ORÍ 32
Kí Ló Bófin Mu ní Sábáàtì?
MÁTÍÙ 12:9-14 MÁÀKÙ 3:1-6 LÚÙKÙ 6:6-11
JÉSÙ WO ỌKÙNRIN TÓ RỌ LÁPÁ SÀN LỌ́JỌ́ SÁBÁÀTÌ
Ní Sábáàtì míì, Jésù wọ inú sínágọ́gù, tó ṣeé ṣe kó wà ní Gálílì, ó sì rí ọkùnrin kan tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ rọ níbẹ̀. (Lúùkù 6:6) Àmọ́ àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ́ Jésù lójú méjèèjì. Kí nìdí? Èyí ṣe kedere nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣé ó bófin mu láti ṣe ìwòsàn ní Sábáàtì?”—Mátíù 12:10.
Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù gbà pé kò sóhun tó burú nínú kéèyàn woni sàn ní Sábáàtì àmọ́ ó gbọ́dọ̀ jẹ́ nígbà tí ẹ̀mí ẹnì kan wà nínú ewu. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ní kò bófin mu kéèyàn to egungun lọ́jọ́ Sábáàtì, bẹ́ẹ̀ sì ni kò yẹ kéèyàn fi báńdéèjì wé ibi tó fi rọ́ lọ́jọ́ yẹn, wọ́n gbà pé àwọn ipò yẹn kò la ẹ̀mí lọ. Ó dájú pé kì í ṣe torí pé àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí ń káàánú ọkùnrin tó ní ìṣòro yẹn ni wọ́n ṣe ń bi Jésù léèrè ọ̀rọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n ń wá bí wọ́n ṣe máa fẹ̀sùn kan Jésù.
Àmọ́, Jésù mọ èrò òdì tó wà lọ́kàn wọn. Ó mọ̀ pé wọ́n ti ki àṣejù bọ ohun tó túmọ̀ sí láti má ṣe iṣẹ́ kankan ní Sábáàtì, èrò wọn yìí kò sì bá Ìwé Mímọ́ mu. (Ẹ́kísódù 20:8-10) Kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ nìyí táwọn èèyàn máa fẹ̀sùn kan Jésù pé ó ń ṣe iṣẹ́ ìyanu lọ́jọ́ Sábáàtì. Torí náà, Jésù wá kúkú ṣe ohun tó máa mú kí wọ́n sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn jáde nígbà tó sọ fún ọkùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ rọ náà pé: “Dìde, máa bọ̀ ní àárín.”—Máàkù 3:3.
Jésù wá yíjú sáwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí yẹn, ó sì sọ fún wọn pé: “Tí ẹ bá ní àgùntàn kan, tí àgùntàn náà sì já sínú kòtò ní Sábáàtì, ṣé ẹnì kan wà nínú yín tí kò ní dì í mú, kó sì gbé e jáde?” (Mátíù 12:11) Ohun ọ̀sìn tó ń mówó wọlé ni àgùntàn. Torí náà, kò sí ẹnì kankan nínú wọn tó lè fi àgùntàn rẹ̀ sílẹ̀ nínú kòtò títí di ọjọ́ kejì, torí tó bá kú àdánù ló máa jẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, Bíbélì sọ pé: “Olódodo ń tọ́jú ẹran ọ̀sìn rẹ̀.”—Òwe 12:10.
Káwọn èèyàn náà lè rí ohun tó ń sọ gan-an, Jésù sọ fún wọn pé: “Ṣé èèyàn ò wá ṣeyebíye ju àgùntàn lọ? Torí náà, ó bófin mu láti ṣe ohun tó dáa ní Sábáàtì.” (Mátíù 12:12) Ó ṣe kedere nígbà náà pé Jésù ò ta ko òfin Sábáàtì bó ṣe wo ọkùnrin yẹn sàn. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn ò lè ta ko ọ̀rọ̀ tó bọ́gbọ́n mu tó sì fàánú hàn tí Jésù sọ. Abájọ tí wọn ò fi lè sọ ohunkóhun mọ́.
Inú bí Jésù, ó sì ní ẹ̀dùn ọkàn torí pé wọn ò lójú àánú. Ó wá wò yíká, ó sì sọ fún ọkùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ rọ náà pé: “Na ọwọ́ rẹ.” (Mátíù 12:13) Lẹ́yìn tí ọkùnrin yẹn na ọwọ́ rẹ̀, ọwọ́ náà pa dà sípò. Ẹ wá wo bí inú ọkùnrin náà ṣe dùn tó! Àmọ́ báwo ló ṣe rí lára àwọn tó fẹ́ dẹkùn mú Jésù?
Dípò kí inú àwọn Farisí yẹn dùn pé ọwọ́ ọkùnrin náà ti sàn, ńṣe ni wọ́n bọ́ síta lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí “wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Hẹ́rọ́dù gbìmọ̀ pọ̀, kí wọ́n lè pa” Jésù. (Máàkù 3:6) Ó ṣe kedere pé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tí wọ́n ń pè ní Sadusí wà lára ẹgbẹ́ òṣèlú yẹn. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, ọ̀tá làwọn Sadusí àtàwọn Farisí tẹ́lẹ̀ àmọ́ ní báyìí rìkíṣí ti pa wọ́n pọ̀, wọ́n dọ̀rẹ́, wọ́n sì gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Jésù.