ORÍ 73
Ará Samáríà Kan Fàánú Hàn
BÉÈYÀN ṢE LÈ NÍ ÌYÈ
ARÁ SAMÁRÍÀ TÓ JẸ́ ALÁDÙÚGBÒ RERE
Ìtòsí Jerúsálẹ́mù ni Jésù ṣì wà, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló sì ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Àwọn kan lára wọn fẹ́ wá kẹ́kọ̀ọ́ ni, àmọ́ àwọn míì ń wá bí wọ́n ṣe máa dán an wò. Ọ̀kan lára wọn ni ọkùnrin kan tó mọ Òfin dáadáa, ó béèrè pé: “Olùkọ́, kí ló yẹ kí n ṣe kí n lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”—Lúùkù 10:25.
Jésù kíyè sí i pé kì í ṣe pé ọkùnrin náà fẹ́ mọ ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe ló fẹ́ kí Jésù dáhùn lọ́nà táá múnú bí àwọn Júù tó wà níbẹ̀. Jésù rí i pé ọkùnrin náà mọ ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn tẹ́lẹ̀. Torí náà, Jésù fọgbọ́n dá a lóhùn kó lè sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀.
Jésù wá bi í pé: “Kí la kọ sínú Òfin? Kí lo kà níbẹ̀?” Ọkùnrin yẹn mọ Òfin Ọlọ́run, torí náà ó sọ ohun tó ti kà nínú Òfin. Ó sọ ohun tó wà nínú ìwé Diutarónómì 6:5 àti Léfítíkù 19:18, ó ní: “‘Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara rẹ àti gbogbo okun rẹ àti gbogbo èrò rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ,’ kí o sì ‘nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.’” (Lúùkù 10:26, 27) Ṣé ó gba ìdáhùn yẹn ṣá?
Jésù sọ fún un pé: “Ìdáhùn rẹ tọ́; máa ṣe bẹ́ẹ̀, o sì máa rí ìyè.” Àmọ́ ìdáhùn yẹn ò tẹ́ ọkùnrin náà lọ́rùn, ó fẹ́ gbọ́ ohun tó máa “fi hàn pé olódodo ni òun,” káwọn èèyàn lè gbà pé èrò òun tọ̀nà àti pé bóun ṣe ń hùwà sáwọn èèyàn dáa. Ló bá tún bi Jésù pé: “Ta ni ọmọnìkejì mi gan-an?” (Lúùkù 10:28, 29) Ìbéèrè tó dà bíi pé kò tó nǹkan yìí lè kó Jésù sí wàhálà. Lọ́nà wo?
Àwọn Júù gbà pé ẹni tó bá ń pa àṣà àwọn mọ́ nìkan làwọ́n lè pè ní “ọmọnìkejì,” ó sì lè dà bíi pé ìwé Léfítíkù 19:18 ti èrò náà lẹ́yìn. Kódà, Júù kan lè sọ pé “kò bófin mu” kóun da nǹkan pọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe Júù. (Ìṣe 10:28) Torí náà, ọkùnrin yìí títí kan àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù pàápàá lè máa wo ara wọn bí olódodo, tí wọ́n bá ṣáà ti ń hùwà tó dáa sẹ́ni tó jẹ́ Júù bíi tiwọn. Wọ́n gbà pé kò pọn dandan káwọn fàánú hàn sẹ́ni tí kì í ṣe Júù torí pé wọn ò kà wọ́n sí “ọmọnìkejì.”
Báwo ni Jésù ṣe máa tún èrò wọn ṣe láì múnú bí ọkùnrin yìí àtàwọn Júù míì? Ìtàn kékeré kan ni Jésù sọ, ó ní: “Ọkùnrin kan ń sọ̀ kalẹ̀ lọ láti Jerúsálẹ́mù sí Jẹ́ríkò, ó sì bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà, wọ́n bọ́ ọ láṣọ, wọ́n lù ú, wọ́n sì fi sílẹ̀ lọ nígbà tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú. Ó ṣẹlẹ̀ pé àsìkò yẹn ni àlùfáà kan ń sọ̀ kalẹ̀ lọ lójú ọ̀nà yẹn, àmọ́ nígbà tó rí ọkùnrin náà, ó gba ọ̀nà tó wà ní òdìkejì kọjá lọ. Bákan náà, nígbà tí ọmọ Léfì kan dé ibẹ̀, tó sì rí i, ó gba ọ̀nà tó wà ní òdìkejì kọjá lọ. Àmọ́ ará Samáríà kan tó ń rìnrìn àjò gba ọ̀nà yẹn ṣàdédé bá a pàdé, nígbà tó rí i, àánú rẹ̀ ṣe é.”—Lúùkù 10:30-33.
Ó dájú pé ọkùnrin tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀ náà mọ̀ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn àlùfáà tó ń sìn ní tẹ́ńpìlì ló ń gbé Jẹ́ríkò títí kan àwọn ọmọ Léfì tó ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Tí wọ́n bá ti ń pa dà bọ̀ láti tẹ́ńpìlì, wọ́n máa ní láti rin ìrìn àjò nǹkan bíi máìlì mẹ́rìnlá (14). Ọ̀nà tí wọ́n ń gbà sì léwu gan-an torí pé àwọn olè máa ń wà níbẹ̀. Torí náà, tí àlùfáà àti ọmọ Léfì kan bá ń kọjá lọ nírú ọ̀nà yẹn, tí wọ́n sì rí Júù bíi tiwọn nínú ewu, ṣé kò yẹ kí wọ́n ràn án lọ́wọ́? Nínú ìtàn yìí, Jésù sọ pé wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀. Ará Samáríà kan ló ran ọkùnrin náà lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ sì rèé àwọn Júù ò ka àwọn ará Samáríà sí èèyàn pàtàkì.—Jòhánù 8:48.
Báwo ni ọkùnrin ará Samáríà yìí ṣe ran Júù tó fara pa náà lọ́wọ́? Jésù sọ pé: “Ó sún mọ́ ọn, ó di àwọn ọgbẹ́ rẹ̀, ó sì da òróró àti wáìnì sí i. Ó wá gbé e sórí ẹran rẹ̀, ó gbé e lọ sí ilé ìgbàlejò kan, ó sì tọ́jú rẹ̀. Lọ́jọ́ kejì, ó mú owó dínárì méjì jáde, ó fún olùtọ́jú ilé náà, ó sì sọ pé: ‘Tọ́jú rẹ̀, ohunkóhun tí o bá sì ná lẹ́yìn èyí, màá san án pa dà fún ọ tí mo bá dé.’”—Lúùkù 10:34, 35.
Lẹ́yìn tí Jésù tó jẹ́ Àgbà Olùkọ́ parí ìtàn yìí, ó béèrè ìbéèrè kan tó gba àròjinlẹ̀ lọ́wọ́ ọkùnrin náà, ó ní: “Lójú tìẹ, èwo nínú àwọn mẹ́ta yìí ló fi hàn pé òun jẹ́ ọmọnìkejì ọkùnrin tó bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà náà?” Ó ṣeé ṣe kó ni ọkùnrin yẹn lára láti sọ pé “ará Samáríà,” ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Ẹni tó ṣàánú rẹ̀ ni.” Jésù wá mú kí ẹ̀kọ́ tó fẹ́ fi ìtàn náà kọ́ ọkùnrin yẹn ṣe kedere, nígbà tó sọ pé: “Ìwọ náà, lọ ṣe ohun kan náà.”—Lúùkù 10:36, 37.
Ẹ ò rí i pé ọ̀nà tí Jésù gbà kọ́ni yẹn lágbára gan-an! Ká ní Jésù kàn dáhùn pé ó yẹ kí wọ́n ka àwọn tí kì í ṣe Júù sí ọmọnìkejì wọn, ṣé ẹ rò pé ọkùnrin yẹn àtàwọn Júù tó wà níbẹ̀ máa gbà pẹ̀lú Jésù? Kò dájú. Àmọ́ torí pé Jésù sọ ìtàn kékeré kan, tó sì tún lo àwọn nǹkan táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa, ìyẹn jẹ́ kí wọ́n rí ìdáhùn sí ìbéèrè náà pé, “Ta ni ọmọnìkejì mi gan-an?” Torí náà, ọmọnìkejì tòótọ́ ni ẹni tó ń fi ìfẹ́ àti àánú hàn sáwọn míì bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ.