ORÍ 21
Jésù Lọ sí Sínágọ́gù Tó Wà ní Násárẹ́tì
JÉSÙ Ń KA ÀKÁJỌ ÌWÉ ÀÌSÁYÀ
ÀWỌN ARÁ NÁSÁRẸ́TÌ FẸ́ PA JÉSÙ
Ó dájú pé àwọn ará Násárẹ́tì ti ń fojú sọ́nà láti rí Jésù. Káfíńtà ni wọ́n mọ̀ ọ́n sí ní nǹkan bí ọdún kan sẹ́yìn, kó tó lọ ṣèrìbọmi lọ́dọ̀ Jòhánù. Àmọ́ ní báyìí, ohun tí wọ́n ń gbọ́ ni pé Jésù ti di oníṣẹ́ ìyanu. Torí náà, ó ń wù wọ́n láti rí i, wọ́n sì fẹ́ kó ṣe iṣẹ́ ìyanu lójú àwọn.
Ẹ wo bó ṣe máa rí lára wọn nígbà tí wọ́n rí Jésù tó ń lọ sí sínágọ́gù bó ṣe máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ohun táwọn èèyàn máa ń ṣe ‘nínú sínágọ́gù láwọn ọjọ́ sábáàtì’ ni pé wọ́n máa ń gbàdúrà, wọ́n á sì ka àwọn ìwé tí Mósè kọ. (Ìṣe 15:21) Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún máa ń ka àwọn ìwé àwọn wòlíì. Torí pé kì í ṣèní kì í ṣàná ni Jésù ti máa ń lọ sí sínágọ́gù, ó ṣeé ṣe kó dá àwọn kan mọ̀ nígbà tó dìde láti kàwé. Wọ́n fún un ní àkájọ ìwé wòlíì Àìsáyà. Ó ṣí ìwé náà sí ibi tó sọ̀rọ̀ nípa Ẹni tí Jèhófà fi ẹ̀mí yàn, inú Àìsáyà 61:1, 2 ni àkọsílẹ̀ yẹn wà nínú Bíbélì.
Jésù wá bẹ̀rẹ̀ sí í kà nípa Ẹni tí wọ́n sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa kéde òmìnira fún àwọn ẹrú, tó máa mú kí àwọn afọ́jú ríran, tó sì máa kéde ọdún ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà. Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù dá àkájọ ìwé náà pa dà fún ìránṣẹ́, ó sì jókòó. Ni gbogbo wọn bá tẹjú mọ́ ọn. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn sọ̀rọ̀, bóyá fún àkókò tó gùn díẹ̀. Mánigbàgbé lọ̀rọ̀ kan tó bá wọn sọ pé: “Òní ni ìwé mímọ́ tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ yìí ṣẹ.”—Lúùkù 4:21.
Ẹnú ya àwọn èèyàn náà torí “àwọn ọ̀rọ̀ tó tuni lára tó ń ti ẹnu rẹ̀ jáde,” débi tí wọ́n fi ń bi ara wọn pé: “Ọmọ Jósẹ́fù nìyí, àbí òun kọ́?” Àmọ́ torí pé Jésù ti mọ̀ pé wọ́n fẹ́ kóun ṣe irú àwọn iṣẹ́ ìyanu tóun ṣe láwọn ibòmíì, ó sọ fún wọn pé: “Ó dájú pé ẹ máa fi ọ̀rọ̀ yìí bá mi wí pé, ‘Oníṣègùn, wo ara rẹ sàn. Tún ṣe àwọn ohun tí a gbọ́ pé ó wáyé ní Kápánáúmù ní ìlú rẹ níbí.’” (Lúùkù 4:22, 23) Àwọn aráàlú Jésù gbà pé ọ̀dọ̀ àwọn ló yẹ kó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwòsàn, pé àwọn ló yẹ káwọn kọ́kọ́ jàǹfààní ẹ̀. Torí náà, wọ́n lè ronú pé ṣe ni Jésù fojú pa àwọn rẹ́.
Torí pé Jésù mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, ó tọ́ka sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan nínú ìtàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ó sọ fún wọn pé àwọn tó jẹ́ opó pọ̀ nígbà ayé Èlíjà, àmọ́ Jèhófà ò rán Èlíjà sí ìkankan nínú wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, opó kan tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, tó ń gbé ní ìlú Sáréfátì nítòsí Sídónì ni Jèhófà rán wòlíì náà sí, ó sì ṣe iṣẹ́ ìyanu láti dá ẹ̀mí opó yẹn àti ọmọ rẹ̀ sí. (1 Àwọn Ọba 17:8-16) Bákan náà, nígbà ayé Èlíṣà, ọ̀pọ̀ adẹ́tẹ̀ ló wà nílẹ̀ Ísírẹ́lì, àmọ́ Náámánì ọmọ ilẹ̀ Síríà nìkan ni wòlíì náà wò sàn.—2 Àwọn Ọba 5:1, 8-14.
Àwọn àpẹẹrẹ tí Jésù sọ yìí fi hàn pé onímọtara-ẹni-nìkan àti aláìgbàgbọ́ làwọn èèyàn náà. Báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe wá rí lára wọn? Inú bí wọn débi pé wọ́n dìde, wọ́n gbá Jésù mú wọ́n sì mú un jáde sí ẹ̀yìn ìlú. Wọ́n mú un lọ sí téńté òkè tí wọ́n kọ́ ìlú Násárẹ́tì sí, kí wọ́n lè taari rẹ̀ sísàlẹ̀. Àmọ́ Jésù bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́. Ẹ̀yìn náà ló forí lé Kápánáúmù tó wà ní apá àríwá Òkun Gálílì.