Ìwọ Ha Ń Kọ́ni Bí Jesu Ti Ṣe Bí?
“Háà ń ṣe ogunlọ́gọ̀ sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀; nitori ó ń kọ́ wọn bí ẹni kan tí ó ní ọlá-àṣẹ, kì í sì í ṣe bí awọn akọ̀wé òfin wọn.”—MATTEU 7:28, 29, NW.
1. Àwọn wo ni wọ́n ń tẹ̀lé Jesu bí ó ṣe ń kọ́ni ní Galili, kí sì ni ìhùwàpadà Jesu?
IBIKÍBI tí Jesu bá lọ, ogunlọ́gọ̀ ń wọ́ tẹ̀lé e. “Ó lọ yíká jákèjádò gbogbo Galili, ó ń kọ́ni ninu awọn sinagọgu wọn ó sì ń wàásù ìhìnrere ìjọba naa ó sì ń ṣe ìwòsàn gbogbo onírúurú òkùnrùn ati gbogbo onírúurú àìlera ara láàárín awọn ènìyàn.” Bí òkìkí ìgbòkègbodò rẹ̀ ti ń tànkálẹ̀, “ogunlọ́gọ̀ ńlá tẹ̀lé e lati Galili ati Dekapoli ati Jerusalemu ati Judea ati lati ìhà kejì Jordani.” (Matteu 4:23, 25, NW) Nígbà tí ó rí wọn, “àánú wọ́n ṣe é, nitori a bó wọn láwọ a sì fọ́n wọn ká bí awọn àgùtàn tí kò ní olùṣọ́ àgùtàn.” Bí ó ṣe ń kọ́ni wọ́n lè nímọ̀lára àánú àti ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí ó ní fún wọn; ó dàbí ẹ̀bẹ̀ amáratuni lójú ọgbẹ́ wọn tí ń mú kí wọ́n fà mọ́ ọn.—Matteu 9:35, 36, NW.
2. Ní àfikún sí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jesu ṣe, kí ni ó mú kí ogunlọ́gọ̀ wọ́ tẹ̀lé e?
2 Ẹ wo irú ìwòsàn ìyanu nípa ti ara tí Jesu ṣe—ní wíwo àwọn adẹ́tẹ̀ sàn, ó mú kí adití gbọ́ràn, ó la ojú afọ́jú, ó mú kí amúkùn-ún rìn, ó mú kí àwọn òkú tún wàláàyè! Dájúdájú ìfihàn agbára Jehofa ní àwọn ọ̀nà yíyanilẹ́nu wọ̀nyí tí ń tipasẹ̀ Jesu ṣiṣẹ́ yóò fa ogunlọ́gọ̀ mọ́ra ní iye púpọ̀ jaburata! Ṣùgbọ́n kìí ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu náà nìkan ni ó fà wọ́n mọ́ra; ogunlọ́gọ̀ rẹpẹtẹ wá pẹ̀lú fún ìmúláradá tẹ̀mí tí a pèsè nígbà tí Jesu ń kọ́nilẹ́kọ̀ọ́. Fún àpẹẹrẹ, kíyèsí ìhùwàpadà wọn, lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ Ìwàásù lílókìkí tí ó ṣe lórí Òkè: “Nígbà tí Jesu parí awọn àsọjáde wọnyi, ipa ìyọrísí rẹ̀ ni pé háà ń ṣe ogunlọ́gọ̀ sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀; nitori ó ń kọ́ wọn bí ẹni kan tí ó ní ọlá-àṣẹ, kì í sì í ṣe bí awọn akọ̀wé òfin wọn.” (Matteu 7:28, 29, NW) Àwọn rábì wọn ń fa àwọn ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ tí àwọn rábì ìgbàanì fẹnusọ yọ gẹ́gẹ́ bí ọlá-àṣẹ wọn. Ọlá-àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni Jesu fi kọ́ wọn: “Awọn ohun tí mo ń sọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti sọ wọ́n fún mi, bẹ́ẹ̀ ni mo ń sọ wọ́n.”—Johannu 12:50, NW.
Ẹ̀kọ́ Rẹ̀ Dé Inú Ọkàn-Àyà
3. Báwo ni ọ̀nà tí Jesu gbà gbé ìhìn-iṣẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ ṣe yàtọ̀ sí ti àwọn akọ̀wé àti Farisi?
3 Ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín ẹ̀kọ́ Jesu àti ti àwọn akọ̀wé àti Farisi kìí ṣe kìkì àwọn ohun tí ó ní nínú—àwọn òtítọ́ láti inú ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní ìyàtọ̀ sí àwọn ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ tí ó tọwọ́ ènìyàn wá—ṣùgbọ́n ọ̀nà tí ó gbà gbé e kalẹ̀ pẹ̀lú. Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi jẹ́ agbéraga wọ́n sì ṣónú, wọ́n ń fi ìgbéraga wá orúkọ oyè gíga wọ́n sì ń bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn ogunlọ́gọ̀ náà gẹ́gẹ́ bí “awọn ẹni ègún.” Ṣùgbọ́n, Jesu jẹ́ onínútútù, oníwàpẹ̀lẹ́, onínúure, abánikẹ́dùn, ó sì máa ń juwọ́sílẹ̀ níye ìgbà, àánú wọn sì ṣe é. Jesu kò fi kìkì àwọn ọ̀rọ̀ òtítọ́ kọ́ni ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ alárinrin láti ọkàn-àyà rẹ̀ wá, èyí tí ó wọ ọkàn-àyà àwọn olùgbọ́ rẹ̀ lọ ní tààràtà. Àwọn ìhìn-iṣẹ́ rẹ̀ tí ń mú ìdùnnú wá fa àwọn ènìyàn súnmọ́ ọn, ó ń sún wọn láti tètè dé tẹmpili láti tẹ́tísí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì mú kí wọ́n máa wọ́ tẹ̀lé e, kí wọ́n sì fi tìdùnnú-tìdùnnú tẹ́tísí i. Wọ́n ń rọ́ wá bí omi láti gbọ́ ọ̀rọ̀, ní kíkéde pé: “Ènìyàn mìíràn kan kò tí ì sọ̀rọ̀ bayii rí.”—Johannu 7:46-49, NW; Marku 12:37; Luku 4:22; 19:48; 21:38.
4. Kí ni ó fa ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn mọ́ra níti gidi nínú ìwàásù Jesu?
4 Dájúdájú, ọ̀kan lára àwọn ìdí ti ẹ̀kọ́ rẹ̀ fi máa ń fa àwọn ènìyàn mọ́ra jẹ́ nítorí ọ̀nà tí ó ń gbà lo àwọn àkàwé. Jesu rí ohun tí àwọn ẹlòmíràn rí, ṣùgbọ́n ó ronú nípa àwọn ohun tí iyè wọn kò sọ sí rí. Lílì tí ń dàgbà ní ìgbẹ́, àwọn ẹyẹ tí ń kọ́ ìtẹ́ wọn, àwọn ènìyàn tí ń gbin ọkà, àwọn olùṣọ́ àgùtàn tí ń mú ọ̀dọ́ àgùtàn tí ó sọnù wá, àwọn obìnrin tí ń lẹ ẹ̀wù tí ó ti gbó, àwọn ọmọdé tí ń ṣeré ní ọjà, àwọn apẹja tí ń fa àwọ̀n wọn—àwọn ohun wíwọ́pọ̀ tí gbogbo ènìyàn ń rí—kò fìgbà kankan jẹ́ ohun yẹpẹrẹ lójú Jesu. Ibikíbi tí ó bá yíjúsí, ó rí ohun tí ó lè lò láti ṣàkàwé Ọlọrun àti Ìjọba Rẹ̀ tàbí láti fa kókó kan yọ nípa ẹgbẹ́ àwùjọ ènìyàn tí ó yí i ká.
5. Orí kí ni Jesu gbé àwọn àkàwé rẹ̀ lé, kí ni ó sì mú kí àwọn òwe-àkàwé rẹ̀ gbéṣẹ́?
5 Jesu gbé àwọn àkàwé rẹ̀ karí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́ tí àwọn ènìyàn ti rí lọ́pọ̀ ìgbà, nígbà tí a bá sì so òtítọ́ pọ̀ mọ́ àwọn nǹkan tí a mọ̀ dáradára yìí, wọ́n tètè máa ń wọnú ọkàn àwọn olùgbọ́ rẹ̀ ṣinṣin. Kìí ṣe pé wọ́n ń gbọ́ irú àwọn òtítọ́ bẹ́ẹ̀ nìkan ni; wọ́n ń fi ojú-inú rí wọn, wọ́n sì lè yára rántí wọn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. A mọ àwọn òwe-àkàwé Jesu dunjú nítorí pé wọ́n rọrùn, kò fi àwọn àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí kò ṣe pàtàkì jin àtilóye òtítọ́ wọn lẹ́sẹ̀ kí ó sì ké e nígbèrí. Fún àpẹẹrẹ, gbé òwe-àkàwé ọkùnrin ará Samaria aládùúgbò rere náà yẹ̀wò. Ní kedere ìwọ yóò rí ohun tí ó túmọ̀sí láti jẹ́ aládùúgbò rere. (Luku 10:29-37) Lẹ́yìn èyí ó tún mẹ́nuba àwọn ọmọkùnrin méjì—ọ̀kan tí ó wí pé òun yóò ṣiṣẹ́ nínú ọgbà-àjàrà ṣùgbọ́n tí kò ṣe é, èkejì tí ó sọ pé òun kì yóò lọ ṣùgbọ́n tí ó lọ. O tètè rí ohun tí kókó pàtàkì tí ó wà nínú ìgbọràn tòótọ́ jẹ́—ṣíṣe iṣẹ́ tí a bá yàn fúnni. (Matteu 21:28-31) Kò sí ọkàn kankan tí ń tòògbé tàbí tí ń rìn gbéregbère nígbà tí Jesu ń fi ẹ̀kọ́ rẹ̀ títanijí kọ́ni. Ọwọ́ wọn dí jọjọ fún gbígbọ́ àti rírí.
Jesu Juwọ́sílẹ̀ Nígbà tí Ìfẹ́ Fihàn Pé Ó Yẹ Bẹ́ẹ̀
6. Nígbà wo ní fífòyebánilò, tàbí jíjuwọ́sílẹ̀, lè ṣèrànlọ́wọ́ ní pàtàkì?
6 Lọ́pọ̀ ìgbà nígbà tí Bibeli bá sọ̀rọ̀ nípa jíjẹ́ afòyebánilò, àkíyèsí-ẹṣẹ̀-ìwé máa ń fihàn pé ó túmọ̀sí láti jẹ́ ẹni tí ń juwọ́sílẹ̀. Ọgbọ́n tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá máa ń juwọ́sílẹ̀ nígbà tí àwọn ipò àyíká amọ́rànfúyẹ́ bá jẹyọ. Nígbà mìíràn ó yẹ kí a máa fòyebánilò, tàbí kí a máa juwọ́sílẹ̀. Àwọn alàgbà níláti máa múratán láti juwọ́sílẹ̀ nígbà tí ìfẹ́ bá fihàn pé ó yẹ bẹ́ẹ̀ tí ìrònúpìwàdà sì pèsè ìpìlẹ̀ fún èyí. (1 Timoteu 3:3; Jakọbu 3:17) Jesu fi àgbàyanu àpẹẹrẹ lélẹ̀ níti jíjuwọ́sílẹ̀, ní fífi àwọn àyàfi sílẹ̀ nínú ìlànà gbogbogbòò nígbà tí àánú àti ìyọ́nú bá béèrè fún un.
7. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àpẹẹrẹ bí Jesu ṣe juwọ́sílẹ̀?
7 Jesu sọ nígbà kan rí pé: “Ṣugbọn ẹni yòówù tí ó bá sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹlu mi níwájú awọn ènìyàn, dájúdájú emi pẹlu yoo sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹlu rẹ̀ níwájú Baba mi tí ń bẹ ní awọn ọ̀run.” Ṣùgbọ́n kò kọ Peteru sílẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Peteru sẹ́ ẹ nígbà mẹ́ta. Ó hàn gbangba pé àwọn àyíká ipò amọ́rànfúyẹ́ kan wà, tí ó dájú pé Jesu gbéyẹ̀wò. (Matteu 10:33, NW; Luku 22:54-62) Àwọn àyíká ipò amọ́rànfúyẹ́ tún jẹyọ nígbà tí obìnrin aláìmọ́ tí ó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ rú Òfin Mose nípa wíwa sáàárín ogunlọ́gọ̀. Jesu kò tìtorí ìyẹn dá a lẹ́bi. Ó lóye ipò àìnírètí rẹ̀. (Marku 1:40-42; 5:25-34; tún wo Luku 5:12, 13.) Jesu ti sọ fún àwọn aposteli rẹ̀ láti máṣe sọ fún ẹnikẹ́ni pé òun ni Messia, síbẹ̀ òun kò rinkinkin mọ́ ìlànà yẹn láìṣeéyípadà nígbà tí ó sọ fún obìnrin ará Samaria kan lẹ́bàá kànga pé Messia ni òun. (Matteu 16:20; Johannu 4:25, 26) Nínú gbogbo àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí, ìfẹ́, àánú, àti ìyọ́nú mú kí jíjuwọ́sílẹ̀ yìí yẹ bẹ́ẹ̀.—Jakọbu 2:13.
8. Nígbà wo ní àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi máa ń yí ìlànà, nígbà wo sì ni wọn kìí ṣe bẹ́ẹ̀?
8 Ó yàtọ̀ sí àwọn akọ̀wé àti Farisi tí wọn kìí juwọ́sílẹ̀. Nínú àwọn ọ̀ràn tí ó kàn wọ́n gbọ̀ngbọ̀n wọn yóò rú àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ Ọjọ́-Ìsinmi láti mú àwọn màálù wọn lọ mumi. Bí màlúù wọn tàbí ọmọkùnrin wọn bá sì bọ́ sínú kànga, wọn yóò rú òfin Ọjọ́-Ìsinmi láti lọ yọ́ ọ́ jáde. Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe tí àwọn gbáàtúù ni, wọn kò ni juwọ́sílẹ̀ rárá! Wọn kò fẹ́ “lati fi ìka wọn sún [àwọn ohun-abéèrè-fún] wọn kẹ́rẹ́.” (Matteu 23:4; Luku 14:5, NW) Lójú Jesu, àwọn ènìyàn ṣe pàtàkì púpọ̀ ju ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìlànà lọ; lójú àwọn Farisi, àwọn ìlànà ṣe pàtàkì ju àwọn ènìyàn lọ.
Dídi “Ọmọkùnrin Òfin”
9, 10. Lẹ́yìn pípadà sí Jerusalemu, níbo ni àwọn òbí Jesu gbé rí i, kí sì ni ìjẹ́pàtàkì àwọn ìbéèrè Jesu?
9 Àwọn kan ṣàròyé pé ìṣẹ̀lẹ̀ kanṣoṣo ni a ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nípa ìgbà tí Jesu wà lọ́mọdé. Síbẹ̀ ọ̀pọ̀ kùnà láti rí ìjẹ́pàtàkì ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn. A ròyìn rẹ̀ fún wa ní Luku 2:46, 47 (NW) pé: “Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta wọ́n rí i ninu tẹmpili, ó jókòó ní àárín awọn olùkọ́ ó sì ń fetísílẹ̀ sí wọn ó sì ń bi wọ́n ní ìbéèrè. Ṣugbọn gbogbo awọn wọnnì tí ń fetísílẹ̀ sí i ni wọ́n ń ṣe kàyéfì mériyìírí léraléra nitori òye rẹ̀ ati awọn ìdáhùn rẹ̀.” Ìwé Theological Dictionary of the New Testament ti Kittel mú èró náà jáde pé nínú ọ̀ràn yìí ọ̀rọ̀ Griki náà fún ‘bíbéèrè’ kìí wulẹ̀ ṣe ìháragàgà ti ọmọdékùnrin kan. Ọ̀rọ̀ náà lè tọ́ka sí àwọn ìbéèrè ọ̀rọ̀ tí a ń lò nínú ọ̀ràn ìgbẹ́jọ́, ìwádìí, ìfìbéèrè ṣàyẹ̀wò, àní “àwọn ìbéèrè atọpinpin àti alálùmọ̀kọ́rọ́yí tí àwọn Farisi àti Sadusi máa ń béèrè,” irú àwọn tí a mẹ́nukàn nínú Marku 10:2 àti 12:18-23.
10 Ìwé atúmọ̀ èdè kan naa ń báa nìṣó pé: “Lójú-ìwòye bí a ṣe ń lò ó yìí a lè béèrè yálà ohun tí . . . [Luku 2:46] ń tọ́ka sí, kò fi bẹ́ẹ̀ nííṣe pẹ̀lú ìbéèrè oníhàáragàgà tí ọmọdékùnrin náà, ṣùgbọ́n bíkòṣe ìjíròrò Rẹ̀ tí ó kẹ́sẹjárí. [Ẹsẹ̀] 47 yóò bá ojú-ìwòye tí a sọ kẹ́yìn yìí mu.”a Ìtumọ̀ ti Rotherham gbé ẹsẹ̀ 47 kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkòlójú yíyanilẹ́nu pé: “Ní báyìí ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́ ọ, nítorí òye rẹ̀ àti àwọn ìdáhùn rẹ̀.” Ìwé Word Pictures in the New Testament ti Robertson sọ pé kàyéfì mérìíyìírí léraléra wọn túmọ̀sí pé “ẹnu yà wọ́n bí ẹni pé ojú wọn fẹ́ yọ jáde.”
11. Kí ni ìhùwàpadà Maria àti Josefu sí ohun tí wọ́n rí tí wọ́n sì gbọ́, èrò wo sì ni ìwé atúmọ̀ ọ̀rọ̀ tí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan gbékalẹ̀?
11 Nígbà tí àwọn òbí Jesu dé síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà, “háà ṣe wọ́n.” (Luku 2:48, NW) Robertson sọ pé ọ̀rọ̀ Griki náà fún gbólóhùn yìí túmọ̀sí “kí àyà já pàrà, kí jìnnìjìnnì boni.” Ó fikún un pé “àyà” Josefu àti Maria “já pàrà” nítorí oun tí wọ́n rí tí wọ́n sì gbọ́. Lọ́nà kan, Jesu jẹ́ olùkọ́ tí ń mú háà ṣeni. Ní ojú-ìwòye ohun tí ó sì ṣẹlẹ̀ nínú tẹmpili yìí pẹ̀lú, ìwé Kittel jẹ́wọ́ pé “láti ìgbà ọmọdé Rẹ̀ ni Jesu ti bẹ̀rẹ̀ ìforígbárí náà nínú èyí tí àwọn alátakò Rẹ̀ yóò níláti túúbá.”
12. Kí ni ó sàmìsí ìjíròrò tí Jesu ní pẹ̀lú àwọn aṣáájú ìsìn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn?
12 Wọ́n sì túúbá nítòótọ́! Ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, Jesu tún borí àwọn Farisi nípa lílo irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn “kò gbójúgbóyà lati ọjọ́ yẹn lọ lati tún bi í ní ìbéèrè mọ́.” (Matteu 22:41-46, NW) A pa àwọn Sadusi pẹ̀lú lẹ́nu mọ́ lórí ìbéèrè nípa àjíǹde, tí “wọn kò ní ìgboyà lati béèrè ẹyọ ìbéèrè kan lọ́wọ́ rẹ̀ mọ́.” (Luku 20:27-40, NW) Àwọn akọ̀wé kò kẹ́sẹjárí lọ́nà kan tí ó sàn jù. Lẹ́yìn tí ọ̀kan lára wọn ti bá Jesu fọ̀rọ̀wérọ̀, “kò sí ẹni kan tí ó ní ìgboyà mọ́ lati bi í ní ìbéèrè.”—Marku 12:28-34, NW.
13. Kí ni ó mú kí abala-ìṣẹ̀lẹ̀ náà nínú tẹmpili ṣe pàtàkì nínú ìgbésí-ayé Jesu, ohun mìíràn wo tí ó yẹ kí a mọ̀ ni èyí sì fihàn?
13 Èéṣe tí ó fi jẹ́ pé ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó kan Jesu àti àwọn olùkọ́ni ní tẹmpili yìí nìkan ni a fàyọ fún rírántí nínú gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbà ọmọdé rẹ̀? Ó jẹ́ àkókò ìyípadà pàtàkì nínú ìgbésí-ayé Jesu. Nígbà tí ó tó bíi ọmọ ọdún 12, ó di ẹni tí àwọn Ju yóò pè ní “ọmọkùnrin òfin,” tí ó ni ẹrù-iṣẹ́ kíkíyèsí gbogbo àwọn àṣẹ rẹ̀. Nígbà tí Maria ṣàròyé fún Jesu nípa pákáǹleke ọpọlọ tí ó ti fà fún òun àti Josefu, èsì tí ọmọkùnrin rẹ̀ fọ̀ fihàn pé ó ṣeéṣe kí ó mọ ọ̀nà ìyanu tí a gbà bí òun àti jíjẹ́ tí òun yóò jẹ́ Messia lọ́jọ́ iwájú. Ìyẹn ni ó hàn nínú sísọ tí ó sọ lọ́nà tí ó ṣe tààràtà pé, Ọlọrun ni Bàbá òun: “Èéṣe tí ẹ fi níláti máa wá mi? Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé emi gbọ́dọ̀ wà ninu ilé Baba mi ni?” Lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú, ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ tí Jesu sọ tí a kọ sínú Bibeli, wọ́n sì fihàn pé ó mọ ète Jehofa fún rírán an wá sórí ilẹ̀-ayé. Nípa báyìí, odidi abala ìṣẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ ọ̀kan tí ó ní ìjẹ́pàtàkì gidigidi.—Luku 2:48, 49, NW.
Jesu Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ọmọdé Ó Sì Lóye Wọn
14. Àwọn kókó fífanimọ́ra wo ni àkọsílẹ̀ Jesu ọ̀dọ́mọdé nínú tẹmpili lè mú wá sọ́kàn àwọn èwe?
14 Àkọsílẹ̀ yìí yẹ kí ó ru ìmọ̀lára àwọn èwe sókè níti gidi. Ó fihàn bí Jesu ṣe ti níláti kẹ́kọ̀ọ́ taápọn-taápọn bí ó ṣe ń dàgbà di géńdé. Jìnnìjìnnì bo àwọn rábì ní tẹmpili nígbà tí wọ́n rí ọgbọ́n “ọmọkùnrin òfin” ẹni ọdún 12 yìí. Síbẹ̀ òun ṣì ń bá Josefu ṣiṣẹ́ nínú ṣọ́ọ̀bù rẹ̀ tí ó ti ń ṣe káfíńtà, “ó sì ń bá a lọ ní fífi ara rẹ̀ sábẹ́” òun àti Maria, ó sì ń bá a lọ “ninu ojúrere lọ́dọ̀ Ọlọrun ati ènìyàn.”—Luku 2:51, 52, NW.
15. Báwo ni Jesu ṣe ṣètìlẹyìn fún àwọn èwe nígbà iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé, kí sì ni èyí túmọ̀sí fún àwọn èwe lónìí?
15 Jesu ṣètìlẹyìn gan-an fún àwọn èwe nígbà iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé: “Nígbà tí awọn olórí àlùfáà ati awọn akọ̀wé òfin rí awọn ohun ìyanu tí ó ṣe ati awọn ọmọdékùnrin tí ń ké jáde ní tẹmpili tí wọ́n sì ń wí pé: ‘Gba Ọmọkùnrin Dafidi là, ni awa bẹ̀bẹ̀!’ ìkannú wọ́n ru wọ́n sì wí fún un pé: ‘Ìwọ ha gbọ́ ohun tí àwọn wọnyi ń wí?’ Jesu wí fún wọn pé: ‘Bẹ́ẹ̀ ni. Ṣé ẹ̀yin kò tí ì ka èyí rí pé, “Lati ẹnu awọn ìkókó ati ọmọ-ẹnu-ọmú ni iwọ ti mú ìyìn jáde”?’” (Matteu 21:15, 16, NW; Orin Dafidi 8:2) Bẹ́ẹ̀ náà ni ó ń ṣètìlẹyìn fún ẹgbàágbèje àwọn èwe àwọn tí wọ́n ń pà ìwàtítọ́ wọn mọ́ tí wọ́n sì ń kígbe ìyìn lónìí, àní ó ti ná àwọn kan lára wọn ní ìwàláàyè wọn láti lè ṣe bẹ́ẹ̀!
16. (a) Ẹ̀kọ́ wo ni Jesu kọ́ àwọn aposteli rẹ̀ nípa mímú ọmọdé kékeré kan dúró láàárín wọn? (b) Ní àkókò wo tí ó ṣekókó nínú ìgbésí-ayé Jesu ni òun tún ṣì ní àyè fún àwọn ọmọdé?
16 Nígbà tí àwọn aposteli ń jiyàn lórí ẹni tí ó tóbi jùlọ láàárín wọn, Jesu wí fún àwọn 12 náà pé: “‘Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni ìkẹyìn ninu gbogbo yín ati òjíṣẹ́ gbogbo yín.’ Ó sì mú ọmọ kékeré kan, ó mú un dúró ní àárín wọn ó sì fi awọn apá rẹ̀ yí i ká ó sì wí fún wọn pé: ‘Ẹni yòówù tí ó bá gba ọ̀kan ninu irúfẹ́ awọn ọmọ kéékèèké bẹ́ẹ̀ nitori orúkọ mi, gbà mí; ẹni yòówù tí ó bá sì gbà mí, kò gba emi nìkan, ṣugbọn ati ẹni tí ó rán mi jáde pẹlu.’” (Marku 9:35-37, NW) Jù bẹ̀ẹ́ lọ, nígbà tí ó forílé Jerusalemu fún ìgbà tí ó kẹ́hìn, láti dojúkọ àdánwò líle tí ń dáyàfoni àti ikú, ó wá àkókò fún àwọn ọmọdé: “Ẹ jẹ́ kí awọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi; ẹ máṣe gbìyànjú lati dá wọn lẹ́kun, nitori ìjọba Ọlọrun jẹ́ ti irúfẹ́ awọn ẹni bẹ́ẹ̀.” Nígbà náà ni ó “gbé awọn ọmọ naa sí apá rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í súre fún wọn, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé wọn.”—Marku 10:13-16, NW.
17. Èéṣe tí ó fi rọrùn fún Jesu láti bá àwọn ọmọdé lò, kí sì ni àwọn ọmọdé gbọ́dọ̀ rántí nípa rẹ̀?
17 Jesu mọ bí jíjẹ́ ọmọdé ti ń rí nínú ayé kán tí ó kún fún àwọn àgbàlagbà. Ó gbé pẹ̀lú àwọn àgbàlagbà, ó bá wọn ṣiṣẹ́, ó nírìírí fífi araarẹ̀ sábẹ́ wọn, ó sì nímọ̀lára ọ̀yàyà, ìmọ̀lára àìléwu pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ẹ̀yin ọmọ, Jesu kan náà ni ó jẹ́ ọ̀rẹ́ yín; ó kú fún yin, ẹ ó sì wàláàyè títíláé bí ẹ bá ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ rẹ̀.—Johannu 15:13, 14.
18. Èrò gbígbádùnmọ́ni wo ni ó yẹ kí a fi sọ́kàn, ní pàtàkì láàárín àwọn àkókò onímásùnmáwo tàbí eléwu?
18 Láti ṣe gẹ́gẹ́ bíi Jesu ti pạ̀ṣẹ kò nira tó bí ó ti lè jọbí ẹni pé ó rí. Ẹ̀yin èwe, ó wà ní sẹpẹ́ fún yín àti fún gbogbo ará yòókù, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kà á nínú Matteu 11:28-30 (NW) pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú emi yoo sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín [tàbí, “Ẹ bọ́ sábẹ́ àjàgà mi pẹ̀lú mi,” àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé] kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nitori onínú tútù ati ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni emi, ẹ̀yin yoo sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nitori àjàgà mi jẹ́ ti inúrere ẹrù mi sì fúyẹ́.” Ìwọ rò ó wò ná, bí o ṣe ń rìn la ìgbésí-ayé já ní ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa, Jesu ń rìn ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú rẹ, ní mímú àjàgà náà rọrùn tí ó sì ń mú ẹrù náà fúyẹ́. Èrò kan tí ó gbádùnmọ́ni ni èyí jẹ́ fún gbogbo ènìyàn!
19. Àwọn ìbéèrè wo nípa ọ̀nà tí Jesu gbà kọ́ni ni a lè máa gbé yẹ̀wò láti ìgbà-dé-gbà?
19 Lẹ́yìn ṣíṣe àgbéyẹ̀wò ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí Jesu gbà kọ́ni, àwa ha rí i pé a ń kọ́ni bí òun ti ṣe bí? Nígbà tí a bá rí àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìlera nípa ti ara tàbí tí ebi tẹ̀mí ń pa, àánú ha ń sún wá láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa ṣíṣe ohun tí a bá lè ṣe? Nígbà tí a bá ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn, àwa ha ń kọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọrun bí, tàbí, gẹ́gẹ́ bí ti àwọn Farisi, àwa ha ń kọ́ni ní àwọn èrò tiwa bí? Àwa ha wà lójúfò láti kíyèsí àwọn ohun tí a ń rí láyìíká wa lójoojúmọ́ tí a lè lò láti mú kí ọ̀ràn ṣe kedere, kí wọ́n lè fojú-inú wòye, kí ó lè fìdímúlẹ̀ ṣinṣin, kí ó sì mú kí àtilóye àwọn òtítọ́ tẹ̀mí sunwọ̀n síi? Àwa ha ń yẹra fún rírinkinkin mọ́ àwọn ìlànà kan láìṣeéyípadà nígbà tí ó bá sàn jù láti lo ìfẹ́ àti àánú, nítorí àwọn àyíká ipò nípa jíjuwọ́sílẹ̀ lórí bí a ṣe lè lo irú àwọn ìlànà bẹ́ẹ̀? Àwọn ọmọdé pẹ̀lú ń kọ́? Àwa ha ń fi irú ìdàníyàn oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti onínúrere-ìṣeun kan naa hàn sí wọn bí Jesu ti ṣe bí? Ìwọ ha ń fún àwọn ọmọ rẹ níṣìírí láti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tí Jesu gbà kọ́ ọ nígbà tí ó wà lọ́mọdé bí? Ìwọ yóò ha hùwà pẹ̀lú ìdúróṣinṣin gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ṣe ṣùgbọ́n kí o ṣetán láti gba àwọn wọnnì tí wọ́n bá ronúpìwàdà padà tọ̀yàyà-tọ̀yàyà, bí àgbébọ̀ adìyẹ ṣe ń fi ìyẹ́ rẹ̀ bo àwọn òròmọ rẹ̀?—Matteu 23:37.
20. Èrò dídùnmọ́ni wo ni a lè fi máa tu araawa nínú bí a ṣe ń ṣiṣẹ́sin Ọlọrun wa?
20 Bí a bá làkàkà láti ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti kọ́ni gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ṣe, dájúdájú òun yóò gbà kí a ‘bọ́ sábẹ́ àjàgà pẹ̀lú òun.’—Matteu 11:28-30.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àmọ́ ṣáá o, ìdí púpọ̀ wà fún wa láti gbàgbọ́ pé Jesu yóò fi ọ̀wọ̀ tí ó yẹ hàn fún àwọn wọnnì tí wọ́n dàgbà jù ú lọ, ní pàtàkì àwọn eléwú lórí àti àwọn àlùfáà.—Fiwé Lefitiku 19:32; Iṣe 23:2-5.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Èéṣe tí ogunlọ́gọ̀ fi ń wọ́ tẹ̀lé Jesu?
◻ Èéṣe tí Jesu fi ń juwọ́sílẹ̀ lórí àwọn ìlànà kan nígbà mìíràn?
◻ Kí ni a lè rí kọ́ láti inú ìbéèrè tí Jesu bi àwọn olùkọ́ ní tẹmpili?
◻ Ẹ̀kọ́ wo ni a lè fàyọ láti inú ìbátan tí ó wà láàárín Jesu àti àwọn ọmọde?