ORÍ 76
Farisí Kan Gba Jésù Lálejò
JÉSÙ BÁ ÀWỌN FARISÍ ALÁGÀBÀGEBÈ WÍ
Nígbà tí Jésù wà ní Jùdíà, Farisí kan ní kó wá jẹun nílé òun. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọwọ́ ọ̀sán ni Jésù lọ sílé rẹ̀. (Lúùkù 11:37, 38; fi wé Lúùkù 14:12.) Ó jẹ́ àṣà àwọn Farisí láti kọ́kọ́ fọ ọwọ́ dé ìgúnpá kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í jẹun. Àmọ́ Jésù ò ṣe bẹ́ẹ̀ ní tiẹ̀. (Mátíù 15:1, 2) Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ láti fọwọ́ dé ìgúnpá, bẹ́ẹ̀ sì ni kò pọn dandan kéèyàn ṣe bẹ́ẹ̀.
Ó ya àwọn Farisí náà lẹ́nu gan-an nígbà tí wọ́n rí i pé Jésù ò tẹ̀ lé àṣà yẹn. Jésù rí i pé ó yà wọ́n lẹ́nu, ó wá sọ pé: “Ẹ̀yin Farisí, ẹ̀ ń fọ ẹ̀yìn ife àti abọ́ mọ́, àmọ́ wọ̀bìà àti ìwà burúkú kún inú yín. Ẹ̀yin aláìlóye! Ṣebí ẹni tó ṣe ẹ̀yìn náà ló ṣe inú, àbí òun kọ́?”—Lúùkù 11:39, 40.
Kéèyàn fọwọ́ tàbí kó má fọwọ́ gangan kọ́ nìṣòro wọn, ìṣòro wọn ni pé alágàbàgebè ni wọ́n. Àwọn Farisí àtàwọn míì tí wọ́n máa ń tẹ̀ lé àṣà yìí ń fọ ọwọ́ wọn lóòótọ́, àmọ́ wọn ò fọ ohun burúkú tó wà nínú ọkàn wọn. Torí náà, Jésù gbà wọ́n nímọ̀ràn pé: “Àwọn ohun tó wá láti inú ni kí ẹ máa fi ṣe ìtọrẹ àánú, ẹ wò ó! gbogbo nǹkan nípa yín máa mọ́.” (Lúùkù 11:41) Ká sòótọ́, ìfẹ́ ló yẹ kó sún ẹnì kan láti fúnni lẹ́bùn, kò yẹ kó jẹ́ torí kẹ́ni náà lè ṣe àṣehàn tàbí káwọn míì lè máa kan sáárá sí i.
Jésù ò sọ pé àwọn ọkùnrin yìí kì í fúnni lẹ́bùn. Àmọ́, ó jẹ́ kí ẹ̀kọ́ tó fẹ́ kọ́ wọn ṣe kedere nígbà tó sọ pé: “Ẹ̀ ń san ìdá mẹ́wàá ewéko míńtì, ewéko rúè àti gbogbo ewébẹ̀ míì, àmọ́ ẹ ò ka ìdájọ́ òdodo àti ìfẹ́ Ọlọ́run sí! Àwọn nǹkan yìí ló pọn dandan kí ẹ ṣe, àmọ́ kò yẹ kí ẹ ṣàìka àwọn nǹkan yòókù yẹn sí.” (Lúùkù 11:42) Lóòótọ́, Òfin Ọlọ́run ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa san ìdá mẹ́wàá ohun tí wọ́n bá gbìn. (Diutarónómì 14:22) Lára wọn sì ni ewéko míńtì, ewéko rúè, àtàwọn ewébẹ̀ míì tí wọ́n fi ń se oúnjẹ. Àwọn Farisí fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ ìdá mẹ́wàá lóòótọ́, àmọ́ ṣé wọ́n máa ń pa Òfin náà mọ́ délẹ̀délẹ̀, irú bíi kí wọ́n ṣe ìdájọ́ òdodo, kí wọ́n sì mọ̀wọ̀n ara wọn?—Míkà 6:8.
Jésù wá ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ẹ gbé, ẹ̀yin Farisí, torí ẹ fẹ́ràn ìjókòó iwájú nínú sínágọ́gù, ẹ sì fẹ́ràn kí wọ́n máa kí yín níbi ọjà! Ẹ gbé, torí pé ẹ dà bí àwọn ibojì tí kò ṣeé rí kedere, tí àwọn èèyàn ń rìn lórí rẹ̀ láìmọ̀!” (Lúùkù 11:43, 44) Òótọ́ ni pé tẹ́nì kan bá lọ rìn lórí irú ibojì bẹ́ẹ̀, ẹni náà máa di aláìmọ́. Jésù fi ọ̀rọ̀ yìí tẹnu mọ́ ọn pé aláìmọ́ làwọn Farisí yẹn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò hàn sáwọn èèyàn.—Mátíù 23:27.
Ni ọkùnrin kan tó mọ Òfin Ọlọ́run dunjú bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàròyé pé: “Olùkọ́, bí o ṣe ń sọ àwọn nǹkan yìí, ò ń sọ̀rọ̀ sí àwa náà.” Jésù rí i pé ó yẹ káwọn míì bíi ti ọkùnrin yìí mọ̀ pé àwọn ò ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Torí náà ó sọ pé: “Kódà, ẹ̀yin tí ẹ mọ Òfin dunjú gbé, torí pé ẹ̀ ń di àwọn ẹrù tó ṣòroó gbé ru àwọn èèyàn, àmọ́ ẹ̀yin fúnra yín ò fi ọ̀kan nínú àwọn ìka yín kan àwọn ẹrù náà! Ẹ gbé, torí pé ẹ̀ ń kọ́ ibojì àwọn wòlíì, àmọ́ àwọn baba ńlá yín ló pa wọ́n!”—Lúùkù 11:45-47.
Òfin àtẹnudẹ́nu àti ìtumọ̀ táwọn Farisí fún Òfin Ọlọ́run ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tó sọ pé wọ́n di ẹrù ru àwọn èèyàn. Wọn ò jẹ́ kí nǹkan rọrùn fáwọn èèyàn rárá. Ṣe ni wọ́n fi dandan mú wọn láti máa ṣe ohun tó nira. Àtìgbà ayé Ébẹ́lì làwọn baba ńlá wọn sì ti ń pa àwọn wòlíì Ọlọ́run. Ó lè dà bíi pé wọ́n ń bọ̀wọ̀ fáwọn wòlíì bí wọ́n ṣe ń kọ́ ibojì fún wọn báyìí, àmọ́ ohun táwọn baba ńlá wọn ṣe làwọn náà ń ṣe. Kódà wọ́n ń wá bí wọ́n ṣe máa pa ẹni tó jẹ́ aṣáájú nínú àwọn wòlíì Ọlọ́run. Jésù sọ pé Ọlọ́run máa gbẹ̀san lára ìran náà. Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ nìyẹn lọ́dún méjìdínlógójì (38) lẹ́yìn náà, ìyẹn lọ́dún 70 S.K.
Jésù wá fi kún un pé: “Ẹ gbé, ẹ̀yin tí ẹ mọ Òfin dunjú, torí ẹ mú kọ́kọ́rọ́ ìmọ̀ lọ. Ẹ̀yin fúnra yín ò wọlé, ẹ sì ń dí àwọn tó ń wọlé lọ́wọ́!” (Lúùkù 11:52) Dípò kí wọ́n máa ṣàlàyé Òfin Ọlọ́run, ṣe ni wọ́n mú kó nira fáwọn èèyàn láti mọ Òfin náà tàbí láti lóye rẹ̀.
Báwo lohun tí Jésù sọ ṣe rí lára àwọn Farisí àtàwọn akọ̀wé òfin yẹn? Nígbà tí Jésù fẹ́ máa lọ, ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ta kò ó tí wọ́n sì ń da ìbéèrè bò ó. Kì í ṣe pé wọ́n fẹ́ mọ ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tí wọ́n ń bi í. Ṣe ni wọ́n fẹ́ kó ṣi ọ̀rọ̀ sọ kí wọ́n lè fàṣẹ ọba mú un.