ORÍ 79
Ìdí Táwọn Èèyàn Náà Fi Máa Pa Run
JÉSÙ SỌ̀RỌ̀ NÍPA ÌṢẸ̀LẸ̀ BURÚKÚ MÉJÌ, Ó SÌ FI KỌ́ ÀWỌN ÈÈYÀN LẸ́KỌ̀Ọ́
JÉSÙ WO OBÌNRIN TÍ Ẹ̀YÌN RẸ̀ TẸ̀ SÀN NÍ SÁBÁÀTÌ
Jésù ti gbìyànjú onírúurú ọ̀nà láti mú káwọn èèyàn ronú nípa àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó tún rí àǹfààní míì láti ṣàlàyé ìdí tíyẹn fi ṣe pàtàkì lẹ́yìn tó wàásù fáwọn kan bó ṣe ń jáde nílé Farisí kan.
Àwọn kan lára àwọn èèyàn náà mẹ́nu ba ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan tó wáyé. Wọ́n sọ̀rọ̀ nípa “àwọn ará Gálílì tí [Gómìnà Róòmù, Pọ́ńtíù] Pílátù po ẹ̀jẹ̀ wọn mọ́ àwọn ẹbọ wọn.” (Lúùkù 13:1) Kí lèrò àwọn èèyàn yìí nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn?
Ìgbà kan wà tí Pílátù mú owó látinú àpótí ọrẹ inú tẹ́ńpìlì kó lè fi ṣètò bó ṣe máa fa omi wá sí Jerúsálẹ́mù. Ó ní láti jẹ́ pé àwọn aláṣẹ tẹ́ńpìlì ló fọwọ́ sí i pé kí Pílátù lọ mú owó náà. Àmọ́ nígbà táwọn èèyàn gbọ́ ohun tó ṣe yìí, inú bí wọn, ọ̀pọ̀ lára wọn sì fẹ̀hónú hàn. Ọ̀rọ̀ àwọn ará Gálílì tó ṣeé ṣe kó kú nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn làwọn èèyàn yìí ń sọ fún Jésù. Wọ́n lè máa dọ́gbọ́n sọ fún Jésù pé ẹ̀san ló ké lórí wọn tí wọ́n fi pa wọ́n nípa ìkà. Àmọ́ Jésù ò gbà pẹ̀lú wọn.
Ó wá bi wọ́n pé: “Ṣé ẹ rò pé torí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Gálílì yẹn pọ̀ ju ti gbogbo àwọn ará Gálílì yòókù lọ ni àwọn nǹkan yìí ṣe ṣẹlẹ̀ sí wọn ni?” Ó sọ pé rárá, ó wá kìlọ̀ fáwọn Júù náà pé: “Àfi tí ẹ bá ronú pìwà dà, bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo yín ṣe máa pa run.” (Lúùkù 13:2, 3) Jésù tún mẹ́nu ba ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú míì tó ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ sígbà yẹn, tó ṣeé ṣe kó wáyé nígbà tí Pílátù ń ṣe iṣé omi náà, Jesu béèrè pé:
“Àwọn méjìdínlógún (18) tí ilé gogoro tó wà ní Sílóámù wó lù, tó sì pa wọ́n, ṣé ẹ rò pé ẹ̀bi wọn pọ̀ ju ti gbogbo èèyàn yòókù tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù ni?” (Lúùkù 13:4) Ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn yẹn máa ronú pé àwọn tó kú yẹn ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni. Jésù tún jẹ́ kí wọ́n rí i pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Ó mọ̀ pé “ìgbà àti èèṣì” máa ń ṣẹlẹ̀, ohun tó sì ṣeé ṣe kó fa irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí nìyẹn. (Oníwàásù 9:11) Torí náà, ó yẹ káwọn èèyàn náà kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun to ṣẹlẹ̀ yẹn. Jésù wá sọ pé: “Àfi tí ẹ bá ronú pìwà dà, gbogbo yín máa pa run, bí wọ́n ṣe pa run.” (Lúùkù 13:5) Kí nìdí tí Jésù fi tẹnu mọ́ kókó yìí?
Ìdí ni pé ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, torí náà ó fi àpèjúwe ṣàlàyé ohun tó ní lọ́kàn, ó ní: “Ọkùnrin kan gbin igi ọ̀pọ̀tọ́ sínú ọgbà àjàrà rẹ̀, ó sì wá síbẹ̀, ó ń wá èso lórí rẹ̀, àmọ́ kò rí ìkankan. Ó wá sọ fún ẹni tó ń rẹ́wọ́ àjàrà pé, ‘Ó ti pé ọdún mẹ́ta báyìí tí mo ti ń wá síbí, tí mò ń wá èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí, àmọ́ mi ò rí ìkankan. Gé e lulẹ̀! Ṣe ló kàn ń fi ilẹ̀ ṣòfò lásán.’ Ó dá a lóhùn pé, ‘Ọ̀gá, jẹ́ kó lo ọdún kan sí i, títí màá fi gbẹ́lẹ̀ yí i ká, tí màá sì fi ajílẹ̀ sí i. Tó bá so èso lọ́jọ́ iwájú, ìyẹn dáa; àmọ́ tí kò bá so, o lè wá gé e lulẹ̀.’”—Lúùkù 13:6-9.
Ó ti lé ní ọdún mẹ́ta báyìí tí Jésù ti wà lẹ́nu bó ṣe máa ran àwọn Júù lọ́wọ́ kí wọ́n lè gbà pé òun ni Mèsáyà. Àmọ́ pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ tó ṣe, kò rí èso tó pọ̀ torí pé ìwọ̀nba èèyàn ló di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ní báyìí tó ti pé ọdún kẹrin, ó túbọ̀ ń fi gbogbo ara ṣe iṣẹ́ náà. Ṣe ni iṣẹ́ ìwàásù tó ṣe ní Jùdíà àti Pèríà dà bí ìgbà tí aroko kan gbẹ́lẹ̀ yí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan ká, tó sì fi ajílẹ̀ sí i. Kí ló wá gbẹ̀yìn gbogbo ohun tó ṣe náà? Ìwọ̀nba àwọn Júù ló tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ ẹ̀. Gbogbo orílẹ̀-èdè yẹn lápapọ̀ ni ò sì ronú pìwà dà, torí náà ìparun ló máa gbẹ̀yìn wọn.
Ohun kan ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ Sábáàtì kan lẹ́yìn ìyẹn tó jẹ́ kó túbọ̀ ṣe kedere pé àwọn èèyàn yẹn ò tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ Jésù. Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn nínú sínágọ́gù. Ó rí obìnrin kan tí ẹ̀mí èṣù ń dà láàmú, ìyẹn sì ti mú kí ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀ gan-an fún odindi ọdún méjìdínlógún (18). Àánú obìnrin náà ṣe Jésù, ó wá sọ fún un pé: “Obìnrin, a tú ọ sílẹ̀ kúrò nínú àìlera rẹ.” (Lúùkù 13:12) Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí Jésù gbé ọwọ́ lé obìnrin yẹn ló nà ró ṣánṣán, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í yin Ọlọ́run lógo.
Ohun tí Jésù ṣe yẹn bí alága sínágọ́gù náà nínú, ló bá sọ pé: “Ọjọ́ mẹ́fà ló yẹ ká fi máa ṣiṣẹ́; torí náà, àwọn ọjọ́ yẹn ni kí ẹ wá gba ìwòsàn, kì í ṣe lọ́jọ́ Sábáàtì.” (Lúùkù 13:14) Kì í ṣe pé ọkùnrin yìí ń sọ pé Jésù ò lágbára láti mú àwọn aláìsàn lára dá, àmọ́ ṣe ló ń dá àwọn èèyàn náà lẹ́bi pé kò yẹ kí wọ́n wá sọ́dọ̀ Jésù lọ́jọ́ Sábáàtì kó lè wò wọ́n sàn. Jésù wá sọ ohun kan tó gba àròjinlẹ̀, ó ní: “Ẹ̀yin alágàbàgebè, ṣebí ní Sábáàtì, ọ̀kọ̀ọ̀kan yín máa ń tú akọ màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ kúrò níbi tó so ó mọ́, tí á sì mú un lọ kó lè fún un ní ohun tó máa mu? Ṣé kò yẹ kí obìnrin yìí, ẹni tó jẹ́ ọmọ Ábúráhámù, tí Sátánì sì ti dè fún ọdún méjìdínlógún (18), rí ìtúsílẹ̀ kúrò nínú ìdè yìí ní ọjọ́ Sábáàtì?”—Lúùkù 13:15, 16.
Èyí mú kí ojú ti àwọn alátakò náà, àmọ́ ṣe ni inú àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ ń dùn tí wọ́n sì ń yin Ọlọ́run lógo nígbà tí wọ́n rí ohun tí Jésù ṣe. Jésù wá fi àpèjúwe méjì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ìjọba ọ̀run, ìyẹn àwọn àpèjúwe tó ti sọ ṣáájú nígbà tó ń kọ́ àwọn èèyàn látinú ọkọ̀ ojú omi létí Òkun Gálílì.—Mátíù 13:31-33; Lúùkù 13:18-21.