a) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a máa ń lọ́ra láti bínú àti pé a jẹ́ afòyebánilò? (b) Báwo la ṣe lè pọkàn pọ̀ sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
16 Nínú bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa àti ìwà wa. Ìfòyemọ̀ máa ń jẹ́ ká lè kó ara wa níjàánu, ó sì máa jẹ́ ká “lọ́ra nípa ìrunú.” (Ják. 1:19) Táwọn èèyàn bá ṣe ohun tó dùn wá, a máa ń gbìyànjú láti fòye mọ ohun tó fà á tí wọ́n fi sọ̀rọ̀ tàbí hùwà lọ́nà bẹ́ẹ̀. Irú ìjìnlẹ̀ òye bẹ́ẹ̀ lè mú kínú wa yọ́, ká sì “gbójú fo ìrélànàkọjá.” (Òwe 19:11) Ìfòyemọ̀ tún máa ń jẹ́ ká lè fi òye bá àwọn èèyàn lò. Ìyẹn ò ní jẹ́ ká retí ohun tó pọ̀ jù lọ́dọ̀ àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni, a máa mọ̀ pé wọ́n láwọn ìṣòro tó ń bá wọn fínra táwa ò mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀. A máa ń fẹ́ gbọ́ èrò wọn lórí ọ̀ràn kan, nígbà tó bá sì yẹ bẹ́ẹ̀, a máa ń gba àbá wọn wọlé.—Fílí. 4:5.
17 Nínú ọ̀nà tá a gbà ń gbé ìgbésí ayé wa. Bá a ṣe jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù, a fòye mọ̀ pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa láti máa wàásù ìhìn rere náà. À ń ṣe àwọn ìpinnu táá jẹ́ ká lè pọkàn pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. A yàn láti fi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa, a sì jẹ́ kí nǹkan ìní díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn ká lè lo gbogbo ìgbésí ayé wa láti fi ṣe iṣẹ́ ìwàásù tó ṣe pàtàkì jù lọ, kó tó di pé òpin dé.—Mát. 6:33; 24:14.
18. Báwo la ò ṣe ní yẹsẹ̀ kúrò lórí ìrìn àjò wa sí ọ̀nà ìgbàlà, kí lo sì pinnu láti ṣe?
18 Ǹjẹ́ kò múnú wa dùn bá a ṣe jíròrò àwọn ànímọ́ tó fani mọ́ra tí Jésù ní? Ó máa ṣe wá làǹfààní gan-an tá a bá gbé àwọn ànímọ́ Jésù míì yẹ̀ wò, tá a sì kẹ́kọ̀ọ́ bá a ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a ó máa tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù pẹ́kípẹ́kí. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní yẹsẹ̀ kúrò lórí ìrìn àjò wa sí ọ̀nà ìgbàlà, a óò sì túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, Ẹni tí Jésù fìwà jọ pátápátá.
a Àwọn Kristẹni tí wọ́n ní ìrètí ti ọ̀run ni 1 Pétérù 1:8, 9 ń bá sọ̀rọ̀. Àmọ́ ìlànà inú ọ̀rọ̀ yìí kan ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tí ìrètí wọn jẹ́ ti orí ilẹ̀ ayé.
b Tó o bá fẹ́ kà nípa àwọn tó lo ìgboyà bí wọ́n tiẹ̀ ń dojú kọ ìpọ́njú, wo Ilé Ìṣọ́, December 1, 2000, ojú ìwé 24 sí 28; Jí! April 22, 2003, ojú ìwé 18 sí 21 (Gẹ̀ẹ́sì); àti January 22, 1995, ojú ìwé 11 sí 15 (Gẹ̀ẹ́sì).