ORÍ 85
Àwọn Áńgẹ́lì Máa ń yọ̀ Tí Ẹlẹ́ṣẹ̀ Bá Ronú Pìwà Dà
ÀPÈJÚWE ÀGÙNTÀN ÀTI ẸYỌ OWÓ TÓ SỌ NÙ
ÀWỌN ÁŃGẸ́LÌ Ń YỌ̀ LỌ́RUN
Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù tẹnu mọ́ ìdí tó fi ṣe pàtàkì kéèyàn lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. (Lúùkù 14:8-11) Ó wù ú gan-an láti rí àwọn èèyàn lọ́kùnrin lóbìnrin tí wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tí wọ́n sì ń wá bí wọ́n á ṣe sin Ọlọ́run. Àmọ́ títí di báyìí, ọ̀pọ̀ lára wọn ló ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ paraku.
Àwọn Farisí àtàwọn akọ̀wé òfin náà kíyè sí i pé irú àwọn èèyàn yìí, ìyẹn àwọn táwọn kà sẹ́ni tí ò já mọ́ nǹkan kan ló ń tẹ̀ lé Jésù, tí wọ́n sì ń gbọ́rọ̀ rẹ̀. Wọ́n wá ń ṣàròyé pé: “Ọkùnrin yìí ń tẹ́wọ́ gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ó sì ń bá wọn jẹun.” (Lúùkù 15:2) Àwọn Farisí àtàwọn akọ̀wé òfin máa ń wo ara wọn bíi pé àwọn sàn ju àwọn tó kù lọ, wọ́n sì máa ń wo àwọn míì bí ìdọ̀tí abẹ́ ẹsẹ̀ wọn. Kí wọ́n lè fi hàn pé àwọn èèyàn tó kù ò já mọ́ nǹkan kan, wọ́n máa ń fi gbólóhùn èdè Hébérù kan pè wọ́n, ìyẹn ‛am ha·’aʹrets, tó túmọ̀ sí “àwọn ẹni ilẹ̀.”
Àmọ́ ìwà Jésù yàtọ̀, ó máa ń bọ̀wọ̀ fún gbogbo èèyàn, ó máa ń ṣoore fáwọn míì, ó sì máa ń fàánú hàn sí wọn. Èyí ló mú kí ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹni rírẹlẹ̀ yìí, títí kan àwọn tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí ẹlẹ́ṣẹ̀ máa wá bí wọ́n á ṣe gbọ́rọ̀ Jésù. Àmọ́, báwo ló ṣe rí lára Jésù nígbà táwọn èèyàn ń ta kò ó torí pé ó ń ran àwọn ẹni rírẹlẹ̀ lọ́wọ́, kí ló sì ṣe?
Àpèjúwe tó ṣe lẹ́yìn náà jọ èyí tó ṣe nígbà tó wà ní Kápánáúmù, ó wọni lọ́kàn gan-an, ó sì jẹ́ ká mọ bọ́rọ̀ yẹn ṣe rí lára ẹ̀. (Mátíù 18:12-14) Nínú àpèjúwe náà, Jésù sọ̀rọ̀ bíi pé olóòótọ́ làwọn Farisí, bíi pé inú agbo rẹ̀ ni wọ́n wà. Ó wá fi àwọn ẹni rírẹlẹ̀ wé àwọn tó ti ṣáko lọ, tí wọ́n sì sọ nù. Jésù sọ pé:
“Ọkùnrin wo nínú yín, tó ní ọgọ́rùn-ún (100) àgùntàn, ló jẹ́ pé tí ọ̀kan nínú wọn bá sọ nù, kò ní fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) yòókù sílẹ̀ nínú aginjù, kó sì wá èyí tó sọ nù lọ títí ó fi máa rí i? Tó bá sì rí i, ó máa gbé e lé èjìká rẹ̀, inú rẹ̀ sì máa dùn. Tó bá wá dé ilé, á pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, á sì sọ fún wọn pé, ‘Ẹ bá mi yọ̀, torí mo ti rí àgùntàn mi tó sọ nù.’”—Lúùkù 15:4-6.
Kí ni Jésù fẹ́ káwọn èèyàn yẹn mọ̀ nínú àpèjúwe yìí? Ó ṣàlàyé pé: “Mò ń sọ fún yín pé, lọ́nà kan náà, inú àwọn tó wà ní ọ̀run máa dùn gan-an torí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó ronú pìwà dà ju olódodo mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) tí kò nílò ìrònúpìwàdà.”—Lúùkù 15:7.
Ó dájú pé bí Jésù ṣe mẹ́nu kan ìrònúpìwàdà máa gún àwọn Farisí yẹn lọ́kàn. Wọ́n máa ń wo ara wọn bí olódodo tí kò nílò láti ronú pìwà dà. Nígbà táwọn kan lára wọn ń rí sí Jésù pé ó ń jẹun nílé agbowó orí kan ní ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn, ó sọ fún wọn pé: “Kì í ṣe àwọn olódodo ni mo wá pè, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.” (Máàkù 2:15-17) Àwọn olódodo àṣelékè yẹn ò rí ìdí tó fi yẹ kí wọ́n ronú pìwà dà, torí náà kò sẹ́ni tó máa yọ̀ ní ọ̀run torí wọn. Ìyẹn sì jẹ́ òdìkejì ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá ronú pìwà dà látọkàn wá.
Kí Jésù lè jẹ́ káwọn èèyàn náà rí bí ọ̀rọ̀ ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà ṣe máa ń rí lára àwọn tó wà lọ́run, ó tún sọ àpèjúwe kan nípa ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ nínú ilé. Ó sọ pé: “Obìnrin wo, tó ní ẹyọ owó dírákímà mẹ́wàá, ló jẹ́ pé tí dírákímà kan bá sọ nù, kò ní tan fìtílà, kó gbá ilé rẹ̀, kó sì fara balẹ̀ wá a títí ó fi máa rí i? Tó bá sì rí i, á pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, á sọ pé, ‘Ẹ bá mi yọ̀, torí mo ti rí ẹyọ owó dírákímà tí mo sọ nù.’”—Lúùkù 15:8, 9.
Àlàyé tí Jésù ṣe lórí àpèjúwe yìí jọra pẹ̀lú àlàyé tó ṣe nípa àgùntàn tó sọ nù. Ó sọ pé: “Mò ń sọ fún yín pé, lọ́nà kan náà, àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run máa ń yọ̀ torí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó ronú pìwà dà.”—Lúùkù 15:10.
Ó mà jọni lójú o, pé ọ̀rọ̀ ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà máa ń múnú àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run dùn! Ọ̀rọ̀ náà jọni lójú torí pé tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá ronú pìwà dà, tó sì ní àǹfààní láti wà nínú Ìjọba ọ̀run, ipò tó máa wà máa ju ti àwọn áńgẹ́lì lọ! (1 Kọ́ríńtì 6:2, 3) Síbẹ̀ àwọn áńgẹ́lì yẹn ò ní bẹ̀rẹ̀ sí í jowú. Báwo ló ṣe yẹ kọ́rọ̀ ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà rí lára àwa náà?