Ẹ̀KỌ́ 58
Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Jèhófà
Àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń rí i pé àwọn ò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun ba àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Ó dájú pé bó ṣe rí lára ìwọ náà nìyẹn. Jèhófà mọyì bó o ṣe jẹ́ adúróṣinṣin sí òun. (Ka 1 Kíróníkà 28:9.) Àwọn nǹkan wo ló lè mú kó nira fún ẹ láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, kí ló sì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí àwọn nǹkan náà?
1. Báwo làwọn míì ṣe lè mú kó nira fún wa láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà?
Àwọn kan lè máa ṣe ohun tí ò ní jẹ́ ká sin Jèhófà bó ṣe yẹ, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máa rọ̀ wá pé ká fi Jèhófà sílẹ̀. Àwọn wo ló lè ní ká ṣe irú ìpinnu burúkú bẹ́ẹ̀? Àwọn kan tó ti fi Jèhófà sílẹ̀ máa ń sọ ohun tí kì í ṣe òótọ́ nípa ètò Ọlọ́run kí wọ́n lè mú kó nira fún wa láti fọkàn tán ètò Ọlọ́run. Bíbélì pe irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní apẹ̀yìndà. Bákan náà, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn kan máa ń sọ ohun tí kì í ṣe òótọ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn sì lè mú kí àwọn tó ń fetí sí ọ̀rọ̀ wọn fi Jèhófà sílẹ̀. Ó léwu gan-an láti máa bá àwọn alátakò yìí sọ̀rọ̀, kò sì yẹ ká máa ka àwọn ìwé wọn, lọ sórí ìkànnì wọn tàbí wo fídíò tí wọ́n gbé jáde. Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Ẹ fi wọ́n sílẹ̀. Afọ́jú tó ń fini mọ̀nà ni wọ́n. Tí afọ́jú bá wá ń fi afọ́jú mọ̀nà, inú kòtò ni àwọn méjèèjì máa já sí.”—Mátíù 15:14.
2. Báwo làwọn ìpinnu tá à ń ṣe ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà?
Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a ò ní fẹ́ ṣe ohunkóhun táá mú ká lọ́wọ́ sí ẹ̀sìn èké. Torí náà, a gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò iṣẹ́ wa, ẹgbẹ́ tá à ń ṣe àtàwọn nǹkan mí ì tá à ń lọ́wọ́ sí, ká sì rí i pé wọn ò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ẹ̀sìn èké. Jèhófà kìlọ̀ fún wa pé: “Ẹ jáde kúrò nínú [Bábílónì Ńlá], ẹ̀yin èèyàn mi.”—Ìfihàn 18:2, 4.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó o ṣe lè dúró lórí ìpinnu ẹ láti jẹ́ adúróṣinṣin táwọn kan bá tiẹ̀ fẹ́ kó o fi Jèhófà sílẹ̀. A tún máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó o ṣe lè jáde kúrò nínú Bábílónì Ńlá, kó o lè fi hàn pé o jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà.
3. Má ṣe máa tẹ́tí sí àwọn olùkọ́ èké
Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá gbọ́ àwọn nǹkan tí kì í ṣe òótọ́ nípa ètò Jèhófà? Ka Òwe 14:15, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́?
Ka 2 Jòhánù 9-11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí ni kò yẹ ká máa ṣe sáwọn apẹ̀yìndà?
Tá ò bá tiẹ̀ bá àwọn apẹ̀yìndà sọ̀rọ̀ lójúkojú, àwọn ọ̀nà míì wo là lè gbà máa tẹ́tí sí ẹ̀kọ́ wọn?
Báwo ló ṣe máa rí lára Jèhófà tá a bá ń fetí sí ohun tí ò dáa táwọn èèyàn ń sọ nípa rẹ̀ tàbí nípa ètò rẹ̀?
4. Jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà tí ẹnì kan nínú ìjọ bá dẹ́ṣẹ̀
Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá mọ̀ pé ẹnì kan nínú ìjọ ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an? Jẹ́ ká wo ìlànà kan tó wà nínú Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́. Ka Léfítíkù 5:1.
Bí ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe sọ, tá a bá mọ̀ pé ẹnì kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an, a gbọ́dọ̀ sọ fáwọn alàgbà. Àmọ́ ká tó sọ fún wọn, a lè fi hàn pé a gba ti ẹni tó hùwà àìtọ́ náà rò tá a bá ní kó lọ sọ ohun tó ṣe fáwọn alàgbà. Tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká lọ sọ ohun tá a mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà fáwọn alàgbà ká lè fi hàn pé a jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Tá a bá ṣe gbogbo ohun tá a sọ yìí, báwo nìyẹn ṣe máa fi hàn pé a jẹ́ adúróṣinṣin sí . . .
Jèhófà?
ẹni tó hùwà àìtọ́ náà?
àwọn míì nínú ìjọ?
5. Jáde kúrò nínú Bábílónì Ńlá
Ka Lúùkù 4:8 àti Ìfihàn 18:4, 5, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Ṣé orúkọ mi ṣì wà nínú ìwé àwọn ọmọ ìjọ ní ọ̀kan lára ibi tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn èké?
Ṣé mo wà nínú ẹgbẹ́ kan tó ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ẹ̀sìn èké?
Ṣé iṣẹ́ tí mò ń ṣe ń ti ẹ̀sìn èké lẹ́yìn?
Ṣé nǹkan kan ṣì wà tó yẹ kí n ṣe láti fi hàn pé mo ti jáde kúrò nínú ẹ̀sìn èké?
Àwọn àyípadà wo ló yẹ kí n ṣe tí mo bá dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni sí èyíkéyìí nínú àwọn ìbéèrè yìí?
Tó o bá fẹ́ pinnu ohun tí wàá ṣe, rí i pé o ṣèpinnu tí ò ní da ẹ̀rí ọkàn rẹ láàmú, táá sì fi hàn pé o jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà.
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Tí mo bá mọ ohun táwọn apẹ̀yìndà ń sọ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, máà lè mọ ohun tó yẹ kí n sọ láti gbèjà òtítọ́.”
Ṣé o rò pé ìyẹn bọ́gbọ́n mu? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Tá a bá fẹ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, a gbọ́dọ̀ yẹra fún àwọn tó bá fẹ́ mú ká kẹ̀yìn sí Jèhófà.
Kí lo rí kọ́?
Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa tẹ́tí sí ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà?
Tá a bá mọ̀ pé ẹnì kan nínú ìjọ ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú gan-an, kí ló yẹ ká ṣe?
Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé ìkìlọ̀ tó sọ pé ká jáde kúrò nínú ẹ̀sìn èké?
ṢÈWÁDÌÍ
Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tó yẹ kó o ṣe tó o bá gbọ́ ohun tí kì í ṣe òótọ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Báwo lo ṣe lè mọ̀ bóyá ẹgbẹ́ kan tàbí ètò kan ń ṣètìlẹyìn fún Bábílónì Ńlá?
“Jẹ́ Kí Ọwọ́ Rẹ Dí Ní ‘Apá Ìgbẹ̀yìn Àwọn Ọjọ́’ Yìí” (Ilé Ìṣọ́, October 2019, ìpínrọ̀ 16-18)
Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan táwọn alátakò máa ń ṣe kí wọ́n lè mú kó nira fún wa láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà?
Ka ìtàn yìí kó o lè mọ bí ọkùnrin kan tó jẹ́ àlùfáà ẹ̀sìn Shinto ṣe fi ẹ̀sìn èké sílẹ̀. Àkòrí ìtàn náà ni “Láti Kékeré Ni Mo Ti Fẹ́ Mọ Ọlọ́run.”
“Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà” (Ilé Ìṣọ́, July 1, 2011)