Ori 8
‘Ijọba naa Ti Súnmọ́lé’
1. Eeṣe tí awọn ọ̀rọ̀ Johannu ninu Matteu 3:1-10 fi bá akoko mu?
Ẹ JẸ́ ki a tubọ ṣayẹwo igbokegbodo “Messia Aṣaaju naa” nigba wíwá rẹ̀ àkọ́kọ́ ní kúlẹ̀kúlẹ̀. Ìfilọ̀ amúnitagìrì naa ni a kọ́kọ́ gbọ́ lati ẹnu Johannu Arinibọmi: “Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dẹ̀dẹ̀.” (Matteu 3:2) Ọba ẹ̀hìn-ọ̀la naa fẹrẹẹ farahan! Bi ‘ọsẹ aadọrin,’ naa “ọsẹ” akanṣe ojurere kan, ti sunmọle, ó ti to akoko fun awọn Ju lati ronupiwada ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí wọn dá si apapọ ofin ododo tí a fi fun wọn lati ọwọ́ Ọlọrun wọn, Jehofa. Nitori pe nisinsinyi Israeli ti fẹrẹẹ wọ̀ inu ọjọ idajọ. Fun ìdí yii, Johannu ń báa lọ lati wí fun awọn aṣaaju isin orilẹ-ede naa tí wọn jẹ́ alagabagebe pe: “Ẹyin ọmọ paramọ́lẹ̀, ta ni ó kilọ fun yin lati sá kuro ninu ibinu tí ń bọ̀? Nitori naa ẹ so eso tí ó yẹ fun ironupiwada. Ati nisinsinyi pẹlu, a ti fi àáké lé gbòǹgbò igi naa; nitori naa gbogbo igi tí kò bá so eso rere, a ó ké e lulẹ, a ó sì wọ́ ọ jù sinu iná.”—Matteu 3:7, 8, 10.
2. (a) Bawo ni baptismu Jesu ṣe yatọ? (b) Bi ó ti “bẹrẹ iṣẹ rẹ̀,” pẹlu ki ni ó nilati wọ̀jà?
2 Nigba naa ni Jesu wá lati Galili sí Jordani tí ó sì sọ pe ki Johannu baptisi oun. Johannu mọ̀ pe Jesu kò ní ẹṣẹ, nitori naa oun kọ̀ lakọọkọ. Bi ó ti wù ki ó rí, baptismu Jesu nilati yatọ. Yoo ṣàpẹẹrẹ fifi araarẹ̀ lélẹ̀ fun Jehofa fun iṣẹ àkànṣe naa eyi tí Baba rẹ̀ ní fun un lati ṣe lori ilẹ̀-ayé. Lọna tí ó baamu wẹ́kú, nigba naa, a baptisi Jesu ninu omi.
“Bi ó ti ń gbadura, ọrun ṣí sílẹ̀, ẹmi mímọ́ si sọkalẹ sí ori rẹ̀ ní àwọ̀ àdàbà, ohùn kan sì ti ọrun wá, ti o si wi pe, Iwọ ni ayanfẹ ọmọ mi; ẹni ti inu mi dun si gidigidi. Jesu tìkáraarẹ̀ ń to bi ẹni ìwọ̀n ọgbọ̀n ọdun.”
Lójú-ẹsẹ̀, gẹgẹ bi Messia ati Ọba ti a yan, ó di ẹni ti a ń gbejako lati ọ̀dọ̀ Ejo laelae nì, Eṣu, ati awọn aṣaaju isin Ju wọnni awọn tí ń fi agabagebe jẹ́wọ́ pe wọn ń ṣiṣẹsin Ọlọrun.—Luku 3:21-23.
3. Bawo ni ipa-ọna Jesu nigba tí ó wà labẹ ìdẹwò ṣe yatọ si ti Adamu ati Efa?
3 “Jesu sì kún fun ẹmi mimọ, ó pada ti Jordani wá, a sì ti ọwọ́ ẹmi mimọ dari rẹ̀ si ijù; ogoji ọjọ ni a fi dán an wò lọwọ Eṣu.” (Luku 4:1, 2) Satani mọ̀ daju pe Jesu ni “Iru-ọmọ” ileri Ọlọrun ẹni tí yoo tẹ Eṣu ati “iru-ọmọ” buruku rẹ̀ pa nigba tí akoko bá tó. Satani ha lè ké ète Jehofa nígbèrí nipa mímú ki Jesu ṣaigbọran si I bi? Jesu ti ń gbàwẹ̀ fun 40 ọjọ. Nitori naa Eṣu késí Jesu tí ebi ń pa pe ki ó sọ awọn okuta kan tí ó wà ní aginju gbigbẹ di awọn ìṣù àkàrá. Nisinsinyi Jesu ní agbara lati ṣe iṣẹ-iyanu, ṣugbọn bi ó ti tọ́, ó fà ofin ododo Jehofa yọ, ní wiwi pe:
“A ti kọwe rẹ̀ pe, Eniyan kì yoo walaaye nipa àkàrà nikan, bikoṣe nipa gbogbo ọ̀rọ̀ tí o ti ẹnu Ọlọrun jade wá.” (Matteu 4:1-4; Deuteronomi 8:3)
Bawo ni oun ti yatọ tó sí Efa ati ọkọ rẹ̀, Adamu, awọn ẹni tí wọn ṣaigbọran nipa jijẹ eso tí a kaleewọ naa bi ó tilẹ jẹ́ pe ọpọ yanturu ounjẹ agbẹ́mìíró miiran wà yí wọn ká!
4. Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n wo ni awa lè rí kọ́ lati inu ọna tí Jesu gbà dojukọ ìdẹwò keji?
4 Ẹmi irẹlẹ Jesu ati gbigbarale Baba rẹ̀ patapata ni a fihan lọna tí ó gbà dojukọ ìdẹwò tí ó tẹle e. Satani gbiyanju lati mú ki Jesu ronu pe oun, gẹgẹ bi Ọmọkunrin Ọlọrun, jẹ́ ẹni pataki kan—gbajúmọ̀ eniyan. Bẹẹni, jẹ́ ki oun fúnraarẹ̀ bẹ́sílẹ̀ láìnídìí lati ori ṣóńṣó tẹmpili, dajudaju awọn angẹli Ọlọrun yoo sì gbá a mú ki ó má baa farapa. Ṣugbọn Jesu ṣá iru ìdábàá oníwà òmùgọ̀ bẹẹ tì, ní fífà ofin Jehofa yọ lẹẹkan sii, ó wi pe:
“A tún kọ ọ pe, Iwọ kò gbọdọ dán Oluwa Ọlọrun rẹ wò.” (Matteu 4:5-7; Deuteronomi 6:16)
Níhìn-ín ni ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n kan wà fun gbogbo awọn wọnni tí wọn sọ pe iranṣẹ Ọlọrun ni awọn jẹ́ titi di òní yii: Ki ẹnikẹni maṣe ṣe ọ̀yájú lori iduro rẹ̀ pẹlu Jehofa lae. Bibukun tí Ọlọrun ń bukun wa kii ṣe nitori awọn iṣẹ-isin tí a ti ṣe sẹhin tabi ipò wa ṣugbọn lori titẹsiwaju wa nìṣó lati maa ṣe igbọran si i pẹlu gbogbo ẹmi irẹlẹ, níní ọ̀wọ̀ jijinlẹ fun awọn iṣeto ati awọn ohun-àbèèrè-fún rẹ̀.—Filippi 2:5-7.
5. (a) Lori ariyanjiyan ti o gba iwaju julọ wo ni ìdẹwò kẹta sinmile? (b) Bawo ni Jesu ṣe tún lò ofin Ọlọrun fun idahunpada? (c) Bawo ni eyi ṣe jẹ́ apẹẹrẹ ológo fun wa lonii?
5 Nisinsinyi, ni ìdẹwò tí ó kẹhin tí ó sì jẹ́ òtéńté ní akoko-iṣẹlẹ yii! Óò, bi Satani bá lè ṣèèṣì mú Jesu kọsẹ̀ lori ariyanjiyan tí ó gba iwaju julọ naa, ti Ijọba naa! Nitori naa “Eṣu gbé e lọ si ori oke giga-giga ẹ̀wẹ̀, ó sì fi gbogbo ilẹ-ọba ayé ati gbogbo ògo wọn hàn án; ó sì wi fun un pe, Gbogbo nǹkan wọnyi ni emi yoo fi fun ọ, bi iwọ bá wólẹ̀, tí o sì foribalẹ fun mi.” Nipasẹ ifohunṣọkan rirọrun yii, ni Satani jiyàn, Jesu lè gbà iṣakoso lori gbogbo ayé araye patapata porogodo nigba naa ati nibẹ, laisi pe oun tún nilati duro fun ọpọ ọ̀rúndún de akoko yiyẹ Jehofa. Ṣugbọn lẹẹkan sii, Jesu tún tọkasi ofin Jehofa, bi oun ti fèsì pe:
“Pada kuro lẹhin mi, Satani: nitori a ti kọwe rẹ̀ pe, Oluwa Ọlọrun rẹ ni ki iwọ ki o foribalẹ fun, oun nikanṣoṣo ni ki iwọ maa sìn.” (Matteu 4:8-10; Deuteronomi 6:13)
Lẹẹkan sii, apẹẹrẹ ológo kan fun awọn wọnni tí ń ṣiṣẹsin Jehofa lonii! Laika bi ọna naa ti lè dabi eyi tí ó jinna tó, ki awọn wọnni tí ń ṣe iṣẹ-isin mímọ́ fun Jehofa maṣe dẹ́kun lae lati fi Ijọba Ọlọrun si ipò àkọ́kọ́ ninu igbesi-aye wọn. Ǹjẹ́ ki wọn maṣe yídà lae lati gbé “awọn ijọba” kekere tiwọn funraawọn kalẹ ninu ẹgbẹ-awujọ ayé Satani onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀-àlùmọ́ọ́nì yii.
“KII ṢE APAKAN AYÉ”
6. (a) Lọna wo ni Ijọba naa gbà súnmọ́lé nisinsinyi? (b) Ní ṣíṣàmúlò 1 Peteru 2:21, apẹẹrẹ Jesu wo ni awọn Kristian gbọdọ tẹle?
6 Ki ni tẹle bibori tí Jesu borí awọn ìdẹwò Eṣu? Akọsilẹ Bibeli sọ fun wa pe:
“Lati igba naa ni Jesu bẹ̀rẹ̀ si waasu wi pe, Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù sí dẹ̀dẹ̀.”
Lọna wo ni Ijọba naa gbà kù sí dẹ̀dẹ̀? Niti pe ẹni naa tí a fòróróyàn lati jẹ́ Ọba, Jesu Kristi fúnraarẹ̀, wàníbẹ̀ nisinsinyi, tí “o ń kọni . . . ó si ń waasu ihinrere ijọba.” Ogunlọgọ nla eniyan ń tẹle e lati ibikan si ibomiran. (Matteu 4:17, 23-25) Jesu mú un ṣe kedere pe awọn wọnni tí wọn tẹwọgba ẹkọ oun kò nilati ‘jẹ́ apakan ayé, gẹgẹ bi oun paapaa kìí tii ṣe apakan ayé.’ Wọn nilati yà araawọn sọtọ kuro ninu ayé ati awọn ọna ìwà-ipá ati oníwà-pálapàla rẹ̀. Gbogbo awọn wọnni tí wọn bá fẹ́ lati tẹle Jesu lonii gbọdọ ṣe bakan naa.—Johannu 17:14, 16; 1 Peteru 2:21; tún wò Matteu 5:27, 28; 26:52.
7. Lójú-ìwòye awọn ọ̀rọ̀ Jesu ninu Johannu 8:44, eeṣe tí ó fi ṣe pataki pe ki awa lonii ṣàyẹ̀wò awọn ẹkọ awọn aṣaaju isin ní ibamu pẹlu Bibeli?
7 Niti ijọsin eke, Jesu sọ fun awọn aṣaaju isin ọjọ rẹ̀ pe: “Ti Eṣu baba yin ni ẹyin ń ṣe, ifẹkufẹ baba yin ni ẹ sì ń fẹ́ ṣe. Apaniyan ni oun lati atetekọṣe, kò si duro ninu otitọ; nitori tí kò si otitọ ninu rẹ̀. Nigba tí ó bá ń ṣeke, ninu ohun tirẹ̀ ní ó ń sọ, nitori eke ni, ati baba eke.” (Johannu 8:44) Ó ṣe pataki julọ fun awọn eniyan gbáàtúù nigba naa lọ́hùn-ún lati já araawọn gbà kuro lọwọ awọn aṣa atọwọdọwọ eke (tí a gbà wọnú Talmud lẹhin naa) tí ó ti gbilẹ̀ ninu isin Ju. Ati lonii, fun awọn wọnni, gẹgẹ bi awọn Ju, tí wọn ti gbé gbogbo igbesi-aye wọn ninu isin awọn babanla wọn, ó ṣe pataki pe ki wọn ṣàyẹ̀wò boya awọn aṣaaju isin wọn ti ‘pa’ ọ̀rọ̀ Ọlọrun ‘tì sapakan’ ki wọn baa lè fi ẹkọ atọwọdọwọ eniyan lasan kọni tabi bẹẹkọ.—Marku 7:9-13.
8, 9. (a) Eeṣe tí Jesu fi wi pe Ijọba oun “kii ṣe apákan ayé yii”? (b) Eeṣe, nigba naa, tí awọn Kristian fi ń bá inunibini pade? (c) Eeṣe tí wọn fi gbọdọ jẹ́ onigboya gidigidi?
8 Nigba tí ó ń jẹ́jọ́ fun iwalaaye rẹ̀, Jesu kede nipa awọn ijọba oṣelu tí ń bẹ ní akoko rẹ̀ pe:
“Ijọba mi kii ṣe apákan ayé yii: ibaṣepe ijọba mi iṣe ti ayé yii, awọn ońṣẹ́ mi ìbá jà, ki a má baa fi mi lé awọn Ju lọwọ: ṣugbọn nisinsinyi ijọba mi kii ṣe lati ihin lọ.”
Orisun Ijọba Jesu jẹ́ ti ọrun. Ó rí ọla-aṣẹ rẹ̀ gbà lati ọ̀dọ̀ Ọba-aláṣẹ Onípò-àjùlọ, Jehofa Ọlọrun, kìí sìí ṣe lati ọ̀dọ̀ Satani. Nitori naa, Satani lo “iru-ọmọ” rẹ̀ ori ilẹ̀-ayé lati ṣe inunibini si Jesu ati awọn ọmọlẹhin rẹ̀.—Johannu 18:36.
9 Nitori naa Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tootọ pe: “Nǹkan wọnyi ni mo ti palaṣẹ fun yin, ki ẹyin ki ó fẹran araayin. Bi ayé bá koriira yin, ẹ mọ̀ pe ó ti koriira mi ṣaaju yin. Ibaṣepe ẹyin ń ṣe ti ayé, ayé ìbá fẹ́ awọn tirẹ̀; ṣugbọn nitori tí ẹyin kii ṣe ti ayé, ṣugbọn emi ti yàn yin kuro ninu ayé, nitori eyi ni ayé ṣe koriira yin.” (Johannu 15:17-19) Awọn olujọsin Jehofa ń ní iriri ikoriira ati inunibini kíkorò títí di òní olóòní yii nitori pe wọn yà araawọn sọtọ kuro ninu ìwà-ìbàjẹ́ iṣelu ati ìwà-ipá tí ó gbòdekan gan-an lonii. Ṣugbọn èrè-ẹ̀san ọlọ́ràá ń durode gbogbo awọn tí ó bori ayé nikẹhin. Gẹgẹ bi Jesu ti mu dá awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lójú: “Ninu ayé, ẹyin yoo ní ipọnju; ṣugbọn ẹ tújúká; mo ti ṣẹgun ayé.”—Johannu 16:33.
Ẹ̀RÍ TÍTÓÓTUN FUN IPO ỌBA
10, 11. (a) Ki ni fihan pe awọn oluṣakoso ayé kò ṣakoso nipasẹ ẹ̀tọ́ atọrunwa? (b) Ní ifiwera, bawo ni Jesu ṣe fi araarẹ̀ hàn gẹgẹ bi ẹni titootun fun ipo-ọba?
10 Awọn animọ wo ni iwọ yoo fẹ́ lati rí ninu oluṣakoso ayé kan? Eyi tí ó pọ̀ julọ ninu awọn oluṣakoso ninu itan ti jẹ́ “akọni ọkunrin,” onigberaga, awúfùkẹ̀. Wọn ti saba maa ń fi ilọsiwaju ara-ẹni ṣaaju aini awọn gbáàtúù eniyan. Awọn kan ti fọ́nnu kíkọ́ awọn ilẹ-ọba ńlá, ṣugbọn nigba tí ó yá gbogbo ilẹ-ọba alagbara wọn ni ó wolulẹ, ni jíjẹ́rìí si otitọ awọn ọ̀rọ̀ Ọba Solomoni pe: “Bikoṣe pe Oluwa bá kọ́ ile naa, awọn tí ń kọ́ ọ ń ṣiṣẹ lasan.” (Orin Dafidi 127:1) Awọn “ọba” wọnyi ti fihan nitootọ pe wọn kò ṣakoso nipasẹ ẹ̀tọ́ atọrunwa. Ipo ọba-aláṣẹ wọn kii ṣe lati ọ̀dọ̀ Jehofa Ọlọrun.
11 Bi ó ti wù ki ó rí, Ọba tí Ọlọrun fòróróyàn, Jesu Kristi, ni a ṣapejuwe rẹ̀ lọna alasọtẹlẹ gẹgẹ bi ẹni tí ń gùn ẹṣin lọ lati bá awọn ọ̀tá rẹ̀ jà “nitori otitọ ati ìwàtútù ati ododo.” A wí nipa rẹ̀ pe: “Iwọ fẹ́ ododo, iwọ koriira iwa-buburu: nitori naa ni Ọlọrun, Ọlọrun rẹ, ṣe fi ami ororo ayọ yàn ọ ṣe olori awọn ọ̀gbà rẹ”—awọn ọba ìlà Dafidi tí ó jẹ ṣaaju rẹ̀. (Orin Dafidi 45:4, 7) Ninu ikoriira rẹ̀ fun ohun gbogbo tí ń tabuku si orukọ mímọ́ Jehofa tí ó sì lodisi awọn ilana ododo Ọlọrun, Ọba ọrun naa laipẹ yoo fọ̀ gbogbo iwa-buruku mọ́tónítóní kuro lori ilẹ̀-ayé yii, pẹlu imurasilẹ fun mímú ijọba ododo wọle dé. Jesu ha ti fi araarẹ̀ hàn bi ẹni tí ó tootun lati jẹ́ irufẹ oluṣakoso bẹẹ bi? Dajudaju oun ti ṣe bẹẹ!
12. Àwòkọ́ṣe iṣẹ-isin mímọ́ wo ni Jesu fi lelẹ fun wa?
12 Nigba tí oun jẹ́ ọkunrin pípé kan, Jesu jẹ́ apẹẹrẹ titayọ ní fifi ifẹ hàn fun Ọlọrun ati aladuugbo. Gẹgẹ bi ọ̀kan lara awọn mẹmba orilẹ-ede Israeli ti Ọlọrun, tí a yasimimọ fun Jehofa, Jesu fi apẹẹrẹ lélẹ̀ ní ṣiṣe igbọran si aṣẹ titobijulọ meji naa. Oun wi pe: “Èkínní ninu gbogbo ofin ni, Gbọ́, Israeli, Oluwa Ọlọrun wa Oluwa kan ni. Ki iwọ ki o si fi gbogbo àyà rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo iyè rẹ ati gbogbo agbara rẹ fẹ Oluwa Ọlọrun rẹ. . . . Ekeji si dabi rẹ̀, Fẹ Ọmọnikeji rẹ bi araarẹ.” (Marku 12:29-31; Deuteronomi 6:4, 5) Jesu yọnda araarẹ̀ láìkù sibikan ninu iṣẹ-isin rẹ̀ si Jehofa ati ní kíkọ́ awọn Ju aladuugbo rẹ̀. Nigba tí awọn wọnyi gbiyanju lati dá a duro ki wọn baa lè gbọ́ pupọ sii, ó sọ fun wọn pe:
“Emi kò lè ṣaima waasu ijọba Ọlọrun fun ìlú miiran pẹlu, nitori naa ni a sá ṣe rán mi.” (Luku 4:43)
Ní ṣiṣe iṣẹ-isin mímọ́, Jesu jẹ́ oṣiṣẹ, ní fifi àwòkọ́ṣe lélẹ̀ fun gbogbo Kristian tootọ lati tẹle.—Fiwe Johannu 5:17.
13, 14. (a) Oju wo ni Jesu fi wò awọn eniyan? (b) Eeṣe tí oun fi jade lọ waasu, eesitiṣe tí oun fi rán awọn miiran jade? (c) Iru abojuto wo ni awọn eniyan lè fojusọna fun labẹ Ijọba naa?
13 Jesu fi araarẹ̀ hàn ní onifẹẹ ati oníyọ̀ọ́nú. Ninu ọkàn-àyà rẹ̀, oun yánhànhàn lati ríi ki awọn eniyan rẹ̀ gbà ominira kuro lọwọ ẹrù-ìnira wiwuwo tí awọn aṣaaju isin wọn apọ́nnilójú gbeka wọn lori. Nitori naa ó sọ fun wọn nipa Ijọba naa, ó sì rán awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ jade, ní wiwi pe:
“Bi ẹyin ti ń lọ, ẹ maa waasu, wi pe, Ijọba ọrun kù sí dẹ̀dẹ̀.”—Matteu 9:35–10:7.
14 Ọba ti a yan yii késí awọn eniyan naa, wi pe: “Ẹ wá sọdọ mi gbogbo ẹyin tí ń ṣíṣẹ̀ẹ́, tí a si di ẹrù wuwo lé lori, emi o sì fi isinmi fun yin. Ẹ gba àjàgà mi si ọrùn yin, ẹ sì maa kọ́ ẹ̀kọ́ lọdọ mi, nitori oninu tutu ati onirẹlẹ ọkan ni emi; ẹyin o sì rí isinmi fun ọkàn yin. Nitori àjàgà mi rọrùn, ẹrù mi sì fúyẹ́.” (Matteu 11:28-30) Jesu, gẹgẹ bi Ọba ọrun tí Ọlọrun yàn lori gbogbo araye, yoo fi iru ìyọ́nú kan-naa hàn, yoo sì rí sii, gẹgẹ bi ó ti ṣe nigba tí ó wà lori ilẹ̀-ayé, pé awọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ninu Ijọba ni a ṣetojọ lati pese ìtura ati abojuto oninuure tí awọn eniyan nílò niti gidi. Gbogbo ẹni tí ń gbé lori ilẹ̀-ayé labẹ iṣakoso Ijọba Jesu yoo rí itura nitootọ fun ọkàn wọn.
ALÁÌLÁLÈÉBÙ NINU ÌWÀTÍTỌ́
15. Bawo ni Jesu ṣe pese idahun pípé pérépéré fun ìpèníjà Satani?
15 Lékè gbogbo rẹ̀, Ọba araye ni ẹhin ọla ṣaṣefihan ìwàtítọ́ aláìlálèébù ati igbọran si Baba rẹ̀ ọrun, titi dé ojú iku oníkà lori igi oró. Bi wakati ìfìyà-ikú-jẹni naa ti ń sunmọle, Jesu gbadura si Jehofa, wi pe: “Baba, ṣe orukọ rẹ lógo.” Ohùn Jehofa dahunpada lati ọrun wá wi pe: “Emi ti ṣe é lógo ná, emi yoo sì tún ṣe é lógo.” Ní yiya orukọ Baba rẹ̀ si mímọ́, Jesu fi idahun pípé-pérépéré fun ìpèníjà Satani. Ó fihan pe eniyan pípé kan lè jẹ́ olùṣòtítọ́ sí Ọlọrun labẹ iru idanwo eyikeyii tí elénìní naa lè mú wá bá a. Nitori naa Jesu lè wi pe: “Nisinsinyi ni idajọ ayé yii dé: nisinsinyi ni a ó lé aládé ayé yii [Satani] jade”—tí yoo di ẹni ẹ̀tẹ́ patapata, tí a ó fi i hàn ní elékèé. Awọn aṣaaju isin Ju, bi ‘iru-ọmọ ejo-nla naa,’ yoo dá ọgbẹ́ onirora kan si “gìgìísẹ̀” “iru-ọmọ” eto-ajọ Ọlọrun tí ó dabi obinrin, ṣugbọn Ọlọrun yoo jí Ọmọkunrin rẹ̀ ti o tóyeyẹ dide si iwalaaye ti ẹmi.—Genesisi 3:15; Johannu 12:27-31.
16, 17. (a) Eeṣe tí a fi lè ní ìgbọ́kànlé tí ó lágbára ninu Ọba lọla fun ilẹ̀-ayé? (b) Bawo ni Ìwé Mímọ́ ṣe tọka fi ireti paradise ilẹ̀-ayé hàn pe ó jẹ́ otitọ-gidi? (c) Ọna igbesi-aye rẹ atẹhinwa ha nilati dá ọ duro ninu nínàgà fun ireti naa bi?
16 Ifẹ Jesu fun ododo, ikoriira rẹ̀ fun iwa-ailofin, ifẹ rẹ̀ jijinlẹ fun araye ati, lékè gbogbo rẹ̀, igbọran aláìyẹhùn rẹ̀ ní ṣiṣe ifẹ-inu Baba rẹ̀ si ògo orukọ Jehofa—gbogbo nǹkan wọnyi fi Ọmọkunrin aduroṣinṣin yii hàn bi ẹni tí ó tootun daradara lati jẹ Ọba ilẹ̀-ayé lẹhin ọla. Iwọ ko ha ni fẹ́ lati wọ̀ inu ìyè ayeraye bi ọmọ-abẹ alayọ ti irufẹ ọba bẹẹ bi?
17 Bi ó ti wù ki ọna igbesi-aye rẹ ti dara tabi buru tó titi di isinsinyi, ireti ìyè ainipẹkun naa lori ilẹ̀-ayé tí a sọ di ológo lè di tirẹ. Họwu, àní olè ti o ronupiwada naa tí wọn fìyà-ikú-jẹ pẹlu Jesu ni a fun ní irufẹ ireti ajinde bẹẹ! Nitori nigba tí ó wi fun Jesu pe, “Ranti mi nigba tí iwọ bá dé ijọba rẹ,” Jesu fèsìpadà pe: “Lóòótọ́ ni mo wi fun ọ lonii, iwọ yoo wà pẹlu mi ní Paradise.” (Luku 23:42, 43, NW) Laipẹ, Paradise yoo di otitọ-gidi. Iwọ, pẹlu, ha ń fi taduratadura nàgà fun ‘dídé’ Ijọba naa ati awọn ibukun rẹ̀ bi?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 77]
ỌKUNRIN TITOBILỌLA JULỌ TÍ Ó TÍÌ GBÉ LORI ILẸ̀-AYÉ RÍ
Gẹgẹ bi Ọba ti a yan, ó fi ìwàtítọ́ hàn titi dé ojú ikú, ó sì rà araye pada kuro ninu ẹṣẹ ati iku nipasẹ ẹjẹ rẹ̀ tí a tasilẹ