ORÍ 27
Jésù Pe Mátíù
MÁTÍÙ 9:9-13 MÁÀKÙ 2:13-17 LÚÙKÙ 5:27-32
JÉSÙ PE MÁTÍÙ TÓ JẸ́ AGBOWÓ ORÍ
KRISTI BÁ ÀWỌN ẸLẸ́ṢẸ̀ JẸUN KÓ LÈ RÀN WỌ́N LỌ́WỌ́
Lẹ́yìn tí Jésù wo ẹni tó rọ lápá rọ lẹ́sẹ̀ náà sàn, ó lo àkókò díẹ̀ ní Kápánáúmù nítòsí Òkun Gálílì. Ọ̀pọ̀ èèyàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn. Bó ṣe ń rìn lọ, ó rí Mátíù tó tún ń jẹ́ Léfì níbi tó jókòó sí ní ọ́fíìsì àwọn agbowó orí. Jésù wá sọ fún un pé: “Máa tẹ̀ lé mi.”—Mátíù 9:9.
Bíi ti Pétérù, Áńdérù, Jémíìsì àti Jòhánù, ó ṣeé ṣé kí Mátíù ti gbọ́ nípa Jésù, bó ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe lágbègbè yẹn. Bíi tiwọn, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Mátíù gbéra tó sì tẹ̀ lé Jésù. Ó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìwé Ìhìn Rere tó kọ, ó ní: “Ló [Mátíù fúnra rẹ̀] bá dìde, ó sì tẹ̀ lé” Jésù. (Mátíù 9:9) Torí náà, Mátíù pa iṣẹ́ agbowó orí tì, ó sì di ọmọlẹ́yìn Jésù.
Nígbà tó yá, Mátíù ṣètò àsè ńlá kan nílé rẹ̀, ó sì pe Jésù bóyá kó lè fi hàn pé òun mọyì bó ṣe sọ òun di ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Yàtọ̀ sí Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, àwọn wo ni Mátíù tún pè? Ó pe díẹ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ tí àwọn náà jẹ́ agbowó orí. Ìjọba Róòmù táwọn Júù kórìíra làwọn agbowó orí yìí ń ṣiṣẹ́ fún, wọ́n máa ń gbowó lórí ọkọ̀ ojú omi tó wá sí etíkun, lórí àwọn ọkọ̀ akẹ́rù àti lórí àwọn ọjà tí wọ́n ń kó wọ̀lú. Ojú wo làwọn Júù fi máa ń wo àwọn agbowó orí? Àwọn Júù kórìíra wọn torí pé wọ́n sábà máa ń fipá gba owó orí lọ́wọ́ àwọn èèyàn, wọ́n sì máa ń gbà ju iye tí ìjọba sọ lọ. Ó tún pe àwọn “ẹlẹ́ṣẹ̀” sí ibi àsè náà, ìyẹn àwọn tó ti sọ ìwà burúkú dàṣà.—Lúùkù 7:37-39.
Nígbà táwọn Farisí olódodo àṣelékè rí Jésù tó ń bá àwọn èèyàn yẹn jẹun, wọ́n bi àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Kí ló dé tí olùkọ́ yín ń bá àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun?” (Mátíù 9:11) Nígbà tí Jésù gbọ́ ohun tí wọ́n sọ, ó sọ pé: “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn, àmọ́ àwọn tó ń ṣàìsàn nílò rẹ̀. Torí náà, ẹ lọ kọ́ ohun tí ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí: ‘Àánú ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ.’ Torí kì í ṣe àwọn olódodo ni mo wá pè, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.” (Mátíù 9:12, 13; Hósíà 6:6) Ojú ayé làwọn Farisí ń ṣe bí wọ́n ṣe ń pe Jésù ní “olùkọ́,” àmọ́ ká ní wọ́n finú kan bá a lò ni, ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ni wọn ò bá kọ́ lára rẹ̀.
Kí nìdí tí Mátíù fi pe àwọn agbowó orí àtàwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ wá sílé rẹ̀ lásìkò tó pe Jésù wá sílé rẹ̀? Ó lè jẹ́ torí kí wọ́n lè tẹ́tí sí Jésù, kí wọ́n sì rí ìtura tẹ̀mí gbà, torí Bíbélì ròyìn pé “ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ń tẹ̀ lé e.” (Máàkù 2:15) Jésù fẹ́ kí wọ́n ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Kò pa wọ́n tì bíi tàwọn Farisí tí wọ́n ka ara wọn sí olódodo. Aláàánú àti onínúure ni Jésù, ó sì máa ṣe ìwòsàn tẹ̀mí fún gbogbo àwọn tó ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí.
Kì í ṣe torí pé Jésù fojú kéré ẹ̀ṣẹ̀ àwọn agbowó orí àtàwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yẹn ló ṣe fi àánú hàn sí wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló gba tiwọn rò tó sì ṣàánú wọn bó ṣe máa ń ṣe sáwọn tó ń ṣàìsàn. Ẹ̀yin náà rántí bó ṣe fi àánú hàn sí adẹ́tẹ̀ kan nígbà tó fọwọ́ kàn án, tó sì sọ pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀! Kí o mọ́.” (Mátíù 8:3) Ǹjẹ́ kò yẹ kí àwa náà máa fi àánú hàn sí àwọn aláìní, ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́, pàápàá nípa tẹ̀mí?